Getting your Trinity Audio player ready...
|
AHESỌ: Ọgbẹni Peter Òbí lọ ṣe àbẹ̀wò sí ààrẹ Bọla Tinubu ní ilé ìjọba Nàìjíríà, Aso Rock, ti ìlú Abuja.
ÀBÁJÁDE ÌWÁDÌÍ: Irọ́ ni. Ayédèrú ní àwòrán tí wọ́n ṣ’atunpin yìí. Kódà, a ṣ’abapade ojúlówó àwòrán náà. Bakan náà, kò sí atẹjade tàbí ìròyìn kankan tó jẹrisi ìpàdé àwọn olóṣèlú méjèèjì.
Ìròyìn Lẹkunrẹrẹ
Ojú òpó kan lórí ìkànnì ibaraẹnisọrẹ Facebook, The Pickers NG fi ìròyìn kan síta pé oludije ẹgbẹ òṣèlú Labour Party, ọgbẹni Peter Òbí, lọ ṣ’abẹwo sí ilé ìjọba Nàìjíríà ni ìlú Abuja, láti lọ pàdé ààrẹ orilẹ-ede Nàìjíríà tuntun, Bọla Tinubu.
“Obi lọ ṣ’abẹwo, Tinubu gba àlejò. Ẹwá wo Obi ní ilé ìjọba Nàìjíríà, Aso Rock,” díẹ̀ lára atẹjade náà ló sọ èyí.
Wọ́n fi àwòrán kan, tó ṣàfihàn ọgbẹni Òbí ati ààrẹ Tinubu tí wọ́n ń bọwọ́, ní inú yàrá kan tó farajọ òkan nínú àwon yàrá ilé ìjọba Nàìjíríà.
Èyí wáyé láàrín gbogbo awuyewuye ìbò tó gbé ọgbẹni Tinubu sí ipò ààrẹ, kódà ìròyìn náà tànká ní àsìkò ti ilé-ẹjọ́ kotemilọrun j’oko ni Abuja.
Ni ọjọ kọọkanlelọgbọn oṣù kẹjọ ọdún yìí, a sakiyesi wípé ọpọlọpọ ènìyàn lo bú ọwọ ìfẹ lu atẹjade náà, àwọn ènìyàn sì sọrọ nípa rẹ̀.
Olumulo kan tí orukọ rẹ̀ ń jẹ́, Neduigweh Chinedu sọ wípé, “Eyi o bójú mu, ìwà ọmọde ati ìwà agọ ni èyí.”
“Ṣé ki wọn máa bá ara wọn yan odì ni? Nítorí wọn kò sí ni ègbé òsèlú kanna, iyen o túmọ sí wípé ki wọn ma ba ara wọn jà,” Magnus Obidike ló sọ èyí.
Nítorí àríyànjiyàn lori ọrọ náà àti oun tí àwọn ènìyàn ń sọ lórí ẹrọ alatagba, DUBAWA pinnu láti ṣe ìwádìí lórí ọrọ náà.
Ifidiododomule
Ọpọlọpọ ìgbà ni a ti ṣ’àkíyèsí bí àwọn ènìyàn ṣe pín ayédèrú àwòrán pàápàá àwòrán àwọn gbajumọ ènìyàn láwùjọ, nítorí náà, a ṣe itọpinpin àwòrán latẹyin wa, lórí àwòrán akalekako náà.
Ìwádìí wà fihàn pé wọn ya àwòrán náà nigba ti oniṣòwo àgbà, Aliko Dangote lọ ṣ’abẹwo sí ààrẹ Tinubu.
Olumulo ìkànnì abẹ́yẹfò kan, Daddy D.O (@DOlusegun) ṣ’atunpin àwòrán náà ni ojú òpó rè.
Kódà, a ríi wípé aami idanimọ kan wà lórí àwòrán ayédèrú náà, èyí jẹ apeere pàtàkì ti àwọn oluyaworan máa n lò láti fi polongo iṣé wọn.
A tún sakiyesi wípé kò sí èèyàn kéta nínú ojúlówó àwòrán tí ó wà lórí ayélujára. Èyí jẹ k’a mòye oun tó faa tí ó fi dàbí pé onítọ̀hún ń wo ibòmíràn, nínú àwòrán akalekako. Ní ṣe ni wọn gbe wọ inú àwòrán náà.
Lakotan, a ṣ’ewadii lórí ayélujára bóyá a lè rí ìròyìn kankan tó jẹrisi ìpàdé ọgbẹni Òbí ati Tinubu ní ilé ìjọba Nàìjíríà ṣùgbón kò sí oun tó jọ bẹẹ.
Àkótán
Ayédèrú àwòrán ní àwòrán akalekako to ṣ’àfihàn ọgbẹni Tinubu àti Obi. Bakan náà, kò sí ojúlówó ìròyìn kankan tabi atẹjade lórí ìpàde laarin àwọn méjèèjì. Nítorí èyí, irọ́ ni ọrọ náà.