{"id":22839,"date":"2025-05-23T09:01:35","date_gmt":"2025-05-23T08:01:35","guid":{"rendered":"http:\/\/dubawa.org\/dir\/?p=22839"},"modified":"2025-05-23T09:01:38","modified_gmt":"2025-05-23T08:01:38","slug":"ilana-ajo-who-nipa-iwonba-iyo-ti-a-nilo-lago-ara","status":"publish","type":"post","link":"https:\/\/dubawa.org\/dir\/ilana-ajo-who-nipa-iwonba-iyo-ti-a-nilo-lago-ara\/","title":{"rendered":"\u00ccl\u00e0n\u00e0 \u00e0j\u1ecd WHO nipa iw\u1ecdnba iy\u1ecd\u0300 ti a nilo l\u2019ago ara"},"content":{"rendered":"\n<p class=\"wp-block-paragraph\">\u00c0l\u00f9f\u00e1\u00e0 Chris Oyakhilome, laip\u1eb9 yii gba awon \u1ecdm\u1ecd ij\u1ecd re <a href=\"https:\/\/www.ripplesnigeria.com\/dont-listen-to-your-doctor-consume-more-salt-christ-embassys-pastor-chris-tells-members-video\/\" target=\"_blank\" rel=\"noopener\"><strong>niyanju<\/strong><\/a> pe ki won ko imoran dokita won danu lori iy\u1ecd\u0300 jije nitori iy\u1ecd\u0300 ni anfaani pupo lago ara.<\/p>\n\n\n\n<p class=\"wp-block-paragraph\">Oyakhilome, eni ti o je oludari ati alakoso ijo Christ Embassy s\u1ecd wipe awon onisegun oyinbo a maa gbani nimoran pe ki eniyan s\u1ecdra fun iy\u1ecd\u0300 jije sugbon imoran toun nipe ki awon eniyan je iy\u1ecd\u0300 daada.<\/p>\n\n\n\n<p class=\"wp-block-paragraph\">O fi fonran kan han w\u1ecdn lori ayelujara to safihan awon d\u1ecd\u0301k\u00edt\u00e0 alawo funfun ti won jerisi iwulo iy\u1ecd\u0300 lago ara. \u1ecc\u0300r\u1ecd\u0300 naa fa ariyanjiyan lori ayelujara, \u00e0w\u1ecdn olumulo b\u1eb9r\u1eb9 sii fi erongba w\u1ecdn han lori oro naa, boya looto ni oro ti alufaa s\u1ecd tabi asinilona ni imoran oludari ijo naa.<\/p>\n\n\n\n<h2 class=\"wp-block-heading\"><strong>B\u00e1wo ni w\u1ecdn \u1e63e n \u1e63\u1eb9\u0300d\u00e1 iy\u1ecd\u0300?<\/strong><\/h2>\n\n\n\n<p class=\"wp-block-paragraph\">Iy\u1ecd\u0300 tabi \u00ecseb\u00e8 je oun kan pataki ti a maa fin se ounje, pa nkan m\u1ecd ki o ma baje, a si maa n lo fun awon nkan miran ninu asa ati ise awujo eniyan. Ti k\u00f2 ba si iy\u1ecd\u0300 ninu \u1ecdb\u1eb9\u0300, \u1ecdb\u1eb9\u0300 naa a di \u00e0t\u1eb9\u0301, k\u00f2 n\u00ed l\u2019adun.<\/p>\n\n\n\n<p class=\"wp-block-paragraph\">Oun \u00e0d\u00e1y\u00e9b\u00e1 ni iy\u1ecd\u0300, won maa n <a href=\"https:\/\/www.usatoday.com\/story\/life\/food-dining\/2023\/08\/13\/where-does-salt-come-from\/70458930007\/#\" target=\"_blank\" rel=\"noopener\"><strong>\u1e63\u2019\u1eb9\u0300d\u00e1<\/strong><\/a> iy\u1ecd\u0300 k\u00far\u00f2 lara apata. \u00c0w\u1ecdn oun \u00e8l\u00f2 \u00cch\u00fal\u1eb9\u0300 ati iwak\u00f9s\u00e0 ni w\u1ecdn ma fi n fa iy\u1ecd\u0300 jade kuro lara awon apata.<\/p>\n\n\n\n<p class=\"wp-block-paragraph\">Ona miran ti a fi n s\u2019eda isebwe ni latara omi osa, awon onimo a lo ifenu omi iyen evaporation lati mu iy\u1ecd\u0300 jade. Ni igba miran, \u00e0w\u1ecdn onimo sayensi a mu omi brine, won a gbe si inu oru ninu y\u00e0r\u00e1 iwadii, bi omi naa se n ho, ni won se n fa iy\u1ecd\u0300 jade.&nbsp;<\/p>\n\n\n\n<h2 class=\"wp-block-heading\"><strong>Kini ajo WHO s\u1ecd?<\/strong><\/h2>\n\n\n\n<p class=\"wp-block-paragraph\">\u00c0j\u1ecd to n risi eto ilera lagbaye, World Health Organization (<a href=\"https:\/\/www.who.int\/news-room\/fact-sheets\/detail\/sodium-reduction\" target=\"_blank\" rel=\"noopener\"><strong>WHO<\/strong><\/a>) ti se agbekal\u1eb9 lori \u00ecw\u1ecd\u0300n iy\u1ecd\u0300 ti eniyan le j\u1eb9 ni \u1ecdj\u1ecd\u0301 kan. Fun eniyan ti \u1ecdj\u1ecd ori re je mejidinlogun tabi eni to dagba juyi l\u1ecd, won ni anfaani lati je iy\u1ecd\u0300 iw\u1ecdn grammu marun, o si se pataki ki a \u1e63e idinku iw\u1ecdn iy\u1ecd\u0300 fun \u00e0w\u1ecdn \u1ecdm\u1ecdde ti o j\u1eb9 \u1ecdm\u1ecd \u1ecdd\u00fan meji si marundinlogun.<\/p>\n\n\n\n<p class=\"wp-block-paragraph\">\u1eccm\u1ecd ikoko si \u1ecdm\u1ecd odun meji \u00f2 nilo iy\u1ecd\u0300 ninu ounj\u1eb9 w\u1ecdn. Lati \u1ecdm\u1ecd \u1ecdw\u00f3 s\u00ed o\u1e63\u00f9 m\u1eb9\u0301f\u00e0, omi \u1ecdyan nikan ni \u1ecdm\u1ecd n\u00edl\u1ecd\u0300, lati osu mefa, \u1ecdm\u1ecd naa a bere sii je ounje miran pelu omi \u1ecdy\u00e0n titi di odun meji, ni asiko yii, w\u1ecdn k\u00f2 nilo iy\u1ecd\u0300.<\/p>\n\n\n\n<p class=\"wp-block-paragraph\">Sugbon, WHO \u1e63\u2019alaye pe bi iw\u1ecdnba iy\u1ecd\u0300 ti eniyan n je dale irufe ounje ti onit\u1ecdun n j\u1eb9 ati agbegbe tabi ilu r\u1eb9\u0300.<\/p>\n\n\n\n<h2 class=\"wp-block-heading\"><strong>Nje iy\u1ecd\u0300 ni anfaani kankan lara?<\/strong><\/h2>\n\n\n\n<p class=\"wp-block-paragraph\">Iy\u1ecd\u0300 (sodium chloride) j\u1eb9 ona kan ti eroja sodiomu maa n gba wo ago ara eniyan. Ori\u1e63i iy\u1ecd\u0300 lo wa, \u00e0w\u1ecdn kan a maa ri eroja iodine, folic acid, iron tabi gbogbo re leekan naa. Iy\u1ecd\u0300 funfun wa, bee ni iy\u1ecd\u0300 alaw\u1ecd miran wa.<\/p>\n\n\n\n<p class=\"wp-block-paragraph\">Iy\u1ecd\u0300 oniy\u1eb9fun wa, b\u1eb9\u0301\u1eb9\u0300 si ni iy\u1ecd\u0300 onikoro wa. Aw\u1ecdn iy\u1ecd\u0300 kan wa ti eroja sodiomu inu re kere (low-sodium),<\/p>\n\n\n\n<p class=\"wp-block-paragraph\">Iyo maa n ran eniyan <a href=\"https:\/\/www.healthline.com\/nutrition\/salt-good-or-bad#too-much-salt\" target=\"_blank\" rel=\"noopener\"><strong>l\u1ecd\u0301w\u1ecd\u0301<\/strong><\/a> lati mu ki \u00e0w\u1ecdn omi ara wa ni gbedeke to t\u1ecd, o maa n se iranw\u1ecd fun \u1eb9ya \u1eb9\u1e63\u1ecd ara, o ma mu ki eroja inu ounje se ara loore daada, p\u1eb9lu i\u1e63an ara.<\/p>\n\n\n\n<p class=\"wp-block-paragraph\">\u1e62ugbon bi iy\u1ecd\u0300 se se pataki lara naa ni o le \u1e63e ijamba fun ilera ti eniyan ba je iy\u1ecd\u0300 laj\u1eb9ju. Jije iy\u1ecd\u0300 <a href=\"https:\/\/von.gov.ng\/fcta-issues-advisory-on-viral-salt-intake-claim\/\" target=\"_blank\" rel=\"noopener\"><strong>laj\u1eb9ju<\/strong><\/a> le fa ifunpa giga, aisan okan, ki eniyan sanra ju, aarun kindinrin, j\u1eb9j\u1eb9r\u1eb9 ikun, o si le se akoba fun eto oki ara lapapo (immune system).<\/p>\n\n\n\n<p class=\"wp-block-paragraph\">Koda, aisan to sop\u1ecd m\u1ecd aj\u1eb9ju iy\u1ecd\u0300 maa n fa iku fun awon eeyan mili\u1ecdnu meji o din di\u1eb9.&nbsp;<\/p>\n\n\n\n<p class=\"wp-block-paragraph\"><a href=\"https:\/\/www.who.int\/news-room\/fact-sheets\/detail\/sodium-reduction\" target=\"_blank\" rel=\"noopener\"><strong>WHO<\/strong><\/a> tunb\u1ecd gbani nim\u1ecdran lati dekun jij\u1eb9 iy\u1ecd\u0300 laj\u1eb9ju. O ni ki eeyan je ounje adayeba, ki o si yera fun ounje inu ora. Gbe iy\u1ecd\u0300 oniyefun (table salt) kuro lori tabili ounje; lo iy\u1ecd\u0300 <a href=\"https:\/\/www.mayoclinic.org\/healthy-lifestyle\/nutrition-and-healthy-eating\/in-depth\/sodium\/art-20045479\" target=\"_blank\" rel=\"noopener\"><strong>di\u1eb9\u0300<\/strong><\/a> sinu ounj\u1eb9 tabi yera fun iy\u1ecd\u0300; lo \u00e0w\u1ecdn eroja miran ti a mu ki ounje dun bii ewe efinrin, ewe rosimari ati beebee lo.<\/p>\n\n\n\n<p class=\"wp-block-paragraph\">Lakotan, iy\u1ecd\u0300 dara lago ara sugbon nitori o je \u00e8r\u00f2j\u00e0 kan to w\u1ecd\u0301p\u1ecd\u0300 ninu ounj\u1eb9, \u00e0w\u1ecdn eniyan a maa j\u1eb9 laj\u1eb9ju, a si ma fa aisan, nitori naa, o se pataki ki a wo odiwon iy\u1ecd\u0300 ti a n je lojumo, ki aisan ma baa fi ara wa \u1e63e ibugbe.<\/p>\n","protected":false},"excerpt":{"rendered":"<p>\u00c0l\u00f9f\u00e1\u00e0 Chris Oyakhilome, laip\u1eb9 yii gba awon \u1ecdm\u1ecd ij\u1ecd re niyanju pe ki won ko imoran dokita won danu lori iy\u1ecd\u0300 jije nitori iy\u1ecd\u0300 ni anfaani pupo lago ara. Oyakhilome, eni ti o je oludari ati alakoso ijo Christ Embassy s\u1ecd wipe awon onisegun oyinbo a maa gbani nimoran pe ki eniyan s\u1ecdra fun iy\u1ecd\u0300 jije sugbon imoran toun nipe ki awon eniyan je iy\u1ecd\u0300 daada. O fi fonran kan han w\u1ecdn lori ayelujara to safihan awon d\u1ecd\u0301k\u00edt\u00e0 alawo funfun ti won jerisi iwulo iy\u1ecd\u0300 lago ara. \u1ecc\u0300r\u1ecd\u0300 naa fa ariyanjiyan lori ayelujara, \u00e0w\u1ecdn olumulo b\u1eb9r\u1eb9 sii fi erongba w\u1ecdn han lori oro naa, boya looto ni oro ti alufaa s\u1ecd tabi asinilona ni imoran oludari ijo naa. B\u00e1wo ni w\u1ecdn \u1e63e n \u1e63\u1eb9\u0300d\u00e1 iy\u1ecd\u0300? Iy\u1ecd\u0300 tabi \u00ecseb\u00e8 je oun kan pataki ti a maa fin se ounje, pa nkan m\u1ecd ki o ma baje, a si maa n lo fun awon nkan miran ninu asa ati ise awujo eniyan. Ti k\u00f2 ba si iy\u1ecd\u0300 ninu \u1ecdb\u1eb9\u0300, \u1ecdb\u1eb9\u0300 naa a di \u00e0t\u1eb9\u0301, k\u00f2 n\u00ed l\u2019adun. Oun \u00e0d\u00e1y\u00e9b\u00e1 ni iy\u1ecd\u0300, won maa n \u1e63\u2019\u1eb9\u0300d\u00e1 iy\u1ecd\u0300 k\u00far\u00f2 lara apata. \u00c0w\u1ecdn oun \u00e8l\u00f2 \u00cch\u00fal\u1eb9\u0300 ati iwak\u00f9s\u00e0 ni w\u1ecdn ma fi n fa iy\u1ecd\u0300 jade kuro lara awon apata. Ona miran ti a fi n s\u2019eda isebwe ni latara omi osa, awon onimo a lo ifenu omi iyen evaporation lati mu iy\u1ecd\u0300 jade. Ni igba miran, \u00e0w\u1ecdn onimo sayensi a mu omi brine, won a gbe si inu oru ninu y\u00e0r\u00e1 iwadii, bi omi naa se n ho, ni won se n fa iy\u1ecd\u0300 jade.&nbsp; Kini ajo WHO s\u1ecd? \u00c0j\u1ecd to n risi eto ilera lagbaye, World Health Organization (WHO) ti se agbekal\u1eb9 lori \u00ecw\u1ecd\u0300n iy\u1ecd\u0300 ti eniyan le j\u1eb9 ni \u1ecdj\u1ecd\u0301 kan. Fun eniyan ti \u1ecdj\u1ecd ori re je mejidinlogun tabi eni to dagba juyi l\u1ecd, won ni anfaani lati je iy\u1ecd\u0300 iw\u1ecdn grammu marun, o si se pataki ki a \u1e63e idinku iw\u1ecdn iy\u1ecd\u0300 fun \u00e0w\u1ecdn \u1ecdm\u1ecdde ti o j\u1eb9 \u1ecdm\u1ecd \u1ecdd\u00fan meji si marundinlogun. \u1eccm\u1ecd ikoko si \u1ecdm\u1ecd odun meji \u00f2 nilo iy\u1ecd\u0300 ninu ounj\u1eb9 w\u1ecdn. Lati \u1ecdm\u1ecd \u1ecdw\u00f3 s\u00ed o\u1e63\u00f9 m\u1eb9\u0301f\u00e0, omi \u1ecdyan nikan ni \u1ecdm\u1ecd n\u00edl\u1ecd\u0300, lati osu mefa, \u1ecdm\u1ecd naa a bere sii je ounje miran pelu omi \u1ecdy\u00e0n titi di odun meji, ni asiko yii, w\u1ecdn k\u00f2 nilo iy\u1ecd\u0300. Sugbon, WHO \u1e63\u2019alaye pe bi iw\u1ecdnba iy\u1ecd\u0300 ti eniyan n je dale irufe ounje ti onit\u1ecdun n j\u1eb9 ati agbegbe tabi ilu r\u1eb9\u0300. Nje iy\u1ecd\u0300 ni anfaani kankan lara? Iy\u1ecd\u0300 (sodium chloride) j\u1eb9 ona kan ti eroja sodiomu maa n gba wo ago ara eniyan. Ori\u1e63i iy\u1ecd\u0300 lo wa, \u00e0w\u1ecdn kan a maa ri eroja iodine, folic acid, iron tabi gbogbo re leekan naa. Iy\u1ecd\u0300 funfun wa, bee ni iy\u1ecd\u0300 alaw\u1ecd miran wa. Iy\u1ecd\u0300 oniy\u1eb9fun wa, b\u1eb9\u0301\u1eb9\u0300 si ni iy\u1ecd\u0300 onikoro wa. Aw\u1ecdn iy\u1ecd\u0300 kan wa ti eroja sodiomu inu re kere (low-sodium), Iyo maa n ran eniyan l\u1ecd\u0301w\u1ecd\u0301 lati mu ki \u00e0w\u1ecdn omi ara wa ni gbedeke to t\u1ecd, o maa n se iranw\u1ecd fun \u1eb9ya \u1eb9\u1e63\u1ecd ara, o ma mu ki eroja inu ounje se ara loore daada, p\u1eb9lu i\u1e63an ara. \u1e62ugbon bi iy\u1ecd\u0300 se se pataki lara naa ni o le \u1e63e ijamba fun ilera ti eniyan ba je iy\u1ecd\u0300 laj\u1eb9ju. Jije iy\u1ecd\u0300 laj\u1eb9ju le fa ifunpa giga, aisan okan, ki eniyan sanra ju, aarun kindinrin, j\u1eb9j\u1eb9r\u1eb9 ikun, o si le se akoba fun eto oki ara lapapo (immune system). Koda, aisan to sop\u1ecd m\u1ecd aj\u1eb9ju iy\u1ecd\u0300 maa n fa iku fun awon eeyan mili\u1ecdnu meji o din di\u1eb9.&nbsp; WHO tunb\u1ecd gbani nim\u1ecdran lati dekun jij\u1eb9 iy\u1ecd\u0300 laj\u1eb9ju. O ni ki eeyan je ounje adayeba, ki o si yera fun ounje inu ora. Gbe iy\u1ecd\u0300 oniyefun (table salt) kuro lori tabili ounje; lo iy\u1ecd\u0300 di\u1eb9\u0300 sinu ounj\u1eb9 tabi yera fun iy\u1ecd\u0300; lo \u00e0w\u1ecdn eroja miran ti a mu ki ounje dun bii ewe efinrin, ewe rosimari ati beebee lo. Lakotan, iy\u1ecd\u0300 dara lago ara sugbon nitori o je \u00e8r\u00f2j\u00e0 kan to w\u1ecd\u0301p\u1ecd\u0300 ninu ounj\u1eb9, \u00e0w\u1ecdn eniyan a maa j\u1eb9 laj\u1eb9ju, a si ma fa aisan, nitori naa, o se pataki ki a wo odiwon iy\u1ecd\u0300 ti a n je lojumo, ki aisan ma baa fi ara wa \u1e63e ibugbe.<\/p>\n","protected":false},"author":1,"featured_media":22840,"comment_status":"open","ping_status":"closed","sticky":false,"template":"","format":"standard","meta":{"_jetpack_newsletter_access":"","_jetpack_dont_email_post_to_subs":false,"_jetpack_newsletter_tier_id":0,"_jetpack_memberships_contains_paywalled_content":false,"hannibal_claim_source":"","hannibal_source_label":"","hannibal_card_color":"blue","_jetpack_memberships_contains_paid_content":false,"footnotes":"","_wpscppro_dont_share_socialmedia":false,"_wpscppro_custom_social_share_image":0,"_facebook_share_type":"default","_twitter_share_type":"default","_linkedin_share_type":"default","_pinterest_share_type":"default","_linkedin_share_type_page":"","_instagram_share_type":"default","_medium_share_type":"","_threads_share_type":"","_google_business_share_type":"","_bluesky_share_type":"","_mastodon_share_type":"","_selected_social_profile":[],"_wpsp_enable_custom_social_template":false,"_wpsp_social_scheduling":{"enabled":false,"datetime":null,"platforms":[],"status":"template_only","dateOption":"today","timeOption":"now","customDays":"","customHours":"","customDate":"","customTime":"","schedulingType":"absolute"},"_wpsp_active_default_template":true},"categories":[2450,1572,121],"tags":[],"verdict":[],"ppma_author":[1920],"class_list":["post-22839","post","type-post","status-publish","format-standard","has-post-thumbnail","hentry","category-yoruba","category-explainers","category-health"],"jetpack_shortlink":"https:\/\/wp.me\/p8R6dE-5Wn","jetpack_likes_enabled":true,"jetpack_sharing_enabled":true,"authors":[{"term_id":1920,"user_id":0,"is_guest":1,"slug":"elizabeth-ogunbamowo","display_name":"Elizabeth Ogunbamowo","avatar_url":"https:\/\/secure.gravatar.com\/avatar\/7043a07f4ff292637cb75d13c8340fa9afb2ec87eceec4eedd980077c8bfd304?s=96&r=g","author_category":"","user_url":"","last_name":"","first_name":"","job_title":"","description":""}],"jetpack_featured_media_url":"https:\/\/i0.wp.com\/dubawa.org\/dir\/wp-content\/uploads\/2025\/05\/Salt.jpg?fit=1024%2C576&ssl=1","_links":{"self":[{"href":"https:\/\/dubawa.org\/dir\/wp-json\/wp\/v2\/posts\/22839","targetHints":{"allow":["GET"]}}],"collection":[{"href":"https:\/\/dubawa.org\/dir\/wp-json\/wp\/v2\/posts"}],"about":[{"href":"https:\/\/dubawa.org\/dir\/wp-json\/wp\/v2\/types\/post"}],"author":[{"embeddable":true,"href":"https:\/\/dubawa.org\/dir\/wp-json\/wp\/v2\/users\/1"}],"replies":[{"embeddable":true,"href":"https:\/\/dubawa.org\/dir\/wp-json\/wp\/v2\/comments?post=22839"}],"version-history":[{"count":1,"href":"https:\/\/dubawa.org\/dir\/wp-json\/wp\/v2\/posts\/22839\/revisions"}],"predecessor-version":[{"id":22841,"href":"https:\/\/dubawa.org\/dir\/wp-json\/wp\/v2\/posts\/22839\/revisions\/22841"}],"wp:featuredmedia":[{"embeddable":true,"href":"https:\/\/dubawa.org\/dir\/wp-json\/wp\/v2\/media\/22840"}],"wp:attachment":[{"href":"https:\/\/dubawa.org\/dir\/wp-json\/wp\/v2\/media?parent=22839"}],"wp:term":[{"taxonomy":"category","embeddable":true,"href":"https:\/\/dubawa.org\/dir\/wp-json\/wp\/v2\/categories?post=22839"},{"taxonomy":"post_tag","embeddable":true,"href":"https:\/\/dubawa.org\/dir\/wp-json\/wp\/v2\/tags?post=22839"},{"taxonomy":"verdict","embeddable":true,"href":"https:\/\/dubawa.org\/dir\/wp-json\/wp\/v2\/verdict?post=22839"},{"taxonomy":"author","embeddable":true,"href":"https:\/\/dubawa.org\/dir\/wp-json\/wp\/v2\/ppma_author?post=22839"}],"curies":[{"name":"wp","href":"https:\/\/api.w.org\/{rel}","templated":true}]}}