Facebook ChecksFact CheckHealthYoruba

Àwọn onímọ̀ sọ wípé kò dára kí obìnrin joko s’orí omi gbígbóná 

Getting your Trinity Audio player ready...

Aheso: Olumulo ìkànnì ibaraẹnisọrẹ Facebook ṣàlàyé pé kí ènìyàn joko sí ori omi efinrin àti iyọ̀ le ṣe itọju oyún ìju, òórùn ojú ara àti ìrora nkan oṣù.

Àwọn onímọ̀ sọ wípé kò dára kí obìnrin joko s’orí omi gbígbóná 

Abajade iwadii: Irọ ni! Kó sí ẹrí to daju ninu imo sáyẹ́nsì pe àwọn nkan wọnyi le ṣe itọju. Koda, awọn onimọ nipa ètò-ara obìnrin kó ṣe atilẹyin fún jíjó abẹ́ obìnrin tàbí kí obìnrin joko sí orí omi gbígbóná.

Ìròyìn lẹkunrẹrẹ 

Ìrora ǹkan oṣù máa n mu inira dani, o si máa n saba mu obìnrin ni isalẹ ikùn, ṣáájú nkan oṣù. Ìrora ǹkan oṣù lè wáyé fẹẹrẹfẹ, o sí lè mu ọpọlọpọ ìnira dani. Ni ọpọlọpọ ìgbà, àwọn obìnrin máa n wa ọna láti mú idinku bá ìnira naa. 

Muhammad lori ikanni Facebook, gbà àwọn obìnrin nimọran kí wọn joko sori omi gbígbóná, kí wọn sì fi ewé efinrin àti iyọ̀ lati mú ki ìju sunki, ṣe itọju àìsàn ilé igbọnsẹ, sisanra lasan ju, ati ìrora nkan oṣù. Ó ṣàlàyé pé kí wọn ṣẹ nkan yìí leyin nkan oṣù. O f’ikun wípé kí wọn joko sórí omi gbígbóná yìí kí o le ṣiṣẹ daadaa.

Ọpọlọpọ ènìyàn ló ka atejade náà, wọn sì satunpin rẹ̀. Nítorí pataki ọrọ naa sí ọrọ ìlera ni àwùjọ, DUBAWA ṣe ìwádìí.  

Ifidiododomule

Jijoko sí ori omi gbígbóná 

Ojú abẹ́ obìnrin wà nínú ara, o sì wà lára àwọn ẹ̀yà ara ti a fi nṣẹda ọmọ. Àwọn ènìyàn kan ṣàlàyé pé kí obìnrin joko sí ori omi gbígbóná le ṣe awẹmọ ojú abẹ àti ilè ọmọ, ó sì lè mú ìnira ǹkan oṣù kúrò. Sùgbón, ojú abẹ́ obìnrin máa n fọ ara rẹ mọ. Àwọn ohùn ti obìnrin máa n ṣe bíi kí a joko sórí omi gbígbóná tabi ki wón fọ inú ojú ara wọn, àwọn nkan wọnyi ò ṣe pàtàkì.

Ó ṣe pàtàkì ki obìnrin ṣe imọtoto ojú abẹ, kí wọn sì yàgò fún àwon ọsẹ òní tùràrí. Ki awọn obìnrin yàgò fún jijoko sori omi gbígbóná. 

Jijoko sí orí omi gbígbóná lè ṣe ijamba fun ojú abẹ, èyí sí le jẹ kí àwọn alamọ ti o máa n fa àkóràn pọ sí laagọ ara.

Ojú abẹ obìnrin jẹ ẹlẹgẹ́, o sí le tete kó àkóràn. Ti obìnrin bá joko sí ori omi gbígbóná, o le fa egbo tàbí ọgbẹ́ sí ojú ara. Èyí ò tumọ síi pé àwọn ewé tàbí egbò kọọkan ò lè ṣe iranlọwọ fún ojú ara, sùgbón kò sí ẹrí tó dájú nínu ìmọ sáyẹ́nsì pe jijoko sí orí omi gbígbóná le ṣe iranwọ kankan fún ojú abẹ.

Kini awọn onimọ sọ?

Gwyneth Paltrow, onímọ̀ nípa ètò-ara obìnrin ṣàlàyé pé ó ṣe pàtàkì kí a rí ojú abẹ́ obìnrin gẹgẹbi oun tó lè fọ ara rẹ̀ mọ́. Èyà ara to nṣẹda máa n ṣe ìdáàbòbò ara rẹ̀.

Ó tùnbọ̀ ṣàlàyé pé o ṣeéṣe kí eruku omi gbígbóná pẹlú efinrin ṣe ijamba fún ojú abẹ́. Onímọ̀ náà sọ wípé ọna ti eniyan lè gbà latí ṣe itọju ojú abẹ́ ni kí obìnrin da’mira lásìkò ìbálòpọ̀. 

Dokita Ṣeṣan Oluwasola, onimọ nipa ètò-ara obinrin ní ilé ìwòsan yunifásítì ni ìlà oòrùn orilẹ-ede Nàìjíríà sọ fún ilé iṣẹ́ AFP Fact Check pé oun kò faramọ́ kí obìnrin joko sí ori omi gbígbóná. Ọgbẹni Oluwasola sọ wípé ṣiṣe èyí le mu ki ojú abẹ bajẹ, o sí le fa egbo tabi ijamba fún ojú ara. Leyin ti egbo yi bá ṣi jina, o le mu ki ojú ara kere síi. 

Talia Crawford, onimọ nipa ètò-ara obinrin àti ọmọ bíbí náà sọ wípé kí àwọn eniyan yàgò fún jijoko sí orí omi gbígbóná nítorí èyí lè mú ijamba lọ́wọ́. Awọ ojú abẹ́ jẹ ẹlẹgẹ́, o sí le tete ni ogbe latarii eruku inú omi gbígbóná ọ̀ún. O túnbọ̀ ṣàlàyé pé jijoko s’ori omi gbígbóná lè fa ààrùn àti àkóràn. 

“Kí ojú abẹ́ obìnrin lè wà ní àlàáfíà, ó gbọdọ ni alamọ to dára àti èyí ti kó dára. Nítorí èyí, kò dára kí ènìyàn fọ ojú ara pẹlu ọsẹ tabi àwọn nkan to ni tùràrí nínú. Omi nikan ni kí ẹ lò,” dókítà Crawford ló sọ èyí.

Ó túnbọ̀ gba ìmọ̀ràn pé àwọn obìnrin tó ní ìnira lójú abẹ́, òórùn àti bẹẹbẹẹlọ ni láti bá dọ́kítà sọrọ ki won le ri ìtọ́jú. 

Àkótán

Àwọn onímọ̀ ò f’ọwọsi kí obìnrin máa joko sí orí omi gbígbóná nítorí ó maa ń ṣe ijamba fún àgọ ara. Kàkà kí obìnrin joko sí ori omi gbígbóná, awọn onimọ gbà imọran pé kí wọn fi omi lasan fọ ojú ara, kí wọn sì ṣe àbẹ̀wò si dokita wọn ti wọn bá ni àrùn tàbí àìsàn kankan. 

Show More

Related Articles

Leave a Reply

Back to top button
Translate »