Fact CheckMainstreamYoruba

Atijo ni fonran to s’afihan Seyi Tinubu ti o gb’oriyin fun ijoba baba re

Getting your Trinity Audio player ready...

Aheso: Olumulo ikanni Facebook s’atunpin fonran kan to s’afihan Seyi Tinubu ti o gb’oriyin fun Ijoba aare Bola Tinubu. 

Atijo ni fonran to s’afihan Seyi Tinubu ti o gb’oriyin fun ijoba baba re

Abajade iwadii: Asinilona! Atijo ni fonran yii, ko si niise pelu oun to n sele ni orileede Naijiria lowolowo bayii. Won se igbasile fonran naa ni odun 2023, laarin osu die ti aare Tinubu g’ori oye. 

Ekunrere alaye

Pelu owon gogo owo epo bentiroolu ni orileede Naijiria, awon ara ilu ti fi ehonu won han lori awon eto ati ilana ti ijoba Tinubu gbe kale.

Leyin ojo die, ti owo epo tun won si, olumulo ikanni ibaraenisore Facebook, ABN TV fi fonran yii si oju opo re, ti o s’afihan Seyi Tinubu, omo aare Bola Tinubu, ni ibi ti o ti n dupe lowo awon omo orileede Naijiria fun atileyin won fun ijoba yii. O si tun parowa fun awon omo orileede Naijiria pe aare Tinubu lo ni ogbon ati agbara lati se ijoba ti yoo mu idera ba ara ilu.

Olumulo yii ko akosile yii si abe fonran naa, “Mo dupe lowo gbogbo omo orileede Naijiria fun igbagbo ti e ni ninu Baba mi, aare wa, mo si fi da yin loju pe, aare Bola Ahmed Tinubu ko ni ja yin kule. Orileede Naijiria, ireti wa ti de, aare ti a tin duro de lo de yi o, Seyi Tinubu lo so bee.”

A sakiyesi pe, awon ti won wo fidio naa ti bu enu ate lu oro ti Seyi Tinubu so, koda won fi ehonu won han lori owongogo owo epo ti ijoba Tinubu da sile.

Olumulo kan, Ifeanyi Onoh so wipe, “Okan mi ko yonu si ijoba yii, paapaa aare Bola Ahmed. Ni se ni orile ede Naijiria n lo lati wahala kan si wahala miran. Kilode ti iye owo epo se wan gogo?”

Eaglemaster King bere ibeere, “Lita kan epo bentiroolu ni won ta ni egberun kan ati apo meji. Se aare Tinubu janikule tabi ko janikule?”

Olumulo miran, Godswill Abel, so wipe, “Ejoor, e ma se ni dandan, e gba wa laaye ki a dibo fun oludari to wun wa, nitori Olorun.”

Nitori oro owongogo epo ni orileede Naijiria, DUBAWA gbe oro naa yewo asi se iwadii lori fonran naa.

Asamudaju

A se itopinpin awon aworan ti a mu lati inu fonran oun, esi ayewo wa fihan pe, Iwe Iroyin Punch s’atunpin fonran naa ni ojo kerindinlogbon, osu keje odun 2023.

Lori ikanni Facebook, iwe iroyin Punch ko akosile yii, “FIDIO: Baba mi ko ni ja yin kule, Seyi Tinubu fi okan ara ilu bale pe baba a sa gbogbo ipa ati agbara re lati mu ijoba irorun wa.”

A ri fonran yii lori ikanni Instagram ati YouTube ni odun 2023.

Ileise Iroyin Eagle Media s’atunpin fonran naa lori ero ibaraenisore ni odun 2023.

Akotan

Abajade iwadii DUBAWA fihan pe ati odun 2023 ni won ti se igbasile fonran yii, kiise odun yii. Ko si ni oun kan se pelu owongogo owo epo bentiroolu.

Show More

Related Articles

Leave a Reply

Back to top button
Translate »