Getting your Trinity Audio player ready...
|
Àhesọ: Ìròyìn kan tí ó lédè ní orí ìtàkùn Instagram kan tí ó ǹjẹ́ Yoruba Nation News ni ó sọ wípé Bobrisky tí wà ní àtìmọ́lé àwọn EFCC fún ẹ̀sùn Owó kíkójẹ ní ọ̀nà àìmọ́.

Àbájáde: Ìwádìí fi hàn wípé Bobrisky kò sí ní àtìmọ́lé àwọn EFCC fún ẹ̀sùn Owó kíkójẹ ní ọ̀nà àìmọ́, bí kò ṣe fún ẹ̀sùn bíba owó Náírà jẹ́.
Ìròyìn Lẹ̀kúnrẹ́rẹ́
Ìròyìn kan tí ó lédè ní orí ìtàkùn Instagram tí ó ǹjẹ́ Yoruba Nation News ni ó sọ wípé Bobrisky tí wà ní àtìmọ́lé àwọn EFCC fún ẹ̀sùn Owó kíkójẹ ní ọ̀nà àìmọ́.
Ọkùnrin amúra bí obìnrin tí orúkọ ábísọ́ rẹ̀ ǹjẹ́ Idris Okuneye, èyí tí ìnagijẹ rẹ̀ ǹjẹ́ Bobrisky ni ó ti wà ní àtìmọ́lé àwọn àjọ tó ń gbógun ti ìwà ìbàjẹ́ àti ṣíṣe owó ìlú kúmokùmo EFCC láti ọjọ́ kẹrin oṣù kẹrin, ọdún 2024.
Ìfìdíọ̀rọ̀múlẹ̀
Gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ tí àjọ EFCC fi léde lórí ìtàkùn X wọn, òtítọ́ ọ̀rọ̀ náà já sí wípé, Bobrisky ti wà ní àgó EFCC láti ọjọ́ kẹrin oṣù kẹrin ọdún 2024, ṣùgbọ́n kìí se nítorí ẹ̀sùn owó kíkójẹ ní ọ̀nà àìmọ́ kankan.
Bobrisky ni àjọ EFCC pè fún ìwádìí àti ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwo látàrí owó níná ní ìná àpà àti àṣìlò owó Náírà ní ọ̀nà tó lòdì sí òfin àjọ CBN.
Nínú fọ́nrán kan tí ó jáde lórí ayélujára ni Bobrisky ti ń ṣe àfihàn ọ̀pọ̀lọpọ̀ owó Náírà tí ó sì tún náa pẹ̀lú. Fọ́nrán yìí jáde láti ibi ayẹyẹ ṣíṣe àfihàn sinimá Àjàkájú tí òṣèré tíátà – Ẹnìọlá Àjàó ṣe.
Gẹ́gẹ́ bí òfin àjọ CBN, fífi owó Náírà lẹ ni lórí, jíjó tàbí rírìn lórí owó Náírà ni yíò túmọ̀ sí àìbọ̀wọ̀ fún owó Náírà àti bíba owó Náírà jẹ́, èyí tí yíò sì mú ìbáwí sísan owó ìtanràn tàbí ẹ̀wọ̀n dání, tàbí àpapọ̀ ìjìyà méjèèjì wọ̀nyí.
Láti túbọ̀ fi ìdí ọ̀rọ̀ yìí múlẹ̀, àjọ EFCC ti fi àbáyọrí ìdájọ́ ẹ̀sùn tì wọ́n fi kan Bobrisky sí orí ìtàkùn won ni ọjọ́ kejìlá oṣù kẹrin ọdún 2024. Nínú ìdájọ́ náà, adájọ́ Abimbola Awogboro tí ilé ẹjọ́ àpapọ̀ ti Ìkòyí, rán Idris Okuneye (Bobrisky) ní ẹ̀wọ̀n oṣù mẹ́fà fún ẹ̀sùn bíba owó Náírà jẹ́.
Àkọtán
Bobrisky kò sí ní àtìmọ́lé àwọn EFCC fún ẹ̀sùn Owó kíkójẹ ní ọ̀nà àìmọ́ ṣùgbọ́n fún ẹ̀sùn bíba owó Náírà jẹ́.
The researcher produced this fact-check per the DUBAWA 2024 Kwame KariKari Fellowship, in partnership with Diamond 88.5 FM Nigeria, to enrich the ethos of “truth” in journalism and enhance media literacy in the country.