Site icon Dubawa

Póópù Francis kò kú o

Francis pope

Ahesọ: Olumulo ikanni ibaraeniṣọrẹ Facebook sọ wípé oludari ìjọ mímọ́ àgùdà, póópù Francis ti jade láyé.

Póópù Francis kò kú o

Ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyẹ́

Ní ọjọ́ kẹrinla oṣù keji ọdún yi, wọn gbe póópù Francis lọ ilé ìwòsàn leyin ti o lugbadi àìsàn òtútù àyà to n da ẹdọforo mejeji rẹ laamu, ti o si sé èémí.

Olumulo ikanni ibaraenisọrẹ́, ABC 168, kọ gbolohun kan si oju opo re ni ojo kerindinlogbon osu keji, ti o daba pe eni mimo naa ti ṣ’alaisi. “Iroyin ni kankan! Iroyin apanilekun lori iku… tele linki yii…” Linki ti won fi si atejade naa ko gbe wa lo ibikan ni pato.

Biotilẹjẹpe olumulo naa o sọ ṣaka pe oludari ìjọ àgùdà ti di oloogbe, sugbon aworan ti o fi si oju opo re daba pe póópù ti kú.

Ni ojo kejidinlogbon oṣù keji, awon olumulo miran ti ṣ’atunpin atejade naa ni opolopo igba, koda idahunsi won tokasi pe won gba oro naa gbo.

Awon olumulo bii Richard Edemekaye dahun pe, “Sun re ni aya ọlọrun.”

Olumulo miran. Englibert Moyo, sọ wipe, “Àsìkò ti to; ayé rẹ̀ ti pin, asiko to fun lati ba olorun pade ni idajọ…” Bakan naa ni Akinyemi Paul sọ wípé, “Sun ree o, Póópù.” 

Nítorí ipò ti eni ọwọ náà wa ati pe iroyin nipa ilera alufaa naa se koko fun opolopo eniyan lagbaye, DUBAWA ṣe iwadii.

Ifidiododomule

Itopinpin kókó ọ̀rọ̀ lórí ayelujara safihan awon ojulowo iroyin nipa ilera Póópù. Ìwé ìròyìn ìjọ àgùdà fi iroyin sita ni ojo kinni osu keta pe ilera ti n pada si ara póópù, leyin ti o ni ipenija aisan sémìí-sémìí, ti o si n gba itoju fun otutu aya pelu irora ninu edo fooro mejeeji.

Iwe iroyin naa salaye pe ni ago mefa irole ojo kini osu keta odun yi, “Alagba mimọ kò ni ibà, ko si ni lukimia.

Ní ọjọ́ keji, ile-ise iroyin Vatican News salaye pe alaafia ti n deba póópù. Ninu atejade kan, won salaye pe ẹni ọ̀wọ̀ náà ṣi n gba èémi atinu ẹ̀rọ wa, ko si ni ibà, ati wipe awon dokita mojuto.

Bakan naa, a rii wipe aworan eni mimọ wa lori atejade naa. Aworan naa ṣ’afihan póópù lori idubule aisan. Ṣùgbọ́n, ni igba ti a se iwadii lori awon ojulowo iwe iroyin, a rii wipe ko si iru aworan naa lode.

O ni aworan kan ni pato to pe akiyesi wa, eyi ni aworan to safihan Póópù lori idubule aisan ti o si n gba eemi inu ẹ̀rọ. A lo ẹ̀rọ́Hive Moderation ki a le mọ bi won se ṣ’ẹda aworan naa, a si rii wipe looto òye àtọwọ́dá (AI) ni wọ́n fi ṣe.

Póópù Francis kò kú o
Aworan èsì Hive Moderation

Akotan

Póópù Francis ò kú gegebi awon olumulo Facebook ti sọ. Ifitonileti ti ìjọ àgùdà gbe jade ati ojulowo irohin fihan pe eni mimọ naa si wa laye biotilẹjẹpe o wa labe itoju ni ile iwosan. Notori naa, irọ ni oro naa.

Exit mobile version