Aṣinilọna ni imọran olorin to ni ki obinrin fi álọ́ọ́mù fọ ojú abe

Ahesọ: Èlò álọ́ọ́mù jẹ oun kan ti obinrin le lo si oju abẹ́ ki o le kórajọ pọ̀, gbajugbaja olorin Niniola Apata lo kọ eleyi mọ orin ‘Ginger Me’ to ṣẹṣẹ gbejade.

Aṣinilọna ni imọran olorin to ni ki obinrin fi álọ́ọ́mù fọ ojú abe

Abajade iwadii: Aṣiniọna ni ọrọ naa. Lílọ èlò álọ́ọ́mù si oju abẹ́ obìnrin ò dara to, ó mu ewu dání. Lo ṣ’abẹwo si dọkita rẹ ti o ba fẹ mọ oun to ni lati ṣe to ba nilo ki oju abẹ́ rẹ kórajọ pọ.

Ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyẹ́

Niniola Apata jẹ gbajugbaja olorin takasufe, o si maa n kọ ẹya orin amapiano ti o wọpọ ni orilẹede South Africa. Arabinrin Niniola a maa fi orin rẹ yin àwọn obinrin àti oun to mu wọn da yatọ.

Ninu orin kan to ṣẹṣẹ gbe jade, “Ginger Me, arabinrin Niniola gba àwọn obinrin nimoran pe ki wọn lo álọ́ọ́mù si oju ara ti won ba fe ki oju abẹ́ wọn kórajọpọ. 

Orin naa ni, “Lo alum, lo alum tó ba fé ko tight, lo alum lo alum s‘abẹ́ die, wa ri pe o ma tight.” Eyi tumọ si pe ti obinrin ba fe ki oju abẹ́ rẹ̀ kórajọpọ tabi l’okun si, o le lo elo álọ́ọ́mù si.

Orin naa ti tanka ori ayelujara ti o si fa ariyanjiyan lori àwọn ikanni ibaraeniṣọre, àwọn eyan fe mọ boya ewu wa ninu imoran naa tabi ko si ailewu. Nitori iwulo èlò álọ́ọ́mù ni ilẹ wa, a ṣe iwadii lori oro naa.

Koda, oniṣegun oyinbo, Chinonso Egemba da si oro naa. Dọkita miran, Ajidahun Olusina (@the_beardedsina), ati àwọn olumulo ikanni abẹ́yefo @moradeke pẹlu @romsha_u, sọ wipe imoran naa ko dara nitori ewu to wa nibe.

Àwọn olumulo miran bii @fertitude, ati @slimveetah kilọ pe ki àwọn eniyan yàgò fun imọran olorin naa ṣugbọn eniyan kan @gagosaurus gboriyin fun Niniola pe oun to sọ dara bẹẹ.

Ifidiododomulẹ

Oriṣi nkan ni a maa n lo èlò álọ́ọ́mù fun. Wọn le loo gege bi ọ̀dá, wọn a maa lo fun ìpara, ati fun ounje sise.

Awọn eeyan maa n saba wa oun lati mu ki oju abẹ́ obinrin kórajọpọ nitori o maa n mu ki wọn jẹ igbadun ibalopọ. L’orileede Naijiria ati ni ile Afrika, o wa lara aṣa wa ki a maa lo àwọn oun èlò si oju abẹ́ obinrin ki o le kórajọpọ, lara àwọn oun èlò naa ni álọ́ọ́mù wa.

Iwadii kan ti wọn gbe jade ni odun 2020 fihan pe ìdá obinrin mokandinlogorin si mokandinlaadorun lo fi èlò álọ́ọ́mù si oju abẹ́ won ki won le jegbadun ibalopo.

Ninu iwadii miran ti àwọn onimo gbejade, lilo èlò álọ́ọ́mù si oju abẹ́ je ona kan ti ọmọdebinein fi n mọ pe oun ti di obinrin to ti balaga. Koda, wọn a ma kọ àṣà naa lara àwọn iya wọn, egbon wọn agba lobinrin, tabi iya agba.

Tayo Ojo, ẹni ti o jẹ dokita ni ile ìwòsàn olùkọ́ni ti ilu Ekiti sọ pe ko si eri to daju ninu imo sayensi pe obinrin le lo oun èlò álọ́ọ́mù si oju abẹ́.

O salaye pe èlò álọ́ọ́mù maa n mu ki nkan kórajọ looto, eyi si le mu ki oju abẹ́ kórajọ fun igba diẹ, ṣugbọn nitori oju abẹ́ obinrin jẹ oun ẹlẹgẹ́, o ṣe pataki ki eniyan ṣọra sẹ.

Ojo fikun wipe ewu po loko longe ti obinrin ba lo èlò álọ́ọ́mù si oju abẹ́ re. O ni asa naa le fa akoran si oju abẹ́, ki oju abẹ́ naa yun obinrin, ati inira lasiko ibalopọ.

Koda o gbani nimoran pe ti obinrin ba fẹ oun to le mu ki oju abẹ́ rẹ kórajọ tabi ni okun sii, o se pataki ki o lọ ri dokita.

Samuel Omopariola, eni ti o je onimọ nipa ilera ara obinrin, to tun jẹ onimo nipa iloyun ati ibimo ni ile iwosan olukoni ti Ile Ife, o si tun je oludari ile iwosan All Women’s Care Fertility to wa ni ilu Owode ni ipinle Osun, da si oro naa. Onimo naa salaye pe ko si eri kankan ninu imo sayensi to ṣ’atileyin lilo èlò álọ́ọ́mù si oju abẹ́.

O ni wipe, o ṣee ṣe ki àwọn obinrin ti won ti bimọ lai ṣe iṣẹ abẹ (vaginal birth), bẹrẹ sii ri pe oju abẹ́ wọn kò kórajọ mọ tabi l’okun bii ti tẹlẹ. Eyi le fa idayafo ti o si maa mu ki obinrin naa ma wa ojutuu si.

Sugbon, onimọ naa sọ wipe, bi obinrin ba tilẹ lo álọ́ọ́mù, ojú abẹ́ naa le kórajọ fun iseju meedogun péré.

O f’ikun wipe àwọn oogun kookan wa ti won fi álọ́ọ́mù se, koda eroja ti ma n ran àwọ̀ eniyan lowo bii allantoin ati hyaluronic acid wa ninu re, sugbon o mu ewu dani.

Dokita Omopariola gba imoran pe obinrin to ba fe ki oju abẹ́ re kórajọ tabi l’okun si, ki wọn ṣe ere idaraya (kegels) tabi iṣẹ́ abẹ (vaginoplasty).

Omopariola tunbo salaye pe àwọn ewu ti lilo álọ́ọ́mù le fa ni ki oju abẹ́ obinrin kere sii, akoran nigba gbogbo, ati ki oju abẹ́ ma dun obinrin. Onimo naa fikun wipe o se pataki ki àwọn obinrin mọ ewu to wa ninu lilo álọ́ọ́mù si oju ara ki won yi yago fun asa naa.

Àwọn akosile miran menuba ijamba ti aṣa yii le se si ilera ara obinrin lapapo. 

Àkótán

Aṣinilọna ni ọrọ pe o dara ki obinrin lo álọ́ọ́mù si oju abẹ́. Awon onisegun oyinbo bu ẹnu atẹ lu àṣà yii, wọn si salaye àwọn ewu ti àṣà naa mu dani bii akoran, airọmọbi ati àwọn ijamba miran si oju abẹ́.

Exit mobile version