HealthMedia LiteracyYoruba

Wíwádìí àwọn àròsọ nípa ìlera ọkàn ati ọpọlọ

Ìlera ọkàn ati ọpọlọ je ipo ọkan ènìyàn yálà bí a ṣé ń ronú, hu ìwà tabi ìṣesí wa.

Botilẹjẹpe ọpọlọpọ ènìyàn ti ń sọrọ nípa ìlera ọpọlọ laye t’awa, oríṣiríṣi àròsọ tí ó jẹ́ irọ́ àti aṣinilọna lo wọ́pọ̀ lórí ọrọ náà, ti o sì n fa abuku fún àwọn to ni àìlera ọpọlọ ni orile-ede Nàìjíríà. Àkọsílẹ̀ yii mẹnuba díẹ lára àwọn àròsọ wọnyi, o sì fi ìdí òdodo múlẹ̀.

Àròsọ àkọ́kọ́: Àbuku ìlera ọpọlọ ò wọ́pọ̀ láwùjọ 

Wíwádìí àwọn àròsọ nípa ìlera ọkàn ati ọpọlọ

Àbájáde ìwádìí: Irọ́ ni

Devora Kestel, ẹni tí ó jẹ́ adarí ẹka tí ó ń rísí ìlera ọpọlọ ni àjọ ìlera l’ágbayé WHO, sọ ninu ọrọ re pe àbuku ìlera ọpọlọ wọ́pọ̀ ni gbogbo orilẹ-ède àgbáyé. Ṣugbọn ó ṣe ni laanu pé, ètò ìlera àti àwùjọ ẹ̀dá ò kọbi ara sí ọrọ náà ni àwọn orilẹ-ede míràn. 

Ìwé ìròyìn Punch gbé ìròyìn pé ilé ìwòsàn to wà fún ìtọ́jú àwọn alárùn ọpọlọ ní ìpińlẹ̀ Eko ṣe itọju aláìsàn tó lè ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbàrin-lé-ní-ọ̀kẹ́-mẹ̀ta-àbọ̀ ni ọdún 2022 nikan. Kódà, gbogbo àwọn tó gba ìtọ́jú yíì wá láti ipinle kan. 

Ni ọdún 2019, àjọ WHO ṣ’àlàyé pé laarin eniyan mẹjọ láwùjọ, eniyan kan ni àìlera ọpọlọ. 

Ni ọdún 2019 kanna, ìròyìn bẹ sílè pé àìlera ọpọlọ ti wọ́pọ̀ lorile-ede Nàìjíríà, lẹyìn ti ilé ìwòsàn to wà fún ìtọ́jú àwọn alárùn ọpọlọ ní ìpińlẹ̀ Eko se igbawọle awọn aláìsàn tó ṣẹṣẹ ni àìlera ọpọlọ. Ìròyìn naa ṣàlàyé pe eniyan kan ninu awọn mẹrin ni orilẹ-ede Nàìjíríà lo ni ààrùn ọpọlọ sugbon ko sí iranwọ fún wọn nítorí kò sí owó àti àwọn onímọ̀ to lè ṣe itọju. 

Ni ọdún 2016, akọsilẹ kan ti àjọ WHO gbejade ṣàlàyé pé orilẹ-ede Nàìjíríà ni àwọn ènìyàn ti n gba ẹ̀mí ara wọn jù. O kéré jù, ẹ̀ẹ́dẹ́gbàásàn-án ọmọ orile-ede yii lo gbẹmi ara wọn, yala ọmọdé tabi agbalagba.

Onimọ nípa ìlera ọkàn, olukọ ati oludasile ilé-isé Psychebabble Foundation, Sandra Anyahaebi, ṣàlàyé pé àfikún ti wa lórí iye ènìyàn to ni àìlera ọpọlọ, kódà àwọn ènìyàn tó n lo òògùn olóró ti lé ní ilopọ àádọta.

Ìwádìí kan ti awọn onimọ gbe jade ní ọdún 2016 ṣ’agbekale rẹ̀ pé àwọn ọmọ orileede Nàìjíríà ni wọ́n ní ìsoríkọ́ jù ni ilẹ̀ Áfíríkà. Nínú èèyàn mílíọ̀nù mọkandilogun ti o ni ìsoríkọ́ ni ile adulawo, mílíọ̀nù méje jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.

Àròsọ Kejì: Mi o le ni ààrùn ọpọlọ tabi ibanuje ọkàn/ ìsoríkọ́

Wíwádìí àwọn àròsọ nípa ìlera ọkàn ati ọpọlọ

Àbájáde ìwádìí: Iro ni

Kò sí eniyan ti kò lè ni ààrùn ọkan tàbí ọpọlọ. Àtẹ̀jáde kan lati àjọ WHO lori ọrọ ìlera ọpọlọ ṣàlàyé pé orísirísi ènìyàn, ìdílé, àwùjọ eniyan àti awọn òkùnfà míràn lo lẹ parapọ dá sí ìdáàbòbò ìlera ọpọlọ eniyan tabi fa ibanuje okan. 

Botilẹjẹpe àwọn ènìyàn míràn lè borí àwọn òkùnfà wọ̀nyí, àwọn ẹlòmíràn ní ìṣòro ìṣẹ́ tàbí òsì, ìwà ipá, àìlera àti aidọgba, irúfẹ́ ènìyàn bẹẹ wà ní ewu. Kódà ipò ọkàn ati ara ẹni le niiṣe pẹlu awọn ewu wọnyi. 

Àròsọ kẹta: Awọn ènìyàn tó ní àìlera ọpọlọ máa n sábà ní ìwà ipá tàbí wọ́n ti ya wèrè 

Wíwádìí àwọn àròsọ nípa ìlera ọkàn ati ọpọlọ

Àbájáde ìwádìí: Aṣinilọ́nà ni ọrọ náà 

Àjọ àwọn olutọju àìlera ọpọlọ ni ilu Amẹrika, American Psychiatric Association (APA) ṣe atẹjade lórí àpẹẹrẹ àìlera ọpọlọ, kò sì sí ounkóun tó farajọ iwa ipa tabi wèrè ninu rẹ̀. 

Arabinrin Anyahaebi f’idi re múlẹ pé àwọn ènìyàn tó ní ààrùn ọpọlọ lè fi ìwà ipá hàn lẹẹkọọkan, ṣugbọn kìíse gbogbo ìgbà ni èyí máa ń ṣẹlẹ̀.

“Awon ènìyàn tó ní àìlera ọpọlọ lè fi ìwà ipá tàbí agídí hàn, ṣùgbọ́n kìíse gbogbo ìgbà ni èyí máa ṣẹlẹ̀.

“Ti a bá sọ pé ‘wèrè’, èyí jẹ àbuku àti ọrọ èébú, kódà, àwọn onímọ̀ ìlera ọpọlọ kii lo ọrọ náà mọ, nítorí ni ọpọlọpọ ìgbà, àwọn ènìyàn tó ní àìlera ọpọlọ tàbí ọkàn, máa n sá fún iranlọwọ tàbí kí wọ́n dáké,” onimọ náà ló sọ èyí. 

Nínú ìròyìn TheCable ni ọdún 2022, ààrẹ àjọ àwọn olutọju àìlera ọkàn ni Nàìjíríà, Taiwo Obindo sọ pé ó lé ní ọgọfa mílíọ̀nù ènìyàn tó ní àìlera ọpọlọ ni orílè-èdè Nàìjíríà ṣùgbón èyí kò túmọ̀ sí pé wọ́n ya wèrè. 

Àkọsílẹ̀ kan láti ori ààyè ayélujára Better Health, ti eka to n mojuto ọrọ ìlera ni ijoba orile-ede Australia ṣàlàyé pé ailera ọpọlọ bíi rudurudu ti ọpọlọ (schizophrenia) lè fa ìwà ipá. 

Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn tí wọ́n ní rudurudu ọkàn ò lè ṣe ẹwu fún àwùjọ ti wọ́n bá gba ìtọ́jú tó pé, tí wọ́n kò si mu ọtí amupara tàbí lo òògùn olóró lọnà àìtọ́.

Àwọn ènìyàn wọ̀nyí, àkọsílẹ náà ṣàlàyé, pé wọn lè fi ìwà ipá hàn, tabi fi ehonu wọn hàn sí àwọn ẹbí ati ore wọn, sugbon wọn á yàgò fún ara ìta. 

Àkọsílẹ náà ṣàlàyé pé àwọn oun kan maa n mu àìsàn náà buru si. Díẹ lára àwọn nkan wọ̀nyí ni: àìrí ìtọ́jú tó péye, aláìsàn tó ti fi ìwà ipá hàn sẹyìn, lilọ oògùn olóró lọnà àìtọ́ àti ọtí amupara, aibalẹ ọkàn, ki eniyan  ni àìlera ọkàn ní ìgbà akọkọ tabi àwọn ìrírí tí kò bójú mu. 

Àròsọ kẹrin: Iporuru ọkàn lè fa ikú 

Wíwádìí àwọn àròsọ nípa ìlera ọkàn ati ọpọlọ

Àbájáde iwadii: Irọ́ ni

Àjọ ìsọ̀kan tí ń mójútó ìnáwó pàjáwìrì fún àwọn ọmọdé, United Nations Children’s Fund (UNICEF) ṣàlàyé Iporuru ọkàn gẹgẹ bi ẹ̀ẹ̀rù ati aifọkanbalẹ lẹyìn iṣẹlẹ kan paapaa ti irufẹ oun tó ṣẹlẹ ba jẹ nkan tó le gan-an tàbí tó mú wàhálà dání.

Àkọsílẹ iwe ìròyìn Medical News Today ṣàlàyé pe iporuru ọkàn lè dá ẹ̀rù ba ènìyàn ṣugbọn kò mú ikú dání. Àmọ́ṣá, ó lè fa ìjàmbá fún ìlera ènìyàn gẹgẹbi ìwádìí kan tí wọ́n ṣe ní ọdún 2005 ṣe wí. Ìwádìí náà ṣàlàyé pé iporuru ọkàn le mu ki ipò ọkan ènìyàn buru si pàápàá nínú àwọn ènìyàn tó ní àìsàn ọkàn tẹlẹ.

Oludasile ilé iṣẹ́ Psychebabble Foundation náà ṣàlàyé pé iporuru ọkàn ò lè fa ikú ṣugbọn o ṣeéṣe kí ó la ẹ̀mí lọ, tí aláìsàn bá ní àwọn àìsàn míràn. 

“Iporuru ọkàn o le fa ikú, botilẹjẹpe ti ènìyàn bá ní iporuru ọkàn, o máa dà bíi pé wọ́n fẹ kú ṣugbọn ipò yìí ò lè pa ènìyàn. Iporuru ọkàn ò lè pa ènìyàn, àyàfi tí onitọun bá ní àisàn míràn.”

Àròsọ kàrún-un: Àwọn ọmọdé ò lè ní ìṣòro àìlera ọpọlọ 

Wíwádìí àwọn àròsọ nípa ìlera ọkàn ati ọpọlọ

Àbájáde ìwádìí: Irọ́ ni

Àjọ WHO ṣ’àlàyé pé ìpín ogún àwọn ọmọdé lágbayé àti àwọn ọmọ tí wọ́n ti bàlágà ni wọ́n ní àìlera ọpọlọ. Kódà àwọn èèyàn tí wọ́n jẹ ọmọ ọdún mẹẹdogun sí mokandilogbon ń gba ẹ̀mí ara wọn. Ìwádìí míràn láti àjọ APA ṣ’agbekale rẹ̀ pé àìlera ọpọlọ máa ń saba bẹrẹ ni ọmọ ọdún mẹrinla. 

Àròsọ kẹfà: Àwọn ènìyàn tó ní àìlera ọpọlọ ò lè ṣe iṣẹ́ tàbí gbé ìgbé ayé tó dára 

Wíwádìí àwọn àròsọ nípa ìlera ọkàn ati ọpọlọ

Àbájáde ìwádìí: Irọ́ ni

Àjọ tó ń dásí ọrọ àìlera ọpọlọ láwùjọ,  National Alliance on Mental Illnesses (NAMI), sọpẹ àìlera ọpọlọ kìíse oun tó lè fa ikọsẹ l’ẹnu iṣẹ ẹni kódà nínú àwọn iṣẹ́ míràn, àìlera ọpọlọ máa ń jẹ kí ènìyàn ṣe àṣeyọrí. 

Àjọ náà ṣàlàyé pe ọpọlọpọ awọn ètò ni wọ́n ti ṣ’agbekalẹ rẹ̀ láti ṣe iranwọ fún àwọn ènìyàn tí ó ní ààrùn ọpọlọ, rí iṣẹ́  gidi, ki wọn sì ṣe dáadáa l’ẹnu iṣẹ́. 

Àkọsílẹ míràn láti ilẹ́ ìwé Academy of Management Insight ṣ’àlàyé pé àìlera ọpọlọ miran ni oun kan ṣe pẹ̀lú iṣẹ́ aladaani.

Arabinrin Anyahaebi sọ pé irọ́ ni àròsọ náà, ó ní òun mọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn tó ní àìlera ọpọlọ ṣùgbọ́n wọ́n ṣe dáadáa l’ẹnu iṣẹ́.  

“Mo mọ àwọn ènìyàn tí wọ́n jẹ́ olùdarí ilé iṣẹ́ tí wọn sì ní àìlera ọpọlọ. Mo mọ àwọn ènìyàn ti wọ́n jẹ́ ọ̀gá ni ibi iṣẹ́ tí wọn sì ní àìlera ọpọlọ. Nitori náà, a ni láti ṣe àgbéyẹ̀wò àṣà àti ìṣẹ́ wa láwùjọ,” arábìnrin náà ló sọ èyí.

Àròsọ keje: Àwọn ènìyàn tó ní ààrùn ọpọlọ jẹ aláìlágbára, wọn kò sí lè ṣe ipinnu fúnra wọn.

Wíwádìí àwọn àròsọ nípa ìlera ọkàn ati ọpọlọ

Àbájáde ìwádìí: Irọ́ ni

Àkọsílẹ àjọ UNICEF ṣ’àlàyé pé tí ènìyàn bá ní ailera ọpọlọ, ko ni nkankan se pelu jíjẹ aláìlágbára tàbí ki ènìyàn má lè ṣe ìpinnu.

Arabinrin Anyahaebi faramọ́ oun tí àjọ UNICEF sọ, onimọ náà sọ wípé àwọn ènìyàn tí ó ní àìlera ọpọlọ ò kìíṣe aláìlágbára.

Àròsọ kẹjọ: Àìlera ọpọlọ jẹ àisàn kògbóòògùn

Wíwádìí àwọn àròsọ nípa ìlera ọkàn ati ọpọlọ

Àbájáde ìwádìí: Aṣinilọna ni ọrọ náà 

Botilẹjẹpe kòsí ìwòsàn fún àwọn àìlera ọpọlọ míràn bíi rudurudu ọkàn, arábìnrin Anyahaebi sọ pé èyí kò túmọ̀ sí pé wọ́n jẹ́ kògbóòògùn tàbí títí láé.

“Mo ní láti sọ pé irọ́ ní ọrọ yìí nítorí àwọn àìlera ọpọlọ kan wà ti kò sí iwosan fún. Ṣugbọn, ó ṣàlàyé pé o ni awọn ọna kọọkan ti wọn le gbà ṣe itoju awọn iṣoro ìlera ọpọlọ ṣùgbọ́n kò sí ìwòsàn fún ààrùn ọpọlọ míràn,” arábìnrin náà ló sọ èyí.

Ilé ìwòsàn Agape Treatment Centre ṣ’àlàyé pé kò sí ìwòsàn fún àìlera ọpọlọ ṣùgbọ́n itọju wà. Ilé ìwòsàn náà fi kun pé àwọn ènìyàn tí wọ́n ní ààrùn ọpọlọ lè lajáá, wọ́n sì lè ní ẹ̀mí gígùn bíi àwọn ènìyàn tó ní ààrùn itọ̀ ṣúgà. 

Àròsọ kẹsán: Ìfi àkókò ṣòfò ní ìtọ́jú 

Wíwádìí àwọn àròsọ nípa ìlera ọkàn ati ọpọlọ

Àbájáde ìwádìí: Irọ́ ni

Lára àwọn ìtọ́jú àìlera ọkàn tí ìmọ̀ sáyẹ́nsì gbekalẹ ni lílo òògùn, ìtọ́jú ní ilé ìwòsan, ọ̀nà ìṣẹgun míràn, iranwọ ara-eni, iranwọ ojugba. 

Àjọ kan tí a mọ̀ sí Substance Abuse and Mental Health Service Administration (SAMHSA) ṣàlàyé pé ìtọ́jú àìlera ọpọlọ tàbí ọkàn dálé irufẹ ènìyàn ti aláìsàn jẹ́. Ó ṣe pàtàkì kí á ṣ’afiyesi pé àwọn ẹlòmíràn máa tètè já ajabọ tí ó bá rí iranwọ ojugba lásìkò ìtọ́jú. 

Kódà, olùdásílẹ̀ ilé-isé Psychebabble Foundation sọ pé wíwá ìtọ́jú tàbí iranlọwọ kìíse ìfi àkókò ṣòfò. 

Àròsọ kẹwa: Àwọn ènìyàn tó ní àìlera ọpọlọ jẹ ẹlẹmi aimọ 

Wíwádìí àwọn àròsọ nípa ìlera ọkàn ati ọpọlọ

Àbájáde iwadii: Irọ́ ni 

Oríṣiríṣi oun ló lè ṣokunfa ìlera tàbí àìlera ọpọlọ fún ènìyàn. Fún àpeere, ipò tàbí ẹdun ọkan, ìbí àti àwọn oun míràn lo nìikan ṣe pẹ̀lú ìlera ọpọlọ ènìyàn. Ẹlòmíràn le máa lo òògùn olóró, jíìnì àti àwọn oun míràn lè jẹ́ kí àwọn ẹlòmíràn ní ìṣòro ọpọlọ.  

Arabinrin Anyahaebi sọ wípé tí a kò bá lè ṣ’àpèjúwe ènìyàn tí ó ní ìju tàbí egbò ara gẹgẹbi ènìyàn tó ní èmí àìmọ́, kò sí ààyè fún wa láti tọkasi ènìyàn tó ní àìlera ọpọlọ gẹgẹbi ènìyàn tó ní èmí àìmọ́.

“Rara. Ṣé ó ṣeéṣe kí a ṣàpèjúwe ènìyàn tó ní ìju tàbí ènìyàn tí wọ́n gé ìká rẹ̀ torí egbò adaajina, gẹgẹbi ènìyàn tó ní èmí àìmọ́? Rara.

“Eniyan tó ní àìlera ọpọlọ kìí ṣe ènìyàn tó ní èmí àìmọ́. Bí a ti ṣ’àlàyé, oríṣiríṣi ǹkán ló lè ṣokunfa àìlera ọpọlọ.”

Àkótán

Ìṣòro àìlera ọpọlọ wọ́pọ̀ láwùjọ, ó sì ṣe pàtàkì kí gbogbo ènìyàn mú ọrọ yìí l’okunkundun. Bí ìwọ tàbí ẹnikẹni lagbegbe rẹ bá ní ìṣòro àìlera ọpọlọ, tètè bèrè fún ìrànlọ́wọ́. Ọpọlọpọ ilé-isé ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ni wọ́n máa n ṣe ìrànlọ́wọ́ fún àwọn tó ní àìlera ọpọlọ, bíi Mental Health Foundation Nigeria, Mentally Aware Nigeria Initiative, ati Psychebabble Foundation.

Show More

Related Articles

Leave a Reply

Back to top button