
Ìròyìn lẹkunrẹrẹ
Ọpọlọpọ ànfààní lo wa lara èso apálá/kùkúńbà, èso náà ko ni kálórì púpọ ṣùgbọ́n ó ní àwọn èròjà ajíra bíi Vitamin C, Vitamin K, eroja asaraloore (protein), eroja amarajipepe (magnesium), èròjà potassium àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀lọ.
Iwon ipin mẹ́rìndínlọ́gọ́rùn-ún omi ló wà nínú eso kùkúńbà. Ilé-isé HealthLine gba ìmọ̀ràn pé ki ènìyàn máa jẹ èso yii bi ọlọrun ti ṣ’èdá rẹ̀, nítorí ti a ba bo, èyí yóò se idinku awon èròjà ajira to wa nínú rẹ̀.
Láìpẹ́ yíí, olumulo ìkànnì ibaraẹnisọre Facebook, Afedo Ojo ṣ’atunpin àwòrán to ṣ’afihan ọpọlọpọ ànfààní to wa lara èso apálá/ kùkúńbà. Ànfààní náà pọ rẹpẹtẹ, èyí lo fàá ti a fi ṣe ìwádìí.
Ọ̀rọ̀ ìlera àwujọ ṣe pàtàkì, ati wípé ìròyìn ti awon ènìyàn bá n kà lori ayélujára lè ṣe ìjàmbá tàbí ànfààní fún ìlera ara wọn, èyí lo fàá ti a fi gbìyànju lati fi ìdí òdodo múlẹ̀.
Ọ̀rọ̀ kini: Wọ́n lè fi èso apálá/ kùkúńbà ṣe itọju òkúta inu kíndìnrín
Òkúta inu kíndìnrín ni àwọn oloyinbo ń pè ní renal calculi, nephrolithiasis tàbí urolithiasis. Èyí máa n saba wáyé ti iyọ̀ bá sá pamọ́ sí inú kindinrin. Kódà, ìtọ̀ ènìyàn a máa hó bíi ìgbà ti wọn da ọṣẹ sínu ẹ́. Òkúta inu kindinrin le ṣe ìjàmbá fún ẹ̀yà títọ̀ ara, èyí ni eya ara ti o nṣẹda, sepamo ati samukuro ìtọ̀ (lati orí kíndìnrín sí apootọ).
Summit Medical Clinic ṣàlàyé pé àwọn ounjẹ kọọkan máa n ba ènìyàn fọ okúta kíndìnrín dànù. Àwọn ounjẹ wọ̀nyí ni apálá/ kùkúńbà, elégédé, seleri, parsley ati bẹẹbẹẹlọ.
Atẹjade OnlyMyHealth ṣàpèjúwe àwọn ànfààní to wa lara èso apálá/ kùkúńbà, bíi omi, èròjà anti-oxidant, nitrate àti àwọn mìíràn ti ọ máa n dena okuta inu kíndìnrín.
Dókítà ti o jé onimọ nipa ìlera kíndìnrín, Ivan Porter ṣ’alaye fún Mayo Clinic pé ki a yàgò fún oun to le fa òkúta inu kíndìnrín, ki eniyan sí je ẹfọ ati èso ti o ni omi lọpọlọpọ bíi èso elégédé/bara olómi, tomaati, apálá/ kùkúńbà, èyí ko le jẹ ki òkúta dúró sí inú kindinrin.
“Awon èso wọ̀nyí ò ni jẹ ki òkúta farahan nínú kindinrin.”

Abajade iwadii: Aṣinilona ni èyí.
Èso apálá tàbí kùkúńbà ni omi púpọ̀ l’ara, èròjà nitrate ati èròjà anti-oxidant ti ọ máa n ba ní fọ okúta inu kindinrin kúrò, o sí le dènà òkúta yii sugbọn kò le yọ ọ.
Ọ̀rọ̀ kejì: Èso apálá/ kùkúńbà le ṣe itọju ààrùn jẹjẹrẹ.
Àkọsílẹ Cancer Centre for Healing ṣàlàyé pé èso kùkúńbà ni akopọ àwọn eroja aṣaraloore inú èso kùkúńbà bíi anti-oxidant, ajíra, mineral, fibre ti o lè satileyin ìlera ara, ti kò si ni si àárun jẹjẹrẹ l’aagọ ara.
O tun ṣàlàyé síwájú pé èso apálá/ kùkúńbà ni awon kemika kan bíi lignans ati phytochemical (cucurbitacin) ti o le ba ni gbógun ti awon sẹẹli to n fa ààrùn jẹjẹrẹ.
Atẹjade International Journal of Health Services, fihàn pé kemika cucurbitacins le ṣe iranwọ fún ènìyàn lati dekun ààrùn jẹjẹrẹ nípasẹ ṣíṣe idena fún sẹẹli jẹjẹrẹ.
Kódà, ìwádìí kan ti wọn ṣe ni ọdún 2022 l’órí èso apálá/ kùkúńbà inú òkun fihàn pé ẹyà èso yii le gbogun ti ààrùn jẹjẹrẹ sùgbọ́n won ni látí ṣe ìwádìí sí.
Ìwádìí yii fihàn pé ó ṣeéṣe ki wọn fi ẹyà èso apálá tàbí kùkúńbà yìí dènà ààrùn jẹjẹrẹ nínú àgọ ara ènìyàn lójó iwájú.

Àbájáde ìwádìí: Aṣinilona ni òrò náà.
Biotilẹjẹpe èso kùkúńbà le gbogun ti awon sẹẹli to n fa ààrùn jẹjẹrẹ, èyí o túmọ sí pe won lè fi ṣe itọju ààrùn jẹjẹrẹ.
Ọ̀rọ̀ kẹta: Kùkúńbà lè wo ọgbẹ́ inú sàn.
Èso kùkúńbà wà lára èròjà ti Kvings Australia ń fi sí inú elerindodo ti wọn fi n se itọju ọgbẹ́ inu. Àwọn èròjà inu èso naa máa n gbogun ti ọgbẹ́ inú ikùn ati duodenal ulcers, ọgbẹ́ tó wà ní ibi tí oúnjẹ ń gbàá kọjá.
Ìwádìí ti Science Direct gbé jáde ní ọdún 2017 fihàn pé àwọn ounjẹ kọọkan bíi èso kùkúńbà ni antacidi, oun ti o máa jẹ ki awon èyà ikùn ṣisẹ́ dáadáa, yomi acid ti a ṣejade ninu ikun eniyan; je ki oúnjẹ gba ona to yẹ; yòó si mu ìrọ̀rùn deba inú ikùn.

Abajade ìwádìí: Òdodo ọ̀rọ̀.
Ìwádìí fihàn pé èso kùkúńbà le yomi acid ti a ṣejade nínú ikùn ènìyàn.
Ọ̀rọ̀ kẹrin: Èso kùkúńbà lè ṣe itọju ààrùn ẹ̀jẹ̀ ríru.
Àkọsílẹ PharmEasy ṣàlàyé pé èso kùkúńbà le mu ifunpa gíga wale, yóò sí dènà ààrùn ọkàn nítorí àwọn èròjà potassium, magnesium ati dietary fibre ti o wá nínú èso náà.
Medical News Today náà f’ikun wípé èròjà fibre ti o wá nínú èso kùkúńbà máa n ba ní ṣe itọju ọ̀rá ara (cholesterol) àti àwọn ààrùn ọkàn ti o tipase ifunpa gíga waye.
Nínú àkọsílẹ kan ti Healthline gbejade, ile-iwosan náà ṣàlàyé pé oun kan to le fa ifunpa gíga ni iyọ̀ jijẹ lapọju. Ti iyọ̀ ba p’oju lara, o máa mu ki omi duro s’ara, èyí ló le fa ẹ̀jẹ̀ rírú.
Potassium jẹ èròjà ti ọ máa n ṣọ́ odiwon iyọ̀ ti o wá ninu kindinrin, èròjà yii sí wa nínú èso kùkúńbà.

Àbájáde ìwádìí: Òdodo ọ̀rọ̀.
Ọpọlọpọ akọsílẹ lo fihàn pé èso kùkúńbà le ṣe itọju ẹ̀jẹ̀ ríru, nítorí èròjà potassium to wa nínú rẹ̀.
Ọ̀rọ̀ kárùún: Èso kùkúńbà le ṣe itọju orí fífọ́.
Àkọsílẹ Entity ati Lehigh Centre ṣàlàyé pé èso kùkúńbà le mu orí-fífọ́ wálẹ̀ nítorí omi to wà nínú kùkúńbà.

Àbájáde ìwádìí: Òdodo ọ̀rọ̀.
Oro kẹfa: Èso kùkúńbà dara fun awọ ara, yóò mú ko máa dan yoyo, ti yóò si mọ́ kedere.
Àkọsílẹ Medical News Today sàlàyé pé ti ènìyàn bá gé èso kùkúńbà wẹwẹ, ti ọ sí fi sí àwọ̀ ara, èyí máa jẹ ki ara dan yoyo, kódà a mu idinku ba ara yiyun tàbí wiwu.
Ìwádìí National Library of Medicine fihàn pé biotilẹjẹpe kemika cucurbitacins ni oro ga’an, n’isẹ ni o máa n gbogun ti igbinikun nínú ara.
Kódà, iwẹ àkọsílẹ nipa idagbasoke eda, (Jarlife’s Journal of Ageing Research and Lifestyle) daba pe èso kùkúńbà máa ṣe ara lóore nítorí a máa so ènìyàn dọtun, ara wa o ni tètè gbó.

Àbájáde ìwádìí: Òdodo ọ̀rọ̀.
Ìwádìí ati àkọsílẹ àwọn onímọ̀ isegun òyìnbó fihàn pé èso kùkúńbà máa n ṣe ara lóore.
Akotan
Ìwádìí wa fihan pé biotilẹjẹpe òtítọ wa ninu àwọn ọ̀rọ̀ ti olumulo ikanni ibaraẹnisọre Facebook sọ nipa ìwúlò èso kùkúńbà, àwọn mìíràn ṣi ni lọ́nà.