Facebook ChecksFact CheckHealthYoruba

Ǹjẹ́ ẹ ti rí fọ́nrán akálékáko tó ṣ’àfihàn ibi tí wọ́n ti n kun èso ápù l’ọda? Aṣinílọ́nà ni

Ahesọ: Fọ́nrán akálékáko kan lórí ìkànnì ibaraẹnisọrẹ Facebook ṣ’àfihàn ibi ti wọn ti n fi kẹ́míkà apanilara kun èso ápù l’ọda láti àwọ̀ ewéko sí àwọ̀ pupa.

Ǹjẹ́ ẹ ti rí fọ́nrán akálékáko tó ṣ'àfihàn ibi tí wọ́n ti n kun èso ápù l'ọda? Aṣinílọ́nà ni

Àbájáde ìwádìí: Irọ́ ni. Àwọn nkán tí wọ́n fi ọ̀dà kún ni inú fónrán náà kìí ṣe èso ápù. Agolo adùn ṣokoléètì lásán ni.

Ìròyìn lẹkunrẹrẹ 

Láìpẹ́ yìí, fọ́nrán kan gbalẹ̀ lórí ẹrọ alatagba pẹlu àròsọ pe wọ́n fi kẹ́míkà kun èso ápù ti wọ́n gbé wọlé si orílè-èdè Nàìjíríà. Awọn olumulo ìkànnì ibaraẹnisọrẹ ṣ’atunpin fọ́nrán náà l’asiko ti àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà n ṣe ifiyesi ailewu oúnjẹ tí wọ́n jẹ.

Okunrin kan ṣàlàyé oun to sẹlẹ nínú fónrán akalekako náà. Okunrin náà so wipe wọn kun eso ápù náà pèlú kemika apanilara lati àwọ̀ ewéko sí àwọ̀ pupa, èyí sì lè ṣe ijamba fún ìlera ara ọmọ ènìyàn. 

Ọkùnrin náà sọ wípé “Ni ilẹ ayé yìí, Ọlọ́run nìkan ló mọ ohun ti o n ṣẹlẹ. Oríṣiríṣi ǹkán ló ń ṣẹlẹ̀. Ẹwo fónrán yìí kí e rí oun tí wọ́n ń ṣe sí ounje tí a ń jẹ. Ṣé ẹ rí bí wọ́n tí ń fi kẹ́míkà pa èso ápù láró. Tí wọ́n ba fi kemika burúkú kun tán, wọ́n a tàá fún àwọn ènìyàn. Ẹ o jẹ èso náà, eya ara yìí o ni ṣiṣe boṣeyẹ.

“Olorun nìkan ló lè ràn wá lọ́wọ́ ni ilẹ ayé yìí nítorí àwọn oun tó n ṣẹlẹ̀ bayii, ọlọrun nikan lo le f’opin sí, ọlọrun nikan lo le ran àwọn ọmọ rẹ lọwọ. Ti o ba ni iyemeji ninu ọlọrun, asiko ti to fún ọ lati gbagbọ.”

Lára àwọn olumulo tí wọ́n wo fónrán náà, àwọn ẹlòmíràn gbàgbọ́, àwọn ẹlòmíràn ò gbàgbọ́. Olumulo ìkànnì ibaraẹnisọrẹ kan, Adj Hamina Haja sọ wípé, “Nitori èyí ni mi ò ṣe kín jẹ èso ápù pupa.” Àwọn olumulo kan gbaniyanju pé tí a bá ra èso ápù, kí a fi ọ̀bẹ bó àwọ̀ ara ápù náà dànù, kí wọ́n jẹ oun tó bá kù, kí wọ́n ma baa gbé kẹ́míkà burúkú mì.

Èso ápù jẹ ọ̀kan lára àwọn èso ti awọn dókítà máa n gbani lamọ̀ràn láti jẹ fún ìlera ara. 

Ilé-isé ìròyìn Medical News Today ṣàlàyé pé éso ápù pé oríṣiríṣi, àwọn ẹ̀yà ápù tó dárúkọ ni: 

McIntosh: èyí jẹ́ èso ápù pupa tí àwọ̀ ara rẹ rọ̀, ṣugbọn o kan lẹnu.

Red delicious: ẹ̀yà èso ápù yìí dùn l’ẹ́nu, kódà ó ní omi lara. 

Fuji: Ẹ̀yà ápù yìí ni àwọ̀ ìyèyè ati àwọ̀ pupa, o sì dùn lẹnu.

Granny Smith: ẹ̀yà ápù tí ó ní àwọ̀ eweko, àwọ̀ rẹ̀ sì jẹ́ agaran.

Golden Delicious: ẹ̀yà ápù yìí ní àwọ̀ ìyèyè, kò sì dùn púpọ̀.

Ìwé ìròyìn WebMD ṣàlàyé pe ọpọlọpọ ànfàní ni ó wà lára èso ápù alawọ ewé: ó máa n ṣe ìrànlọ́wọ́ fún ìlera ẹyà eda ara ounjẹ, ìlera ọkàn, kódà o máa n ṣe idinku àìsàn àtọgbẹ ati bẹẹbẹẹlọ. Lakotan, èso ápù máa n ṣe idinku ewu àìsán jẹjẹrẹ.

Ǹjẹ́ ẹ ti rí fọ́nrán akálékáko tó ṣ'àfihàn ibi tí wọ́n ti n kun èso ápù l'ọda? Aṣinílọ́nà ni
Oun tí àwọn ènìyàn sọ nípa fọ́nrán náà 

Ifidiododomule

Itọpinpin àwòrán lori ayélujára fihàn pé wọ́n ti ṣ’atunpin fọ́nrán náà sí orí ẹ̀rọ alatagba ni oṣù kinni odun 2022. 

Ní ìgbà tí a wo fónrán náà fínífíní, a ríi wípé, àwọn oṣiṣẹ ilé-iṣé náà fi ika ọwọ won sì inu ‘eso ápù’ náà kí wọn lè gbàa mu dáadáa. Eyi jẹ àpẹrẹ àkọ́kọ́ pe oun ti won dimu náà kọ farajọ èso ápù ni, kìí ṣe ojúlówó, gẹgẹbi ati mọ̀ pé kò ṣeéṣe ki a ti ìka bọ èso ápù tí a kò gé.

Bákan náà, DUBAWA lo ẹ̀rọ INVID láti ṣe idanimọ orísun fónrán náà kí a le mọ̀ bóyá ojúlówó ni tabi ebu. Ìwádìí wà fihàn pé olumulo ìkànnì ibaraẹnisọrẹ TikTok, Me Lavie @cacao_ing fi fónrán náà sí ojú òpó rẹ̀ ni ọjọ kẹta oṣu kejìlá ọdún 2021. Kódà, olumulo náà kọ ‘eku odun keresimesi’ sí orí fónrán náà. Fónrán ori TikTok yìí tún gùn jù èyí tí a rí lori ẹrọ Facebook. 

A ri àwòrán ‘èso ápù’ náà ti wọ́n tó sì inú àpótí ẹbùn ti wọn n lò fún kérésìmesì lati fihan pe ẹbùn fún asiko naa ni. Leyin eyi, kò sí àlàyé míràn nípa bí wọ́n ṣe ń lo àpótí ẹbùn náà fún ìdánilójú pé bóyá èso ápù ni tàbí bẹ́ẹ̀kọ́.

Ní ìgbà tí a wo oun tí àwọn ènìyàn sọ nípa fọ́nrán náà, a ríi wípé ọpọlọpọ ènìyàn lo ni ìbéèrè lórí fónrán náà, botilejepe ede àwọn ará Vietnam ni wọ́n fi kọ, sugbon a lo èro Google Translate lati se ìtúmọ̀ awọn ọrọ náà sí èdè gẹ̀ẹ́sì.

Olumulo ojú òpó TikTok @cacao_ing yìí ṣe àtúnpín fónrán míràn láti fi se idahun ìbéèrè kan. Fónrán kejì yìí se àfihàn àwọn ìgbésẹ̀ ti onitọun gbé lati ṣẹda òun tó farajọ èso ápù yìí. Kódà, fónrán kejì yìí ṣàfihàn bi wọn se kùún l’ọda sí awọ pupa ki ó lè f’ojú jọ èso ápù.

Ààyè ti wọn fi sílẹ̀ ni isale ‘àpú’ náà jẹ ọ̀nà tí wọ́n gbà fi suwiti rogodo/ṣokoléètì síi. Lẹyìn èyí, won a jọ isalẹ rẹ pa. Eni tí wọn ta lọọrẹ náà a fi ọ̀pá kan fọ oun tó farajọ àpù náà láti kó suwiti rogodo/ṣokoléètì inu rẹ̀ kúrò.

Ǹjẹ́ ẹ ti rí fọ́nrán akálékáko tó ṣ'àfihàn ibi tí wọ́n ti n kun èso ápù l'ọda? Aṣinílọ́nà ni

Àwòrán agolo ṣokoléètì tí wọ́n ti fọ́

DUBAWA tún lo èrọ ayélujára ti o máa ń ṣe akojọpọ ìròyìn ifidiododomule, iyen Google Fact-check explorer a sì ri iroyin kan ti won gbé jade ní ọdún 2022 lori Factly. Ìròyìn náà ṣe itọpinpin fónrán náà sí ọdọ olumulo ìkànnì TikTok @cacao_ing, kódà o fi múlẹ pe lóòtó ni oun tó farajọ ápù yìí jẹ ẹbùn tí awọn ara Chinese máa n fun ara won lasiko keresimesi tabi ayajọ awọn ololufẹ. Kódà wọ́n tà àpótí ẹbùn náà lórí ẹ̀rọ alatagba bi a se ríi ni ibí ati ibí.

Àkótán 

Iro àti aṣinilọna ni ahesọ pé wọn kún èso ápù l’ọda ni òkè òkun, wọ́n sì gbé wọ Nàìjíríà. Fónrán náà ṣàfihàn ibi tí wọn ti n ṣe ìpèsè awọn ohun tó farajọ ápù ṣugbọn agolo suwiti/ṣokoléètì lásán nii, èyí tí wọ́n lò gẹgẹbi ẹbùn ní àsìkò kérésìmesì tàbí ayajọ ololufẹ ní ìlú China. 

Show More

Related Articles

Leave a Reply

Back to top button