Facebook ChecksFact CheckSecurityYoruba

Iroyin ofege àti aṣinilona gbòde kan lẹyin ìbúgbàmù to ṣẹlẹ ni Ibadan

Getting your Trinity Audio player ready...

Láìpẹ́ yìí, ìbúgbàmù kan mi Bódìjà ni ibile ariwa tí Ibadan, ìpínlè Óyo. Ninu atejade kan, agbẹnusọ ọlọ́pàá ipinlẹ, Adéwálé Oyefeso sàlàyé pé iṣẹlẹ náà wáyé nì àgó mẹjọ kù isẹju merindinlogun ni ọjọ́ kerindinlogun oṣù kini ọdún 2024.

Àwọn olùgbé ìlú ti o jìnà díẹ̀ sí Bódìjà bíi Eleyele (12.67km), Ologuneru (9km), Mokola (7km), ati Akobo (9km), pẹlu àwọn ibòmíràn, ṣàlàyé lorí Facebook, oró ti ìbúgbàmù náà dà l’agbegbe wọn.

Gomina ìpínlẹ̀ Óyo, ogbeni Seyi Makinde sàlàyé pé àwón ènìyàn kan fi àdó olóró  àtọwọ́dá pamọ́ sí ilè wọn, èyí tó ṣokunfa ìbúgbàmù, ti o pa ènìyàn márùún, àwọn ènìyàn mẹtadinlọgọrin sì farapa.

Makinde fi awon ènìyàn lọkàn balẹ pé eto idoola ẹmi ṣi n tẹ siwaju ati wipe ìwádìí n lọ lórí iṣẹlẹ náà, o sí ṣe ileri pé ijọba ipinlẹ naa yóò san owó itọju awon ènìyàn to f’arapa.

Iroyin ofege gbòde kan

Ènìyàn kan to ba DUBAWA sọrọ, arabinrin Adebimpe Fọláṣadé, sọ wípé òun ríi wípé àwọn oju òpó kọọkan lóri ayelujara n fi iroyin ofege sita lori iṣẹlẹ náà, pẹlu awon aworan ti o bani lẹru.

Aheso àkọ́kọ́: Gaasi ìdáná lo fa ibugbamu náà

L’ori ikanni ibaraẹnisọre Facebook, olumulo kan ti ọ pe ara re ni ‘Docktor Ment’ sọ wípé gaasi ìdáná lo fa ìbúgbàmù naa. O túnbọ̀ sọ wípé ilé ìtajà ìgbàlódé, Ace Mall ti dáwo, lẹyìn ibugbamu to l’agbara ọ̀ún.

Ó sọ wípé, “Olorun lo mò bí ibi ti iṣẹlẹ náà ti waye gangan yóò ṣẹ rí bayii nitori ibugbamu gaasi idana náà mile titi kódà ni ibí to jina sí ilu ti o ti sele, o l’agbara gaan oooo.”

Iroyin ofege àti aṣinilona gbòde kan lẹyin ìbúgbàmù to ṣẹlẹ ni Ibadan

Abajade iwadii: Irọ́ ni. Ileese gaasi idana ti olumulo náà n tọka sí ni Gasland Nigeria Limited ti o wá ni ìlù Bódìjà. Yato sí ohun ti àwọn ẹlẹrìí oṣojumi sọ fún DUBAWA, ileese gaasi náà fí atejade kan sita ní ibi ti wọn ti fi awon oníbàárà won lọkàn balẹ pé kó sí òún to jọ bẹẹ.

“Ise n lọ deede ni ileese wà, sugbon a woye ijamba ti ibugbamu náà ti da sile, a sí kedun pẹlu awon ti ọrọ náà kan, ṣugbọn ibugbamu náà ko ti ọ́dọ̀ wa wá,” atejade Gasland ló ṣàlàyé èyí.

Aheso keji: ìbúgbàmù náà sẹlẹ̀ ni òpópó-ònà Aderinola

Olumulo ikanni ibaraẹnisọre Facebook Oladele Ìdòwú Joseph sọ wípé òpópó-ònà Aderinola ni ìbúgbàmù náà ti waye.

“Isele náà kii ṣe ìbúgbàmù gaasi. Ko ṣẹlẹ ni ileese Gasland, kìí sí ṣe Samonda. Ibugbamu nla ni, o sí ṣẹlẹ ni òpópó-ònà Aderinola ni ilu Bódìjà, ní báyìí, a kò tíì mó oun ti ṣokunfa,” akọsilẹ olumulo náà loju òpó rẹ ni èyí.

Iroyin ofege àti aṣinilona gbòde kan lẹyin ìbúgbàmù to ṣẹlẹ ni Ibadan

Abajade iwadii: Irọ́ ni. Nínú atejade agbenuso olopaa ilu náà, ati nínu àlàyé Gomina ipinle naa, a ríi daju wipe ibugbamu náà wáyé nì òpópó-ònà Dejó Oyeleso. Biotilẹjẹpe áwọn òpópó-ònà méjèèjì wọnyi wa ni ilu Bódìjà, ona jin sí ra, ni iwọn ibusọ meji tàbí maili kan.

Iroyin ofege àti aṣinilona gbòde kan lẹyin ìbúgbàmù to ṣẹlẹ ni Ibadan
Orísun àwòràn: Google map.

Aheso kẹta: Ẹ̀rọ apinnaka (transformer) lo ṣokunfa ìbúgbàmù náà

Olumulo ikanni ibaraẹnisọre Facebook, Oyindamola Okuneye sọ wípé ẹ̀rọ apinnaka (transformer) lo gbana ti ọ sí ṣokunfa ibugbamu to wáyé.

Iroyin ofege àti aṣinilona gbòde kan lẹyin ìbúgbàmù to ṣẹlẹ ni Ibadan

Abajade iwadii: Irọ́ ni. Alaye Gomina ipinle naa fihan pé àdó olóró IED ti awon awakusa gbe pamo lọnà aito lò ṣokunfa ìbúgbàmù náà.

Aheso kẹrin: Ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ènìyàn ló kú nínú iṣẹlẹ náà.

Leyin wakati diẹ ti iṣẹlẹ náà wáyé, arakunrin kan l’ori ikanni abeyefo X, Oga Yenne (Uyo Influencer) [@ogayenne] béèrè pé ṣé lootọ ni pe eedegbeta ènìyàn ló jade laye latarii ibugbamu ọ̀ún.

O sọ wípé, “Mo lero pé àwón ènìyàn Ibadan wa ni alaafia. Ṣe lootọ ni wípé eedegbeta ènìyàn ló ti gbémi mi léyìn ti ibugbamu náà wáyé?

Iroyin ofege àti aṣinilona gbòde kan lẹyin ìbúgbàmù to ṣẹlẹ ni Ibadan

Abajade iwadii: Irọ́ ni. Ni ìgbà ti a fi ìròyìn yii sita, èèyàn márùún ni ijoba ìpínlè sọ wipe wọ  padanu emi won, ni ìgbà ti awon metadinlogorin sí farapa.

Aheso karun: Ènìyàn kan fi àwòrán ṣàpèjúwe oun to ṣẹlẹ ni ilu Ibadan.

Olumulo ikanni abeyefo X, The Cruise TV [@the_cruisetv], leyin to gbe aheso pé ileese gaasi idana ni Ibugbamu naa ti bú jade, o tun fi aworan kan si oju opo re pe láti ibi isele naa ni, kódà ó rọ àwọn olumulo miran ki wọn satunpin àwòràn naa ki ọpọlọpọ ènìyàn lè ríi.

Iroyin ofege àti aṣinilona gbòde kan lẹyin ìbúgbàmù to ṣẹlẹ ni Ibadan

Abajade iwadii: Aṣinilona ni òrò yìí. Itopinpin àwòrán lateyinwa fihàn pé àwòrán ti olumulo náà pin loju òpó rẹ̀ ti wà lori ayelujara lati oṣu kẹsan odún 2014. Kódà, àyẹ̀wò wa fihan pé aworan naa ti wa lori ayelujara saaju asiko náà.

Akotan

Biotilẹjẹpe orisirisii ìròyìn ofege àti aṣinilona ni awon ènìyàn gbe kaakiri ayelujara lori iṣẹlẹ náà, alaye ìjọba fi múlẹ̀ pe ado olóró atọwọda IED ti awon awakusa gbé pamọ́ lọna àìtọ́ lò ṣokunfa ìbúgbàmù naa ni òpópó-ònà Dejó Oyeleso. Ní báyìí, ènìyàn márùún ti jáde láyé, àwọn metadinlogorin sí ti farapa.

Show More

Related Articles

Leave a Reply

Back to top button