Getting your Trinity Audio player ready...
|
Àhesọ: Ṣúgà ma ń fa ẹ̀jẹ̀ ríru sí ara ènìyàn ju iyọ̀ lọ.
Àbájáde Ìwádìí: Àhesọ yìí ṣinilọ́nà. Àwọn onímọ̀ ìlera sọ wípé ṣúgà pẹ̀lú iyọ̀ jìjọ ní agbára kannáà láti fa ẹ̀jẹ̀ ríru.
Ìròyìn Lẹ́kùńrẹ́rẹ́
Gẹ́gẹ́ bí àjọ tó ń rí sí ètò ìlera lágbayé (WHO), ẹ̀jẹ̀ ríru (aipatẹ́sọ́nù) ma ń wáyé nígbà tí ìfunpá ènìyàn bá wọ tàbí ga ju 140/90 mmHg lọ.
Láìpẹ́ yìí, Callipgious Kemi (@AdekemiSaliu), aṣàmúlò X kan sọ wípé ṣúgà ma ń fa ẹ̀jẹ̀ ríru sínú ara ènìyàn ju iyọ̀ lọ.
“Ẹ̀jẹ̀ rírú jẹmọ́ ìṣòro ṣúgà ju iyọ̀ lọ. Iyọ̀ kọ́ ló ma ń fàá. Ṣúgà ni,” arábìnrin yìí wí.
Èyí wáyé lẹyìn tí arábìnrin náà dá dọ́kítà kàn, Chinonso Egemba (@Aproko_doctor) lohùn, lẹyìn tí dọ́kítà ọ̀hùn rọ àwọn ènìyàn láti dẹkùn jíjẹ iyọ̀ púpọ̀ nítorí pé o ń fa ẹ̀jẹ̀ ríru.
Nígbà tí à ń ṣe ìwádìí yìí, gbólóhùn arábìnrin yìí tí gba oríṣiríṣi èsì lẹ́nu àwọn aṣàmúlò X míràn. Kódà, àwọn kan bíi Dr G The Frontliner (@iamSwaga22) fèsì pé irọ́ ni arábìnrin Kẹ́mi pa. Ó wípé “Kẹ́mi, ǹjẹ́ o mọ̀ wípé irọ́ ni èyí?”
Ẹlòmíràn, Edible Euphoria (@VickeysBatter) gba ohun tí arábìnrin Kẹ́mi wí gbọ́. Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, o wípé “Mo gbà ọ́ gbọ pátápátá.”
Nítorí rògbòdìyàn tó tẹ̀lẹ́ àhesọ yìí lórí ìkànnì X, DUBAWA pinu láti ṣe ìwádìí yìí.
Ìfìdíòdodomúlẹ̀
Heathline sàlàyé pé ọjọ́ orí, jíínì, tàbí ipò ìlera wà lára àwọn ohun tí n fa ẹ̀jẹ̀ ríru. Àwọn ohun mìíràn ní àrùn kiídìnrín, àìsùn ati àrùn ọkàn.
Bákanáà, ìwé ìròyìn Medical News Today àti Cleveland Clinic fìdí èyí múlẹ̀.
Ǹjẹ́ ṣúgà ma ń fa ẹ̀jẹ̀ ríru?
Gẹ́gẹ́ bí ìwádìí Healthline, ṣúgà wà lára ǹkan tó ń ṣ’okùnfa ẹ̀jẹ̀ ríru. Ìwé ìlera yìí fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé àwọn ohun mímu ẹlẹ́rìndòdò tó ní ṣúgà nínú lè mú kí ènìyàn sanra jù. Sísanra jù náà sì lè fa aipatẹ́sọ́nù.
Dókítà Arefa Cassoobhoy, nínú ìfọ̀rọ̀wérọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú WebMD lórí ètò ìlera, sọ wípé ṣúgà yàrá má ń fa ìfunpá gíga ju iyọ̀ lọ.
Àmọ́ o, kìí ṣe irú ṣúgà tó wà nínú èso tàbí ẹ̀fọ́ tí à ń jẹ. Ṣúgà èyí tí a má ń fi sínú oúnje fúnrawa là ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀.
Arábìnrin Cassoobhoy wípé mímu sódà tó ju ìwọn “24 ounces” lójúmọ́ lè fa aipatẹ́sọ́nù. Tí kálórì ìdá 25 tí ènìyàn ń jẹ lójúmọ́ bá wá láti ṣúgà tí a fi kún oúnjẹ, onítọ̀hún yóò yàrá ní ẹ̀jẹ̀ ríru ju ẹni tí tirẹ̀ kò tó iye yìí.
Gbajúgbajà onímọ̀ oúnjẹ, Kare Patton, bá Cleveland Clinic sọ̀rọ̀, léyìí tó yànàná àwọn ìjàm̀bá tí ṣúgà ń ṣe fún ọkàn. Gẹ́gẹ́ bí ó ṣe sọ, jíjẹ ṣúgà lájẹjù yóò mú kí ewu ìtọ̀ ṣúgà, ẹ̀jẹ̀ ríru àti ọ̀rá ara pọ̀ si.
Patton wípé a lè so sísanra jù mọ́ jíjẹ oúnjẹ onísúgà, èyí tó ń dákún ẹ̀jẹ̀ ríru.
Ìyọ̀ wá ńkọ́?
Gẹ́gẹ́ bí Blood Pressure UK ṣe sọ, iyọ̀ má ń jẹ́ kí ènìyàn gba omi sára. Èyí túmọ̀ sí wípé, iyọ̀ àjẹjú (nínú oúnje) yíò mú kí omi pọ̀jù nínú ẹ̀jẹ̀. Èyí yíò mú kí agbáara pọ̀jù nínú òpó ẹ̀jẹ̀. Ohun tí ń fa ẹ̀jẹ̀ ríru níyì.
Blood Pressure UK wípé kiídìnrín méjèèjì má ń bá ènìyàn yọ ohun tí kò wúlò mọ́ lára. Ó sì tún ma ń ṣe ìṣàkóso fún ìfunpá. Tí wọ́n bá ti gba omi ara tí kò wúlò, wọn yóò lọ sí àpòòtọ̀. Èyí ma ń wáyé nípasẹ̀ ohun tí a mọ̀ sí osimósísì, ipasẹ̀ tí omí fi ń rin ìrìn àjò láti inú ẹ̀jẹ̀, níbi tí sódíọ̀mù ti kéré, lọ sí ẹ̀yà ara tí ó ti ga.
Iyọ̀ ma ń pèsè sódíọ̀mù sínú ara. Tí a bá sì jẹ ẹ́ lájẹjù, yóò kó ìdààmú bá ìpele sódíọ̀mù àti omi nínú ara. Èyí lè jẹ́ kí iṣẹ́ pọ̀jù fún àwọn òpó ẹ̀jẹ̀ inú kídìnrín.
Ilé Ẹ̀kọ́ Ètò Ìlera Ìlú Havard T.H. Chan A Harvard T.H fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé kídìnrín ma ń gbìyànjú láti jẹ́ kí sódíọ̀mù má ju omi lọ lára. Bí sódíọ̀mù bá sì ṣe pọ̀ sí, omi tó yẹ kó kúrò lára, kì yóò kúrò nítorípé ará nílo omi láti ṣe idinku sódíọ̀mù. Èyí yíò jẹ́ kí ọkàn ma fi agbára káká ṣiṣẹ́. Èyí kì yóò jẹ́ kí ẹ̀jè ó já geerege.
Bákannáà, tí ẹ̀jẹ̀ bá pọ̀jù lára, yóò dákún iṣẹ́ fún ọkàn àti ojú ọnà tí ẹ̀jẹ̀ ń gbà. Èyí yóò jẹ́ kí ojú ọnà yìí tínrín, tí yóò sì fa ẹ̀jẹ̀ ríru.
Iyọ̀ tàbí ṣúgà, èwó ló ń fa aipatẹ́sọ́nù jù?
Healthline fi dánilójú pé àti ṣúgà, àti iyọ̀, méjèèjì ló ń fa aipatẹ́sọ́nù lọ́gbọọgba. Gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ WHO, oúnjẹ tí iyọ̀ rẹ̀ bá pọ̀ lápọ̀jù, tàbí kí ọ̀rá pọ̀jù lára ló ma ń fa ẹ̀jẹ̀ ríru.
Èrò amòye
DUBAWA gbọ́ ọ̀rọ̀ láti ẹnu Temitoluwa Omotoso, amòye nípa oúnjẹ. Ó sàlàyé wípé sódíọ̀mù àti omi gbọdọ̀ wà ní ìpele kànnà nínú ara. Tí sódíọ̀mù bá ti pọ̀jù lára, ìpele omi náà yóò wá sókè si láti lè jẹ́ kí sódíọ̀mù ọ̀ún ó wálẹ̀.
“Nígbà tí omi kò bá kúrò ní ara, iye ẹ̀jẹ̀ yóò wá sókè si. Èyí yóò jẹ́ kí agbára ẹ̀jẹ̀ náà wá sókè si,” ó sàlàyé.
Arábìnrin Omotoso sàlàyé si wípé bí ẹ̀jẹ̀ bá ń fi agbára káká gba ojú ọnà tí ẹ̀jẹ̀ ń gbà, ọnà yìí yóò máa kéré si.
Ó tẹ̀síwájú pé, tí ènìyàn bá ń jẹ ṣúgà lájẹjù, yóò jẹ́ kí isulínì ara ó kéré si. Èyí yóò jẹ́ kí gúlúkósì pọ̀ si nínú ẹ̀jẹ̀, léyìí tí yóò fa ẹ̀jẹ̀ ríru.
Bumi Ojo, amòye mìíràn láti ilé ẹ̀kọ́ gíga “University College Hospital, Ibadan,” sàlàyé pé ìgbàkígbà tí ènìyàn bá jẹun, eroja carbohydrate yóò wo palẹ̀ di ṣúgà tí yóò wọ inú ẹ̀jẹ̀. Tí ṣúgà yìí bá dé inú ẹ̀jẹ̀, yóò dúró sí ibẹ̀ títí di ìgbà tí kẹ́míkà tí a mọ̀ sí isulínì bá wá gbé ṣúgà yìí lọ sí ẹ̀yà ara tó nílo rẹ̀.
Tí ṣúgà bá wá takú sínú ẹ̀jẹ̀ nítorí àìsí isulínì tí yóò gbé kúrò, ọnà tí ẹjẹ ń gbà yóò ki síi. Arábìnrin Ojo wípé bí ó bá ṣe ki síi ni ẹ̀jẹ̀ kì yóò rí àyè gbà lọ sí ẹ̀yà ara tó nílo rẹ̀. Àwọn ẹ̀yà ara yìí yóò máa ránṣẹ sí ọkàn tí yóò jẹ́ kí ọkàn o túbọ̀ da ẹ̀jẹ̀ púpò si. Bí agbára ọkàn bá ṣe pọ̀ sí ni ẹ̀jẹ̀ yóò ma ru síi.
Amòye yìí fi ìdí rẹ̀ múlẹ pé ṣúgà nìkan kọ́ ló ma ń fa ẹ̀jẹ̀ ríru. Ó wípé ṣúgà yóò parapọ̀ mọ́ iyọ̀ àti àwọn ǹkan míràn bíi ọ̀rá láti fa ẹ̀jẹ̀ ríru.
Àkótán
Ṣúgà nìkan kọ́ ló ma ń fa ẹ̀jẹ̀ ríru. Iyọ̀ náà lè fàá sí ara ènìyàn. Àhesọ yìí sinilọ́nà.