EconomyFact CheckYoruba

Irọ́ ni o! Àwọn ile-ifowopamọ wonyi ò da iṣẹ́ sílẹ̀

Getting your Trinity Audio player ready...

Ahesọ: Àjọ Nigeria Interbank Settlement System Plc (NIBSS) ti pàṣẹ fún àwon bánkì orile-ede Naijiria láti yọ ile ifowopamọ Opay, Piggyvest àti Palmpay kúrò nínú àwọn bánkì tí wọ́n lè fi owó ránṣẹ sí.

Irọ́ ni o! Àwọn ile-ifowopamọ wonyi ò da iṣẹ́ sílẹ̀

Àbájáde ìwádìí: Irọ́ ni! Atejade àjọ NIBSS kò mẹ́nuba bánkì mẹtẹẹta wọnyi. Kódà, Piggyvest àti Opay ti ṣàlàyé pé irọ́ ni ìròyìn náà. 

Ìròyìn lẹkunrẹrẹ

Àjọ NIBSS fi ìwé ranṣẹ sí àwọn ilé ifowopamọ orilẹ-ede Nàìjíríà, ó sì pàṣẹ pé kí wọ́n yọ àwọn ileeṣẹ kan ti àwọn èèyàn n lò láti fí san owó lórí ayélujára ‘Payment Service Solution Providers, Switches and Super Agents, kúrò nínú ikanni ifoworanse wọn. 

Àwọn ìkànnì ifoworanṣẹ náà ni lílo ààmì àṣírí (USSD), ẹ̀rọ POS, ATM àti ti orí ayélujára.

Àjọ NIBSS gbé ìlànà náà kale láti yọ ileeṣẹ ti awọn èèyàn ń lò láti fi san owó lórí ayélujára kúrò nínú ikanni ifoworanṣẹ wọn. Ni bayii, àwọn ileeṣe wọnyi lè fi owó ránṣẹ sí bánkì sùgbón wọn kò lè gba owó wọlé.

Ọpọlọpọ olumulo ìkànnì ibaraẹnisọrẹ àti àwọn ìkànnì míràn lori ayelujara lo fi ehonu wọn hàn lórí ọrọ yìí, wọn sì bèrè oun tó fàá ti ajo NIBSS fi gbé ìgbése yìí. 

Olumulo ikanni abeyefo (X) fi àwòrán kan sí ori oju òpó rè pe, ”Won yóò se iyokuro ile ifowopamọ Opay, Palmpay àti awon ileeṣẹ kan ti awọn eeyan n lo lati fi san owó lori ayelujara, kuro l’ori ikanna ifoworanse bánkì.” O tunbo ṣàlàyé wipe, “Ohun ti ijoba orilẹ-ede Nàìjíríà mọ láti ṣe ni kí wọn dùn mahuru mahuru mọ ọmọ ìlú. Ilẹ ifowopamọ Opay, Piggyvest àti Palmpay ti ṣe ohun pupo fún àwon omo orilẹ-ede Nàìjíríà pàápàá nígbà ti kó sí ọwọ pepa n’ita, o ṣe wa jẹ awọn banki wọnyi ni wọ́n fẹ́ kó kásẹ̀ nlẹ? Ìjọba féràn láti mú aye le fún àwon èniyàn.”

Orísirísi ọrọ ló tèlé atejade ti olumulo náà fi si ojú òpó rẹ; olumulo kan Frederick Eze sọ pe kìí ṣe òdodo ọrọ: “Awon banki wọnyi ò si lara wọn. É ṣe ìwádìí fínífíní kí e to fi ìròyìn sita.”

Olumulo miran, Ore-ọfẹ faramọ atejade náà, o ni, “Ijoba o mọ ju kí won fi ojú pọn awọn ara ilu.”

A ríi wípé atejade náà wà lórí àwọn ojú òpó kan lórí ikanni ibaraẹnisọrẹ Facebook, abeyefo X àti awon ìkànnì agberoyin kọọkan. 

Nítorí àríyànjiyàn to tẹ̀lẹ́ ọrọ naa, DUBAWA fi idi ododo múlẹ.

Ifidiododomule

DUBAWA ṣ’ayẹwo atejade àjọ NIBSS, a sí ríi wípé àjọ náà ṣe àgbéjáde àtòjọ ileeṣẹ ti awọn eeyan n lo lati fi san owo lori ayelujara. A wo awọn ileese meji lẹ lógbón ti wọn mẹnuba, kó sí Opay, Palmpay àti Piggyvest nínu rẹ. 

Irọ́ ni o! Àwọn ile-ifowopamọ wonyi ò da iṣẹ́ sílẹ̀
Àtòjọ bánkì ti NIBSS dárúkọ, Orísun àwòrán: Medium

Ilẹ ifowopamọ Moniepoint, Kuda, PiggyVest, Opay, Paga àti Palmpay ò si lori àtòjọ naa. Koda, àtòjọ ọ́ún mẹnuba awọn ileeṣẹ ti wọn kò tíì gbá ìwé àṣẹ láti bánkì àpapọ̀.

Lórí ìkànnì abẹ́yefò X, Opay ṣàlàyé pé, “A fẹ jẹ kó yé àwọn èèyàn pe atẹjade ajọ NIBSS ko ni nkankan ṣe pelu ileeṣẹ Opay. Ohun ti wọn n sọ niiṣe pẹlu awọn ileeṣẹ kan ti awọn eeyan n lo lati fi san owo lori ayelujara ‘Payment Service Solution Providers, Switches and Super Agents. Ileeṣẹ Opay ti gba àṣẹ láti ọwọ́ bánkì àgbà orílè-èdè Nàìjíríà CBN. Kó sí oun kankan to má sele sí owo yin.”

A túnbọ̀ ríi wípé ileeṣe PiggyVest sọ fun awọn onibara rẹ pe “Ọrọ ti ajọ NIBBS sọ kò ṣe ipalara kankan fun Palmpay. E ma ṣe naani ìròyìn ofege náà. Gbogbo akaanti àwọn oníbàárà wa lo wá ni sẹpẹ. Mimi kan ò ni mi owó yin.”

Lẹyin naa lo kede nọmba ibarasẹnisọrọ ti wọn le pe fun iranlọwọ.

Àjọ NIBSS ṣàlàyé ninu atejade rẹ pé àwọn bánkì ayélujára kọọkan lè fi owó ranṣẹ si awọn araalu amọ wọn kò le maa gba owó wọlé nítorí ó lòdì si òfin kí àwọn eniyan f’owo pamọ́ síbẹ̀.

Ìlànà náà woye bí awọn bánkì orilẹ-ede Nàìjíríà ṣe le yọ awon ileeṣẹ ti awọn èèyàn fi n san owó lórí ayélujára náà kúrò ni ara àwọn ilé ifowopamọ ti wọn le maa fowo ranṣẹ si kuro ninu ẹrọ wọn.

Sùgbón ọrọ yìí kó tabá Ileeṣẹ Opay, Palmpay àti PiggyVest.

Àkótán

Ileeṣe Opay, Palmpay àti Piggyvest kò sí lára àwọn ileese ti NIBSS pàṣẹ pé kí wọn yo kúrò  ni ara awọn ile ifowopamọ ti wọn le maa fowo ranṣẹ si. Ilana náà niiṣe pẹlu awọn banki ayelujara ti wọn kò ni onte tabi aṣẹ bánkì àpapọ.

Show More

Related Articles

Leave a Reply

Back to top button
Translate »