Getting your Trinity Audio player ready...
|
Àlùfáà Chris Oyakhilome, laipẹ yii gba awon ọmọ ijọ re niyanju pe ki won ko imoran dokita won danu lori iyọ̀ jije nitori iyọ̀ ni anfaani pupo lago ara.
Oyakhilome, eni ti o je oludari ati alakoso ijo Christ Embassy sọ wipe awon onisegun oyinbo a maa gbani nimoran pe ki eniyan sọra fun iyọ̀ jije sugbon imoran toun nipe ki awon eniyan je iyọ̀ daada.
O fi fonran kan han wọn lori ayelujara to safihan awon dọ́kítà alawo funfun ti won jerisi iwulo iyọ̀ lago ara. Ọ̀rọ̀ naa fa ariyanjiyan lori ayelujara, àwọn olumulo bẹrẹ sii fi erongba wọn han lori oro naa, boya looto ni oro ti alufaa sọ tabi asinilona ni imoran oludari ijo naa.
Báwo ni wọn ṣe n ṣẹ̀dá iyọ̀?
Iyọ̀ tabi ìsebè je oun kan pataki ti a maa fin se ounje, pa nkan mọ ki o ma baje, a si maa n lo fun awon nkan miran ninu asa ati ise awujo eniyan. Ti kò ba si iyọ̀ ninu ọbẹ̀, ọbẹ̀ naa a di àtẹ́, kò ní l’adun.
Oun àdáyébá ni iyọ̀, won maa n ṣ’ẹ̀dá iyọ̀ kúrò lara apata. Àwọn oun èlò Ìhúlẹ̀ ati iwakùsà ni wọn ma fi n fa iyọ̀ jade kuro lara awon apata.
Ona miran ti a fi n s’eda isebwe ni latara omi osa, awon onimo a lo ifenu omi iyen evaporation lati mu iyọ̀ jade. Ni igba miran, àwọn onimo sayensi a mu omi brine, won a gbe si inu oru ninu yàrá iwadii, bi omi naa se n ho, ni won se n fa iyọ̀ jade.
Kini ajo WHO sọ?
Àjọ to n risi eto ilera lagbaye, World Health Organization (WHO) ti se agbekalẹ lori ìwọ̀n iyọ̀ ti eniyan le jẹ ni ọjọ́ kan. Fun eniyan ti ọjọ ori re je mejidinlogun tabi eni to dagba juyi lọ, won ni anfaani lati je iyọ̀ iwọn grammu marun, o si se pataki ki a ṣe idinku iwọn iyọ̀ fun àwọn ọmọde ti o jẹ ọmọ ọdún meji si marundinlogun.
Ọmọ ikoko si ọmọ odun meji ò nilo iyọ̀ ninu ounjẹ wọn. Lati ọmọ ọwó sí oṣù mẹ́fà, omi ọyan nikan ni ọmọ nílọ̀, lati osu mefa, ọmọ naa a bere sii je ounje miran pelu omi ọyàn titi di odun meji, ni asiko yii, wọn kò nilo iyọ̀.
Sugbon, WHO ṣ’alaye pe bi iwọnba iyọ̀ ti eniyan n je dale irufe ounje ti onitọun n jẹ ati agbegbe tabi ilu rẹ̀.
Nje iyọ̀ ni anfaani kankan lara?
Iyọ̀ (sodium chloride) jẹ ona kan ti eroja sodiomu maa n gba wo ago ara eniyan. Oriṣi iyọ̀ lo wa, àwọn kan a maa ri eroja iodine, folic acid, iron tabi gbogbo re leekan naa. Iyọ̀ funfun wa, bee ni iyọ̀ alawọ miran wa.
Iyọ̀ oniyẹfun wa, bẹ́ẹ̀ si ni iyọ̀ onikoro wa. Awọn iyọ̀ kan wa ti eroja sodiomu inu re kere (low-sodium),
Iyo maa n ran eniyan lọ́wọ́ lati mu ki àwọn omi ara wa ni gbedeke to tọ, o maa n se iranwọ fun ẹya ẹṣọ ara, o ma mu ki eroja inu ounje se ara loore daada, pẹlu iṣan ara.
Ṣugbon bi iyọ̀ se se pataki lara naa ni o le ṣe ijamba fun ilera ti eniyan ba je iyọ̀ lajẹju. Jije iyọ̀ lajẹju le fa ifunpa giga, aisan okan, ki eniyan sanra ju, aarun kindinrin, jẹjẹrẹ ikun, o si le se akoba fun eto oki ara lapapo (immune system).
Koda, aisan to sopọ mọ ajẹju iyọ̀ maa n fa iku fun awon eeyan miliọnu meji o din diẹ.
WHO tunbọ gbani nimọran lati dekun jijẹ iyọ̀ lajẹju. O ni ki eeyan je ounje adayeba, ki o si yera fun ounje inu ora. Gbe iyọ̀ oniyefun (table salt) kuro lori tabili ounje; lo iyọ̀ diẹ̀ sinu ounjẹ tabi yera fun iyọ̀; lo àwọn eroja miran ti a mu ki ounje dun bii ewe efinrin, ewe rosimari ati beebee lo.
Lakotan, iyọ̀ dara lago ara sugbon nitori o je èròjà kan to wọ́pọ̀ ninu ounjẹ, àwọn eniyan a maa jẹ lajẹju, a si ma fa aisan, nitori naa, o se pataki ki a wo odiwon iyọ̀ ti a n je lojumo, ki aisan ma baa fi ara wa ṣe ibugbe.