Fact CheckPoliticsYoruba

Irọ́ ponbele ni! Ọ̀gbẹ́ni Tinubu ò fún ẹnikẹni ni owó kankan fún ayẹyẹ iburawọle sí ipò ààrẹ

Ahesọ: Ọgbẹni Bola Tinubu n pin ẹgbẹrun lọnà ogún náírà fún àwọn ènìyàn ṣaaju ayẹyẹ iburawọle sí ipò ààrẹ. 

Àbájáde ìwádìí: Irọ́ ni. Ìwádìí wà fihàn pé kò sí oun tó jọ bẹẹ. Agbẹnusọ ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress sọ wípé kò sí òtítọ́ nínú ọ̀rọ̀ náà. 

Ìròyìn lẹkunrẹrẹ

Atejade kan ti o tànká orí ikanni ibaraẹnisọrọ WhatsApp gbé aheso kan pé Ọgbẹni Bọla Tinubu, eni tí a ṣẹṣẹ dìbò yan sí ipò ààrẹ lorile-ede Nàìjíríà, n pin egberun lọnà ogun náírà fún àwọn ènìyàn ṣáájú ètò iburawọle tí yóò wáyé ní ọjọ́ ajé, ọjọ́ kokandinlogbon oṣù kàrún. 

“Asiwaju Bola Ahmed Tinubu fẹ ṣe ìtọre àánú ẹgbẹrun lọnà ogún náírà fún gbogbo ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, èyí ni lati gboriyin fún wọn lori bi wọn ṣe fi ìbò gbe wọlé,” atejade naa ló sọ báyìí. 

Ní igbẹyin atẹjade yìí, àwọn olumulo ni lati tẹle linki ti yóò gbé wọn lọ aaye ayelujara kan, ki wọn mọ bóyá wọ́n ni ẹ̀tọ́ si owó náà. 

Ọgbẹni Tinubu tí ó jẹ́ oludije sí ipò ààrẹ ni abẹ àsìá ẹgbẹ òṣèlú APC, gbégbá orókè ní ìdíje naa léyìn ti àjọ elétò ìdìbò kéde pé o rí ìbò mílíọ̀nù mẹjọ, o le díẹ̀.

Ni ọpọlọpọ igba, àwọn ètò owó iranwọ ti won sope oloselu tabi gbajú-gbajà oniṣowo lo seda rẹ, la ti rí tí o jẹ́ àrékérekè tàbí irọ́. 

Ìtànkálẹ̀ iroyin náà, bí olóṣèlú náà ṣe gbajumọ to, àti wípé a kò fẹ ki ẹnikẹni faragba jìbìtì, èyí ló jẹ ki a ṣe ìwádìí lórí ọrọ yi.

Ifidiododomule

Ni ìgbà ti a tẹle linki náà, ti a sì fi alaye nipa ara eni síi, atẹjade kan wọle si orí ẹrọ ibaraẹnisọrọ wa pé kí a ṣ’atunpin linki náà pèlú àwọn ọrẹ wa mẹẹdogun ati àkójọpọ̀ ènìyàn máàrún. Eyi jẹ àmì àpẹẹrẹ nla pé ayédèrú ní atẹjade náà àti wípé àwọn oni jìbìtì máa n saba fi gba àlàyé nípa ènìyàn sílẹ̀.

Àwòrán ààyè ayélujára náà. 

Bakan naa, ni igba tí a ṣe àyẹ̀wò finnifinni lórí ààyè ayélujára náà, a ríi wipe, awọn onijibiti náà fẹ ṣẹ̀tàn àwọn ènìyàn lati gbagbọ pe ori ikanni ibaraẹnidọrẹ Facebook ni awọn itakuroso náà ti wa. Sugbon, a ri ìyàtọ̀.

Lórí ìkànnì ibaraẹnidọrẹ Facebook, oun tó ṣáájú ni aami ‘feran’, aami ‘dahunsi tabi fèsì’ tẹle, ààmì to ṣafihan àkókò ti a fi atẹjade ranṣẹ lo gbẹyin. Ṣùgbọ́n lórí ààyè ayélujára yìí, ààmì àkókò lo sáájú, ti ààmì ‘feran’ sí tẹle, ‘dahunsi’ lọ gbẹyin. 

Ọrọ ìwòye lori ìkànnì ibaraẹnidore àti orí ààyè ayélujára náà.              

A tún ṣe ìwádìí lórí àwọn oríṣiríṣi ojúlówó ìwé ìròyìn tí ó wà lorile-ede yii, ko sí ìròyìn náà lórí ikankan nínú wọn. 

A kàn sí agbẹnusọ ẹgbẹ́ òṣèlú APC Felix Morka, o sì sọ fún wa pé irọ́ pọnbele ni atẹjade náà. 

Àkótán

Ìwádìí wà ati èsì agbẹnusọ ẹgbẹ́ òṣèlú APC fihàn wípé iro ni ọrọ naa. 

Show More

Related Articles

Leave a Reply

Back to top button