ExplainersHealth

Ibà Lassa: Títànkálẹ̀ àìsàn, àmì, ìtọ́jú, àti ìdènà gẹ́gẹ́ bí àjọ NCDC ṣe kéde pàjáwìrì lórílẹ̀-èdè.

Ní oṣù kẹta, ọdún 2023, àjọ tó rí sí ìṣàmójútó àrùn ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà “NCDC” ṣe ìkéde pàjáwìrì lórí àìsàn Ibà Lassa. Dọ́kítà Ìfẹ́dayọ̀ Adédiba, Olùdarí Àgbà àjọ yìí sọ pé ìpe pàjáwìrì yìí di dandan lẹ́yìn tí ìṣẹ̀lẹ̀ àrùn yíì túnbọ̀ ń gbilẹ̀ si l’órílẹ̀-èdè.

Nínu àbọ̀ rẹ̀ lóri Ibà Lassa, àjọ yìí kéde pé ènìyàn mẹ́rìnlélọ́gọ́rùn ló ti bá ibà yìí lọ nínú ìṣẹ̀lẹ̀ mẹ́rìndínlójìlélẹ́gbẹ̀ta tí wọ́n ti rí kà lọ́dún yìí, ní ìpínlẹ̀ méjìlélógún.

Kíni Ibà Lásà?

Ibà Lassa jẹ́ àìsàn láti ara èkúté. A ṣàwárí rẹ̀ ní ìlú Lassa, ní ìpínlẹ̀ Borno, ní agbègbè Àríwá Nàìjíríà, ní ọdún 1969. Fáírọ́sì yìí wọ́pọ̀ ní Ìwọ̀-oòrùn Áfíríkà tí Liberia, Sierra Leone, Guinea pẹ̀lú Nàìjíríà wà lára rẹ̀. Lassa fairọ̀sì to jẹ́ tí ẹbí “Arenavirus” ló ń fa àisàn yìí.

Ènìyàn le kó ibà yìí nípa níní nkán ṣe pẹ̀lú èkúté ilé tó bá ni lára, ìgbẹ́ tàbí ìtọ̀ wọn. Bákanáà ni a lè ko o nínú òógùn tàbí ikun’mú ẹni tó ti ní iba náà.

Àwòrán ẹni tí ibà mú. Orísun àwòrán: pulse.ng.

Ìpè pàjáwìrì lórílẹ̀-èdè torí Ibà Lassa: kíni ìtumọ̀ èyí?

Gẹ́gẹ́ bí àlàyé Dókítà Sandra Mba, ọ́físà tó rí sí ìṣẹ̀lẹ̀ Ibà Lassa fún àjọ Nigeria Centre for Disease Control (NCDC), tí ìpè pàjáwìrì bá wáyé l’órílẹ̀-èdè, ẹ̀ka òṣìṣẹ́ kékeré, yóò gbìmọ̀ pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀ka káàkiri orílẹ̀-èdè láti parapọ̀ gbógun ti Ibà Lassa yìí.

Dọ́kítà Mba wípé ìkéde yìí wáyé lẹ́yìn tí àbájáde ìwádìí (risk assessment) fi hàn pé ìṣẹ̀lẹ àrùn Lassa le gbòòrò lọ́pọ̀lọpọ̀ ní Nàìjíríà tí yóò sì mú ọ̀pọ̀ ẹ̀mi lọ. Láfikún, ó wípé ìkéde yìí yóò ṣe àrídájú si pé wọn kó ohun àmúlò jọ láti ọwọ́ àwọn ẹ̀ka ìjọba mìíràn bíi “Ministry of Agriculture and Rural Development, Ministry of Environment” pẹlu àwọn ẹ̀ka aládàáni, láti lè kojú àrùn yìí yege. 

Títànkálẹ̀ àrùn

Ọ̀nà wọ̀nyí ni a lè gbà pín àìsan Ibà Lassa:

1.  Èkúté ilé: Tí ènìyàn bá ní ǹkán ṣe pẹ̀lú ìtọ̀, ìgbẹ́, itọ́ tàbí ẹ̀jẹ̀ èkúté tí àrùn náà wà lára rẹ̀, ó lè kó o.

2. Ènìyàn-sí-ènìyàn: Fáírọ̀sì yìí lè mú ni tí ènìyàn bá ní ǹkán ṣe pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀, ìtọ̀, oógun, tàbí itọ́ ẹni tí àrùn yìí wà lára rẹ̀. 

3. Ohun èlò: Fífọwọ́kan ohun èlò bíi aṣọ, beedi àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ, tí fairọ̀sì yìí wà lára rẹ̀ le sọkùn fàá sí ara ènìyàn.

4. Oúnjẹ: Jíjẹ oúnjẹ tí ekú tó ní àrùn yìí ti tọ̀ tàbí yàgbẹ́ sí tún le fàá.

5. Afẹ́fẹ́: Mímí afẹ́fẹ́ tí àrùn náà wà nínú rẹ̀ sínú le sọkùn fàá sára ènìyàn. 

Àwọn àmì àìsàn

Púpọ̀ nínú àwọn tó ní àrùn yìí ni kìí ní ìrírí àmì àìsàn. Tí àmì bá sì farahàn, ó lè tó ọ̀sẹ̀ mẹ́ta lẹ́yìn tí wọ́n kó o. 

Lákọ̀ọ́kọ́, àwọn ènìyàn lè ní ibà, ẹ̀fọ́rí, ara ríro, ọ̀nà ọ̀fun dídùn àti kí ó ma rẹ èèyàn. Àwọn àmì yìí f’ara pẹ́ àìsàn tí à ń rí lójoojúmó. Èyí jẹ́ kí ó nira láti dá Ibà Lassa mi ní ipele ìbẹ̀rẹ̀. 

Bí ó bá ṣe ń peléké síi, àwọn àmì tó le yóò ma farahàn. Àmì bíi inú dídùn, ìgbẹ́ gbuuru, èémí líle, ẹ̀jẹ̀ láti imú àti ẹnu. Kódà, o lè dá iṣẹ́ àwọn ẹ̀yà ara kànkan dúró tí èyí sì lè já sí ikú.

Òkùnfà Ewú 

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ǹkan lo lè mú kí ewú kíkó àrùn yìí pọ̀ si. Àwọn ni:

1. Gbígbé ní agbègbè tó ti wọ́pọ̀ tàbí rírin ìrìn àjò lọ sí ibẹ̀: Níwọ̀n ìgbà tí àrùn yìí wọ́pọ̀ jù lágbégbè Ìwọ̀-oòrùn Áfíríkà, àwọn olùgbé agbègbè yìí tàbí ẹni tó má ń rin ìrìn àjò lọ síbẹ leè kó àrùn náà.

2. Níní nkán ṣe pẹ̀lú èkúté: ọ̀nà gbóògì tí àrùn yìí fi ń tàn ni èyí. Àwọn òṣìṣẹ́ láàbù tàbí àgbẹ̀ tó ń sin eku lè ko pẹ̀lú ìrọ̀rùn.

3. Fífọwọ́kan òógùn: Àwọn òṣìṣẹ́ ìlera àti mọ̀lẹ́bí ẹni tó ní Ibà Lassa lè tètè kó o tí wọ́n bá fí ara kan òógùn, ìtọ̀ tàbí ikun’mú rẹ̀.

Dídènà Ibà Lassa

Dídènà Ibà Lassa nílò ète wọ̀nyìí:

1. Ṣọ́ra fún èkúté: Bo àwọn oúnjẹ àti omi rẹ dáadáa. Má ṣe jẹ́ kí ekú tọ̀ tàbí yàgbẹ́ síi.

2. Ṣé ìmọ́tótó: Jíjẹ́ kí àyíká rẹ mọ́ tóní tóní yóò dènà àìsàn púpọ̀ pẹ̀lú ibà ọ̀rẹrẹ̀ yìí. Bákanáà ni kì yóò jẹ́ kí ekú ráyè wọ ilé rẹ. 

3. Wíwọ aṣọ ìdáàbòbò: Ó ṣe pàtàkì láti wọ aṣọ ìdáàbòbò tí a bá ń ṣe ìtọ́jú aláìsàn Ibà Lassa. Olùtọ́jú gbọdọ̀ dé ìgò sójú, wọ gúlọ́fù pẹ̀lú. Èyí kì yóò jẹ́ kí ara rẹ̀ kan itọ́ tàbí òógùn ara aláìsàn.

4. Ìdánilékọ̀ọ́ fún ará ìlú: Jíjẹ́ kí àwọn ará ìlú ó mọ̀ nípa àrùn yìí àti àwọn ọ̀nà láti dẹ́kun rẹ̀ yóò dín ìjànbá rẹ̀ kùn. 

5. Dídín èkúté kùn: Bí a bá dín èkúté kùn pẹlú páńpẹ́ tàbí ògùn ekú, àrùn ibà Lassa yóò dínkùn.

Àwọn òṣìṣẹ́ ìlera níbi ìtọjú àwọn ènìyàn tó ti kó Ibà Lassa ní Orílẹ̀-èdè Sierra Leone. Ọjọ́ keje, oṣù keji, ọdún 2011. Àwòrán: VOA News.

Ìtọ́jú

Kò sí ìtọ́jú kan pàtó fún Ibà Lassa. Nígbà tí àrùn náà kọ́kọ́ jáde, wọ́n ti lo àwọn ògùn bíi “ribavirin”. Ṣùgbọ́n, kò tí sí àrídájú tó múlẹ̀ nípa agbára rẹ̀ fún Lassa fairọ̀sì.

Láfikún, wọ́n gbọdọ̀ gbé aláìsàn lọ sí ilé ìwòsàn fún ìtọjú bíi “electrolyte replacement, oxygen therapy, àtí blood transfusions.” Fún àpẹrẹ, tí aláìsàn ò bá lè mí dáadáa, ilé ìwòsàn ni ẹ̀rọ tó lè ràn ọ́ lọ́wọ́ wà.

Àkótán

Ibà Lassa jẹ́ àìsàn tó nílò àmójútó pàtàkì. Àrùn yìí ma ń wọ ara ènìyàn láti ara ìgbẹ́ tàbí ìtọ̀ èkúté tí àrùn náà wà lára rẹ̀. Bákannáà ló sì lè káàkiri láti ara ènìyàn -dé-ènìyàn. Àwọn àmì àìsàn yìí lè wá láti kékeré lọ di ńlá. Ara rẹ̀ ni ẹ̀fọ́rí, ara ríro, òtútù, ikọ́ àti ọnà ọ̀fun dídùn.

Show More

Related Articles

Leave a Reply

Back to top button