Facebook ChecksFact CheckHealthYoruba

Kò sí ẹ̀rí tó dájú pé akọ aláǹgbá le wo ikó-ife

Getting your Trinity Audio player ready...

Àhẹ̀sọ: Ẹnìkan tó dá sí  ètò rédìò kan ṣọ pé jíjẹ akọ aláǹgbá le wo àrùn ikọ́-ife. 

<strong>Kò sí ẹ̀rí tó dájú pé akọ aláǹgbá le wo ikó-ife</strong>

Ábájáde: Ìwádìí láti ọwọ́ àwọn oníṣègùn òyìnbó fì dí rẹ̀ mú lẹ̀ pé kò sí àrídájú pé jíjẹ akọ aláǹgbá le wo àrùn ikó-ife. Ófégé ni ọ̀rọ̀ náà.

Àlàyé Lẹ́kùńrẹ́rẹ́

Ẹnìkan tó dá sí ẹ̀tò rédìò kan “Ìlèèra Lọrọ̀” lórí  Diamond 88.5FM, Iléṣà, Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun ṣọ pé jíjẹ akọ aláǹgbá le wo àrùn ikó-ife. Ó tèsíwájú pé kí ẹni tí àrùn ikọ́-ife yọ lẹ́nu pa akọ  aláǹgbá kó din, kó sì jẹ́, àrùn ikọ́-ife yóò sàn. 

Àwọn ènìyàn  tó lé ní mílíọ́nù mẹ́ta ló ń tẹ́tísí ètò yìí nìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun, tí àwọn tí wọ́n lé ní mílíọ́nù mẹ́fà sì ń gbọ́ ní àwọn ìpínlẹ̀ tó sún mọ́ ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun.

Gẹ́gẹ́bí àjọ elétò ìlẹ̀ẹ̀ra lágbààyé, WHO, ṣe wí, àrùn ikọ́-ife ló pa àwọn èèyàn tó tó 1.3 million lọ́dún 2022. 

WHO tèsíwájú pé àrùn ikó-ife ṣe é wò, tó sì le sàn. Àrùn ọ̀hún ni àwọn èèyàn lùgbàdì nígbà tí wọ́n bá ṣe alábápàdé itó tàbí atẹ́gùn tó wá láti ọ̀dọ àwọn èèyàn tí wón ní àrùn ikó-ife.

Ìfìdíòdodomúlẹ̀

Ìwádìí àwọn oníṣègùn òyìnbó fì’dí rẹ̀ mú lẹ̀ pé àwọn ògùn tó le pa kòkòrò aìfojúrí (antibacteria) ni àwọn oníṣègùn òyìnbó  lò látí ṣe ìtọ́jú àrùn ikó-ife.

Wọ́n sàlàyé pé lílo ògùn ọ̀hún fún ǹǹkan bí oṣù mẹ́fà nìkan ni àrùn ikó-ife tó le sàn. 

DUBAWA kàn sí Dókítà Akíntúndé Ibrahim, ẹ̀ka ìtọ́jú àyà nílé ìwòsàn olùkóni Fáṣitì Ọbáfẹ́mi Awólówọ̀, Ilé-Ifẹ̀, Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun lórí ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀. 

Ó wípé “àwọn oníṣègùn òyìnbó kò ní àrídájú pé jíjẹ akọ aláǹgbá le wo àrùn ikó-ife, gbogbo èèyàn tó bá ní ikó-ife  kó tètè gba ilé ìwòsàn lọ fún ìtọ́jú tó péye kí àrùn ọ́hún tó pọ̀ lára rẹ̀”. 

A tún kàn sí Dókítà Dèjì Gbàdàmósí, ilé ìwòsàn ìjọ́ba  Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun, Asúbíaró, Òsògbo, ẹ̀ka ìtọ́jú àyà àti ikó-ife, tó ti ṣe ìtọ́jú àrùn ikó-ife fún ǹǹkan bí ogún ọdún, lórí ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀, ṣàlàyé pé irọ́ ni pé jíjẹ akọ aláǹgbá le wo àrùn ikọ́-ife. 

Gbàdàmósí tèsíwájú pé “ọ̀rọ̀ ẹnu lásán ni pé jíjẹ akọ aláǹgbá le wo àrùn ikó-ife, ẹnikẹ́ni tó bá ní àrùn ọ̀hún, kó tètè lọ ṣe àyẹ̀wò àti ìtọ́jú ní’lé ìwòsàn”. 

DUBAWA tún kàn sí Arábìnrin Ọdúnayọ̀ Òní, òṣìṣẹ́ nọ́ọ́sì àti adarí ẹ̀ka ìtọ́jú ikọ́-ife àti ẹ̀tẹ̀ ìjọ́ba ìbílẹ̀ ìlàoorùn Ilésà Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun, lórí ìbánisọ̀rọ̀ ṣàlàyé pé kò sí àrídájú pé jíjẹ akọ aláǹgbá le wo àrùn ikó-ife. 

Òní tèsíwájú pé “kòkòrò aìfojúrí bacteria ló fa ikọ́-ife, tí jíjẹ akọ aláǹgbá kò le wo sàn, ẹnití ó bá ní àrùn ikó-ife  kó lọ sí lé ìwòsàn fún ìtọ́jú”. 

Àkótán

Àhèsọ pé jíjẹ akọ aláǹgbá le wo àrùn ikó-ife jẹ́ ófégé tó le si àwọn èèyàn lọ́nà.

The researcher produced this fact-check per the DUBAWA 2024 Kwame KariKari Fellowship, in partnership with Diamond 88.5 FM Nigeria, to facilitate the ethos of “truth” in journalism and enhance media literacy in the country.

Show More

Related Articles

Leave a Reply

Back to top button