Aheso: Atẹjade akalekalo kan lórí ìkànnì ibaraẹnidọrẹ Facebook lo sọ wípé gbajúmọ̀ òṣèré tíátà Lateef Adedimeji ti di olóògbé.
Àbájáde ìwádìí: Irọ́ ni. Ìwádìí wà àti gbólóhùn tí a gbà sílẹ̀ lati ọdọ akẹgbẹ òṣèré tíátà náà, fihan pé irọ́ ni ọ̀rọ̀ náà.
Ìròyìn lẹkunrẹrẹ
Lateef Adedimeji je gbajú-gbajà òṣèré tíátà ọkùnrin, o sì ti gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ àmì ẹ̀yẹ nínú iṣẹ́ eré ìdárayá, o jẹ ọmọ ìlú Abeokuta ni ìpínlẹ̀ Ògùn. Láti ọmọ ọdún mẹẹdogun ni o sì ti bẹrẹ sí ṣe isẹ tíátà.
Ní ọjọ kẹta oṣu karun, olumulo ìkànnì ibaraẹnidore Facebook, Kabiru Usman, fi fónrán fídíò kan sí ojú òpó rè pé òṣèré tíátà náà ti di olóògbé. Ogbeni Kabiru lo àwòrán oṣere náà ni inú fonrán iṣẹju mokandilogun kan, o sì kọ ọrọ yìí sí ori fónrán naa “Sun re ooo, gbajú-gbajà òṣèré tíátà ti a mọ sí Lateef Adedimeji,” ti o fi daba pe eléré ìdárayá náà ti di olóògbé.
Awọn eniyan ti wo fónrán náà ni ọpọlọpọ igba, o le ni mílíọ̀nù kan. Nítorí bi aheso naa ti tànká, pàtàkì ọrọ náà àti ènìyàn ti ọrọ naa kàn, lo je ki DUBAWA wadii ọrọ naa.
Ifidiododomule
Ní ojú òpó gbajugbaja òṣèré náà lórí ìkànnì ibaraenisere Instagram, a ríi wipe o fi atejade kan sí bẹ ni ọjọ́ kẹrinla oṣù karun ọdún yii. Atejade naa so wípé, “Fi ogbon dahun sí iwa agọ̀.”
A ríi wípé atẹjade náà ló fi sí orí ìkànnì abẹ́yẹfò, gbajúmọ̀ òṣèré @TheDimejiLateef.
Ní ìgbá tí a ṣe itọpinpin kókó ọ̀rọ̀ lórí ìròyìn bóyá òṣèré náà kú, kò sí èsì lati ojúlówó ìwé ìròyìn kankan.
DUBAWA kàn sí Juliana Olayode, akẹgbẹ Ọgbẹni Lateef, tó sọ fún wa wípé kò sí oun kankan tó ṣeé.
“Kò kú o. Ki awọn ènìyàn yii fi òpin sí àwọn ọrọ agbasọ wọnyi. Irú radarada wo leleyii?” Arabinrin Juliana ló sọ báyìí.
Arabinrin naa ṣ’atunpin fónrán kan ti o ṣafihan oun ati Ogbeni Lateef ni ibi ètò eré ìdárayá kan ni ọjọ kẹrindilogun oṣù karun, ọdún 2023.
Àkótán
Ìwádìí wà ati gbólóhùn alabaṣiṣẹpọ Ogbeni Adedimeji fihan pé irọ́ ni iroyin naa. Òṣèré tíátà Adedimeji kò kú.