Ọ̀rọ̀: Ohun kan tí wọ́n ń gbé káàkiri ìtàkùn WhatsApp sọ pé ẹsẹ̀ ni ènìyàn ti ń darúgbó bọ̀ wá sí òkè.
Kò sí àrídájú ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì tí ó sọ pé ẹsẹ̀ ni ènìyàn ti ń darúgbó bọ̀ wá sí òkè nítorí pé dída arúgbó ní ipa ní ẹ̀yà ara kan ju òmíràn lọ.
Ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ Àpilẹ̀kọ
Ní àìpẹ́ yìí, ọrọ kan gba ìtàkùn ìbáraenidọ́rẹ̀ẹẹ́ WhatsApp kan pé dída arúgbó máa ń bẹ̀rẹ̀ láti ẹsẹ̀ wá sí òkè.
Àgbéjáde náà sọ síwájú si pé “Bí ènìyàn ṣe ń dàgbà si, bí ọpọlọ àti ẹsẹ̀ ṣe ń ṣiṣẹ́ sí máa ń dínkù, yàtọ̀ sí ìgbà èwe. *Jọ̀wọ́ rin*”
Ó ṣe àfikún pé “Ohun tó ń ran egungun lọ́wọ́ yóò sọnù ní ìgbà tó bá yá, tó ń jẹ́ kí àìlera egungun máa bá àwọn àgbàlagbà fíra jùlọ.
Ìwádìí síwájú si tún ṣe àfihàn pé àpilẹ̀kọ náà gba ìtàkùn Facebook kan, pẹ̀lú onírúurú àpilẹ̀kọ láti ọwọ́ Seth Smith àti Reach-Together Mudras àti Colour Therapy, tí àwọn ènìyàn ń ṣe àfihàn pé wọ́n fẹ́ràn, tí wọ́n sì ń fi ṣọwọ́ láti ìtàkùn kan sí ìkejì.
Ìlànà Dídàgbà
Dídàgbà pàápàá nínú ayé ènìyàn jẹ́ ìkórajọpọ̀ ìyàtọ̀ ní àkókò kan, èyí sì lè fi ara hàn nípa ìrísí, ọkàn àti ìhùwàsí.
Àjọ elétò ìlera àgbáyé (WHO) sọ pé nínu nǹkan ẹlẹ́mìí, dídá arúgbó máa ń wáyé láti ara àwọn èròjà kan tó ti ń dẹnu kọlẹ̀, èyí sì ń jẹ́ kí ipá pin ènìyàn, kí ewu àrùn máa pọ̀ síi, àti lẹ́yìn-o-reyìn, ikú.
Àwọn ìyàtọ̀ yìí lè fi ààyè sílẹ̀ fúnra wọn àbí kó jẹ́ léraléra, díẹ̀ sì ni wọ́n fi ní nǹkan ń ṣe pẹ̀lú ọjọ́ orí. Iyato o àwọn àgbàlagbà ò rí bákannáà. Kọjá a àwọn àyípadà àgọ́ ara, dída arúgbó ní nǹkan án ṣe pẹ̀lú àwọn ipele idagbasoke míràn bíi ìfẹ̀yìntì, kíkó lọ sí ilé tó dára àti ikú ọ̀rẹ́ àbí alábàárìn.
Kò sí ipele kan ṣoṣo tí ó lè ṣe àlàyé okùnfà dída arúgbó. Ìdí ni pé dída arúgbó jẹ́ ohun tó máa ń dé bá oníkálukú ní ọ̀nà ọ̀tọ̀. Àwọn onímọ̀ nípa ìṣesí ẹ̀dá ti ṣe ìwádìí pé bí ènìyàn ṣe ń dàgbà síi, àyípadà máa ń wáyé ní àwọn ẹ̀yà ara wọ̀nyí:
Ìpèsè èròjà ìdàgbàsókè.
Ọlọ́pàá àgọ́ ara
Awọ aral
Oorun
Egungun, iṣan àti oríkèéríkèé
Ọyàn
Ojú
Nǹkan ọmọbìnrin àti ọmọkùnrin
Ọkàn àti àwọn ẹ̀yà ara tó ń gbé ẹ̀jẹ̀ káàkiri
Kídìrín
Ìfun
Ẹ̀yà ara tó ní nǹkan án ṣe pẹ̀lú ọpọlọ.
Gẹ́gẹ́ bí àwọn onímọ̀ nípa èrò ọkàn ṣe sọ, bí oníkálukú ṣe ń di arúgbó yàtọ̀ síra, ó sì bẹ̀rẹ̀ láti ìgbà tí ènìyàn tí ń dàgbà. Se dída arúgbó ń bẹ̀rẹ̀ láti ẹsẹ̀ wá sí òkè lóòótọ́?
Dída arúgbó àti ẹsẹ̀
Ẹsẹ̀ ènìyàn jẹ́ ohun tó ní agbára, tó sì ní ojúṣe gbígbé gbogbo ara. Ó ṣe àkójọ onírúurú ẹ̀yà, bíi egungun mẹ́rìndínlógún, oríkèéríkèé mẹ́tàlélọ́gbọ̀n àti ọgọ́rùn-ún ẹ̀yà ara tó ń so egungun pọ̀.
Gbogbo ìwọ̀nyí ló ṣe kókó torí ẹsẹ̀ ní láti ṣe onírúurú iṣẹ́ bíi eré sísá, ìrìn ati òkè gígùn.
Gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ìwádìí kan tí wọ́n gbé jáde nínú ìwé ìmọ̀ Physical Therapy and Rehabilitation Journal, àwọn àyípadà to jọ mọ́ ọjọ́ orí ní ẹsẹ̀ fi mọ́ àyípadà awọ ara, tí yóò di háráhárá, tútù, tí yóò sì lè korokoro. Èyí ni bí ibi ṣóṣóró ẹsẹ̀ ṣe ń fẹ̀ síi, tí ó sì lè jẹ́ kí ìkà ẹsẹ̀ má dùn ń wò mọ́.
Iṣẹ̀ ẹ̀yà ara náà yóò máa ní àdínkù díẹ̀ díẹ̀, bẹ́ẹ̀ sì ni oríkèéríkèé, iṣan àti ipá láti lè kojú ú wàhálà.
Ṣùgbọ́n ṣé dída arúgbó máa ń bẹ̀rẹ̀ láti ẹsẹ̀?
ÌFÌDÍMÚLẸ̀
Onímọ̀ ìlera arúgbó kan, Dr Ezekiel Medunoye sọ pé kò sí ìfẹsẹ̀múlẹ̀ ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì tí ó sọ pé dída arúgbó bẹ̀rẹ̀ láti ẹsẹ̀ wá sí òkè.
Gẹ́gẹ́ bí ó ṣe sọ, “àwọn iṣẹ́ ẹ̀yà ara máa rí àdínkù bí ènìyàn ṣe ń dàgbà. Fún ìdí èyí, kò sí ẹ̀yà ara kan tó ń kọ́kọ́ darúgbó, ní bí gbogbo ẹ̀yà ṣe ń ṣiṣẹ́ pọ̀. Mo rò pé àwọn ẹ̀yà ara máa ń kojú ìṣòro lórí àì lè kó àwọn ipa tó yẹ.”
Elétò ìlera ẹbí kan, Ademola Ayodele sọ pé bí àgbà ṣe ń bá ẹ̀yà ara kọ̀ọ̀kan yàtọ̀ síra, ṣùgbọ́n kìí ṣe ẹsẹ̀ ni àgbà kọ́kọ́ máa ń bá wàyí, àfi tí ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì bá tún fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀.
Ó ṣe àfikún,”ni ìgbà tí àwọn egungun bá dẹ́kun àti máa dàgbà si, àrídájú ló jẹ́ pé irú ẹni bẹ́ẹ̀ ti dé gbèdéke rẹ̀ ní ọjọ́ orí. Tí ó bá sì jẹ́ pé ohun tí Wọ́n ń sọ nìyẹn nípa pé ẹsẹ̀ ni ènìyàn ti ń darúgbó bọ̀, mo lè gbà bẹ́ẹ̀. Ẹ̀wẹ̀, gbogbo ẹ̀yà ara ló ń ṣiṣẹ́ pọ̀, ní bí oníkálukú ṣe ń ṣe iṣẹ́ tirẹ̀ láti ṣiṣẹ́ pọ̀ fún rere.”
Ó sọ pé, “A ò lè sọ pé ibi báyìí ni dída arúgbó ti ń bẹ̀rẹ̀ nítorí ó kó onírúurú ipele pọ̀ ni, ẹ̀yà ara kọ̀ọ̀kan sì ń dàgbà ní ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, ṣùgbọ́n kìí ṣe ẹsẹ̀ ni àgbà kọ́kọ́ ń dé bá wàyí, àfi tí ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì bá tún fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀.”
Iṣẹ̀ ìwádìí kan ní àìpẹ́ ṣe àfihàn pé bí àwọn ènìyàn ṣe ń di arúgbó yàtọ̀ síra. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé gbogbo ẹ̀yà ara ló ń di arúgbó nínú àwọn ènìyàn mìíràn, àwọn kan tètè di arúgbó ṣáájú ìyókù. Fún ìdí èyí, ìyàtọ̀ díẹ̀ wà nínú bí oníkálukú ṣe ń di arúgbó.
Iṣẹ̀ ìwádìí mìíràn ṣe àfihàn pé bí ènìyàn ṣe ń di àgbà, ẹsẹ̀ nílò ìrànwọ́ láti di àgbà dáradára nítorí pé onírúurú àyípadà ló ń wáyé. Àwọn ẹ̀yà tó kó ara wọn jọ sí inú ẹsẹ̀ yóò máa kọ iṣẹ́ díẹ̀ díẹ̀, ṣùgbọ́n iṣẹ́ ìwádìí náà ò sọ pàtó pé ẹsẹ̀ ni ènìyàn ti ń darúgbó bọ̀. Ẹ̀wẹ̀, ó dá àbá pé bí ènìyàn ṣe ń di arúgbó, ríró àwọn iṣan ní agbára lè ṣe ìrànwọ́ fún iṣẹ́ ẹsẹ̀, èyí sì ní ipa rere sí dídúró déédéé, àti lílè yí kiri ní àkókò tó bá yẹ.
Àkótán
Kò sí àrídájú kan pàtó pé dída arúgbó bẹ̀rẹ̀ láti ẹsẹ̀ wá sí òkè, ní bí ipa tí dída arúgbó ní sí ẹ̀yà ara kọ̀ọ̀kan ṣe yàtọ̀ síra. Ẹ̀wẹ̀, ó dára láti ṣe ìtọ́jú ẹsẹ̀ dáradára.
Aṣèwádìí yìí pèsè àpilẹ̀kọ afi ìdí òdodo múlẹ̀ yi fún Dubawa 2021 Kwame KariKari Fellowship pelu Crest FM láti ṣe ìrànwọ́ fún ìfìdí òótọ́ múlẹ̀ nínú iṣẹ́ ìròyìn àti láti mú kí ẹ̀kọ́ gbèrú síi ní orílẹ̀ èdè yìí.