Ọjọ́ rọ̀ ni mo ṣ’abapade arabinrin Bella, ọmọ ọdún mẹrindinlọgbọn, o ṣẹṣẹ de lati ile ìtura Tuco’s Palace Hotel, ile ìtura kan to wa ni ilu Ogba ni ipinle Eko, lati se iṣẹ́ aṣéwó. Ori àtẹ̀jiṣẹ́ telegram ni Bella ti bẹrẹ iṣẹ́ yi ni ọdún 2023, ọ̀rẹ́ rẹ kan lo fi ona yii han-an. Ni osu kerin ọdún 2025, Bella ti mọ iṣẹ́ aṣéwó naa se daadaa. iṣẹ́ aṣéwó ti awon kan a maa pe ni ‘hookup’ tabi oloṣo tumọ si ki eeyan maa ni ibalopọ fun owó.
Ilé ìtura Tùcó Palace máa n gba àwọn aṣéwó láàyé kí wọ́n rìn ní gbérigbé ilé ìtura náà. Àwọn okunrin a wa ra ọtí, leyin naa, won a gbe aṣéwó wọ yara fun ibalopọ, eyi je ona kan ti ile ìtura naa a fi ri owó sii. Lagabaye, iye iṣẹ́ aṣéwó le ni bilionu mẹ́rìndínláàdọ́wàá owó dola laarin odun kan, orileede Naijiria ni a tii rii ipin mefa owó naa,

Gbajúmọ̀ ni arabin Bella jẹ́ ni ilé ìtura Tuco’s palace. Gbogbo awon eniyan lo mo, ti won si fe ba ni gbolohun. Laarin iseju die ti a wo ile ìtura yii, Bella ti ni onibaara okunrin ti o fe ba ni ibalopo. Awon mejeeji joko si ẹgbẹ́ arawon lai f’ohun, niwaju won igo oti joko sori tabili, won mu siga lowo.
Ijoko mi ko jina si ibi ti Bella wa ninu yara igbafe ile ìtura yii. Ore mi kan lo mu mi mo Bella lale ojo naa, o si fun mi ni nomba ero ibaraenisoro. A bere sii ni gbolohun lori ero ibaraenisoro Whatsapp lori iriri re ninu iṣẹ́ aṣéwó paapaa lori àtẹ̀jíṣẹ́ Telegram.
Bella maa n ri onibaara lati ẹgbẹ́ kan ori àtẹ̀jíṣẹ́ Telegram, ti won pe oruko re ni “Obawole, Ogba, ati Iju Ishaga.” Awon ẹgbẹ́ miiran ti le ma fi oro bii ‘hookup’ tabi oloso sinu apejuwe won ki eeyan le tete mo iru iṣẹ́ ti won se, sugbon ẹgbẹ́ yii ko ni iru oro bee.

Oruko ẹgbẹ́ yii ni oruko agbẹgbẹ́ ti o wa ni ijoba ibile Ifako-Ijaiye ati Ikeja ni ipinle Eko. Awon agbẹgbẹ́ naa sunmo ara won, oun ti won si n se lori awon ẹgbẹ́ wọ̀nyí ni ki onibaara ati aṣéwó ni agbẹgbẹ́ kan naa pade arawon.

Awon ẹgbẹ́ wọ̀nyí kii se gbogbo eeyan lo le debe, nitori naa ko si ona ti ara ita se ma mo oun to n lo nibe. Telegram gba olumulo laaye lati da ẹgbẹ́ sile pelu omo ẹgbẹ́ oke mewaa leekan naa awon eyan si ni aye lati satunpin aworan ati fonran. Awon omo iya kanna, Pavel ati Nikolai Durov lo s’eda àtẹ̀jíṣẹ́ Telegram ni osu kejo odun 2013. Ni odun to koja, ikanni yii ti ni to iye olumulo bilionu kan. Orisi oun elo ibaraenisoro lo pejo sori àtẹ̀jíṣẹ́ naa. Oun elo kan ti kii je ki ara ita le mo oun to n lo ninu ẹgbẹ́ kan lo gba awon enikan laaye lati da ẹgbẹ́ aṣéwó sile lori ikanni yii.
Bella ran mi lowo lati dara po mo ẹgbẹ́ aṣéwó lori Telegram, o si ko mi bi mo se le tete sabapade onibaara, o gba ero ibanisoro mi, o si ko awon oro wọ̀nyí si ori ikanni naa.
“Ti e ban wa eniyan ti o ma ba ni ni ibalopo fun igba die tabi loru moju, mo le ba yin se ere idaraya lopolopo,” Bella siju lati bere lowo mi pe nje mo mo ere idaraya se ninu ibalopo, mo so fun wipe mo mo se. O fi da mi loju pe mo ma bere sii ri onibaara lori awon ẹgbẹ́ wọ̀nyí. Ko paro. Awon onibaara bere sii fi àtẹ̀jíṣẹ́ ranse si mi. Awon miran tile bere sii pe mi lori ero ibanisoro mi pe won nilo ibalopo.
Bella kilo fun mi pe kii yera fun arakunrin kan lori ikanni naa ti o maa n gba owó lowo awon omo ẹgbẹ́. Oruko arakunrin naa ni Cattea.

Won ti n fi ero igbalode gbe aṣéwó fun onibaara
aṣéwó miran ti mo ṣ’abapade ni ile ìtura Tuco’s Palace naa kilo fun mi pe ki n yera fun Cattea. Oun naa wa lori ẹgbẹ́ aṣéwó yii ni Telegram ki Cattea to yo kuro nitori ko san “idamewa.” Oruko arabinrin yii ni Bibire. Bibire so fun mi wipe oun san ẹgbẹ́run meji naira lati je omo ẹgbẹ́ yii. O fi eri han mi pe looto oun san owó fun Cattea.
O salaye pe isoro oun bere ni igba ti Cattea bere sii bere owó loorekoore, o si hale mo oun pe, oun a yo kuro ninu ẹgbẹ́ naa. Ti Cattea be se bee, Bibire o ni le ri onibaara. O ni oun fun arakunrin naa ni ẹgbẹ́run kan naira leemeji, oun si dawo duro. Cattea yo kuro ninu ẹgbẹ́ naa.
Ella Johnson, omo ẹgbẹ́ yii naa salaye iyanje ti o ti dojuko lenu iṣẹ́ aṣéwó yii, bi o tile jepe ipenija tire ko ti owó Cattea wa. Ella wa ni awon ẹgbẹ́ miran ti o maa ba awon aṣéwó wa onibara ni orisirisi agbẹgbẹ́ ni ilu Eko. ẹgbẹ́ yii maa n gbe aṣéwó pade onibaara ni awon agbẹgbẹ́ olola ni ipinle Eko. Ella so wipe oun san ẹgbẹ́run mewa naira fun awon alakoso ẹgbẹ́ wọ̀nyí lati darapo mo ẹgbẹ́ naa: @lekkibeach, @ibejuLekki ati @ajahconnect. Laarin ose kan, alakoso ẹgbẹ́ naa yo Ella kuro ninu ẹgbẹ́ yii, o ni ki o mu aadorin ẹgbẹ́run owó naira wa ki o to le lo ikanni oun.

Ella so fun mi wipe ni opo igba, tokotaya ni awon alakoso ẹgbẹ́ aṣéwó lori ikanni Telegram fun agbẹgbẹ́ awon olola. Awon tokotaya yii gbagbo pe ko si oun kan to le se won, won a si maa yan awon eyan je.
“Oro yii n da mi lori ru, lenu ojo meta yii,” Ella lo so bee.
Yato si pe awon alakoso ẹgbẹ́ ti yan Ella je, arabinrin yii ti dojuko ipenija lenu iṣẹ́ aṣéwó yii. Ni igba miran, awon kan ti ja kule, won ti fi eebu ara bu, awon miran si ti naa. O salaye pe ni igba kan, oun san ogbon ẹgbẹ́run naira lati wo moto lo ba onibaara sugbon onibaara naa ko wa. Ni igba kan, Ella so fun onibaara kan ki o san
Biotilejepe awon aṣéwó bii Ella ni orisirisi idojuko lenu iṣẹ́ aṣéwó naa, awon alakoso awon ẹgbẹ́ wọ̀nyí ri obitibiti owó latari pe won da ẹgbẹ́ naa sile. Yato sii pe won maa n bere owó loorekoore lowo awon aṣéwó wọ̀nyí, ni se ni won maa n gba owó fun iforukosile lori awon ikanni wọ̀nyí. Ni igba ti Ella fe darapo mo ẹgbẹ́ aṣéwó @ajahconnect, ẹgbẹ́run mewa naira pere lo san, ni igba ti mo fe darapo mo ẹgbẹ́ naa, alakoso so pe ki n san ẹgbẹ́run marundilogoji. Omo ẹgbẹ́ ẹgbàajọ lo wa lori ẹgbẹ́ naa.
Awon ẹgbẹ́ alaṣéwó ti won yo kuro lori ikanni Whatsapp gbile sori ikanni Telegram
Ikanni Telegram gba awon eeyan laaye lati se idasile ẹgbẹ́ aṣéwó lorisirisi, opolopo irufe ẹgbẹ́ bayii lowa lori ikanni yii jakejado orileede Naijiria, koda iru ẹgbẹ́ naa wa ni ile eko giga. Mo ri ẹgbẹ́ eerindinlaadorun.

Koda, awon ẹgbẹ́ miran kuro lori ikanni WhatsApp lo ori ikanni Telegram. Okan lara awon ẹgbẹ́ naa ni Olosho Connect Naija ni ibi ti awon okunrin maa bebe lati je eru ibalopo, ti awon obinrin a si ma ta fonran ibalopo won. Awon omo ẹgbẹ́ kookan a maa fi ipolongo pe won wa o sere sinima onibalopo ati ibasepo awon transgender — awon ti won yi iseda won pada.

Arakunrin Henry Okinmoye Otareh, eni ti o je alakoso ẹgbẹ́ yii salaye pe ni igba kan ri, ẹgbẹ́ naa wa lori ikanni Whatsapp, sugbon Whatsapp fofin de, nibayi, ẹgbẹ́ naa fe di gbajugbaja ẹgbẹ́ aṣéwó kaakiri Naijiria.
“A fe ki awon eniyan lati gbogbo ilu ni orileede Naijiria darapo mo ẹgbẹ́ yii, lati ipinle Eko, Port Harcourt, Asaba, Owerri, Enugu, Umuahia, Uyo, Calabar,” Henry lo so eyi, ti o si ra owo ebe si omo ẹgbẹ́ ki won satunpin linki ẹgbẹ́ naa, si gbogbo eeyan, koda awon eniyan ni ilu kekere ati ileto.
Opo igba ni won ti se iyipada oruko ẹgbẹ́ Olosho Connect Naija ki won to wa fowo mu eleyi to ba alakoso ẹgbẹ́ naa lara mu.

Alakoso ẹgbẹ́ yii a ni ki awon okunrin san ẹgbẹ́run marun naira si nomba ile ifowopamo re, awon aṣéwó a maa san ẹgbẹ́run meta naira si ẹgbẹ́run ogun.

Lori ikanni yii, obinrin gbodo fi ara re han gege bi aṣéwó. Fun idi eyi, mo fi aworan mi ati ojo ori mi ranse si June Din, alakoso ẹgbẹ́ naa. Laarin iseju maruun, June ti so mi di ogbontarigi aṣéwó lori ikanni naa. Eyi tunmo sii pe awon okunrin le bere sii pe mi fun ibalopo.

Mo bere lowo June pe iṣẹ́ abo wo ni won se fun awon aṣéwó lori ikanni naa, o si so fun mi pe ko si oun to jo bee.
“iṣẹ́ olosho ni eyi, ko si aabo fun enikeni. Wa ma se abapade awon eniyan ti o ti riri laiye e, ewu to wa nibe niyen,” June so eyi fun mi, mo si bere sii sokun.
Biotilejepe ko si eto aabo kankan fun awon omo ẹgbẹ́ ti won se iṣẹ́ aṣéwó, awon alakoso ẹgbẹ́ rii daju pe won daabobo ẹgbẹ́ naa. Lori ikanni yii, o ko le ya aworan itakuroso lori ẹgbẹ́ naa, eniyan o si le se igbasile oun kankan lati ori ẹgbẹ́ naa. Won lo imo atowoda (AI), ChatKeeperbot lati rii daju pe awon ifiranse kan o de ori ẹgbẹ́ naa, won si n lo Safeguard, eto aabo kan fun ẹgbẹ́ naa. Ti aṣéwó ba n ba onibaara soro lowo, ti o si gbiyanju lati se igbasile aworan itakuroso oun, ero Safeguard yi a fohun sita. Oun kan to ya wa lenu ni wipe, o ko le fi ejo ẹgbẹ́ naa sun ikanni Telegram.
Iroyin ofege gbode kan, awon alakoso ẹgbẹ́ n lo aworan ihoho obinrin fun ipolongo
Arakunrin Henry, ninu ohun ti a gbasile, so aheso pe, iṣẹ́ aṣéwó je iṣẹ́ ajogunba lagbaye, o si fikun pe ko si oun kan to ma dojuko ẹgbẹ́ naa.
Sugbon itan ko wa pe, imo ero ni iṣẹ́ adayeba, ti awon eniyan n se lati odun milionu meji seyin. Arakunrin Rudyard Kipling ni o koko gbe aheso pe iṣẹ́ aṣéwó je ajogunba, ni sẹnturi kọkandinlogun sẹyin nigba ti o awon eniyan se ariyanjiyan.
Henry tun so aheso pe awon obinrin a gbadun ibalopo nigba ti okunrin ba san owó fun, pe opolopo obinrin ni o maa n beru ni asiko ibalopo, nitori ofin ti maa n poju laarin awon ololufe. Sugbon, Elizabeth Adewale, eni ti o je dokita olutoju awujo ati onimo nipa ibalopo so pe iro ni oro ti Henry so, “fun opolopo obinrin, won kii b’eru ni asiko ibalopo.”
Yato si iro kabiti kabiti ti Henry pa, nise ni o maa n s’atunpin aworan ihoho obinrin lori ikanni Telegram. Fonran ihoho mesan ni Henry gbe si oju patako re lori ikanni Telegram. Akosile yii, ‘mo ni awon obinrin kaakiri orileede Naijiria ti won le ba o ni ibalopo.” Mo gbiyanju lati se iwadii lori okan lara awon fonran naa ti o safihan obinrin kan to da bi agunbaniro to wa ni ihoho omo luabi. Won ko fi oun kan bo oju re ni.”
Itopinpin aworan ateyinwa lori ero Google fihan pe Henry mu fonran naa lati ori aaye ayelujara kan ti won ti maa n satunpin fonran ibalopo tabi ihoho obinrin. A ko ni fi oruko ẹgbẹ́ naa si ibi yii.
Olumulo ikanni ibaraenisore Facebook ti satunpin fonran yii ni ojo keta, osu kefa odun 2024. Olumulo to satunpin fonran yii, Kopala chimz fi aworan omije bo oju ara omobinrin yii. Mo kan si Facebook ki won se iyokuro fonran yii sugbon won ko se be. Oun ti won salaye ni wipe, fonran naa ko bojumu fun awon omode.

Kiise ipolongo iṣẹ́ aṣéwó nikan ni Henry n se, arakunrin yii a ma gbe awon obinrin fun iṣẹ́ aṣéwó lo si oke okun. Okan lara awon àtẹ̀jíṣẹ́ re ni ojo ketadinlogun osu keji odun 2025 lo bayii,
“Ti o ba fe lo si ilu Ghana fun iṣẹ́, kan si mi ni bayi!” Leyin wakati die, Henry tun te àtẹ̀jíṣẹ́ miran pe, “Ti o ba le lo fun iṣẹ́ aṣéwó igba ranpe ni ilu Calabar ti o si le se ere idaraya ibalopo daadaa, kan si mi. A nilo re ni kiakia.”
Mo kan si henry nipa iṣẹ́ aṣéwó ni Ghana, o si se ileri lati fun mi ni esi.
Egbẹ́ alaṣéwó pelu emi pupo
Ilana Telegram ko gba enikeni laaye lati se oun ti ko ba ofin mu ni ilu won. Awon nkan bayi ni ki eniyan maa lo omode ni ilokulo, ki eniyan maa ta tabi ra oja ti ko to.”
Mo te àtẹ̀jíṣẹ́ si Telegram ni ojo kejidinlogun osu kinni odun 2026 lori oun ti Olosho Connect Naija n se ti ko ba ofin ikanni naa mu, ati wipe kini oun ti Telegram n se si iru awon ẹgbẹ́ yii.
Biotilejepe Telegram o fesi si àtẹ̀jíṣẹ́ mi, won se iyokuro ẹgbẹ́ yii lori ikanni won ni ojo kejilelogun osu kini odun 2026.

Sugbon, ko tan s’ibe. Leyin ose kan, arakunrin Henry si ẹgbẹ́ miran lori Telegram pelu oruko kanna ti o si satunpin linki ki awon eniyan darapo mo. Niroti o da mi mo gege bi ojulowo aṣéwó, o fi àtẹ̀jíṣẹ́ ranse si mi pe kin darapo mo ẹgbẹ́ naa.

Ajafunetoomoniyan paapaa fun awon obinrin, Oluwafunmbi Ogunsola gba ni nimoran pe, yato si pe Telegram se iyokuro awon ẹgbẹ́ wọ̀nyí, ikanni naa gbodo se ikilo fun awon alakoso ẹgbẹ́ pe ki enikeni ti o ba se ese kanna leemewa, o seese ki won yo iru eni be kuro lori ikanni na patapata.
“Telegram ni lati mojuto awon ẹgbẹ́ wọ̀nyí ki won si rii daju pe awon alakoso naa ko bere ẹgbẹ́ miran. Ti awon alakoso ẹgbẹ́ aṣéwó ba ru ofin ikanni naa, ki won fi ofin de won ki won ma le lo ikanni naa titi lailai,” Oluwafunmbi lo so eyi.
Ofin wa, sugbon agbofinro ka’woko
Ofin ti o de iwa odaran ni ariwa orileede Naijiria ko fi aaye gba iṣẹ́ aṣéwó. Ni apa guusu orileede wa, ofin lodi si ki eniyan maa gbe obinrin lo fun iṣẹ́ aṣéwó, abala 223, 224 ati 225 iwe ofin naa lo satileyin oro yii. Ara awon nkan ti ofin ko faramo ni ki eniyan maa pese yara tabi aaye fun okunrin lati gbe aṣéwó, tabi ki eeyan maa ko awon obinrin ni iṣẹ́ aṣéwó. Christiana Longe, eni ti o je amofin ati osise ni ile iṣẹ́ Centre for Journalism Innovation and Development, salaye pe ẹgbẹ́ Olosho Connect Naija ti ru abala 222, 223 ati 224 ti iwe ofin.
Awon ofin miran bii Trafficking in Persons (Prohibition) Enforcement and Administration Act, ofin ti orileede Naijiria se lati dẹ́kun títà ènìyàn, fipá mú iṣẹ́, àti ìfipá-banilòpọ̀ pelu ofin agbaye ti o fe fi òpin sí gbogbo ọnà tí a ń gbà kórira àwọn obìnrin (CEDAW), ko gba enikeni laaye lati j’àǹfààní latari pe obinrin kan se iṣẹ́ aṣéwó, ofin yii dena awon eniyan ti o gbe obinrin lo fun iṣẹ́ aṣéwó, awon ti o ni ile aṣéwó ati awon ti maa n ta eniyan.
Ki owo ofin le tete te Henry ati June, mo fi ejo Olosho Connect Naija sun Godwin Eyake, eni ti o je olori ajo to n gbogun ti fifi ẹtan tabi ipa ko awọn eeyan lati ilu kan lọ sibomi-in, ‘Nigerian Agency for the Prevention of Trafficking in Persons’, (NAPTIP ti ipinle Cross River. Koda mo fi linki ẹgbẹ́ naa ranse ki awon agbofinro le maa sakiyesi oun to n lo lori ẹgbẹ́ naa. Mo si bere igba ti won a gbe igbese lori esun naa.
Iyalenu lo je fun mi nigba ti arakunrin Godwin so pe awon ẹgbẹ́ naa ko se ese kankan. Sugbon o salaye pe ti obinrin kankan ba le wa fi esun iyanje kan won, bii ifipa gba owó iṣẹ́ re, ti elomiran si na iwi naa ni awon to le gbe igbese. O fikun wipe ajo naa le gbe igbese ti okan lara awon to n gbe obinrin fun iṣẹ́ aṣéwó ba bere sii hale mo awon aṣéwó naa, ti o ba bere sii so pe oun a fi ihoho won han gbogbo aye.
Amofin, Dogo Joy so pe ipin keji abala ofin 223 ati ipin B abala ofin 225 ti salaye lekunrere ijiya to to si awon eniyan to n gbe obinrin lo fun iṣẹ́ aṣéwó, bi won ko tile je anfaani kankan latibe.
“Ofin o so pe onitoun gbodo je anfaani owó kankan lati iṣẹ́ aṣéwó, enikeni ti o ba ni ile aṣéwó gbodo dokujo ijiya to to,” amofin Joy lo so eyi, “yala ile aṣéwó ti won ko s’ori ile tabi eyi ti o wa lori ayelujara”.
Amofin Joy fikun pe ijiya ofin yii ti kuro lasa nitori ati opo odun seyin ni won se ofin yii. Arufin a san ogoruun naira tabi ki o lo si ewon osu mefa tabi ijiya mejeeji. O ni o ti to akoko fun ijoba Naijiria lati se atunyewo awon ofin to niise pelu ese iyanje obinrin.
Ajo NAPTIP se ileri lati gbe igbese
Leyin ti ajo NAPTIP ipinle Calabar ko lati gbe igbese, mo fi esun kan olu ile iṣẹ́ ajo naa latari àtẹ̀jíṣẹ́ email. Ijeoma Mary Amugo, ẹnìí tí ó jẹ́ olùdarí ẹ̀ka tí ó n rí sí ofin ni àjò náà, ṣo pé àwọn ẹgbẹ́ náà ti rù fin. Ninu esi re, ajo naa se ileri lati rii wipe awon to n risi iwa ibaje lori ayelujara maa se iwadii won.
Prisca Iwendi, eni ti o je ajafunetoomo obinrin parowa si NAPTIP ki won gbe ajo kekere kan sile ti o maa sayewo ati iwadii lori awon ẹgbẹ́ aṣéwó ti o wa lori ayelujara. O ni o se pataki ki won mojuto awon ile ìtura ti won gbekale gegebi ile aṣéwó.
Anna Fisher, oludasile Nordic Model Now, ile iṣẹ́ kan to n gbiyanju lati dena iṣẹ́ aṣéwó lagbaye, so wipe o se pataki ki Telegram gbiyanju sii lati f’opin si iṣẹ́ aṣéwó lori ikanni naa.
“Awon ẹgbẹ́ ori ayelujara wọ̀nyí ti fikun iṣẹ́ aṣéwó lawujo,” Anna lo so eyi. “A gbagbo pe ona kan soso ti won le fi dekun tita ati rira omo eniyan ni ki a se iyokuro awon ẹgbẹ́ wonnyi lori ikanni ibaraenisoro ati lori ayelujara patapata.”
Ni ojo ketalelogun osu keta, awon alakoso egbe asewo Olosho Connect Naija bere sii lo ero oye atowoda (artificial intelligence) ti won pe ni Ban Protector lati se idamo awon oniroyin ninu egbe naa, ki o si yon won kuro. Leyin ojo merin, ni ojo ketadinlogbon osu keta, atejise Telegram gbesele akanti mi lori ikanni naa, esun ti won fi kan mi ni pe won fura pe mo fi atejise ranse si awon eniyan ti ko bere fuun, nitori naa, n ko le se iwadii ise asewo lori ikanni naa siwaju sii.