YorubaFacebook ChecksFact CheckMainstream

Ṣe lóòtó ni àwọn asofin orilẹ-ède Nàìjíríà pin ìpínlè Ọ̀yọ́ sí méjì?

Getting your Trinity Audio player ready...

Aheso: Olumulo ikanni ibaraẹnisọrẹ Facebook, Odumayo Funke Olufemi sọ wípé àwọn aṣòfin ti fi òfin pín ìpínlè Ọ̀yọ́ sí méjì. 

Ṣe lóòtó ni àwọn asofin orilẹ-ède Nàìjíríà pin ìpínlè Ọ̀yọ́ sí méjì?

Àbájáde ìwádìí: Irọ́ ni. Ìwádìí DUBAWA fi mu’lẹ pé ìdí ijiroro ni wọn ṣì wà ni ilé ìgbìmọ̀ asojuṣofin Nàìjíríà.

Ẹkunrẹrẹ alaye

Won seda ìpínlè Ọ̀yọ́, ti o jẹ ọkan lára àwọn ilú apa iwọ oorun orilẹ-ède Nàìjíríà, ni ọdún 1976. Ìjọba ìbílè metalel’ọgbọn ati agbègbè ìjoba ìbílè mokandilọgbọn ló wa níbẹ̀, olú ìlú si jẹ Ibadan. Òun ni ìpínlè kẹta to tobijulọ ni orilẹ-ède Nàìjíríà nipasẹ iye olùgbé ibẹ̀, ìpínlè náà lo ni ilẹ̀ to tobijulo ni Nàìjíríà.

Ijiroro nipa ṣiṣẹda ìpínlè miran láti ìpínlè Ọ̀yọ́ kìíse tuntun. Koda, ìgbìyànjú ti waye láti ṣẹda ìpínlè Oke-Ogun ati Ibadan láti ìpínlè Ọ̀yọ́ ṣùgbón àwọn ìgbìyànjú wọnyí, pabo lo jà sí. 

Ni ojo kerinlelogun osu kewa ọdún 2024, olumulo ikanni ibaraẹnisọrẹ Facebook, Odumayo Funke Olufemi gbe ahesọ pé wọn ti ṣẹda ìpínlè meji ọtọọtọ láti ìpínlè Ọ̀yọ́: “Ipinle Ọ̀yọ́ tuntun” ti olu ìlú náà sì jẹ ìletò Ọ̀yọ́ ati “Ipinle Ibadan” ti olu ìlú náà sì jẹ Ìbàdàn. 

“Won ti pin ìpínlè Ọ̀yọ́ sí méjì: akọkọ ni Ìpínlè Ọ̀yọ́ tuntun ti olu ìlú náà sì jẹ ìletò Ọ̀yọ́ ati ìpínlè Ìbàdàn ti olu ìlú náà sì jẹ Ìbàdàn,” atejade náà lo sọ bayìí. 

Ọpọlọpọ ènìyàn lo ka atẹjade náà ti wọn sì bù ọwọ́ ife lùú. 

Olumulo kan, Ayanfeoluwa Abiodun fèsì pé, “Eyin ènìyàn wọnyi ṣa fẹ dà wahala sílẹ pẹlú ọrọ yii. Won kò tíì ká aba fún idasilẹ ìpínlè yii léèmeta,” bẹ́ẹ̀ sì ni olumulo míràn Achilles Achilles fèsì pé, “Eyi dara lọpọlọpọ”.

Iṣamudaju

A sè itopinpin kókó ọrọ, “Ipinle Ọ̀yọ́” ati “Iseda ìpínlè,” DUBAWA ríi wípé ọrọ náà tanka orí ẹ̀rọ alatagba. 

Ni ọjọ́ kejilelogun oṣù kẹwa ọdún yii, àwọn ilé-iṣẹ́ ìròyìn bíi The Punch ati Premium Times gbe ìròyìn nipa àbá fun idasilẹ ipinlẹ meji lati ìpínlè Ọ̀yọ́ tuntun, ti wọn sì ṣàlàyé pé wọn ti ka abà naa fun igba keji ni ile igbimọ aṣojuṣofin. Aṣòfin Adeniyi Adeyemi ati awọn mẹfa mii lo je onigbọwọ fun. Àbá náà ni ki wọn da ipinlẹ Ọ̀yọ́ tuntun sílè, pẹlu ilu Ọ̀yọ́ gẹgẹbi olu ilu, ki wọn si sọ awọn agbegbe yooku di ipinlẹ Ibadan, eyi ti yoo sọ ilu ibadan di olu ilu fun.

Ìròyìn The Punch ṣàlàyé pé asofin Adeyemi, eni ti o n soju fún ẹkun Ọ̀yọ́ Federal, so wipe aba naa kiise tuntun. O mẹnuba ipade apero kan tí wọn ṣe ni ọdún 2014, ni ibi ti wọn ti gba àbá naa wọle pe ki wọn da ipinlẹ Ọ̀yọ́ tuntun silẹ.

“O se pataki ki wọn pin ipinlẹ Ọ̀yọ́ si meji nitori bi o ṣe jẹ ọkan ninu awọn ipinlẹ to tobi julo ni apá iwo oorun orilẹede Naijiria, pẹlu ìjoba ìbílè mẹtalelọgbọn ati awon olugbe ti o ju mílíọ̀nù máàrún lọ. O dà mí lójú pé ti wón ba ṣẹda ìpinlẹ tuntun, yoo le da duro.”

Nínú òfin orilẹ-ède Nàìjíríà, o se pataki ki wọn ka àbá náà léèmeta ni ilé igbimọ asojusofin méjèèjì. 

Báwo ni àbá ṣe ń di òfin ní orilẹ-ède Nàìjíríà?

Ki aba to di ofin, yóó gbá àwọn ọ̀nà wọnyi kọjá:

  1. Ijiroro lori aba: sise idanimọ oun kan pàtàkì to mu aba náà wa. 
  2. Kika aba ni àkókò
  3. Kika aba ni ẹlẹẹkeji 
  4. Ìpàdé igbimọ: ni ibí yii ni wọn ti ma ṣe ìtúpalẹ̀ aba náà, wọn le fi iwẹ ranṣẹ sí awujo eniyan láti dasi. 
  5. Kika aba ni ẹlẹẹkẹta
  6. Fífi ami otemilorun sì àbá
  7. Ààrẹ orilẹ-ède a fì ààmì otemilorun sì àbá naa. Ààmì ààrẹ orilẹ-ède ni o se pataki julo, òun lo le mu ki aba di ofin. Gẹgẹbi apá kejidinlogota iwé ofin orileede, aare gbodo saami sì àbá naa láàrín ogbon ojo. 

Ti a ba tẹle àwọn igbese ti a ka sílè wọnyí, a ri daju pé won kò tii saami sì àbá láti pin ìpínlè Ọ̀yọ́ sí méjì, béè sì ni kò tíì di ofin, ni àsìkò ti a gbè ìròyìn yii jade.

Akotan  

Iro lásán ni ọrọ naa. Botilejepe ijiroro n lọ lori àbá náà, èèmejì péré ni wọn ti kà ofin yii ni ilé igbimọ asojusofin orilẹ-ède Nàìjíríà.

Show More

Related Articles

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Back to top button
Translate »