Getting your Trinity Audio player ready...
|
Aheso: Express, ojú òpó kan lórí ikanni ibaraeniṣọrẹ, Facebook gbe ahesọ pe alaga àjọ eleto ìdìbò INEC, Mahmood Yakubu ti tọrọ aforiji lọwọ awọn ọmọ Naijiria fun ipa tí ó kó ninu ifọwọyi èsì ìdìbò ọdún 2023.

Abajade iwadii: Irọ ni! Kò sí ẹ̀ri tó dájú pe alaga INEC sọ oun to jọ bẹẹ. Koda, ko si ojulowo ile-ise iroyin kankan to gbe ìròyìn naa. Ni pataki jùlọ, a rii wipe oju òpó ayelujara ti wọn fi iroyin naa si jẹ ayederu.
Ẹkunrẹrẹ àlàyé
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú àwọn ọmọ orileede Nàìjíríà lo fi ẹ̀họ́nú wọn hàn leyin ètò ìdìbò ọdún 2023 ti o gbe ààrẹ Bola Tinubu sí ipò adarí orileede. Awọn oludije bii ogbeni Peter Obi ati Atiku Abubakar bu enu atẹ́ lu èsì ìdìbò naa ati awon oun ti ààrẹ Tinubu n gbe se.
Odún meji leyin ìdìbò, oju opo kan lori ikanni Facebook, Express fi atejade kan sita, ti o gbe ahesọ pe Mahmood Yakubu, alaga àjọ eleto ìdìbò Naijiria, INEC ti tọrọ iforiji lọwọ awon ọmọ Naijiria lori ipa ti o ko ninu ifọwọyi esi ìdìbò odun naa. Iroyin naa daba pe ogbeni Mahmood fowoyi esi ìdìbò naa nitori oun ati àwọn ara ile rẹ̀ wa ninu ewu.
Ninu iroyin naa, ogbeni Mahmood sọ wípé iwa yi ko bu iyi kun òun. A ṣe akiyesi pe iroyin naa ti tanka ori ikanni Facebook, àwọn olumulo ikanni Whatsapp naa ṣ’atunpin atejade naa ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ igba.
Nitori bii oro naa se kan ajọ to n dari eto ìdìbò ni Naijiria ati itankale re lori ayelujara, DUBAWA se iwadii lori oro naa.
Ifidiododomulẹ
DUBAWA ka atejade naa l’ẹ̀kúnrẹrẹ lori Daily Excessive. Ni igba ti a ka iroyin naa, a rii wipe oro naa ko ni agbekale to dara. Iroyin naa o salaye ibi ti ogbeni Mahmood ti jẹ́wọ́ pe oun fọwọyi èsì ìdìbò.
Iwadii DUBAWA lori aye ayelujara Daily Excessive fi awon apẹẹrẹ ayederu linki han. Linki ọ̀ún gbe wa lọ awon aaye ayelujara ti won ti n ta ọja.
A gbiyanju lati mọ ipilẹ aye ayelujara Daily Excessive lori Scam Adviser, iwadii wa fihan pe ayederu ni aye ayelujara naa.
Koda, oju opo Facebook to satunpin iroyin naa, odun 2019 ni won seda re. Awon olumulo meji kan sọ pe oju opo naa kii gbe ojulowo iroyin.
Nigba ti DUBAWA se itopinpin koko oro lori ero Google lati fi mọ boya awon iwe iroyin miran gbe iroyin naa, ko si oun to jọ bẹẹ.
DUBAWA kan si Rotimi Oyekanmi, eni ti o je agbenuso ogbeni Mahmood ki o le fi idi ododo mule lori oro naa sugbon ko fesi.
Akotan
Aṣinilọna ni iroyin akalekako pe ogbeni Mahmood tọrọ iforiji lowo awon omo Naijiria fun ifowoyi esi ìdìbò odun 2023.