African LanguagesFact CheckPoliticsYoruba

Steve Harvey ò wá sí Nàìjíríà láti wá ṣe ìpolongo ìdìbò fún Peter Obi

Ọ̀rọ̀: Aṣàmúlò ìtàkùn ìbáraenidọ́rẹ̀ẹẹ́ Facebook kan wípé gbajúgbajà atọkùn ètò tẹlifíṣàn ní ìlú Amẹ́ríkà, Steve Harvey, tiwà ní Nàìjíría láti gbárùkù ti olùdíje Lébọ́ Patì (Labour Party), Peter Obi.

Steve Harvey ò wá sí Nàìjíríà láti wá ṣe ìpolongo ìdìbò fún Peter Obi

Ìwádìí DUBAWA ṣe àfihàn wípé òtító kọ́ ni èyí. Steve Harvey ò sí ni Nàìjíría, bẹ́ẹ̀ sì ni kò fi ìgbà kan kéde àtìlẹ́yìn rẹ̀ fún ìkankan  láàárín àwọn  olùjíde ipò olórí orílẹ̀èdè Nàìjíría.

Ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ Àpilẹ̀kọ

Steve Harvey Sr. jẹ́ ọmọ Amẹ́ríkà tó ti gba ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àmì ẹ̀yẹ nínu ṣíṣé atọ́kùn fún èto tẹlifíṣàn. Ó ti ṣé àkóso “Steve Harvey Morning Show” àti “Family Feud,” láàárín àwọn ètò òmíràn. Ó bẹ̀rẹ iṣẹ́ yìí gẹ́gẹ́ bíi apanilẹ́rìín ní bíi ọdún 1980.

Ẹ̀yà àkọ́kọ́ ètò àgbéléwò rẹ̀ ní Nàìjíría, yíò jáde nínu oṣù kẹẹ̀wá, pẹ̀lú òṣèré fímù Yorùbá, Bísọ́lá Aiyéọ̀la, gẹ́gẹ́ bíi atọ́kùn.

Ìgbà tí ọmọ àárùndínláàdọ́rin yìí bẹ ọgbà òwò ẹrú wò ní “Elmina Castle”  ní orílẹ̀èdè Gánà, ní bíi ọdún mẹ́ta sẹyìn, ni ó kọ́kọ́ fi ẹsẹ̀ tẹ  ilẹ̀  Áfíríkà. Ṣùgbọ́n, ìyàlẹ́nu ni ó jẹ́ bí a ṣe rí ìròyìn lórí ẹ̀rọ ayélujára  wípé arákùnrin Harvey bẹ Nàìjíría wò, láti gbárùkù ti Peter Obi.

Steve Harvey ò wá sí Nàìjíríà láti wá ṣe ìpolongo ìdìbò fún Peter Obi
Ohun tí wọ́n kọ sórí ẹ̀rọ ayélujára

O kà pé, “Òṣèré Amẹ́ríkà, èyí tí ó ṣàkàwé Obi gẹ́gẹ́ bíi ẹni tí òhun ní ìgbàgbọ́ nínu rẹ̀ ti wà ní Nàìjíría pẹ̀lú mọ̀lẹ́bí rẹ̀, yíò sì ṣe àbẹ̀wò sí àwọn ibi ìgbafẹ́ kan pẹ̀lú àwọn ilé tí wọ́n kó ẹrú si. Èyí yíò ṣé àfihàn ìtàn Nàìjíría àti Afíríkà síi.”

Steve Harvey ò wá sí Nàìjíríà láti wá ṣe ìpolongo ìdìbò fún Peter Obi

Wọ́n ti kéde ọ̀rọ̀ yìí lórí  ìtàkùn ìbáraenidọ́rẹ̀ẹẹ́ Facebook. Ènìyàn 1,400 sì ti kà nípa oro yìí.

Steve Harvey ò wá sí Nàìjíríà láti wá ṣe ìpolongo ìdìbò fún Peter Obi
              Ìròyìn tí wọ́n n yíí ka

ÌFÌDÍMÚLẸ̀

Lákọ̀ọ́kọ́, DUBAWA fi ẹ̀rọ́ Gúgù ṣe ìwádìí ṣùgbọ́n, a kò rí ìwe ìròyìn kan tí ó kọ nípa wíwá arákùnrin Harvey sí orílẹ̀èdè Nàìjíría. Pẹ̀lú èyí, kò tún sí àhesọ nípa rẹ̀ lórí ẹ̀rọ sóṣía midìà òsèré yìí.

DUBAWA wá lo “Google Reverse Image Search,” irinṣé tí ó gba aṣàmúlò rẹ̀ láàyè láti ṣàgbéyẹ̀wò àwòràn. Èyí wá fi hàn pé fọ́tò tí wọ́n lò yìí ti wà lóri ẹ̀rọ ìbáraenidọ́rẹ̀ẹẹ́ Instagram rẹ̀ láti ọjọ́ ọgbọ̀n, óṣù kẹta. Lábẹ́ rẹ̀ sì ni ó kọ 

“Switched location to ABU DHABI 🙏🏿” sí. Èyí tí ó túmọ̀ sí, “mo ti wà  ní  ABU DHABI.”

Steve Harvey ò wá sí Nàìjíríà láti wá ṣe ìpolongo ìdìbò fún Peter Obi
Àbájáde Google Reverse Image Search
Steve Harvey ò wá sí Nàìjíríà láti wá ṣe ìpolongo ìdìbò fún Peter Obi
Ẹ̀rọ ìtàkùn Instagram Harvey

Síbẹ̀ si, a tún ri wípé Emirate Palace Hotel, Abu Dhabi ní ilẹ̀ United Arab ni ó ti ya àwòrán yìí.

Steve Harvey ò wá sí Nàìjíríà láti wá ṣe ìpolongo ìdìbò fún Peter Obi

Àkótán

Steve Harvey ò fìgbàkan bẹ Nàìjíría wò, bẹ́ẹ̀ sì ni kò ṣe ìpolongo ìdìbò fún Peter Obi. Torí náà, kò sí òdodo nínú ọ̀rọ̀ yìí.

Show More

Related Articles

Leave a Reply

Back to top button
Translate »