{"id":24515,"date":"2025-09-19T13:17:16","date_gmt":"2025-09-19T12:17:16","guid":{"rendered":"http:\/\/dubawa.org\/dir\/?p=24515"},"modified":"2025-09-19T13:17:18","modified_gmt":"2025-09-19T12:17:18","slug":"ileejo-kan-ni-ki-arabinrin-yii-san-owo-itanran-leyin-ti-o-ko-lati-%e1%b9%a3abewo-si-okunrin-to-fun-ni-owo-oko-kini-ofin-so","status":"publish","type":"post","link":"https:\/\/dubawa.org\/dir\/ileejo-kan-ni-ki-arabinrin-yii-san-owo-itanran-leyin-ti-o-ko-lati-%e1%b9%a3abewo-si-okunrin-to-fun-ni-owo-oko-kini-ofin-so\/","title":{"rendered":"Il\u00e9\u1eb9j\u1ecd\u0301 kan ni ki arabinrin yii san ow\u00f3 \u00ectanr\u00e0n leyin ti o k\u1ecd\u0300 lati \u1e63\u2019abewo si okunrin to fun ni ow\u00f3 \u1ecdk\u1ecd\u0300. Kini \u00f2fin s\u1ecd?"},"content":{"rendered":"\n<p class=\"wp-block-paragraph\">Tita omonikeji l\u1ecd\u1ecdre j\u1eb9 oun kan pataki ninu \u00ecb\u00e1\u1e63ep\u1ecd\u0300 \u1ecdm\u1ecd eniyan, paapaa laarin awon ti w\u1ecdn j\u1eb9\u0301 ololuf\u1eb9. Biotilejepe itaniloore ati owo iranw\u1ecd\u0301 laarin ololufe w\u1ecdp\u1ecd, o le fa aaw\u1ecd tabi arinyanjiyan laarin w\u1ecdn.<\/p>\n\n\n\n<p class=\"wp-block-paragraph\">Laipe yii, \u00e0w\u1ecdn olumulo ikanni X \u1e63\u2019atunpin <a href=\"https:\/\/x.com\/NigeriaStories\/status\/1959538256359436383?t=gmQx5BjNuQSmnLJhkvmZqQ&amp;s=08\">fonran<\/a> kan ti o \u1e63\u2019afihan obinrin kan ti or\u00fak\u1ecd r\u1eb9 n j\u1eb9 Jennifer ti o f\u2019oj\u00fa ba il\u00e9\u1eb9j\u1ecd\u0301, leyin ti o gba ow\u00f3 \u1ecdk\u1ecd\u0300 l\u2019\u1ecdw\u1ecd okunrin kan ti ko si mu adehun r\u1eb9 \u1e63\u1eb9.<\/p>\n\n\n\n<p class=\"wp-block-paragraph\">Ninu fonran ti o gbode kan yii, ad\u00e1j\u1ecd\u0301 naa n s\u2019\u1ecd\u0300r\u1ecd\u0300 ni \u00e8d\u00e8 Igbo, pe o ku si Jennifer l\u2019\u1ecdw\u1ecd\u0301 ki o san ow\u00f3 itanran egberun irinwo o le aadota tabi ki o fi \u1eb9w\u1ecdn \u1ecddun meje finra.<\/p>\n\n\n\n<p class=\"wp-block-paragraph\">DUBAWA \u1e63\u2019akiyesi orisirisi esi ti awon eniyan n f\u1ecd si fonran naa. Awon kan gbagbo, awon kan \u1e63\u2019alaigbagbo.<\/p>\n\n\n\n<p class=\"wp-block-paragraph\">Olumulo kan, Dr Izu s\u1ecd pe \u201ciwa odaran ni, idajo yii dara pup\u1ecd.\u201d Elomiran @<a href=\"https:\/\/x.com\/OmoEkoAwori\/status\/1959563242511970507\">OmoEkoAwori<\/a> s\u1ecd\u0301 pe iru idajo bee ru oun loju, \u201cSe ileejo wa fun iru ejo bayii?\u201d<\/p>\n\n\n\n<p class=\"wp-block-paragraph\">Iru ejo bayii k\u1ecd lo ma k\u1ecdk\u1ecd gbode lori ayelujara. Ni ib\u1eb9r\u1eb9 \u1ecddun yii, ileejo kan ni ipinle \u1ecc\u1e63un <a href=\"https:\/\/www.channelstv.com\/2025\/01\/27\/lady-fined-%E2%82%A6150k-for-failing-to-visit-boyfriend-after-taking-%E2%82%A63k-tp\" target=\"_blank\" rel=\"noopener\"><strong>d\u00e1j\u1ecd\u0301<\/strong><\/a> pe ki arabinrin kan san egberun lona aadojo leyin ti orekunrin re fun ni egberun meta naira fun ibewo ti ko si mu adehun re se.<\/p>\n\n\n\n<p class=\"wp-block-paragraph\">Nitori bi oro naa se gbode kan ati irufe esi ti awon olumulo ikanni naa n f\u1ecd, DUBAWA k\u1ecd ak\u1ecdsil\u1eb9 yii lati \u1e63\u2019alaye boya ile-\u1eb9j\u1ecd\u0301 m\u00e1j\u00eds\u00edr\u00e9\u00e8t\u00ec le joko gb\u1ecd iru esun b\u1eb9\u1eb9.<\/p>\n\n\n\n<h2 class=\"wp-block-heading\"><strong>Il\u00e9 \u1eb9j\u1ecd\u0301 m\u00e1j\u00eds\u00edr\u00e9\u00e8t\u00ec<\/strong><\/h2>\n\n\n\n<p class=\"wp-block-paragraph\">A \u1e63\u2019akiyesi pe \u00e0w\u1ecdn olumulo ikanni yii n bere boya o \u1e63ee\u1e63e ki il\u00e9\u1eb9j\u1ecd\u0301 m\u00e1j\u00eds\u00edr\u00e9\u00e8t\u00ec da iru ej\u1ecd bee fun eeyan ati pe se o ba ofin mu ki ileejo naa dajo ni ede ibile.<\/p>\n\n\n\n<p class=\"wp-block-paragraph\">Ileejo m\u00e1j\u00eds\u00edr\u00e9\u00e8t\u00ec je il\u00e9\u1eb9j\u1ecd\u0301 <a href=\"https:\/\/docs.google.com\/document\/d\/15OMJNrSMvYus5riekHGm_7LIMDynzFszKO2Vgd5Yukw\/edit?tab=t.0\" target=\"_blank\" rel=\"noopener\">\u00e0k\u1ecd\u0301k\u1ecd\u0301<\/a> ti opolopo eeyan maa n gbe oro lo lati fi esun kan elomiran. Ileejo m\u00e1j\u00eds\u00edr\u00e9\u00e8t\u00ec ni won ti maa n gbo ejo ti ese naa ko ba j\u1ecdm\u1ecd ti iwa odaran. Awon ileejo kekeeke yii lo maa n gbo ejo kekeeke ti won a si dajo bo ti ye.<\/p>\n\n\n\n<p class=\"wp-block-paragraph\">Lori esun odaran, ti o ba se \u1eb9\u0300\u1e63\u1eb9\u0300 kekere, ileejo m\u00e1j\u00eds\u00edr\u00e9\u00e8t\u00ec a dajo ese ti ijiya re ko ju odun meji lo, sugbon iwa <a href=\"https:\/\/reyabogado.com\/us\/which-courts-have-criminal-jurisdiction-in-nigeria\" target=\"_blank\" rel=\"noopener\"><strong>odaran<\/strong><\/a> bii agbebon, ipaniyan, tabi jibiti olowo gobio, il\u00e9\u1eb9j\u1ecd\u0301 giga ni won a ti gbo ejo yii.<\/p>\n\n\n\n<p class=\"wp-block-paragraph\">Ofin ipinle kookan ni ileejo m\u00e1j\u00eds\u00edr\u00e9\u00e8t\u00ec maa n fi n d\u2019aj\u1ecd. Sibesibe, \u00e0\u1e63\u1eb9 ileej\u1ecd m\u00e1j\u00eds\u00edr\u00e9\u00e8t\u00ec wa lataara <a href=\"https:\/\/www.learnnigerianlaw.com\/learn\/legal-system\/inferior\" target=\"_blank\" rel=\"noopener\">ofin orileede <\/a>paapaa ofin to niise pelu iwa odanran ni guusu orileede Naijiria (Criminal Code Act) ati ofin ihuwasi eniyan (Penal Code) ti ariwa orileede Naijiria. Bakan naa, ipinle kookan a maa ni ofin ti ileejo m\u00e1j\u00eds\u00edr\u00e9\u00e8t\u00ec le lo lati dajo.<\/p>\n\n\n\n<h2 class=\"wp-block-heading\"><strong>Kini ofin so nipa gbigba owo l\u2019ona eburu?<\/strong><\/h2>\n\n\n\n<p class=\"wp-block-paragraph\"><a href=\"https:\/\/lawsofnigeria.placng.org\/laws\/C38.pdf\" target=\"_blank\" rel=\"noopener\"><strong>Abala 419<\/strong><\/a><strong> <\/strong>ofin orileede Naijiria nipa iwa odaran menuba ese gbigba owo tabi oun miran lowo elomii l\u2019\u1ecdna eburu. Ofin naa ko gba enikeni laaye lati gba owo pelu itanje tabi ki eeyan hu iwa jibiti lati gba dukia tabi ki eeyan so fun enikan ki o fun elomiran ni dukia r\u1eb9\u0300.<\/p>\n\n\n\n<p class=\"wp-block-paragraph\">Ofin naa ri gege bi <a href=\"https:\/\/lawsofnigeria.placng.org\/laws\/C38.pdf\" target=\"_blank\" rel=\"noopener\">iwa odanran,<\/a> pelu ijiya odun meta l\u2019\u1ecdgba \u1eb9w\u1ecdn tabi odun meje ti owo naa ba to egberun kan abi jube lo.<\/p>\n\n\n\n<p class=\"wp-block-paragraph\">Ti eniyan ba fi iwa etan gba owo lowo elomiran, o jebi esun itanje.&nbsp;<\/p>\n\n\n\n<p class=\"wp-block-paragraph\">Ki a le ni oye boya iwa Jennifer je iwa odaran, DUBAWA ba awon amofin s\u1ecdr\u1ecd, won si la wa looye.<\/p>\n\n\n\n<p class=\"wp-block-paragraph\">Francis Oche, \u1eb9ni ti o j\u1eb9 amofin ni ile-eko giga Yunifasiti Veritas salaye pe abala ofin 419 ti orileede Naijiria niise pelu gbigba owo l\u2019ona eburu.<\/p>\n\n\n\n<p class=\"wp-block-paragraph\">\u201cTi o ba m\u1ecd\u1ecdm\u1ecd tan elomii j\u1eb9, gba owo, ti o si k\u1ecd lati mu adehun r\u1eb9 \u1e63\u1eb9, iwa odaran ni. Fun apeere, eniyan kan fun o ni owo \u1ecdk\u1ecd lo sibikan, sugbon o mu adehun naa \u1e63\u1eb9 tabi k\u1ecd lati da owo pada, iwa odaran nii.\u201d<\/p>\n\n\n\n<p class=\"wp-block-paragraph\">O f\u2019ikun alaye re pe ti afuni ba bere owo re, ti o si ko lati da owo naa pada, iwa odaran nla ni.<\/p>\n\n\n\n<p class=\"wp-block-paragraph\">Amofin naa s\u1ecd wipe, \u201caw\u1ecdn opo meta adehun lo wa: ak\u1ecdk\u1ecd ni pe awon eniyan naa gbodo ni adehun (fifuni ati gbigba), oun keji ni nkan ti o so w\u1ecdn p\u1ecd bii owo, iketa si ni wipe, adehun naa wa labe ofin.\u201d<\/p>\n\n\n\n<p class=\"wp-block-paragraph\">Ti eniyan ba gba owo l\u2019\u1ecdna ait\u1ecd, iwa jibiti nii, abala ofin 419 ti orileede Naijiria mu eniyan bee.<\/p>\n\n\n\n<h2 class=\"wp-block-heading\"><strong>Il\u00e9\u1eb9j\u1ecd\u0301 wo lo ni agbara lati joko gb\u1ecd iru esun yii?<\/strong><\/h2>\n\n\n\n<p class=\"wp-block-paragraph\">DUBAWA bere lowo amofin Francis pe ileejo wo lo le joko gbo irufe oro yii, o si salaye fun wa pe, \u201cile-ejo m\u00e1j\u00eds\u00edr\u00e9\u00e8t\u00ec le joko gb\u1ecd oro naa ti ese naa ko ba p\u1ecd, iyen ti ijiya esun ko ba koja odun meji ni \u1ecdgba \u1eb9w\u1ecdn. \u1eb8\u0300\u1e63\u1eb9\u0300 to ba buru ju bayi l\u1ecd, il\u00e9\u1eb9j\u1ecd\u0301 giga ni won a gbe l\u1ecd.\u201d<\/p>\n\n\n\n<p class=\"wp-block-paragraph\">Amofin Peter salaye pe iye owo ti ol\u00f9p\u1eb9\u0300j\u1ecd\u0301 ba na lo maa s\u1ecd irufe il\u00e9\u1eb9j\u1ecd\u0301 to maa gbo ejo naa. Ti owo naa ba kere si milionu meje naira, il\u00e9\u1eb9j\u1ecd\u0301 m\u00e1j\u00eds\u00edr\u00e9\u00e8t\u00ec le joko gbo, sugbon ti owo naa ba ju bayi lo, igbejo le waye ni il\u00e9\u1eb9j\u1ecd\u0301 giga ipinle tabi il\u00e9\u1eb9j\u1ecd\u0301 giga ti orileede.<\/p>\n\n\n\n<p class=\"wp-block-paragraph\">O tunbo f\u2019ikun pe ile-ejo kotemil\u1ecdrun maa n gbo ejo ti won gbe wa lati awon il\u00e9\u1eb9j\u1ecd\u0301 mejeeji wonyi\u2014 il\u00e9\u1eb9j\u1ecd\u0301 m\u00e1j\u00eds\u00edr\u00e9\u00e8t\u00ec ati il\u00e9\u1eb9j\u1ecd\u0301 giga, bee si ni a tun ni il\u00e9\u1eb9j\u1ecd\u0301 to ga julo ni orileede Naijiria.<\/p>\n\n\n\n<p class=\"wp-block-paragraph\"><strong>Se o seese ki adajo maa so ede abinibi l\u2019asiko igbejo?&nbsp;<\/strong><\/p>\n\n\n\n<p class=\"wp-block-paragraph\">Francis salaye pe o seese ki adajo il\u00e9\u1eb9j\u1ecd\u0301 majisireeti lo ede abinibi ni awon igba kookan lasilo igbejo.<\/p>\n\n\n\n<p class=\"wp-block-paragraph\">O s\u1ecd wipe, \u201cil\u00e9\u1eb9j\u1ecd\u0301 ibile ati il\u00e9\u1eb9j\u1ecd\u0301 majisireeti le se igbejo ni ede abinibi paapaa ti olupejo ati olujejo o ba gbo ede geesi.\u201d<\/p>\n\n\n\n<p class=\"wp-block-paragraph\">\u1e62ugb\u1ecdn ni il\u00e9\u1eb9j\u1ecd\u0301 giga, ede g\u1eb9\u1eb9si ni won maa lo. Ko ba ofin mu ki enikeni se igbejo ni ede abinibi ni il\u00e9\u1eb9j\u1ecd\u0301 giga. Ti okan lara awon olujejo tabi olupejo o ba gbo ede geesi, won a pe \u00f2gbuf\u1ecd\u0300 ki o tunmo oun ti won s\u1ecd.<\/p>\n\n\n\n<p class=\"wp-block-paragraph\">O salaye lekunrere pe il\u00e9\u1eb9j\u1ecd\u0301 gbodo ri pe ejo naa ye awon ti won wa ni il\u00e9\u1eb9j\u1ecd\u0301 yekeyeke.<\/p>\n\n\n\n<p class=\"wp-block-paragraph\">Ogbeni Peter fikun wipe ede geesi ni won maa n lo ni il\u00e9\u1eb9j\u1ecd\u0301 l\u2019orileede Naijiria, ko si bojumu ki adajo lo ede abinibi.<\/p>\n\n\n\n<p class=\"wp-block-paragraph\">Sugbon o seese ki okan lara olupejo tabi olujejo ma gbo ede geesi, ogbufo a ran onitoun lowo lati tunmo oun ti il\u00e9\u1eb9j\u1ecd\u0301 n so si ede abinibi.<\/p>\n\n\n\n<p class=\"wp-block-paragraph\">O salaye pe il\u00e9\u1eb9j\u1ecd\u0301 ibile ni anfaani lati lo yala ede geesi tabi ede abinibi nitori irufe awon eniyan ti won maa n saba lo ibe.<\/p>\n\n\n\n<p class=\"wp-block-paragraph\">Sugbon eleyi o tunmo si pe ede abinibi nikan ni w\u1ecdn a fi se igbejo ni gbogbo igba.&nbsp;<\/p>\n\n\n\n<h2 class=\"wp-block-heading\"><strong>Akotan<\/strong><\/h2>\n\n\n\n<p class=\"wp-block-paragraph\">Biotilejepe gbigba owo l\u2019\u1ecdna ait\u1ecd l\u1ecdw\u1ecd elomiran je ese labe ofin Naijiria, ijiya to t\u1ecd\u0301 si onitoun ati il\u00e9\u1eb9j\u1ecd\u0301 ti yoo joko gbo oro naa dale iye owo ti olupejo fun olujejo ati iwa jibiti olujejo.<\/p>\n\n\n\n<p class=\"wp-block-paragraph\">Il\u00e9\u1eb9j\u1ecd\u0301 majisireeti le gbo ejo naa bi a ti salaye ninu akosile yii, sugbon ede geesi ni won gbodo fi se igbejo, biotilejepe adajo le lo ede abinibi lekookan.&nbsp;<\/p>\n","protected":false},"excerpt":{"rendered":"<p>Tita omonikeji l\u1ecd\u1ecdre j\u1eb9 oun kan pataki ninu \u00ecb\u00e1\u1e63ep\u1ecd\u0300 \u1ecdm\u1ecd eniyan, paapaa laarin awon ti w\u1ecdn j\u1eb9\u0301 ololuf\u1eb9. Biotilejepe itaniloore ati owo iranw\u1ecd\u0301 laarin ololufe w\u1ecdp\u1ecd, o le fa aaw\u1ecd tabi arinyanjiyan laarin w\u1ecdn. Laipe yii, \u00e0w\u1ecdn olumulo ikanni X \u1e63\u2019atunpin fonran kan ti o \u1e63\u2019afihan obinrin kan ti or\u00fak\u1ecd r\u1eb9 n j\u1eb9 Jennifer ti o f\u2019oj\u00fa ba il\u00e9\u1eb9j\u1ecd\u0301, leyin ti o gba ow\u00f3 \u1ecdk\u1ecd\u0300 l\u2019\u1ecdw\u1ecd okunrin kan ti ko si mu adehun r\u1eb9 \u1e63\u1eb9. Ninu fonran ti o gbode kan yii, ad\u00e1j\u1ecd\u0301 naa n s\u2019\u1ecd\u0300r\u1ecd\u0300 ni \u00e8d\u00e8 Igbo, pe o ku si Jennifer l\u2019\u1ecdw\u1ecd\u0301 ki o san ow\u00f3 itanran egberun irinwo o le aadota tabi ki o fi \u1eb9w\u1ecdn \u1ecddun meje finra. DUBAWA \u1e63\u2019akiyesi orisirisi esi ti awon eniyan n f\u1ecd si fonran naa. Awon kan gbagbo, awon kan \u1e63\u2019alaigbagbo. Olumulo kan, Dr Izu s\u1ecd pe \u201ciwa odaran ni, idajo yii dara pup\u1ecd.\u201d Elomiran @OmoEkoAwori s\u1ecd\u0301 pe iru idajo bee ru oun loju, \u201cSe ileejo wa fun iru ejo bayii?\u201d Iru ejo bayii k\u1ecd lo ma k\u1ecdk\u1ecd gbode lori ayelujara. Ni ib\u1eb9r\u1eb9 \u1ecddun yii, ileejo kan ni ipinle \u1ecc\u1e63un d\u00e1j\u1ecd\u0301 pe ki arabinrin kan san egberun lona aadojo leyin ti orekunrin re fun ni egberun meta naira fun ibewo ti ko si mu adehun re se. Nitori bi oro naa se gbode kan ati irufe esi ti awon olumulo ikanni naa n f\u1ecd, DUBAWA k\u1ecd ak\u1ecdsil\u1eb9 yii lati \u1e63\u2019alaye boya ile-\u1eb9j\u1ecd\u0301 m\u00e1j\u00eds\u00edr\u00e9\u00e8t\u00ec le joko gb\u1ecd iru esun b\u1eb9\u1eb9. Il\u00e9 \u1eb9j\u1ecd\u0301 m\u00e1j\u00eds\u00edr\u00e9\u00e8t\u00ec A \u1e63\u2019akiyesi pe \u00e0w\u1ecdn olumulo ikanni yii n bere boya o \u1e63ee\u1e63e ki il\u00e9\u1eb9j\u1ecd\u0301 m\u00e1j\u00eds\u00edr\u00e9\u00e8t\u00ec da iru ej\u1ecd bee fun eeyan ati pe se o ba ofin mu ki ileejo naa dajo ni ede ibile. Ileejo m\u00e1j\u00eds\u00edr\u00e9\u00e8t\u00ec je il\u00e9\u1eb9j\u1ecd\u0301 \u00e0k\u1ecd\u0301k\u1ecd\u0301 ti opolopo eeyan maa n gbe oro lo lati fi esun kan elomiran. Ileejo m\u00e1j\u00eds\u00edr\u00e9\u00e8t\u00ec ni won ti maa n gbo ejo ti ese naa ko ba j\u1ecdm\u1ecd ti iwa odaran. Awon ileejo kekeeke yii lo maa n gbo ejo kekeeke ti won a si dajo bo ti ye. Lori esun odaran, ti o ba se \u1eb9\u0300\u1e63\u1eb9\u0300 kekere, ileejo m\u00e1j\u00eds\u00edr\u00e9\u00e8t\u00ec a dajo ese ti ijiya re ko ju odun meji lo, sugbon iwa odaran bii agbebon, ipaniyan, tabi jibiti olowo gobio, il\u00e9\u1eb9j\u1ecd\u0301 giga ni won a ti gbo ejo yii. Ofin ipinle kookan ni ileejo m\u00e1j\u00eds\u00edr\u00e9\u00e8t\u00ec maa n fi n d\u2019aj\u1ecd. Sibesibe, \u00e0\u1e63\u1eb9 ileej\u1ecd m\u00e1j\u00eds\u00edr\u00e9\u00e8t\u00ec wa lataara ofin orileede paapaa ofin to niise pelu iwa odanran ni guusu orileede Naijiria (Criminal Code Act) ati ofin ihuwasi eniyan (Penal Code) ti ariwa orileede Naijiria. Bakan naa, ipinle kookan a maa ni ofin ti ileejo m\u00e1j\u00eds\u00edr\u00e9\u00e8t\u00ec le lo lati dajo. Kini ofin so nipa gbigba owo l\u2019ona eburu? Abala 419 ofin orileede Naijiria nipa iwa odaran menuba ese gbigba owo tabi oun miran lowo elomii l\u2019\u1ecdna eburu. Ofin naa ko gba enikeni laaye lati gba owo pelu itanje tabi ki eeyan hu iwa jibiti lati gba dukia tabi ki eeyan so fun enikan ki o fun elomiran ni dukia r\u1eb9\u0300. Ofin naa ri gege bi iwa odanran, pelu ijiya odun meta l\u2019\u1ecdgba \u1eb9w\u1ecdn tabi odun meje ti owo naa ba to egberun kan abi jube lo. Ti eniyan ba fi iwa etan gba owo lowo elomiran, o jebi esun itanje.&nbsp; Ki a le ni oye boya iwa Jennifer je iwa odaran, DUBAWA ba awon amofin s\u1ecdr\u1ecd, won si la wa looye. Francis Oche, \u1eb9ni ti o j\u1eb9 amofin ni ile-eko giga Yunifasiti Veritas salaye pe abala ofin 419 ti orileede Naijiria niise pelu gbigba owo l\u2019ona eburu. \u201cTi o ba m\u1ecd\u1ecdm\u1ecd tan elomii j\u1eb9, gba owo, ti o si k\u1ecd lati mu adehun r\u1eb9 \u1e63\u1eb9, iwa odaran ni. Fun apeere, eniyan kan fun o ni owo \u1ecdk\u1ecd lo sibikan, sugbon o mu adehun naa \u1e63\u1eb9 tabi k\u1ecd lati da owo pada, iwa odaran nii.\u201d O f\u2019ikun alaye re pe ti afuni ba bere owo re, ti o si ko lati da owo naa pada, iwa odaran nla ni. Amofin naa s\u1ecd wipe, \u201caw\u1ecdn opo meta adehun lo wa: ak\u1ecdk\u1ecd ni pe awon eniyan naa gbodo ni adehun (fifuni ati gbigba), oun keji ni nkan ti o so w\u1ecdn p\u1ecd bii owo, iketa si ni wipe, adehun naa wa labe ofin.\u201d Ti eniyan ba gba owo l\u2019\u1ecdna ait\u1ecd, iwa jibiti nii, abala ofin 419 ti orileede Naijiria mu eniyan bee. Il\u00e9\u1eb9j\u1ecd\u0301 wo lo ni agbara lati joko gb\u1ecd iru esun yii? DUBAWA bere lowo amofin Francis pe ileejo wo lo le joko gbo irufe oro yii, o si salaye fun wa pe, \u201cile-ejo m\u00e1j\u00eds\u00edr\u00e9\u00e8t\u00ec le joko gb\u1ecd oro naa ti ese naa ko ba p\u1ecd, iyen ti ijiya esun ko ba koja odun meji ni \u1ecdgba \u1eb9w\u1ecdn. \u1eb8\u0300\u1e63\u1eb9\u0300 to ba buru ju bayi l\u1ecd, il\u00e9\u1eb9j\u1ecd\u0301 giga ni won a gbe l\u1ecd.\u201d Amofin Peter salaye pe iye owo ti ol\u00f9p\u1eb9\u0300j\u1ecd\u0301 ba na lo maa s\u1ecd irufe il\u00e9\u1eb9j\u1ecd\u0301 to maa gbo ejo naa. Ti owo naa ba kere si milionu meje naira, il\u00e9\u1eb9j\u1ecd\u0301 m\u00e1j\u00eds\u00edr\u00e9\u00e8t\u00ec le joko gbo, sugbon ti owo naa ba ju bayi lo, igbejo le waye ni il\u00e9\u1eb9j\u1ecd\u0301 giga ipinle tabi il\u00e9\u1eb9j\u1ecd\u0301 giga ti orileede. O tunbo f\u2019ikun pe ile-ejo kotemil\u1ecdrun maa n gbo ejo ti won gbe wa lati awon il\u00e9\u1eb9j\u1ecd\u0301 mejeeji wonyi\u2014 il\u00e9\u1eb9j\u1ecd\u0301 m\u00e1j\u00eds\u00edr\u00e9\u00e8t\u00ec ati il\u00e9\u1eb9j\u1ecd\u0301 giga, bee si ni a tun ni il\u00e9\u1eb9j\u1ecd\u0301 to ga julo ni orileede Naijiria. Se o seese ki adajo maa so ede abinibi l\u2019asiko igbejo?&nbsp; Francis salaye pe o seese ki adajo il\u00e9\u1eb9j\u1ecd\u0301 majisireeti lo ede abinibi ni awon igba kookan lasilo igbejo. O s\u1ecd wipe, \u201cil\u00e9\u1eb9j\u1ecd\u0301 ibile ati il\u00e9\u1eb9j\u1ecd\u0301 majisireeti le se igbejo ni ede abinibi paapaa ti olupejo ati olujejo o ba gbo ede geesi.\u201d \u1e62ugb\u1ecdn ni il\u00e9\u1eb9j\u1ecd\u0301 giga, ede g\u1eb9\u1eb9si ni won maa lo. Ko ba ofin mu ki enikeni se igbejo ni ede abinibi ni il\u00e9\u1eb9j\u1ecd\u0301 giga. Ti okan lara awon olujejo tabi olupejo o ba gbo ede geesi, won a pe \u00f2gbuf\u1ecd\u0300 ki o tunmo oun ti won s\u1ecd. O salaye lekunrere pe il\u00e9\u1eb9j\u1ecd\u0301 gbodo ri pe ejo naa ye awon ti won wa ni il\u00e9\u1eb9j\u1ecd\u0301 yekeyeke. Ogbeni Peter fikun wipe ede geesi ni won maa n<\/p>\n","protected":false},"author":1,"featured_media":24516,"comment_status":"open","ping_status":"closed","sticky":false,"template":"","format":"standard","meta":{"_jetpack_newsletter_access":"","_jetpack_dont_email_post_to_subs":false,"_jetpack_newsletter_tier_id":0,"_jetpack_memberships_contains_paywalled_content":false,"hannibal_claim_source":"","hannibal_source_label":"","hannibal_card_color":"blue","_jetpack_memberships_contains_paid_content":false,"footnotes":"","_wpscppro_dont_share_socialmedia":false,"_wpscppro_custom_social_share_image":0,"_facebook_share_type":"default","_twitter_share_type":"default","_linkedin_share_type":"default","_pinterest_share_type":"default","_linkedin_share_type_page":"","_instagram_share_type":"default","_medium_share_type":"","_threads_share_type":"","_google_business_share_type":"","_bluesky_share_type":"","_mastodon_share_type":"","_selected_social_profile":[],"_wpsp_enable_custom_social_template":false,"_wpsp_social_scheduling":{"enabled":false,"datetime":null,"platforms":[],"status":"template_only","dateOption":"today","timeOption":"now","customDays":"","customHours":"","customDate":"","customTime":"","schedulingType":"absolute"},"_wpsp_active_default_template":true},"categories":[2450,123],"tags":[],"verdict":[],"ppma_author":[1920],"class_list":["post-24515","post","type-post","status-publish","format-standard","has-post-thumbnail","hentry","category-yoruba","category-mainstream"],"jetpack_shortlink":"https:\/\/wp.me\/p8R6dE-6np","jetpack_likes_enabled":true,"jetpack_sharing_enabled":true,"authors":[{"term_id":1920,"user_id":0,"is_guest":1,"slug":"elizabeth-ogunbamowo","display_name":"Elizabeth Ogunbamowo","avatar_url":"https:\/\/secure.gravatar.com\/avatar\/7043a07f4ff292637cb75d13c8340fa9afb2ec87eceec4eedd980077c8bfd304?s=96&r=g","author_category":"","user_url":"","last_name":"","first_name":"","job_title":"","description":""}],"jetpack_featured_media_url":"https:\/\/i0.wp.com\/dubawa.org\/dir\/wp-content\/uploads\/2025\/09\/image-66.png?fit=459%2C669&ssl=1","_links":{"self":[{"href":"https:\/\/dubawa.org\/dir\/wp-json\/wp\/v2\/posts\/24515","targetHints":{"allow":["GET"]}}],"collection":[{"href":"https:\/\/dubawa.org\/dir\/wp-json\/wp\/v2\/posts"}],"about":[{"href":"https:\/\/dubawa.org\/dir\/wp-json\/wp\/v2\/types\/post"}],"author":[{"embeddable":true,"href":"https:\/\/dubawa.org\/dir\/wp-json\/wp\/v2\/users\/1"}],"replies":[{"embeddable":true,"href":"https:\/\/dubawa.org\/dir\/wp-json\/wp\/v2\/comments?post=24515"}],"version-history":[{"count":1,"href":"https:\/\/dubawa.org\/dir\/wp-json\/wp\/v2\/posts\/24515\/revisions"}],"predecessor-version":[{"id":24517,"href":"https:\/\/dubawa.org\/dir\/wp-json\/wp\/v2\/posts\/24515\/revisions\/24517"}],"wp:featuredmedia":[{"embeddable":true,"href":"https:\/\/dubawa.org\/dir\/wp-json\/wp\/v2\/media\/24516"}],"wp:attachment":[{"href":"https:\/\/dubawa.org\/dir\/wp-json\/wp\/v2\/media?parent=24515"}],"wp:term":[{"taxonomy":"category","embeddable":true,"href":"https:\/\/dubawa.org\/dir\/wp-json\/wp\/v2\/categories?post=24515"},{"taxonomy":"post_tag","embeddable":true,"href":"https:\/\/dubawa.org\/dir\/wp-json\/wp\/v2\/tags?post=24515"},{"taxonomy":"verdict","embeddable":true,"href":"https:\/\/dubawa.org\/dir\/wp-json\/wp\/v2\/verdict?post=24515"},{"taxonomy":"author","embeddable":true,"href":"https:\/\/dubawa.org\/dir\/wp-json\/wp\/v2\/ppma_author?post=24515"}],"curies":[{"name":"wp","href":"https:\/\/api.w.org\/{rel}","templated":true}]}}