Fact CheckHealthYoruba

Iro ni o! Ọtí líle ò lè jẹ́ kí ǹkan ọmọkùnrin kéré

Aheso: Mímú ọtí líle lè jẹ́ kí ǹkan ọmọkùnrin kéré si.

Àbájáde ìwádìí: Irọ́ ni. Kò sí ẹ̀rí tí ó dájú ninu ìmọ sáyẹnsì pé ọtí líle lè jẹ́ ki ǹkan ọkùnrin kéré si.

Ìròyìn lẹkunrẹrẹ

Ọtí líle jẹ òun kan pataki ti àwọn ọmọ ènìyàn máa n fi gb’afẹ́ lati ayédáyé. Ọtí líle jẹ òun mímu ti o ni ethanol, o fere dàbí oògùn. Won máa n fi èso, wòrò irúgbìn àti àádùn ṣ’èdá ọtí líle.

Ọpọlọpọ ènìyàn l’agbaye lo máa n jẹ ìgbádùn ọtí líle. Ṣùgbọ́n, atẹjade kan ni ojú òpó olumulo ìkànnì abeyefo Twitter, Olami (@MaryamOlami) ṣàlàyé pe mímú ọtí líle lè jẹ ki ǹkan ọkùnrin kéré si.

Àwòrán atẹjade náà lójú òpó Olami.

Botilejepe ojú òpó Olami ò ṣiṣẹ mọ lórí ìkànnì yìí, ṣáájú àsìkò yìí, ọpọlọpọ awọn ènìyàn ti ká atejade náà.

Ojú òpó Olami ò ṣiṣẹ mọ lórí ìkànnì abeyefo 

Nítorí ipa tí ọrọ náà le ko lórí ọrọ ìlera l’awujọ lo fàá tí DUBAWA fi se ìwádìí ọrọ náà. Àti wípé, o ṣéeṣe ki àwọn ènìyàn máa k’ẹgan àwọn ọkùnrin ti ǹkan ọmọkùnrin wọn kéré tàbí ki wọn se asopọ rẹ pẹlu mímú oti líle. 

Ifidiododomule

Ti ọmọkùnrin ba ti bàlágà, ǹkan ọmọkùnrin rẹ̀ máa tóbi si. Wọn máa n lo fún ìbálòpọ̀, wọn sì máa fi n tọ̀. Ìwé ìròyìn Medical News Today ṣàlàyé pé ìsúnkì ǹkan ọmọkùnrin ni ki o kéré síi.

Ìwádìí imo sáyẹ́nsì lórí Ibaṣepọ to wà láàrin ǹkan ọmọkùnrin ati ọtí mímu èyí ti National Library of Medicine gbejade fihan pé, mímú ọtí líle lapọju jẹ òun kan gbòógì ti wọn máa fi n ṣe idanimọ ọkunrin ti ǹkan ọmọkùnrin re ko se déédé. Ìwádìí náà dá lé orí ọgọrun ọkunrin ọmuti paraku ti wọn ko sí àgọ atúnwàṣe. 

Ìwádìí na filelẹ pé mímú oti líle lè ní ipa búburú lórí Ibalopọ láàrin okunrin ati ololufẹ rẹ ṣugbọn ko mẹnuba ìsúnkì ǹkan omokunrin gẹgẹbi ìkan lára re.  

Àjọ Sexual Medicine Society of North America gba ni nímọ̀ràn pé mímú oti líle fe ṣokunfa ìdákọ́lẹ̀ ǹkan ọmọkùnrin nítorí ọ le dènà ẹjẹ ṣiṣan sí inú ǹkan omokunrin. Àmọ́sá, èyí o tunmọ sí pé ǹkan ọmọkùnrin máa súnkì. Àti wípé, orisirisii ǹkan ló lè ṣokunfa iwọn ǹkan ọmọkùnrin, ara wọn ni ajogunba, ọjọ́ orí, ìlera ara ati igbe ayé. 

Ìwádìí míràn lórí ipa ti ọtí líle nko lori ǹkan ọmọkùnrin fihàn pé mímú oti amupara le jẹ ki awọn omoonu kankan maa ṣiṣe deede, èyí a fa idinku omoonu ọkunrin eyi ti a mo sí testosterone, ti máa n fa idakole nkan omokunrin. 

Atẹjade yii lati ile iwosan Mayo Clinic, sagbekale rẹ pe mímú oti ni iwonba le se anfaani fún nkan omokunrin. Ṣugbọn ìwádìí náà kò filelẹ pé mímú oti líle lo n mu ǹkan ọmọkùnrin súnkì.

Ọrọ àwọn onimọ 

David Thomas, eni tí o jẹ onimo nipa arun ọpọlọ àti ọkan salaye pé tí ènìyàn bá mu ọtí líle, o ma wọ inú ikùn ni ibi ifun yóò sì wo inú ẹjẹ lọ. Onimọ náà ṣàlàyé pé ìwúrí nínú ọpọlọ ni o máa n je ki nkan omokunrin dìde. Ọpọlọ máa sọ fun ǹkan ọmọkùnrin ki o sinmi, eyi yóò jẹ kí ẹjẹ ṣan wọ inú nkan ọmọkùnrin ti o máa fi dide tabi sanra si.

Tumi Motsei, alakoso ọja ni Sanofi salaye pe ọtí líle lè ṣe ibaje sí ẹya ẹ̀ṣọ́ ara. Ti ọkunrin ba ti mu ọtí amupara, o le ṣe àkóbá fún Ìbálòpọ̀ ati àwọn omoonu ọmọkùnrin.

Onimọ nipa ilẹ ìmọ ijinlẹ, Onoja Onoja, ninu ìfòròwánilénuwò pẹlu DUBAWA salaye pé kò sí ẹrí tó dájú ninu ìmọ sayensi pe mímú ọtí líle lè mú kí ǹkan omokunrin sunki. 

Àkótán 

Kò sí ẹrí tó dájú ninu ìmọ sayensi pe mímú ọtí líle lè mú kí ǹkan omokunrin súnkì. Botilejepe mímú oti amupara le se ijamba fún Ibalopọ laarin lọkọ-laya, pẹlu ki nkan omokunrin ma lee dide soke, amosa oti líle ò lè mú kí ǹkan ọmọkùnrin kere si. 

Show More

Related Articles

Leave a Reply

Back to top button