ArticleExplainersHealthYoruba

Oun ti o ní láti mọ nípa àìsàn Anthrax

Ẹka ìjọba tí ó ń mójútó ọ̀rọ̀ isẹ́ ọ̀gbìn ati ìgbèríko ni Nàìjíríà (the Federal Ministry of Agriculture and Rural Development, FMARD) ṣe ìkìlọ laipẹ yìí pé kí àwọn ọmọ orilẹ-ede Nàìjíríà yàgò fún jíjẹ pọ̀nmọ́, ẹran ìgbẹ́ àti ẹran sísun ki wọ́n má ba lugbadi àìsàn Anthrax. 

Ìkìlọ náà télè iroyin ìtànkálẹ̀ àìsàn Anthrax ní ìwọòrùn ìlẹ áfríkà bíi àríwá ìlú Ghana, Burkina Faso àti Togo.

Ní agbègbè Binduri ní ilà oòrùn Ghana, ìròyìn bẹ silẹ pe ènìyàn kan jáde láyé lẹ́yìn tí ó jẹ òkú màlúù tí ó lugbadi àìsàn Anthrax. Bakan náà, ni àgbègbè yìí, màlúù mẹrin lo ti kú nipasẹ àìsàn náà.

Kini àìsàn Anthrax?

Àìsàn Anthrax jẹ́ àìsàn tó burú, kòkòrò afàìsàn àìlèfojúrí Bacillus anthracis ló  máa ń fa. Kòkòrò afàìsàn àìlèfojúrí yii maa ń gbé ní inú iyẹ̀pẹ̀, o sí máa ń kọlu ẹranko ìgbẹ́ àti ẹranko ilé. 

Màlúù, àgùntàn àti ewúrẹ wa lára àwọn ẹran ọ̀sìn ti o le lugbadi àìsàn yìí tí wọ́n bá mú omi ti kòkòrò afàìsàn àìlèfojúrí yii ba wa tabi ti wọ́n fàá sí imú. 

Mayo clinic ṣ’àlàyé pé ènìyàn le fara kaṣa àìsàn náà tí ó bá ní ounkoun ṣe pẹlu ẹranko tó ṣ’aare (ti kòkòrò afàìsàn àìlèfojúrí Bacillus anthracis ba n jija kadi).

Ènìyàn le ko àìsàn náà tí ó bá jẹ pọ̀nmọ́ tàbí fọwọkan ẹgbọn-owu láti ara ẹranko to ṣ’aìsàn. Nítorí náà, àwọn ènìyàn kan le tètè kó àìsàn yìí ju àwọn ẹlòmíràn lọ.

Èyí ni àwọn ènìyàn tó ń ṣiṣẹ ọgbin, awọn oniwadii ati oṣiṣẹ ilé-ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ tí ó ń ṣe ìwádìí kòkòrò afàìsàn àìlèfojúrí náà, àwọn tó ń ṣiṣẹ pẹlu ẹgbọn-owu àgùntàn àti àwọn alápatà.

Àwọn aami aiṣan ati ìtànkálẹ̀

Egbò adaajina, inu kikan, àìlèjẹun, èébì ati ìjayà wa lára àwọn ààmì àìsàn Anthrax. Ṣùgbọ́n, ààmì àìsàn niiṣe pẹlu ìtànkálẹ̀ àìsàn náà. Àkọ́kọ́ ni èyí tí a fi ara kó, eyi ti a fa sí imú, eyi ti a gbe mi (nipa jíjẹ tàbí mímu) àti èyí tí wọ́n fi abẹ́rẹ́ fasara.

  1. Àìsàn Anthrax ti a fi ara kó (Cutaneous): Kòkòrò afàìsàn àìlèfojúrí naa le wo inu agọ ara nipase egbò tàbí ogbe lórí àwọ̀. Ẹni tó fara kasa àìsàn náà lè ní ileroro awọ-ara, to sì ma bẹrẹ síi buru síi, ìléróró náà a fojú jọ ìléróró kòkòrò, yoo sì ni àpẹẹrẹ dúdú láàrin, kódà àwọn ẹyà ara kọọkan a bere síi wù. Eyi lo wọpọ julọ ṣùgbón kìí tètè ṣ’eku pani.  

2. Afasimu (Inhalation): ènìyàn lè fa àisàn náà sì imu. Èyí ló burú jù, botilejepe kò wọ́pọ̀. Ọgbẹ́ inú ọ̀fun, ibà, ara riro, àyà riro, iko, èébì, wa lára ààmì àìsàn.

3. Àìsàn Anthrax tí a gbé mì (Ingestion/Gastrointestinal): Awọn eniyan lè lugbadi àìsàn yìí tí wọ́n ba jẹ tabi mu ounjẹ tabi omi to gbe kòkòrò afàìsàn àìlèfojúrí. Èyí lè jẹ nípa jíjẹ ẹran tí wọn kò sè jiná to ti ara eranko to ṣ’aare wa. Ààmì àpẹẹrẹ jẹ: ibà, òtútù, ọrùn wíwú, èébì to ni ẹ̀jẹ̀ nínú, ìgbẹ́ tó ní ẹ̀jẹ̀ nínú, orí fífọ́, inú rirun.

4. Àìsàn Anthrax ti a gba sára nipasẹ abere (Injection anthrax): Eyi ko wọpọ rara, yóò sì maa kolu awọn eniyan to máa n lọ ogun oloro abẹrẹ gungun. Àpẹẹrẹ àìsàn ni egbò lagbegbe ibi ti a ti gùn abere náà, iba, tabi ki ara èèyàn wu. Eyi le fa ààrùn yinrunyinrun, gììrì tabi eya ara to da’ṣẹ́ sílẹ̀.

Ko ṣeeṣe ki ènìyàn fara kaṣa àìsàn yìí latara ẹlòmíràn. 

Idena

Ki a lè dẹkun àìsàn yìí, ijoba àpapọ̀ ti ṣe ìpèsè abẹ́rẹ́ àjẹsára fun àwọn ẹranko tó lè tètè f’ori lugbadi àìsàn náà. 

Kódà, ìjọba ti kìlọ̀ fún àwọn ènìyàn pé ki wọ́n ma ṣe jẹ pọ̀nmọ́, ẹran sísun àti ẹran ìgbẹ́ lásìkò yii títí wọn yóò fi ṣe ojutu ọ̀rọ̀ náà. 

Ìwé ìròyìn Medical News Today ti p’eni níjà pé kí àwọn ènìyàn má jẹ ẹran ti wọn kò sè jiná, kí àwọn alápatà sí rii wípé wọn pa ẹran ní ọ̀nà tó tọ́.

“Àwọn ènìyàn tó ń ṣiṣẹ pọ̀nmọ́, ẹgbọn-owu ati bẹẹ bẹẹ lọ gbọdọ ṣọra gidi, pàápàá ti wọn bá gbé àwọn oun wọnyi wá láti òkè òkun,” ìwádìí náà ló so báyìí.

Itoju

Wọn gbọdọ bẹrẹ itọju àìsàn Anthrax lásìkò, ki ọ má bàa burú sí. 

Wọn lè lo egbòogi antibiotics lati se itọju àìsàn náà. Àjọ tó rísí ètò ìlera ni Amẹrika, CDC salaye pe egbòogi yìí lè ṣe itọju oríṣi ẹ̀yà àìsàn náà.

Àwọn ènìyàn tó n ṣiṣẹ́ ọsin àti àwọn tí a dárúkọ tẹlẹ lo máa ń sábà gba abẹrẹ àjẹsára náà; wọn kìí lòó lẹ́yìn ti wọn ba fi ara kó àìsàn náà. Ṣùgbọ́n, wọn lè fún aláìsàn ní abẹrẹ àjẹsára tí àwọn agbesunmọmi ba fi àìsàn náà ṣe ikọlu sí ìlú.

Show More

Related Articles

Leave a Reply

Back to top button