Getting your Trinity Audio player ready...
|
Iroyin lẹkunrẹrẹ
Oríṣiríṣi agbekale ilana imototo lo tẹ̀lé àjàkálẹ̀ ààrùn COVID-19, biotilẹjẹpe òmíràn kò bójúmu. Òkan lára wọn ni ki a máa fi ọṣẹ fọ èso ati ẹ̀fọ́ ti a n jẹ, ilé-isé ìròyìn Times of India fagilé iroyin náà ni ọdún 2020.
Laipẹ yíí, fọ́nrán akalekako kan ṣàfihàn arábìnrin kan ti o n ṣàlàyé ìdí ti òun fi n fọ ẹ̀pà pẹlú ọṣẹ. Ilé-isé ìròyìn Instablog gbé ìròyìn náà, pẹlu ọ̀rọ̀ ifori yìí, “Arabinrin kan ṣàlàyé bi o ṣe n ṣe imototo ẹ̀pà ki o to jẹ.”
Arábìnrin náà sọ wípé òun bẹrẹ síí fọ ẹpa nítorí ìrírí rẹ̀ pèlú ontaja kan.
Ni ọjọ eti, ojo kerindinlogbon oṣù kini ọdún 2024, ẹgbẹrun lónà ẹdẹgbẹrin ènìyàn ló wo fónrán náà lori ikanni Instagram, àwọn olumulo sí sọ̀rọ̀ nipa fónrán yií. Kódà, ó lé ní ẹgbẹrun marun ènìyàn to ṣ’atunpin fónrán náà. Olumulo kan, @Datedogeh08 sọ wípé, “Kò sí ọ̀nà tí arábìnrin yìí ṣe lè ṣan ọṣẹ kúrò l’ára ẹpa pátápátá, n’isẹ ni o n da èmi ara rè legbodo nipasẹ jije kemika nínù ẹpa.”
Olumulo míràn, @Jancyskin dá àbá pé arábìnrin náà lè lo ìsebẹ̀ tàbí iyọ̀, o fikun wipe nise ni arabinrin inu fónrán ọ̀ún ń ṣi àwọn ènìyàn l’ọna. “Kini idi ti kò fi lo iyọ? Jáwọ kúrò nínú aṣinilona, jọwọ.”
Ìbéèrè ti a ni látí dáhùn ni bóyá oun ti arábìnrin yii ń ṣe dára fún ìlera ara wa, jẹ́ àìléwu tàbí o lè ṣe ìjàmbá. A wòye itankalẹ fónrán náà ati iye ènìyàn ti o ti wòó, DUBAWA pinnu lati fi ìdí òdodo múlẹ̀.
Ṣé o bójúmu ki a fi ọṣẹ fọ oúnje?
Ajo ti o n risi ètò ìlera àwujọ ni ilu Amerika Centers for Disease Control and Prevention (CDC), ṣàlàyé pé ki a fi omi fọ èso ati ẹ̀fọ́ ti a fè jẹ. Àjọ náà sọ pé kò bójúmu kí a lo ọṣẹ tàbí ounkoun ti a fin fọ aṣọ, fọ èso tàbí ẹ̀fọ́.
Eka ijọba orilẹ-ède Amẹrika tí ó ń rísí ètò iṣẹ́ ọgbin náà kìlọ̀ pé kò dára ki a lo ọṣẹ fi fọ ǹkan oúnjẹ.
Àkọsílẹ ti Washing Post gbejade ni ọdun 2021 ṣàgbékalẹ̀ rẹ̀ pé ewu wa nínú ki a fi ọṣẹ fọ èso ati ẹfọ, kódà ó le ṣe ìjàmbá fún ènìyàn to n jẹ. Pàápàá ti onítọ̀ún o ba ṣan ọṣẹ náà kúrò dáadáa kúrò l’ára èso náà.
Àkọsílẹ míràn ṣàlàyé pé àwọn kẹ́míkà, tùràrí àti àwọn oun èlò kọọkan wa nínú ose ti ènìyàn ò gbọ́dọ̀ gb’emì. Àkọsílẹ náà f’ikun wípé lílo ọṣẹ fún ǹkan oúnjẹ le ṣ’àkóbá fún adùn oúnjẹ.
Jason Bolton, ọjọgbọn nipa ètò oúnjẹ ni ilé-èkó gíga Yunifasiti Maine Cooperative Extension, so fun ilé-isé Washingpost pé, “Ni ọpọlọpọ igba, oun ti wọn pò papọ̀ sí inú ọṣẹ le ṣe ìjàmbá fún ìlera ara ènìyàn tí a bá gb’emì. Ọṣẹ lè ṣe àkóbá fún inú, yóò sí fà ki ènìyàn máa bì tàbí ya igbẹ gbuuru. Kódà, o le da inu agọ ara wa láàmú,” ọjọgbọn náà lo sọ bẹ́ẹ̀.
Ọ̀nà wo ni a lè gbà ṣe ìmọ́tótó ǹkan oúnjẹ?
Nígbà ti àwọn ènìyàn kan bíi arábìnrin inu fónrán yií n lo ọṣẹ latí fi fọ èso ati ẹ̀fọ́, Ben Chapman, ọjọgbọn ati onimo nipa ètò oúnjẹ ní Yunifásítì ìlú North Carolina State University sọ pé lílo omi tó mọ́ nìkan ti to lati fọ ìwọn aadọrun kokoro àìlèfojúrí ti o le wà nínú oúnjẹ wa.
Kódà, ilé-isé Healthline filelẹ pé omi ti tó. Sugbọn, o ṣàlàyé pé ki a fọ nigba ti a nilo re gangan.
Hampton Farms sọ wípé a lè lo omi tó lọ́ wọ́rọ́wọ́ fi ṣan èso tàbí ǹkan oúnjẹ leemeji tàbí eemeta.
Akotan
Biotilẹjẹpe o ṣe pataki ki a ṣàn àwọn oun jíjẹ bíi ẹ̀fọ́ ki a to loo fi dana, awon onímọ̀ ti filelẹ pe lílo omi to mọ tonitoni ti to lati fọ wọn mọ. Kò dára ki a lo ọṣẹ nítorí èyí lè ṣe ìjàmbá fún ǹkan jíjé àti ènìyàn to fe jẹ.