YorubaFact CheckHealth

Irọ nla! Kokoro afàìsàn ò lè dàgbà sí ojú ara obìnrin tí wọn ko dábẹ́ fun

Getting your Trinity Audio player ready...

Aheso: Olumulo ikanni abeyefo, X, salaye pé kòkòrò afàìsàn àìlèfojúrí lè tètè dàgbà sí ojú ara obìnrin tí wọn kò dábẹ́ fún. 

Irọ nla! Kokoro afàìsàn ò lè dàgbà sí ojú ara obìnrin tí wọn ko dábẹ́ fun

Ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé

Abẹ́ dídá fún ọmọbìnrin jẹ àṣà ti ọ mu ewu dani, o wa lara ìṣe àwọn ènìyan, èyi si ti fà ijamba fún ọpọlọpọ ọmọbinrin. Biotilẹjẹpe òpòlopò akitiyan ni ijoba ti se láti dẹkùn didabẹ fun ọmọbìnrin, awon eniyan kọọkan ṣi n ṣeé kaakiri agbaye, kódà ni orilẹ-ède Nàìjíríà. 

Laipẹ yíí, arákùnrin kan lori ikanni abeyefo sọ ọ̀rọ̀ kàn nipa didabẹ fun ọmọbìnrin. Ó so wípé ó ṣeéṣe ki ọmọbìnrin ti wón kò kọla/dabẹ fún fẹràn ìwa ṣìná tabi panṣaga, nítorí kòkòrò afàìsàn àìlèfojúrí ti o wá ni oju abẹ rẹ.

”Kokoro afàìsàn àìlèfojúrí n dàgbà si abẹ ti wón kò kola fún. Bi ọmọbìnrin ṣe n dàgbà nì kọkọrọ ọ̀ún dàgbà. Èyí máa n fa ki ọmọbìnrin fẹran ajọṣepọ pẹlu ọkùnrin ni ona àìtọ́, yóò si máà ni orekunrin púpọ̀. Bí o ba le ri eni tó mọọ ṣe, o dara ki a dabẹ fún ọmọbìnrin ni èwe jù kì wọn dàgbà di òní ṣìná.”

Atejade yìí jẹ èsì sí ìbéèrè arákùnrin kan, Muhammad Abdulakeem (@realmuhammadd) pé ǹjẹ́ o dára ki wọn dabe fún ọmọbinrin. “Ejo ṣe o se pataki ki a dabẹ fún ọmọbìnrin? Ariyanjiyan ti bẹ silẹ lóri ọrọ naa,” Abdulkareem lo bere oro yí. 

Àwọn olumulo kọọkan bíi Andy (@andybankz_) dáhùn wipe, “Biotilejepe àlàyé rẹ rí bákan, ṣugbọn didabe fun ọmọbìnrin máà rán ọmọbìnrin lọ́wọ́ latí yago fún ṣìná. Áwọn ọmọ òde òní lè ma faramọ aheso yìí, ṣugbọn àwòn òbí wa ṣe, o si ko ipa pàtàkì ni àwùjo eniyan.”

Àwọn olumulo miran bíi Ayomideji (@TheBlackDeji) àti Bolatito (@Teetoalaso), ko faramọ, won ni,“Má ṣe dabẹ fún ọmọbìnrin”. 

Aheso yíì tunbọ tọ́kasí àwọn ewu to rọ̀mọ́ didabẹ fún ọmọbìnrin.

Ifidiododomule 

Làti ayedaye ni won ti n dabe fun ọmọbìnrin, eyi si ni ipa l’ori ilera ọpọlọpọ obìnrin. Àjọ ti o n rísí ọ̀rọ̀ àwọn ọmọdé lágbayé UNICEF ṣàlàyé pé didabẹ fun ọmọbìnrin jẹ, “gbogbo oun ti wón ṣe láti yọ ojú ara ọmọbìnrin tàbí ṣe ikọlu sí ojú ara omobinrin tí kò si ni ànfààní fún ìlera ọmọbìnrin náa. 

Ajo ti o risi eto ilera àwùjọ l’agbaye WHO sọ wípé didabẹ fún ọmọbìnrin lodi si ẹ̀tọ́ ọmọbìnrin, o si jẹ ọnà kan ti won fi n fiyaje ọmọbìnrin pàápàá bì wọn ti n ṣe lai bikita ifọwọsi ọmọ náà. Koda, didabẹ fún ọmọbìnrin jẹ ọnà kan ti awujo eniyan fi ṣe ainaani èmi ọmọbìnrin nitori ìṣe naa le fa iku.

Òpin didabẹ fún ọmọbìnrin jẹ òkan lára àwọn afojusun ìjọba àgbayé fún ọdún 2030.

Àwòrán lórí ẹrọ alatagba ṣafihan àwọn obinrin ti wón máà n ṣe iṣẹ abẹ pèlu ohun èlò wọn. Awon ohun elo wonyi — ọ̀bẹ̀, àfọ́kù ìgò, abẹ, àlùmágàjí — ni wón lò láti ṣe ìjànbá fún ọpọlọpọ ọmọbinrin láti ikọkọ ṣí ọmọ odun meedogun. 

Biotilẹjẹpe won ti fi ofin de ìṣe yì ni awon orílè-èdè àgbáyé, àwọn ènìyàn ṣì n dabẹ fún ọmọbìnrin wọn nítorí àṣà. Àwọn ìdílé àti àwùjọ èniyàn máà n rii gege bí òun ti o t’ọna láti ríi dájú pé ọmọbìnrin ò féran ṣìná tabi panṣágà l’ojo iwájú. 

Atẹjade àjọ UNICEF lórí didabẹ fun ọmọbìnrin ni osu keta ọdún 2024 fihàn pe:

– O kere ju, igba mílíọ̀nù ọmọbìnrin, ni wọn ti ṣe iṣẹ abẹ fún lagbaye. 

— Ilè áfríkà ni àṣà náà ti wọpọ, pẹlú ogorun mílíọ̀nù, o le díẹ̀.

– Ilé Àsìá lo tẹle pèlú ọgọrin mílíọ̀nù 

– Won ri mílíọ̀nù kan si meji ni awon agbegbe kerejekereje.

Christiane Mundaute, eni ti o jẹ aṣojú UNICEF ni Nàìjíríà sàlàyé pé orilẹ-ede wa ni o gbe ipò kẹta ninu awon orílè-èdè ti didabẹ fun ọmọbìnrin ti wọpọ julọ lagbaye. Eyi túmò si pé opolopo awon ọmọbirin orilẹ-ede Nàìjíríà ni wọn ti kọla fún. 

Àjọ WHO ṣàlàyé pé didabe fun ọmọbìnrin le fa ìjàmbá fún ìlera ará bíi aarun ojú ara obìnrin, ti awon oloyinbo pé ni bacterial vaginosis (BV). Ilé-isé Cleveland Clinic salaye pé BV je àkóràn ojú ara ti kòkoro àìlèfojúrí màá n fa. Gbogbo ojú ara obìnrin ni o ni kòkòrò àìlèfojúrí ti o dara ati eyi ti o buru, sùgbón ti kòkoro àìlèfojúrí to burú bá dàgbà síi, eyi le fa arun karun si ojú ara. Àpẹẹrẹ BV ni omira tàbi oje to n run tuu bi ẹja.

Ọ̀ye àwọn onímọ̀ 

Arabinrin Opeyemi Elizabeth Agunbiade, onimọ nipa ilera Ibalopọ takọ-tabo ati ibi, ti o tún jẹ́ adari ètò ni àjọ to n risi eto ilera agbègbè ni ipinle Ondo, Ondo State Primary Health Care Development Agency (OSPHCDA), salaye pé didabe fun ọmọbìnrin kò lé dẹkùn idagbasoke kókóro afaisan àìlèfojúrí ni oju ara. Koda, o so wipe kokoro lactobacilli wa nínú ojú ara obìnrin ti o si dẹkùn àkóràn fún obìnrin yala ẹ̀ni ti wọn dábẹ́ fún, tàbi ẹni ti wón kò dábẹ́ fún. 

Ó sọ wipe, “Awon kòkòrò kan wa ti wón máà n gbé inú ojú ara obìnrin. Ise kòkòrò lactobacilli yii ni ìdáàbòbò ojú ara kuro lọwọ àkóràn. Lactobacilli yii máà n dáàbòbò ojú ara kúrò l’ọ́wọ́ awon ààrùn míìrán, yálà obìnrin tí wọn kọla fún, tabi obìnrin tí wọn kò kọla fún.

“Kokoro yíi wa lara iseda ti o si maa n dáàbòbò ojú ara kuro lọwọ akoran. Ti awon kókóro míràn ba bọ si ojú ara tàbí ti a fì ọsẹ fọ kòkòrò idaabobo yii kúrò, òún lo máà n ṣokunfa akoran.”

Arabinrin Abiola Deborah Owolabi, osise ẹtọ ilera láwùjọ bù enu ate lu aheso náa. O ṣàlàyé pé, obìnrin tí wón dabe fún, ati obìnrin tí wọn kò dabe fún, gbogbo wón lò lé ni àkóràn ojú ara, won ṣi le hu ìwà aibikita, o tẹsiwaju, o salaye pé o se patako ki a ṣ’agbeyẹwo ìmọ́tótó, ìṣe ni àwùjọ èniyàn ati ipo ọkan onitọun. 

Owolabi sọ wípé, “Dipo ki wọn dabe fún ọmọbinrin, o se pataki ki a sè idanileko ìlera ẹ̀yà ara ìbí ati imọtoto ara, nitori ewu to so p’omo didabe fun ọmọbìnrin. Kii ṣe kikola si ojú ara ọmọbìnrin la fí dẹkùn akoran. Didabẹ fun ọmọbìnrin máà n fa egbò si ojú ara, ko sì ni anfààní si ilera ọmọbìnrin naa. Kódà, ìjàmbá nla ni o jẹ fun awon ọmọbinrin ati obìnrin ti o ti balaga, yala ìjàmbá ti a le fi oju ri tabi eyi to niiṣe pẹlú ipò okan.”

Eniyan kan ti won ti dabe fún, so iriri rè

Danilola Adegbaju, eni ti wón dabe fún, sọ wípé kò sí ànfààní kankan nínu ki wọ́n dabẹ fun obìnrin, yatọ sí ìrora.

Adegbaju salaye pé won dabe fún òun ni ìgbà to jẹ ọmọ ọdun marun, o so wipe ìrora nàá ga lọpọlọpọ, koda ọ̀bẹ kan ti wón fi ṣe ikọla fun-un ni wón lò fún awon ọmọbinrin miran, eyi to le fa itankalẹ aarun. Nínú ọ̀rọ̀ rere, ó tako ìgbàgbọ pé didabẹ fún ọmọbìnrin máà n dẹkùn ṣìná, arábìnrin náà sọ pé ìṣe naa jé ifiyajeni.

Adegbaju kọ̀ lati kola tabi dabe fún ọmọbinrin rẹ̀, lataari ìrírí rè àti wípé ko sì ànfààní ti o n se fun ilera ara ọmọbìnrin.

“Ọmọ ọdún márùún ni mo je ni ìgbà ti wón dabẹ fún mí, nigba ti mọ ni ọmọbìnrin, nko gbà ki won dabe fún, nitori ìrora ti mó jẹ nígbà naa. Òun to sì fàá ti wón fi dabe funmi ni ìgbà ti mó ti gbonju ni wípé, maami o fẹ. Ebi baba mi lo faake kori pé won gbodo dabe fún mí, nítorí àṣà ìdílé wọn ni. Nìgbà ti mó si gbọ ifilo pé ko dára ki wọn dabe fún ọmọbinrin, mo pinnu pé nko ni faramọ. 

”Awon èèyàn mi gbagbo pé ti wón kò bà dabẹ fún ọmọbinrin, kò tíì dì obìnrin, sùgbon léyìn ti mo gbonju ni mo mọ pé didabe fún ọmọbìnrin le fa aisan sí àgọ ara. Oun tí mo mọ ni wípé ti wón ba ke ido ọmọbìnrin kuro, ti ọmọ náà ba tọ, egbò yẹn a jina, sugbọn saaju idabẹ, yóó máà ni irọra. Mi o ri ànfààní oun ti wón gé kuro, nitori iyawo arákùnrin mi, ti o wá láti òkè oya, wón kò dabe fún, o si bimo lalaafia. Eyi fihan pe ifiyajeni ni eto idabe fún ọmọbìnrin.”

O rọ awon eniyan ki won yago fún aṣa yii, ó sì gba imọran ki wọn lo ẹkọ afi ìfitónilétí lati f’opin si didabe fún ọmọbìnrin.

Akotan 

Irọ́ ni ọ̀rọ̀ ti arakunrin A.A. Alhaji of Nupeland sọ lórí ikanni abeyefo pé ti wón kò bà dabe fún ọmọbinrin, ọmọ náa ma féràn ṣìná. 

Show More

Related Articles

Leave a Reply

Back to top button
Translate »