Photo source: Premium Times Nigeria.
|
Getting your Trinity Audio player ready...
|
Laipẹ yii, ààre Bọla Tinubu kí àwọn ọmọ Nàìjíríà ku àmójubà ọdún tuntun biotilẹjẹpe àwọn ara ilu n kerora eto oro aje ti ijoba rẹ̀ gbekale. Àjo to n risi onka lorilẹede Nàìjíríà(NBS) salaye pe ọ̀wọ́ngógó oun èlò ti lọ soke si.
Si bẹẹ, àwọn osiṣẹ́ ijọba ò tíì bẹẹrẹ síí gba gbẹndeke owo oṣù osise ti o je egberun lona aadorin naira, biotilejepe ijọba ti buwọlu àfikún owó oṣù osise lati oṣù keje ọdún to koja.
Àwọn ọmọ orilẹede Nàìjíríà si n kerora iyokuro owo iranwo ori epo bẹntiróòlù ti o fa ipenija fun ara ilu. Ninu oro re ni ojo kinni ọdún yii, aare Tinubu so wipe oro aje orilẹede Nàìjíríà tii n dara sii biotilejepe àwọn ara ilu se iwọde ojo mewa lati fi ehonu won han lori abuku ijoba yii.
O fikun wipe iye owo epo bẹntiróòlù ti ń já wálẹ́ díẹ̀díẹ̀, ti owó ilẹ̀ òkèrè tí Nàìjíríà ní ní ìpamọ́ n lo sókè si, náírà sì ti ń gbèrú, gbogbo oun to tokasi ìgbá ọ̀tun ni oro aje orilẹede Nàìjíríà.
Aare so wipe, “àwọn itokasi oro aje orilẹede wa safihan idagbasoke. Owo epo bentiroolu ti n wale, saa meta otooto ni owo òkèrè tí Nàìjíríà ní ní ìpamọ́ n lo sókè, koda owo naira tii n lagbara sii legbe dola, eyi to tumo sii pe oro aje wa n dagbasoke.”
Dubawa sakiyesi ọrọ merin lara oun ti aare so ti a si se iwadii lori won.
Ọrọ kini: Iye owo epo bentiroolu ti n walẹ diẹdiẹ
Ni kete ti aare Tinubu yo owo iranwo ori epo ni ọdún 2023, iye ti àwọn ara ilu n ra epo bentiroolu bere sii lo soke si paaapaa ni ọdún to koja. Àwọn awako bere sii ra epo ni egbeta naira. Sugbon, ni oṣù kesan ọdún 2024, owo epo goke lo si egberin naira. Ni gba ti a gbenule oṣù kewa ọdún ọ̀ún, owo epo goke lọ egberun naira o le die.
Orisi nkan lo sokunfa idinku owo epo lati ojì dín ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ́fà si ojì lé ní ẹgbẹ́rún naira, gegebi ajo NNPC ti kede. Koda egbe àwọn to n pin epo bẹntiro jakejado Nàìjíríà, IPMAN kede pe àwọn ọmọ ẹgbẹ oun yoo se idinku owo epo ti won ba raa lati ilé iṣẹ́ ìfọpo Dangote Petroleum Refinery, eyi ti yoo mu irorun ba àwọn ara ilu.
Iṣẹda aworan: Phillip Anjorin/DUBAWA

Abajade iwadii: Asinilona ni oro naa
Ọrọ keji: Okoowo ile okeere ni orilẹede Nàìjíríà dagbasoke si laarin saa meta
Ni saa kini ọdún 2024, ifilo lati ajo NBS fihan pe apapo isoowo oja orilẹede Nàìjíríà je trilionu mejilelogbon odin die. Eyi je idagbasoke ipin mefalelogoji lati saa to koja, ti o si je ipin marundinlaadojo ni saa kanna ni ọdún 2023.
Apapo iye oja ti a ta si orilẹede miran je trilionu mokandilogun naira, eyi je ilosoke peluipin mokanlelaadota ni afiwe pelu saa kerin ọdún 2023. Okoowo epo robi lo po ju ti o je trilionu meedogun iyen ipin ogorin. Iye to si ku je trilionu mefa, to safihan idagbasoke oro aje.
Apapo okoowo ilu okeere orilẹede Nàìjíríà fun saa keji ọdún 2024 je mokanlelogbon trilionu, eyi dara ju saa keji ọdún 2023 ti okoowo je trilionu mejila. Ifiranse oja si ile okeere lati orilẹede yii goke lo trilionu mokandilogun naira, sugbon, ni asiko naa, oja to wole si orilẹede Nàìjíríà je trilionu mejila o le die.
Ni saa keta ọdún, apapo okoowo je trilionu marundilogoji, eyi je afikun ipin ogorin si saa keta ọdún 2023, ati afikun ipin metala ti saa keji ọdún 2024. Okoowo ifiranse oja si ile okeere ja si afikun ipin merindilogun lati saa to koja pelu ipin Eejidinlogorun lati ọdún to koja si Ogun trilionu, Okoowo epo bentiroolu lo poju. Okoowo orilẹede Nàìjíríà dagbasoke si pelu trilionu mefa o din die.
Isẹda aworan: Phillip Anjorin/DUBAWA

Abajade iwadii: Otitọ ni
Ọrọ keta: Owó òkèrè tí Nàìjíríà ní ní ìpamọ́ ti lo soke sii
Banki apapo orilẹede Nàìjíríà salaye pe owo òkèrè tí Nàìjíríà ní ní ìpamọ́ je bilionu mejilelogbon owo dọ́là ni oṣù kejila ọdún 2023. Ni ojo kokandilogun oṣù kesan ọdún 2024, owo òkèrè tí Nàìjíríà ní ní ìpamọ́ ti lo soke si bilionu mokandilogoji owo dọ́là. àwọn oun to sokunfa idagbasoke oun ni iselopo epo robi, ifoworanse ati àwọn ilana igbalode ti banki agba orilẹede Nàìjíríà gbe kale lati mu owo okeere wole sii.
Ni ogbon ojo, oṣù kejila ọdún 2024, owo òkèrè tí Nàìjíríà ní ní ìpamọ́ ti lo soke si ogoji bilionu dola laarin ọdún kan. Sugbon, o se ni lanu pe naira ja wale pelu ipin ogoji si owo dola.
Iṣẹda aworan: Phillip Anjorin/DUBAWA

Abajade iwadii: Otito ni oro naa
Oro Kerin: Owo naira ti lagbara si owo dola
Ni ojo kokanlelogbon oṣù kejila ọdún 2024, owo dola kan je egberun kan, le ni eedegbeta naira, ti a ba se afiwe pelu ti ipari ọdún 2023, a o rii wipe owo naira ja wale ni iye ipin mokanlelogoji o din die. Eyi tumo si pe, owo naira ja wale laarin ibeere ọdún 2024 si opin ọdún oun.
Iye pasiparo owo naira si dola ni ọdún 2024 fihan pe owo naira ni ipenija ni ọdún naa paapaa pelu bi àwọn ara ilu se nilo owo okeere, fun gbigbe oja wole ati àwọn oun miran. Owo naira ja wale lopolopo ni ọdún 2024, ni igba kan ninu ọdún naa, owo naira si dola kan je egberun kan le ni egbeta naira.

Abajade iwadii: Asinilona ni oro oun.
