Mahimmancin goge hakora da daddare
|
Getting your Trinity Audio player ready...
|
Aheso: Olumulo ikanni Instagram kan sọ wípé ti ènìyàn ba kọ̀ lati fọ enu ni ale ki o to sun, o le yọrí si aisan ọkàn.

Abajade iwadii: Òdodo ọ̀rọ̀. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ iwadii fihan pe eniyan le ni aisan ọkàn ti ko ba mọ ìmọ́tótó eyín ṣe.
Ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé
Àìsàn ọkàn je orisirisi ailera to dojuko okan ati òpó eje lara eniyan. Àjọ to n rísí ètò ìlera lagbaye WHO ṣ’alaye pé àìsàn ọkàn jẹ́ àìlera kan to ma n saba se ikú pà’yànlagbaye.
Ó si wa je kàyéfì ni ìgbà ti olumulo ikanni Instagram yi, @thefarmacyreal so àìsàn ọkàn mọ imọtoto eyín. Olumulo naa sọ wípé ti eniyan ba kọ̀ jale lati fọ ẹnu ni alẹ́ ki o to sùn, iwadii ti fihan pe onítọ̀ún le tètè ni àìsàn ọkàn.
Olumulo naa ṣ’alaye pé ti a ba sun ni alẹ́, ara o ni le ṣ’ẹda itọ́ daada, kòkòrò inu ẹnu le gba ibẹ ṣe àkóbá fún ọkàn.
“Oun ti ẹ kò mọ ni wipe, kòkòrò ailefojuri inu ẹnu le sa wo inu ẹ̀jẹ̀, ti a si ṣe akoba fun òpó ẹ̀jẹ̀. Eyi le fa ki kòkòrò kórajọ si inu Ìṣọ̀n-ẹ̀jẹ̀ àlọ. Oun lo maa n ṣ’okunfa ifunpa giga, aarun rọwọrọsẹ, ọkàn a da iṣẹ́ sílẹ̀, ìkọlù ọpọlọ ati bẹẹbẹẹlọ,” olumulo naa lo sọ èyí.
A ṣ’akiyesi ariyanjiyan àwọn olumulo miran lori ọ̀rọ̀ náà, a si pinnu lati se iwadii.
Iṣamudaju
A rii wipe olumulo naa fi linki atọka akọsile kan si inu atejade rẹ̀. Akọsile lati ilé-iṣẹ́ Medical News fihan pe lootọ, ti eniyan ò ba fọ ẹnu ṣáájú oorun alẹ́, ó ṣeeṣe ki ọkàn onítọ̀ún da iṣẹ́ sílẹ̀.
O mẹ́nuba iwadii kan ti wọ́n gbe jade ni ọdún 2023 pelu akori yii, “O seese ki okan da ise sile ti eniyan o ba fo enu ni ale”. Awon onimo naa se iwadii lati mo boya asiko ti eeyan fo enu ko ipa lori ilera okan, won si rii wipe fifọ enu saaju ounje aarọ se pataki, amọ́ eyin fifọ saaju orun alẹ́ lo se pataki julọ.
Akosile American Heart Association, àjọ to n rísí ìlera ọkàn ni ilu Amerika, ṣe itọkasi iwadii ọdún 2018 kan. Iwadii naa fi idi re mu’lẹ pe fífọ ẹnu lẹẹmeji lojumọ fún iṣẹju méjì le ran ilera ọkàn lọ́wọ́.
Agbekalẹ iwadii na ni pe kokoro to dojuko erigi le mu ki ẹ̀jẹ̀ riru buru si, o si tún le gbogun ti ògùn ti wọ́n fi n ṣe itọ́jú ìfúnpá gíga.
Ni igba ti a ṣe itọpinpin koro ọ̀rọ̀ lori ẹ̀rọ ti a fi se awari iwadii àwọn onímọ̀ Google Scholar lori irẹpọ fifọ eyín ati aisan ọkàn, a rii awon iwadii odun 2023 kan ati ti 2024 kan lori “Irẹpọ to wa laarin bi a se fọ eyin ati ilera okan.”
Iwadii ti àwọn ọnímọ̀ gbe jade ni ọdún 2024, ṣàlàyé pé fífọ ẹnu loorekore lè dẹkun ìkọlù àìsan ọkàn.
Àkótán
Ọ̀títọ́ ni ọ̀rọ̀ náà. Iwadii ti àwọn ọnimọ gbé jáde ti ṣ’agbekale ìrẹ́pọ̀ tí o wa laarin ìmọ́tótó eyín àti àìsàn ọkàn.
