YorubaFacebook ChecksFact CheckPolitics

Ǹjẹ́ EFCC rí owó àti oògùn olóró n’ilé ọmọ El-Rufai, gẹ́gẹ́ bí aṣàmúlò Facebook ṣe sọ?

Getting your Trinity Audio player ready...

Àhesọ: Aṣàmúlò Facebook kan sọ pé EFCC ṣàwárí owó àti oògùn olóró ní ilé ọmọ El-Rufai, ní Kaduna.

Ǹjẹ́ EFCC rí owó àti oògùn olóró n’ilé ọmọ El-Rufai, gẹ́gẹ́ bí aṣàmúlò Facebook ṣe sọ?

Àbájáde Ìwádìí:  Lótìtọ́ láwọn àjọ EFCC ṣàwárí àwọ́n ohun tí wọ́n dárúkọ wọ̀nyí. Ṣùgbọ́n, ìpínlẹ̀ Èkó ni won ti rí wọ́n, kìí ṣe ilé ọmọ El-Rufai. Àhesọ yìí ṣini lọ́nà. 

Ìròyìn Lẹ́kùńrẹ́rẹ́

Gómìnà ìpínlẹ̀ Kaduna tẹ́lẹ̀rí, Nasir El-Rufai ti máa ń kópa nínú àwọn ọ̀rọ̀ àríyànjiyàn. Ní ọjọ́ kẹrin oṣù kejìlá, ọdún 2024, aṣàmúlò kan lórí Facebook, Hammed Ishola, sọ pé àjọ tó ń rí sí ìwà ọ̀daràn ọrọ̀ ajé àti ìwà ọ̀daràn ẹlẹ́yàmẹ̀yà (EFCC) ya wọ ilé ọmọ gómìnà tẹ́lẹ̀ ní Kaduna, Bello El-Rufai. Wọ́n sì rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ owó dọ́là àti ògùn olóró nínú ilé náà.

Aṣàmúlò náà kọ̀wé pé, “EFCC ṣàwárí $800 million, 700 billion, àti iye oògùn olóró N1 Trillion nílé ọmọ Nasir El-Rufai, ní Kaduna.”  

Bákan náà ló tún kọ̀wé pé ìkọlù yìí yọrí sí ìjà láàrín àwọn òṣìṣẹ́ àjọ EFCC àti ẹgbẹ́ ààbò aládáni tó ń ṣe àbójútoló ilé náà.

Títí di ọjọ́ kẹ́rìnlélogún, Oṣù Kejìlá, ọdun 2024, ènìyàn márùndínláàádọ̀ta ló ti buwolu àtẹ̀jíṣsẹ́ yìí tí ọgọ̀ta ènìyàn sì tí dá sí ọ̀rọ̀ náà. Bákannáà ni ènìyàn mẹ́tàlélọ́gbọ̀n ti pín àtẹ̀jíṣẹ́  yìí.

Ǹjẹ́ EFCC rí owó àti oògùn olóró n’ilé ọmọ El-Rufai, gẹ́gẹ́ bí aṣàmúlò Facebook ṣe sọ?
Àtẹ̀jade tí wọ́n ń pín kiri. Orísun àwòrán: Facebook.

Ní ìdáhùn sí àtẹ̀jíṣẹ́ náà, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn aṣàmúlò gbàgbọ́ nínú òtítọ́ ẹ̀sùn yìí, wọ́n sì pè fún ìjìyà lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, nígbà tí àwọn díẹ̀ mìíràn wípé ọ̀rọ̀ àtijọ́ nìyìí.

Titilayo Morohunfolu kọ̀wé, ó wípé, “Haaa Jésù Kristì! Ní Nàìjíríà lónìí! Ẹ̀wọ̀n tàṣrà.”

Aṣàmúlò mìíràn, Rasheed Ajibola, sọ pé, “Àwọn tí arákùnrin yìí ràn lọ́wọ́ ti padà mú wá’lẹ̀. Òfin Karma yóò tún wá ṣeré láárín òun àti Atiku (El-Rufai).”

“ìròyìn àtijọ tí wọn túntẹ̀jáde  lọ́dún 2024 rèé,“ Aremu Olabode, olùmúlo Facebook mìíràn, ṣe àkíyèsí.

Nítorí awuyewuye tí àtẹ̀jade yìí ti ń fà àti irúfẹ́ ènìyàn tó kópa nínú rẹ̀, DUBAWA pinnu láti ṣàyẹ̀wò òtítọ́ rẹ̀.

Ìfìdíòdodomúlẹ̀

DUBAWA fi àwòrán tí aṣàmúlò Facebook pín sí Google Reverse Image Search. Àbájáde rẹ̀ tọ́ka sí àtẹ̀jíṣẹ́ Facebook tí wọ́n pín ní 2017. 

Àtẹ̀jíṣẹ́ náà ṣàlàyé bí EFFC ṣe ya wọ ilé kan ní Ìpínlẹ̀ Èkó, níbi tí wọ́n ti rí mílíọ̀nù mẹ́tàlélógojì dọ́là (£34 million). Ìwé ìròyìn British Broadcasting Corporation (BBC) tún ròyìn irúfẹ́ àlàyé kan náà ní April 13, 2017.

Business Day tún fi kún un pé àkójọpọ̀ owó náà wà nínú àwọn àpótí ààbò nínú ilé náà. 

Ní ọjọ́ kọkàndínlógún, oṣù kẹrin, ọdún 2017, Premium Times ròyìn ìṣẹ̀lẹ̀ náà, ó sì mẹ́nuba pé ààrẹ tẹ́lẹ̀rí Goodluck Jonathan, gómìnà Central Bank of Nigeria (CBN) tẹ́lẹ̀rí Godwin Emefiele, àti alága àjọ tó ń rí sí ìwà ọ̀daràn ọrọ̀ ajé àti ìṣúná owó (EFCC) tẹ́lẹ̀rí Ibrahim Magu, láàrin àwọn mìíràn, ni ìgbìmọ̀ ààrẹ yóò bi í léèrè lórí owó tí wọ́n rí láti ilé kan ní Ikoyi, ìpínlẹ̀ Èkó.

Àwọn ìwádìí mìíràn mú wa lọ sí àtẹ̀jíṣẹ́ Vanguard nípasẹ̀ X, èyí tí ó tọ́ka sí owó tí aṣàmúlò Facebook mẹ́nu kàn, gẹ́gẹ́ bí àwọn nkan tí wọ́n rí nínú ilé Ikoyi ní oṣù kọkànlá, ọdún 2017.

Nígbà tí a ń ṣe ìwádìí síwájú sí i, a ṣàyẹ̀wò fún àwọn ìròyìn láti ṣàwárí bóyá àjọ tó ń gbógun ti ìwà ìbàjẹ́ ya wọ ilé ọmọ El-Rufai láìpẹ́ yìí. Ṣùgbọ́n a kò rí ọ̀kankan tí ó gbóríyìn fún ọ̀rọ̀ náà. Kàkà bẹ́ẹ̀, a rí oríṣiríṣi ìròyìn láti ọwọ́ àwọn ilé iṣẹ́ ìròyìn. Wọ́n jẹ́rìí sí ẹ̀sùn náà gẹ́gẹ́ bí èké.

Ní ọjọ́ karún-un oṣù Kejìlá, ọdún 2024, Punch ròyìn pé àjọ EFCC wípé àwọn kò mílíọ̀nù ọgọ́rùn-ún mẹ́jọ dọ́là ($800 bilionu) àti oògùn olóró tí iye rẹ̀ jẹ́ ₦1 trillion ní ilé El-Rufai. Vanguard tún ṣe àtẹ̀jáde irúfẹ́ ìròyìn kan náà ní Dec. 5, 2024.

Àyẹ̀wò kíkún lórí ojú òpó Facebook àjọ EFCC fi àtẹ̀jíṣẹ́ kan hàn tí ó ní àjọ tó ń gbógun ti ìwà ìbàjẹ́ náà kò ṣàbẹ̀wò sí ilé gómìnà ìpínlẹ̀ Kaduna tẹ́lẹ̀rí tàbí kí wọ́n ṣàwárí àwọn ohun tí ẹni tí ó ń pe ẹjọ́ náà mẹ́nu kàn.

Àkótán

Àwọn àwárí DUBAWA fi hàn pé àkójọpọ̀ owó àti àwọn oògùn tí aṣàmúlò Facebook tọ́ka sí ni wọ́n ṣàwárí nínú ilé kan, n’ípinlẹ̀ Èkó, l’ọ́dún 2017. Wọn kò ní nkankan ṣe pẹ̀lú El-Rufai.

Miracle Akubuo ló kọ́kọ́ ṣ’àkọsílẹ ìwádìí yìí lé’dè gẹ̀ẹ́sì, tí Sunday Awóṣòro sì túmọ̀ rẹ̀ sí ède Yorùbá.

Show More

Related Articles

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Back to top button
Translate »