African LanguagesArticleElectionsYoruba

Ìwà ọ̀daràn nípa ètò ìdìbò tí ẹ gbọ́dọ̀ mọ̀ ṣáájú ìdìbò ọdún 2023

Ní ọdún 2022, ètò ìdìbò gómìnà ti wáyé ní ìpínlẹ̀ méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ní orílẹ-èdè Nàìjíríà: ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun àti Èkìtì. Botilẹjẹpe kò sí idaamu kankan l’asiko ìdìbò náà, àmọ́ṣá àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú fi owó ra ìbọ̀. 

Àṣeyọrí ètò ìdìbò tàbí èyí tí kò ní kọ́nukọ́họ nínú, jẹ́ àpapọ̀ akitiyan àwọn olùdíje, ìjọba, oludibo àti àwọn eso aláàbò.

Kí orílè-èdè Nàìjíríà lè ṣe àṣeyọrí ní ètò ìdìbò ààrẹ ọdún 2023, a gbọdọ gbìyànjú láti dẹ́kun ìwà ìbàjẹ́ lásìkò ìdìbò. Nitori eyi ni àjọ elétò ìdìbò Nàìjíríà (INEC) ṣe ń pè fún agbekalẹ àjọ miran tí yóò ma ṣọsẹ fún àwọn oniwa’baje (National Electoral Offences Commission).

Alága àjọ INEC, Mahmood Yakubu sọ pé nínú ìpẹ̀jọ́ ààrùn-le-l’ọgọfa (125) lórí ọ̀ràn ìdìbò ti àjọ náà gbé lọ ilé ẹjọ́, ọgọ́ta (60) idalẹjọ lásán ni ilé-ẹjọ́ ti ṣe láti ọdún 2015.

Nítorí ọ̀rọ̀ yìí, ẹgbẹ́ Socio-Economic Rights and Accountability Project (SERAP) pe àjọ INEC níjà láti fi ìjìyà tó tọ́ fún àwọn oníwà ìbàjẹ́ ní ètò ìdìbò gómìnà ìpínlẹ̀ Èkìtì.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìwà òdaràn nípa ètò ìdìbò ni òfin là kalẹ̀ tí a sì gbọdọ̀ l’oye nípa wọn, kí a má baà ṣe àṣìṣe l’asiko ìdìbò. Apileko yìí ṣe ìfilọ́lẹ̀ àwọn ìwà ìbàjẹ́ wọ̀nyí ṣáájú ìdìbò ọdún 2023.

Ààbò fún olùdìbò

Èyí túmò sí pé gbogbo olùdìbò ló ní ẹ̀tọ́ láti dìbò yan olùdíje wọn lọ́jọ́ ìdìbò. Kí ẹnikẹ́ni má ṣe dí olùdìbò kankan l’ọ́nà.

Apá kẹjọ, abala òfin méjì lé l’ọ́gọ́fà (122) ti òfin ètò ìdìbò ọdún 2022 tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ gbékalẹ̀, palaṣẹ pé gbogbo ènìyàn tó wà ní ibùdó ìdìbò: alamojuto ètò ìdìbò, àwọn ìgbákejì/olùrànlọ́wọ́ wọn, olùdíje àti àwọn òṣìṣẹ́ àjọ ètò ìdìbò ní ibùdó ìdìbò gbọdọ ríi wípé ààbò tó péye wà fún olùdìbò. 

Ní àsìkò ìdìbò, àwọn aṣojú ẹgbẹ ́òṣèlú ní ibùdó ìdìbò ma ń s’ábà tàpá s’ófin. Kódà, àwọn aṣojú ẹgbẹ́ òṣèlú wọ̀nyí ma ń sanwó fún olùdìbò, wọ́n a sì ní kí wọ́n ṣ’afihan ìwé pélébé ìbò kí wọ́n lè mọ olùdíje tí wọ́n dìbò yàn. Ìyà ẹ̀ṣẹ̀ fún ẹni tó bá tàpá s’ofin ni ẹ̀wọ̀n oṣù mẹ́fà, tàbí kí o san owó ìtanràn ẹgbẹ̀rún lọnà ọgọrùn náírà,  tàbí méjèèjì lápapọ̀.

Ẹni tí kò forúkọ sílẹ̀ ṣáájú ìdìbò, tó sí dìbò 

Ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ dìbò l’ojo ìdìbò gbọ́dọ̀ forukọsilẹ pẹ̀lú àjọ ètò ìdìbò ní Nàìjíríà (INEC) kí wọ́n sì gba kaadi ìdìbò alálòpé wọn (Permanent Voters Card PVC) èyí tí yóò fún wọn l’anfaani láti dìbò.

Ní ọjọ́ ìdìbò, òṣìṣẹ́ INEC ní ibùdó ìdìbò yóò ṣe ifọwọsi fún oludibo láti dìbò nípa lílo àlàyé tó wà lórí kaadi ìdìbò alálòpé náà kí wọn tó lè dìbò.

Apá kejo, abala òfin mẹrin lé l’ọ́gọ́fà (124) ti òfin ètò idibo ṣ’eto owo itanran egberun lọnà ọgọrùn tabi ẹwọn oṣu mẹfa, tabi méjèèjì fún ẹnikẹ́ni tí ó bá dibo, tabi gbiyanju lati dibo ni ibùdó ìdìbò ti orúkọ wọn kò ti forukọsilẹ. 

Gbigba/fifuni ni abẹtẹlẹ ati iditẹ: sisanwo fún ibo

Sisanwo fún ìbò jẹ́ oun tí ó wọ́pọ̀ ní orílè-èdè Nàìjíríà, kódà èyí ṣẹ́yọ ní ìdìbò gómìnà ìpínlẹ̀ Èkìtì àti Osun.

Olùdìbò máa tasẹ̀ to àgèrè s’ofin tí ó bá gba owó, ẹ̀bùn, àwìn tàbí dúkìá, ipò, ilé tàbí iṣẹ́ ṣáájú, l’asiko àti ní ìparí ètò ìdìbò, ní paṣiparọ fún ìdìbòyàn olùdíje, yíyẹra fún ìdìbò tàbí gbà láti má dìbò ní àsìkò ìdìbò.

Òfin orílè-èdè wa kò fi ààyè gba ẹnikẹ́ni láti fún tàbí gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀. Apá kẹjọ, abala òfin ọkan le l’ọ́gọ́fà ṣètò pé ẹnikẹ́ni tó bá ru òfin yóò san eedegberun lọnà eedegbeta naira owó ìtanràn tàbí kó lọ ẹ̀wọ̀n oṣù méjìlá tàbí ìjìyà méjèèjì.

Iwa rudurudu ni ibùdó ìdìbò

Àlàáfíà gbọ́dọ̀ jọba ní ibùdó ìdìbò kí oun gbogbo lè lọ ní irọwọrọse, ṣùgbọ́n irọkẹkẹ tàbí ìwà rudurudu lè bẹ́ sílẹ̀ ní ibùdó ìdìbò. Ní ìgbà míràn, àríyànjiyàn tàbí ìjàkadì nípa ẹni tó ma kọ́kọ́ dìbò lè dá wàhálà sílẹ̀ ní ibùdó ìdìbò.

Ìwà rudurudu tí ó d’ènà ìdìbò jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ ńlá tó lòdì sí ìjoba tiwa-n-tiwa. Apá kẹjọ, abala ààrùn di laadoje ti òfin ètò idibo filelẹ pé ènìyàn tó bá jẹ̀bi ẹ̀sùn ìwà rudurudu ní ibùdó ìdìbò máa ní láti san owó ìtanràn eedegberun lọnà eedegbeta naira tàbí kí ó lọ ẹ̀wọ̀n oṣù méjìlá tàbí kó f’orifa ìyà ẹ̀ṣẹ̀ méjèèjì. 

Ìdìbòyàn lónà ti ko tọ ati ọrọ èké 

Apá kẹjọ, abala òfin età le l’ọ́gọ́fà ṣàlàyé èyí gẹgẹbi ìdìbòyàn lọna àìtọ́ tabi ki ènìyàn kede pe oludije ti kuro ninu idije tabi ki ènìyàn sọrọ nípa ìsesí olùdíje. Ki ènìyàn dìbò ní ọna àìtó jẹ ìgbìyànjú láti ṣe ifọwọyi eto idibo fún ànfààní ara ẹni.

Ẹnikẹ́ni ló lè gbé aheso tabi kede pe olùdíje si ipo ààrẹ ti kuro ninu idije. Pàápàá, awọn ẹgbẹ alatako ni o máa n s’ábà ṣe irufẹ nkán bẹ lati da wàhálà sílẹ ní ègbé òsèlú olùdíje náà.

Bi eyi ba waye, onitoun a ni lati san owo itanran egberun lọnà ọgọrùn tabi kí o lo ẹwọn oṣù mẹfa tabi kí o fori fa iya ese méjèèjì.

Idunkokomoni/Ihale

Enikeni to ba hale mo enikeji re, ti o lo iwa ipa, boya ni tikarare tàbí fún ẹlòmíràn yóò jiya ẹsẹ yìí. 

Eyi le je ki ènìyàn ṣe omolakeji re ni jàmbá tabi hale mọ onitoun, lati je ki won dibo fún olùdíje kan tabi kò lati dibo fún olùdíje.

Enikeni to ba jẹbi esun yii ti tapa sí apá kejo, abala keji dì l’aadoje òfin ètò idibo ti o ṣètò pé ẹlẹsẹ náà yóò san owo itanran mílíọ̀nù kan tàbí kí o wa ni atimole fún ọdún mẹta.

Ki ènìyàn ní ipa lori ẹlòmíràn lọnà tí ko tọ 

Irufẹ iṣẹlẹ yi máa n waye ti ènìyàn ba fún ẹlòmíràn lọwọ, pèsè owo tabi san abẹtẹlẹ boya lojukoju tabi nipasẹ ẹlòmíràn, ni ìgbà kúgbà lẹyìn tí a ti dá ojo idibo, lati ni ipa lori bi ẹlòmíràn ṣe máa dìbò tabi kí onitoun má dibo.

Apá kejo, abala età din ladoje, ṣ’agbekalẹ owo itanran ẹgbẹrun lọnà ọgọrùn tabi atimole osu mẹfa tabi iya ese méjèèjì.

Ki ènìyàn ji tabi ṣe iparun oun elo ìdìbò

Iwa odaran nipasẹ eto ìdìbò yii wa labẹ irufin ti o le wáyé l’ọjọ́ ìdìbò, apá kẹjọ, abala kẹrin din l’aadoje ti òfin ètò ìdìbò.

Ẹnikẹ́ni ti o ba ji tabi ṣe iparun oun ìdìbò tabi irinṣẹ ìdìbòyàn, ti tapa sofin, yóò sì lọ ẹwọn odun meji.

Ẹ̀wẹ̀, ẹnikẹ́ni tí ó bá ní pépà ìdìbò lọwọ l’ọna àìtó yóò san owó ìtanràn àádọta mílíọ̀nù tàbí kí ó lọ ẹ̀wọ̀n ọdún mẹwàá. Ìjìyà ẹ̀ṣẹ̀ yìí tọ́ sí ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ̀bi ẹ̀sùn ṣíṣe atẹjade pepa ìdìbò l’ọna àìtó, ṣiṣe ìpèsè rẹ̀ tàbí ṣíṣe agbewole rẹ̀ sorile-ede Nàìjíríà.

Òfin orílè-èdè Nàìjíríà ti ṣe ìfilọ́lẹ̀ àwọn aṣemáṣe ti o le wáyé l’asiko idibo, gbogbo rẹ̀ wà ní orí ayélujára àjọ elétò ìdìbò INEC, a ṣe àkọsílẹ̀ àwọn èyí tó se pàtàkì nínú wọn kí ẹ lè fi kún ìmọ̀ yín. 

Show More

Related Articles

Leave a Reply

Back to top button
Translate »