MainstreamEconomyFact CheckYoruba

Ọmọ Nàìjíríà kọ́ làwọn ọkùnrin tó ń f’àdá bẹ́’rawọn nínu fọ́nrán

Getting your Trinity Audio player ready...

Àhesọ: Aṣàmúlò Facebook kan pín fídíò okùnrin méjì tó wọ̀’yá ìjà pẹlú àdá nílùú India. Aṣàmúlò ọ̀hún wípé ọmọ íbò l’àwọn méjèèjì, wọ́n sì ń jà lórí ẹni tí yóò dárí agbègbè tí wọ́n ti ń tá oògùn olóró.

Ọmọ Nàìjíríà kọ́ làwọn ọkùnrin tó ń f’àdá bẹ́’rawọn nínu fọ́nrán

Ìròyìn Lẹ́kùńrẹ́rẹ́

Aare Saka, aṣàmúlò Facebook kan ló pín fọ́nrán okùnrin méjì tó wọ̀’yá ìjà pẹlú àdá nílùú India. Aṣàmúlò ọ̀hún wípé ọmọ íbò l’àwọn méjèèjì, wọ́n sì ń jà lórí ẹni tí yóò dárí agbègbè tí wọ́n ti ń tá oògùn olóró. 

Lẹ́yìn tí ìjà náà parí, a ríi tí ọ̀kan nínù àwọn ọkùnrin yìí bẹ̀rẹ̀mú ohun tó dàbí ọwọ́ tí wọ́n gé já sílẹ̀. 

Àpèjúwe tí wọ́n kọ sábẹ́ fọ́nrán ọ̀hún wípé, “Clement Okafor àti Kenneth Chukwudi n fí àdá bẹ́’rawọn sí wẹ́wẹ́ lórí ọ̀rọ̀ ẹni tí yóò máa darí agbègbè tí wọ́n ti ń ta oògùn olóró nílu India. Ẹwo bí Okafor ṣe bẹ̀rẹ̀ mú ọwọ́ rẹ̀ nílẹ̀.”

Yàtọ̀ sí Saka, àwọn mìíràn ti pín fọ́nrán ọ̀hún gẹ́gẹ́bí a se ríi níbí àti ibí.

L’ẹ́nu ọjọ́ mẹ́ta yìí, àwọn ènìyàn ti ń pín oríṣiríṣi irọ́ tó jẹ’mọ́ ẹ̀yà Igbo, Yorùbá àti Hausa lórí afẹ́fẹ́. Ìdí èyí ní DUBAWA fí ṣe àgbéyẹ̀wò yìí.

Ìfìdíòdodomúlẹ̀

DUBAWA lo Google Reverse Image láti ṣe ìwádìí lórí àwọn ẹ̀ya fọ́nrán yìí. Àbájáde, lórí ìròyìn kan tí LA VERDAD kọ ní May 15, 2024 lédè Spanish wípé “Ọ̀rẹ́ méjì ń fi àdá jà lórí ọ̀rọ̀ obìnrin; ọ̀kan sì pàdánù ọwọ́ rẹ̀.”

Gẹ́gẹ́bí ìròyìn ọ̀hún ṣe ṣàlàyé, ìṣẹlẹ yìí wáyé ní’pínlẹ̀ Dominican Republic ní’nu ilé epo kan. Wọ́n yàra gbé arákùnrin tó pàdánù ọwọ́ rẹ̀ lọ sílé ìwòsan sùgbọ́n ẹnìkejì sálọ pẹlú ọ̀kadà.

L’ọ́jọ́kan náà, ìwé ìròyìn New York Post tẹ ìròyìn yìí jáde. PAGINA CENTRAL, ìwé ìròyìn miiran sàlàyé pé ìjà yìí wáyé láàrin Nelvin Felix àti Kelvin Melquiades Trinidad ní Municipality ti Consuelo, agbègbè San Pedro de Macorís, Dominican Republic.

Atún rí ìròyìn ohun níbí àti ibí.

Àkótán

Ìwádìí DUBAWA ṣàfihàn pé ìlú Dominican Republic nì’jà yìí tí wáyé, tórí obìnrin. Kìí ṣe torí ẹni tí yóò máa ṣàkóso agbègbè tí wọ́n ti ń ta oògùn olóró nílu India. Bákannáà, kòsí àrídájú pé ọmọ ẹ̀yà ìgbò láwọn ọkùnrin wọ̀nyí.

Miracle Akubuo ló kọ́kọ́ ṣ’àkọsílẹ ìwádìí yìí lé’dè gẹ̀ẹ́sì, tí Sunday Awóṣòro sì túmọ̀ rẹ̀ sí èdè Yorùbá.

Show More

Related Articles

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Back to top button
Translate »