Láìsí ìyípadà airotẹlẹ bíí ti ìdìbò odun 2015 àti 2019, olùdìbò mílíọ̀nù merinlelọgọrin (84 million) ni wọ́n fi orúkọ sílẹ̀ láti dìbò yan ẹni tí yóò jẹ ààrẹ tuntun orílè-èdè Nàìjíríà ní oṣù kejì ọdún 2023.
L’ásìkò ìdìbò, awon ènìyàn féràn láti yago fún ohunkohun to níìṣe pẹlu ìdìbò, nítorí aibikita sí ẹ̀tọ́ olùdìbò, eyi sí je ẹdun ọkan fún àwọn aṣèjọba. Àgbéyẹ̀wò kan ti Saheed Olasunkanmi ṣe lori “Eko Olùdìbò ati Ìdìbò ni Nàìjíríà: Ọrọ ati ìṣòro ìdìbò gbogbogbò ọdún 2019” fihàn pé ọpọlọpọ olùdìbò ní kò ní ìmọ kíkún lóri ìbò torí ikọlu àwọn ológun.
Kí a lè kojú aìbìkítà àwọn olùdìbò, ẹ̀kọ́ nípa ìbò àti àjọ ètò ìdìbò tó munadoko ṣe pàtàkì sí àṣeyọrí ètò ìdìbò, kí a lè fi ìdí ìjọba ara ẹni múlẹ̀ ní orílè-èdè Nàìjíríà.
Ní ọjọ́ karundilọgbọn oṣù kejì ọdún 2022, ìjọba ṣe agbekalẹ òfin ìdìbò tuntun, àmọ́ṣá ọpọlọpọ ìyípadà fún olùdíje, ẹgbẹ́ ́òṣèlú àti àwọn ti máa n ṣ’agbekalẹ ètò ìmúlò, ní àwọn eniyan o tíì mọ̀/gbọ́ nípa rẹ̀.
Kíni ẹ̀tọ́ olùdìbò l’ọjọ́ ìbò, báwo ni wọ́n si lè jà fún ẹ̀tọ́ wọn?
Ẹ̀tọ́ láti dìbò
Ìwé òfin ọdún 1999 fi ìdí re múlẹ pé gbogbo ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tí ó ṣe ojúṣe rẹ ni ìbámu pẹlú ifilelẹ òfin ló ní ẹ̀tọ́ láti dìbò àti láti dije fún ipò ìjọba.
Pẹlu kaadi ìdìbò alálòpé wọn, olùdìbò le dìbò lẹyìn tí ó bá ti se àrídájú pé orúkọ rẹ̀ wa lórí ìwé ìforúkọsílẹ̀ ìdìbò.
Awọn olùdíje náà lè dìbò. Ṣáájú ọjọ ìdìbò, olùdíje tí ó bá ti se ojúṣe rẹ ni ibamu pẹlu òfin, pàápàá jùlọ èyí tí ẹgbẹ òṣèlú fọwọsi ìdíje rẹ̀, onítọ̀ún ni ẹ̀tọ́ láti dìbò.
Ẹ̀tọ́ láti dìbò ní ìkọ̀kọ̀
Olùdìbò ni ẹ̀tọ́ láti dìbò (yan oludije ti won fẹ) ní ìkọ̀kọ̀. Wọ́n ṣ’agbekalẹ àgọ́ ìdìbò kí wọ́n lè ṣe àtìlẹ́yìn fún ìdìbò ni ìkọ̀kọ̀ àti láti pèsè ààbò fún olùdìbò.
Ìwà ipá ní àsìkò ìdìbò àti àwọn ìwà ọ̀daràn míràn wọ́pọ̀ ní ilẹ̀ Áfíríkà, àgọ́ ìdìbò ń pèsè ààbò fún àwọn olùdìbò.
Ẹ̀tọ́ sí àlàyé tàbí ìròyìn nípa ètò ìdìbò
Ní àsìkò ìdìbò, olùdìbò ní ẹ̀tọ́ láti bèèrè ìbéèrè kankan láìsí ìbẹrù ifiyajẹni láti ọ̀dọ̀ àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò. Àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba tó wà ní ìbùdó ìbò gbọ́dọ̀ dahun sí ìbéèrè yòówù tí olùdìbò bá béèrè pàápàá jùlọ ìbéèrè tó niiṣe pẹ̀lú ètò ìdìbò.
Bákan náà ni olùdìbò ni ẹ̀tọ́ láti ní ìmọ nípa ètò ìdìbò lẹyìn ìbò. Òfin Freedom of Information Act, ti wọn ṣ’agbekale rẹ ni ọdún 2011 fún gbogbo ènìyàn — ati awọn olùdìbò — ni ẹ̀tọ́ láti bèèrè Ìfìlọ̀ tàbí àlàyé kankan láti ọwọ́ ẹnikẹni tí ó ba wa ní ọfiisi ìjọba. Owó ìjọba ni won fin ṣ’atileyin ìdìbòyàn, èyí sí fún olùdìbò ni ẹ̀tọ́ lati bèèrè ìbéèrè ni ibùdó ìdìbò.
Àkíyèsí èsì ìdìbò
Àwọn olùdìbò lè dúró lẹ́yìn ti wọn bá dìbò tán, kí wọ́n lè f’ojusi àbájáde ètò ìdìbò. Oṣiṣẹ àjọ ètò ìdìbò INEC tabi oṣiṣẹ àjọ míràn ò ní ẹ̀tọ́ láti halẹ̀ mọ́ olùdìbò láti kúrò ní ibùdó ìdìbò, yálà nígbà tí wọ́n fẹ́ ṣẹṣẹ dìbò, lásìkò ìdìbò táti lẹ́yìn tí wọ́n ti ka ìbò.
Awọn olùdìbò ni ibùdó ìdìbò le darapọ̀ mọ́ àwọn oṣiṣẹ INEC láti ka ìbò láti ṣe ìdíkù iwa ìbàjẹ́. Olùdìbò lè ṣe ipenija àwọn òṣìṣẹ́ àjọ ìdìbò lórí ìwà àìtọ́. Ṣugbọn, olùdìbò ò gbọdọ̀ halẹ̀ mọ ọ̀ṣìṣẹ́ ètò ìdìbò láti yí ésì ìdìbò padà.