YorubaFact CheckHeadlineHomepage

Ǹjẹ́ o ṣeéṣe kí oogun ìfètòsọ́mọbíbí fa oyún ìju fun obìnrin

Getting your Trinity Audio player ready...

Ahesọ: Arakunrin kan lori ikanni ibaraenisọrọ X sọ wipe o ṣeéṣe ki lilo oogun ìfètòsọ́mọbíbí lọpọ igba fa oyún ìju fun obinrin.

Ǹjẹ́ o ṣeéṣe kí oogun ìfètòsọ́mọbíbí fa oyún ìju fun obìnrin

Abajade iwadii: Kò sí ẹ̀rí tó dájú nínú ìmọ̀ sayẹnsi to fi idi ọ̀rọ̀ náà múlẹ̀. Àwọn iwadii kan ṣe atileyin ọrọ naa, bẹẹ l’awon iwadii miran tako ọrọ naa, wọn ni lilo oogun ìfètòsọ́mọbíbí le ran obìnrin l’ọ́wọ́, ki wọn ma lugbadi oyún ìju.

Ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyẹ́

Oyún ìju jẹ́ koko to ṣe pataki ninu ọrọ ilera àwùjọ obìnrin orílé èdè Nàìjíríà. Koda, àwọn iwadii ti fihan pe ailera naa wọ́pọ̀ ní ìlú ogoni ni ipinle Rivers, ti ko si fi bẹ́ẹ̀ wọ́pọ̀ ni iwọ̀ oorun, ṣùgbọ́n awọn obìnrin ti ko tii mọ okunrin ni iwọn mejidinlaadota ti ni ailera yii ni ìlú Ibadan ní ipinle Ọ̀yọ́.

Bakan naa, iwadii fi múlẹ̀ pe àwọn obìnrin ti ọjọ́ orí wọn jẹ ọdún merindinlọgbọn si marundinlaadota lo saba maa n ni ailera naa. Bíotìlẹ́jẹ́pé iwadii pọ rẹpẹtẹ nípa oyún ìju, ìròyìn ofege gbode kan lori ayelujara paapaa nipa oun ti o le fa oyún ìju.

Laipe yii, arakunrin kan ti o je olumulo ikanni ibaraenisọrọ X @Neo_official sọ wipe lilo oògùn ìfètòsọ́mọbíbí l’aloju le fa oyún ìju s’ara obìnrin.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn lo ti ka atejade oju opo naa, ti won si ti buwọ ife luu. Nitori pataki ọ̀rọ̀ naa si ilera àwọn obìnrin lawujọ, DUBAWA gba lati fi idi òdodo oro yii múlẹ̀.

Ifidiododomulẹ

Oyún ìju jẹ okan lára àwọn oun ti o maa n mu inu ikùn obìnrin wu, ṣùgbọ́n kiise àìsàn jẹjẹrẹ. Àwọn èròjà òmóònù inu ara obìnrin, estrogen àti progesterone le mu ki ewu rẹ̀ pọ̀si. Àmọ́, kò si ẹni ti o mọ oun tó ṣ’okunfa oyún ìju ni pato.

Kìíṣe gbogbo ìgbà ni oyún ìju maa n ní àmì apẹẹrẹ, ṣugbọ́n apeere to wọpọ́ ni ki ẹjẹ to n jade lasiko nkan oṣu pọ ju bo ṣe yẹ, ìrora nínú eegun ẹ̀yìn, inira lasiko ibasepo, obìnrin naa yoo ma a tọ̀ loorekoore. Ni opolopo igba, awon obìnrin ti wọn ti balaga ni o wa ninu ewu oyún ìju.

Àwọn iwadii imọ ijinle sagbekale rẹ̀ pe, oyún ìju maa dagbasoke ni àsìkò ti eroja omoonu ba pọju l’ago ara bii ìgbà ti eeyan ba loyún sinu, o si maa kéré sii ni ìgbà ti eroja omoonu ba dinku bii igba ti obìnrin ba diwo sise nkan osu.

Awon onimọ isegun oyinbo n se iwadii lori oun to le sokunfa idagbasoke oyún ìju ati ona itoju. Oun meji pataki, eroja omoonu estrogen ati progesterone le mu ki oyún ìju ga si, mejeeji lo si wa ninu oogun ìfètòsọ́mọbíbí.

Nínú atejade Mayo Clinic, àwọn nkankan le mu ki obìnrin wa ninu ewu oyún ìju. Awon naa ni ki obìnrin sanra ju boseye, ajogunba, obìnrin ti ko tii bimo, obìnrin to tete bere nkan osu, ati ki obìnrin ma dawo nkan osu lasiko to ye.

Iwadii ti won gbe jade ni odún 2021 yii salaye pe lilo oogun ìfètòsọ́mọbíbí le je ki obìnrin wa ninu ewu oyún ìju, tabi ki o dagba si, nitori eroja omoonu estrogen ti o maa n fa idagbasoke oyún ìju. Bakan naa ni iwadii miran filelẹ pe lilo oogun ifetosomobubi fun igba pipe le je ki obìnrin bori ewu oyún ìju.

Ọrọ l’ẹnu onímọ̀

Onímọ̀ nipa iṣẹ́ abẹ, Yan Katsnelson, ṣ’àlàyé pé kò sí ẹ́ni ti o mo oun kan pato ti o n fa oyún ìju. Àmọ́, awon oniwadii imo ijinle gbagbo pe nigba ti eroja omoonu ba po lara, oyún ìju le bere sii dagba. Kiise ètò ìfètòsọ́mọbíbí kan lówà fún àwọn eniyan to ni oyún ìju.

Ni igba miran, eto ìfètòsọ́mọbíbí le ran obìnrin lowo lati mojuto nkan osu ati omoonu progesterone ati estrogen. Sugbon, awon eroja omoonu ọ̀ún to wa ninu oogun ìfètòsọ́mọbíbí ọ̀ún le mu ki oyún ìju dagba si.

Ẹni tó bá ní ailera oyún ìju ni lati ba dokita won soro lori irufe eto ìfètòsọ́mọbíbí ti won ma lo, paapaa ti o ba je eeyan to ti lugbadi oyún ìju.

Dokita Stan, onimo nipa isegun oyinbo salaye pe aheso lasan ni oro pe lilo orisi meji si meta oogun ìfètòsọ́mọbíbí le mu ki oyún ìju dagbasoke, o ni ko si eri to daju ninu imo sayensi to satileyin oro naa. Okunfa oyún ìju kiise oun kan ni pato, iyato ninu eroja omoonu lago ara le fa, sugbon ko si idaniloju pe lilo oogun ìfètòsọ́mọbíbí le fa oyún ìju.

Àkótán

Aṣinílọ́nà ni ọ̀rọ̀ pé oògùn ìfètòsọ́mọbíbí a maa fa oyún ìju. Kò sí ẹ̀rí tó dájú nínú ìmọ̀ sayẹnsi tó ṣ’atilẹyin ọ̀rọ̀ naa. Àwọn onímọ damọran pe ti ẹnikeni ba ni oun kan to ru wọn loju nipa ìfètòsọ́mọbíbí tabi oyún ìju, ó ṣe pataki ki wọn ba dokita wọn s’ọrọ.

Show More

Related Articles

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Back to top button
Translate »