ExplainersEducationYoruba

Àmì ẹ̀yẹ àgbáyé: Tani Kayọde Adewale, oludanilẹkọ imo isiro l’ede Yoruba?

Getting your Trinity Audio player ready...

Awọn Yoruba p’òwe, wọ́n ni bi a kò bá dẹ́kun ìgbìyànjú, bó pẹ́ bó yá akitiyan á dópin lọ́jọ́ kan, a le fi eyi ṣ’apejuwe oro arakunrin Kayode Adewale, eni to o je oluko imo isiro (Mathematics).

Laipe yii, ile-ise Varney Foundation kede orúkọ aadọta olùkọ́ l’agbaye ti wọn laami laka fun ọdún 2025, lara won si ni arakunrin Adewale ti o maa n kọ àwọn akeekọ ni imọ ìṣirò pelu èdè Yoruba ki o le ye wọn yekeyeke.

Varkey Foundation pelu ajọsepọ ajọ agbaye to n se igbelaruge ẹkọ, imọ sayẹnsi ati àṣà (UNESCO) lo ṣ’agbekalẹ àmì ẹyẹ naa lati gboriyin fun awon olukọ ti wọn fi ọna igbalode kọ awon akeekọ ni agbegbe wọn. Àmì ẹyẹ naa ni won pe ni àmì ẹ̀yẹ ọlọ́lá fun awon olukọ, ìyẹn Noble Prize of Teaching.

Se bi won ni àìfi ọ̀sán sún ńlẹ̀ ẹyẹ ẹ̀gà ló jẹ́ kó gbayì bẹ́ẹ̀, arakunrin Adewale jẹ olukọ imọ sayẹnsi, imọ isiro ati iṣẹ ẹrọ ni ile eko girama Imagbon/Imaka Comprehensive High School ti ipinle Ogun.

Biotijẹpe imọ ìṣirò maa n sábà jẹ kàyéfì fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ akeeko, arákùnrin Adewale ṣ’eto ọna ìgbàlódé ti yóò fi mú ìmọ̀ ìṣirò ati imọ sayensi r’ọrun fún àwọn akeekọ rẹ nipase lílo èdè Yorùbá àti Haúsá.

Kódà, olukọ náà ko je ki awon akeeko re ni imolara aini oun elo ikeeko, niṣeni o gba wọn ni iyanju ki won lo ẹrọ alagbeka wọn ki wọn fi ka’we yanju.

Olùkọ́ naa se àgbékalè àwọn ẹrọ ayelujara bii Technology-Assisted Management Solution (TAIMS), Inquiry Learning Space (ILS) ati PhET simulation, ti àwọn akeekọ fi n kọ nipa isi6ro lori fóònù alagbeka wọn. Eyi si ti mu ki won pegede ninu awọn ìdánwò wọn.

Àwọn ẹrọ ìgbàlódé ti arákùnrin Adewale gbe sílẹ jẹ ko ṣeeṣe fún ènìyàn láti kekọ pelu awọn akegbe wọn ni igbakugba bi won ko tile si ni ibùdó kan naa. Eyi si tu fun won ni anfaani ki won le se imulo ẹ̀rọ igbalode.

Arakunrin Adewale tun sagbekale ètò kan ti wọn pè ní Transformation1090 Initiative, nípasẹ̀ ètò náà, o ti ko awọn olùkọ́ ẹgbẹ́ rẹ̀ to le ni ẹgbàáẹ́ẹdógún, ni imọ lori bi olùkọ́ se le fi ẹ̀rọ ìgbàlódé kọ awọn akeeko ni ayé òde oni.

Won ni ìrèké ò níbùdó; ibi gbogbo ló gba alágbára, arakunrin Adewale tun je oludasilẹ Ogun517GoToSpace, ètò ti o fi n kọ awọn akeekọ ati olùkọ́ ẹgbẹ́ re ni imọ òfuurufú tabi sánmà. Kódà o ti ni ajọsepọ pẹlu àwọn onímò lati àjọ NASA ki won le tun mu ẹ̀kọ́ òfuurufú jinle sii ni orílè-èdè Nàìjíríà.

Nipa Ami eye agbaye fun oluko 

Ikede ti àjọ Varkey Foundation gbé jáde mẹnuba àwọn èèyàn mọ̀kan dín ní àádọ́ta ti wọn yẹ fun àmì ẹyẹ naa. Lara won ni: Ali Mokgalaka, Andreja Pavlović, Ángel Luis González Serrano, Ann Marie Vanneste, Brett Dascombe, Carla Neely, Celine Haller, Danilo Kovač, Dominic Orina, Erick Hueck, Faith Senyo, Gayatri Narasimhan, Giuseppe Fiamingo, Hans Diaz, Helder Guastti da Silva, Ile Mihajlovski, Ioanna Zafeiriou, Jesus Castañeda Rivera, Jorge Patric Peña Guevara, Junmerth Jorta and Karina Sarro ati awon eniyan miran.

Àmì ẹyẹ àgbáyé fún olùkọ́ maa n se ayẹsi àwọn olukọ ti won laami laka l’agbaye nipasẹ akitiyan won lori ètò ẹ̀kọ́ ni agbègbè wọn. Wọ́n ṣe àgbékalè àmì ẹyẹ náà ni ọdún 2014, làti ìgbà náà, ọdọọdún ni wọn máà ń ṣe ayẹsi àwọn olùkọ́ pẹ̀lú iranlọwọ UNESCO. 

Ẹ̀bùn owó ní ìlọ́po mílíọ̀nù kan owó dọla ni wọn máà fún ẹni to bá gbé gba oroke. Èyí ni lati gbóríyìn fún iṣẹ takun takun tí awọn olùkọ́ n se.

Show More

Related Articles

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Back to top button
Translate »