Ìdírèé tí o kò gbọdọ̀ fún ènìyàn tó farapa nínú ìjàmbá lómi mu

Ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà, tí a bá rí ènìyàn to ni ìjàmbá ọkọ̀, wọ́n a máa bèèrè fun omi. Gẹgẹbi ènìyàn to ni ikaanu ọmọlakeji rẹ̀, niṣeni a ma fẹ fun wọn ni omi mu ki won ma baa pòùngbẹ. Ṣugbọn, ma danwo, o lewu!

Ó ṣe pàtàkì ki a ni òye bóyá ó bójúmu ki a bu omi mu fún àwọn to farapa ninu ìjàmbá ọkọ, nítorí èyí ni ipa lóri ìlèra wọn.

Ninu akọsile yii, DUBAWA ṣàlàyé ìgbẹ́sẹ̀ ti a le gbe ati ìdí ti a kò gbọdọ fún ènìyàn tó ni ìjàmbá ọkọ̀ lómi mu.

Awon idi naa ni a la kalẹ bayii.

  1. Egbò inu ara tí kò foju han s’ode

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn to farapa nínú ìjàmbá ọkọ̀ le ni egbò inu ara ti kò fojú hàn s’ode. Tí a bá fun irúfẹ́ ènìyàn bẹ lomi mu, egbo naa ma dagun sii, èyí si buru jáì. 

  1. Giri ati Ipadanu ẹjẹ

Ènìyàn tó farapa nínú ìjàmbá ọkọ̀ le bẹrẹ sii ni giri nítorí o ti padanu ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀jẹ̀. Ti a ba fun irú ènìyàn  bẹẹ ni omi mu, omi naa ma toro ẹ̀jẹ̀ onitọun, ẹjẹ ò ni yi gbogbo ara ka, eyi le mu ki ọkàn da iṣẹ silẹ.

  1. Omi le sápá onítọun lórí

Ti ènìyàn  to ni ìjàmbá ọkọ ba ti dàkù tabi o wa l’ẹsẹ̀ kan ayé ati ọrun, ti wọn ba fun iru ènìyàn bẹ́ẹ̀ lomi mu, eyi le fa otutu aya (pneumonia) tabi iku ojiji ti omi yen ba wọ inu edo fóóró lọ́. Nitori ipò ti ara ènìyàn tó ni ìjàmbá ọkọ wa, nkan le tete gba odi lara wọn, pàápàá ti wọn ba mu omi, sáájú akiyesi oniṣegun.

  1. Ẹni to nilo iṣẹ abẹ

Elomiran to farapa ninu ìjàmbá ọkọ le nílò iṣẹ abẹ. Ní inú ìṣègùn òyìnbó, o ṣe pàtàkì ki ẹni to fe la iṣẹ abẹ kọja ma jẹun tabi mu omi saaju asiko iṣẹ abẹ, ki nkan ma baje.

  1. Ẹjẹ Riru

Ti olukolu ìjàmbá ba mu omi, ni ìgbà miran eyi le ṣ’okunfa ẹjẹ riru, ti o le mu ki ojú egbò ṣi silẹ, a si fa ipadanu ẹjẹ. Àwọn oniwadii kan rii wípé ènìyàn to ba ni aisan kan ti kò ni je ki eya oki ara won sise daada, ti irufe ènìyàn  be ba mu omi, o le tete ni aisan eje riru. 

  1. Onitọun l’ero pe oun nilo omi sugbon ko ri bẹẹ

Ti òùngbẹ nla ba mu ènìyàn lẹyin to farapa, ni ọpọlọpọ igba, eyi sele nitori pe won padanu ẹjẹ, kìíṣe pé wọn ní lò omi. A le ro pe a n ran won lọwọ pelu omi ti a bu mu fun won ni, sugbon o mu ewu dani, o seese ki a ma tete gbe won lọ ile ìwòsàn, ti onitoun ba sii padanu ẹjẹ, onisegun nikan lo le se itọju won.

Oun to bojumu

Dípò ki a fun eni to farapa ninu ìjàmbá lomi mu, awon oun ti a le se niwonyi.

Oun akọkọ ni ki a pe nọmba awọn onitoju alaisan ti pajawiri ki a fito wọn leti pe ìjàmbá ọkọ sele ki a si bere iranlowo wọn. O se pataki ki a salaye oun to sele, ibi ti o ti sele ati iye ènìyàn to farapa.

Àkótán

Ko si ènìyàn to gbadura fun ìjàmbá ọkọ, bẹẹ gegebi ènìyàn eleran ara, niseni a ma fẹ ran eni to ni ìjàmbá lọ́wọ́, èyí dára. Ṣùgbọ́n, ó ṣe pàtàkì ki a mọ oun to yẹ ki a ṣe ati ọna ti a le gbe gba. Kò bojumu ki a bomi mu fun ẹni to farapa ninu ìjàmbá ọkọ, eyi le fa oun to buru jai fun ilera won.

Exit mobile version