ExplainersHealthYoruba

Ṣé idoti ati ìwà ọ̀bùn ló ń ṣ’okunfa àkóràn ojú ara obìnrin? Oun tí o ní láti mọ̀ rèé

Getting your Trinity Audio player ready...

Arábìnrin kan tí a lè pe orúkọ rẹ̀ ní Lisa Joel, ṣàlàyé oun tí ojú rẹ̀ rí ní ilé ìwòsàn laipẹ yìí àti bí wọn ṣe fi abuku kàán lórí àkóràn ojú ara obìnrin, n’isẹ ni wọn ṣàpèjúwe rẹ gẹgẹbi obìnrin onidọti. 

Èyí ló fàá tí arabinrin náà ṣe fi ara pamọ́ ti o ba ti ní àárun yíì ki wọn má baà fì abuku kan. Ọpọlọpọ obìnrin lo wa ni ipò arábìnrin Joel, ti awọn ènìyàn ti fi abuku kan pé wọn jẹ́ ọ̀bùn nítorí wọn ní àkóràn ojú ara obìnrin. 

Kini àkóràn ojú ara obìnrin?

Àkóràn ojú ara obìnrin jẹ ààrùn o le fa ki eniyan máa yunra, ó lè fa iyipada àwọ̀ ojú ará tàbí itọ, o sì lè fa ìnira ti obìnrin ba fé tọ̀. 

Èyí lè jẹ ki ojú ara máa ṣe winiwini bíi ìgbà tí nnkan n rin nibe, o le mu ki nkan funfun máa jade loju ara, o sì lè fa yiyun ojú ara lọpọlọpọ ìgbà. Igbimo àwọn dókítà ti o n ṣíṣe igbẹgbi, American College of Obstetricians and Gynecologists ṣàlàyé wipe idamẹta awọn obinrin ló maa ní àkóràn ojú ara obìnrin ni awọn ìgbà kookan. 

Awon oloyinbo máa n pé àkóràn ojú ara obìnrin ni Vaginitis, ìyen ki ojú ara wú. Ààmì apẹrẹ ààrùn náà ni ki ojú ara máa yun obìnrin, òórùn burúkú, títa ríro ojú ara ati ìrora. Ṣugbọn, o se pàtàkì kí a mọ pé àkóràn ojú ara le ma fi ààmì kankan hàn. 

Ki lo le ṣokunfa àkóràn ojú ara?

Botilejepe oríṣiríṣi igbagbọ ni awọn ènìyàn ni nípa oun tó n ṣokunfa àkóràn ojú ara, ọpọlọpọ ènìyàn lo nigbagbo wípé aini ìmọ́tótó lo n fàá. Ṣugbọn, eyi kọ ló máa n sábà fa àkóràn ojú ara obìnrin. Àwọn oun tó maa n fàá ni ààrùn ojú ara, ààrùn ibalopọ ati bẹẹbẹẹlọ.

Kòkòrò àìlèfojúrí/elu 

Àkóràn ojú ara to wọpọ julọ ni a n pé ni Vaginitis, kòkòrò àìlèfojúrí/ elu ti o sì máa n fa ni a mọ sí candida. Orúkọ míràn ti wọn pé Viginitis ni èdè òyìnbó ni ulvovaginal candidiasis tabi vaginal candidiasis.

Orisirisi candida lo wa. Candida máa n saba wa ninu àgọ́ ara ènìyàn ni iwọntunwọnsi. Ṣugbọn ni ìgbà míràn, candida lè sadede dagbasoke ju bo ti yé lọ, èyí sì máa fà àkóràn ojú ara. Àwọn oun tó lè ṣokunfa eyi ni ki obìnrin lóyún sinu, òògùn ifetosọmọbibi tabi nkan oṣù. 

Àwọn oun míràn to le fa àkóràn ojú ara yìí ni ki eniyan ni àtọgbẹ to burú jai, ààrùn HIV tàbí AIDS. Aami àpẹẹrẹ ààrùn ojú ara ni ki ọyun funfun máa jade lara obinrin. Àkóràn ojú ara le mu ki obinrin máa yun ojú ara, ki ibe wu tabi ki o pọn. 

Kokoro àìlèfojúrí/ Alamọ

Oun míràn ti o máa n ṣokunfa àkóràn ojú ara ni alamọ. Gẹgẹbi candida ti n gbè nínú ara obìnrin, bee náà ni awọn alamo kan ti a n pé ni lactobacilli wa nínú ara. Ṣugbọn tí lactobacilli bá kéré ju, obìnrin lé ní àkóràn ojú ara. Kokoro Gardnerella jẹ alamọ ti o ma sábà n fa àìsàn ojú ara. Ti obìnrin ba ni àisàn ojú ara (bacterial vaginosis), o le máa ri ọyun funfun sugbon o ṣeéṣe ki obìnrin náà ma yun ojú ara. Kódà, ni àsìkò Ibalopọ, o ṣeéṣe ki ojú ara bèrè síí run bi ẹja to ti bàjẹ́. 

Ààrùn ibalopọ

Ni ìgbà míràn, ààrùn Ibalopọ máa n fa àkóràn ojú ara fún obìnrin. Àìsàn Ibalopọ kan ti o máa n saba fa àkóràn ojú ara fún obìnrin ni àwọn oloyinbo n pé ni Trichomoniasis. Kòkòrò trichomonas vaginalis ni o sì máa n fàá, kòkòrò náà máa n ti ara ololufe kan sí omiran ni àsìkò Ibalopọ. Aami àpẹẹrẹ Trichomoniasis ni ki ojú ara máa ta obìnrin, ọyun alawo èwe ti o sì máa run bi ẹja. Àwọn ẹlòmíràn máa ni inira ti wọn ba fé tọ.

Àìsàn Ibalopọ míràn ni atọsi. Èyí o saba ni aami àpẹẹrẹ kankan ṣugbọn o le mu ki oun funfun kan máa jade loju ara obìnrin, inira ti ènìyàn bá fẹ tọ ati lásìkò Ibalopọ. Àwọn obinrin ti wọn ba ni àisàn atọsi máa n saba ni chlamydia, nítorí èyí, obinrin ti àyẹwò ẹjẹ ba fihàn pé o ni àkóràn alamọ kan, a gba ìtọ́jú fún àkóràn alamọ keji. 

Ọlọjẹ

Ọlọjẹ jẹ oun kan pàtàkì ti o máa n fa àìsàn Ibalopọ. Ọlọjẹ bíi herpes simplex virus (HSV) tabi human papillomavirus (HPV), máa n saba wọle s’ago ara lásìkò ibalopọ. O le fa ọgbẹ tabi egbò sí ojú ara obìnrin, èyí sì máa n mu ìrora dani. 

Ikorira nkan

Èyí kìí ṣe àkóràn lọ títí, sugbon obìnrin lé ní ààrùn ojú ara ti ara rẹ ba kọ àwọn oun èlò kọọkan bíi ọsẹ ìwẹ̀ òní lọ́fíndà. Oun tí o ní láti ṣe ni ki o mú àwọn oun èlò yìí kúrò. Ni ìgbà míràn, ṣiṣe ìyọkúrò oún èlò yìí ò tó, o ni lati gba ìtọjú fún ìwòsàn tó péye. 

Aiṣedede èròjà omoonu inu ara obìnrin 

Èyí ni a mọ sí atrophic vaginitis. Ni ìgbà míràn, èròjà omoonu le dede walẹ ni ìgbà tí nnkan oṣù wọn ba dawo duro (menopause), ojú ara a sì kere, gbẹ sí. Aiṣedede èròjà omoonu yìí lè fa àkóràn ojú ara obìnrin. 

Itọju àkóràn ojú ara 

Orisirisi aba ni awọn eniyan máa n mu wa ti ènìyàn bá ní àkóràn ojú ara sugbon gbogbo èyí pin sí ọ̀nà méjì: lilo òògùn tabi ọna adayeba. Botilejepe òmìrán nínú àwọn àbá yìí sise daada, ni ìgbà míràn, nise ni o n jani kulẹ. 

Ọ̀nà adayeba

Wàrà àwọn ará Giriki (Greek Yogurt): oun kan pàtàkì ti àwọn ènìyàn má n lo fun itọju àìsàn ojú ara ni a mọ sí Greek yogurt, nítorí èròjà probiotics ti o wa ninu rẹ lè gbógun ti Candida Albicans. Greek Yogurt yìí máa n ni alamọ bíi Lactobacillus acidophilus. Àwọn alamo yìí máa n ṣe ìdáàbòbò ojú ara obìnrin, o sì lè gbógun ti aisan. 

Ìwádìí fi le’lẹ pé kí eniyan máa jẹ wàrà yìí lè ṣe iranlọwọ fun ifun-ounje, yòò sí ṣe idinku iwukara (yeast) nínú ara ènìyàn. Tí ènìyàn o ba feran wàrà, o le lo òògùn ti o ni èròjà probiotics tabi jẹ àwọn oúnjẹ míràn. Ti o ba fẹ lo wàrà fún itọju ìwúkàrà, o se dandan ki o lo Greek Yogurt nítorí kò sí adun kankan ninu rẹ. 

Kanafuru: èròjà aṣaraloore ni èyí, o sì ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ anfaani. O le bá ní gbógun ti àtọgbẹ tabi itọ ṣuga. O máa n gbógun ti awọn alamọ, o sì jẹ ona kan pàtàkì ti ènìyàn lè ṣe idojuko àìsàn ojú ara. 

Essential Oregano oil: Ti o ba fẹ fi èyí ṣe itọju àkóràn ojú ara obìnrin, o di dandan ki o ṣàwarí òróró oregano ti wọn gbà sílẹ lataara ẹwẹ igbo oregano tabi Origanum vulgare.  Ìwádìí fihàn pé ororo ara oregano lè gbógun ti ìdàgbàsókè kòkòrò C. Albicans. 

ÌKÌLỌ: Ma ṣe mu àwọn ororo wọnyi. Oun kan ti o le ṣe ni ki o fa ororo na sí imu tabi ki wọn fi kun nkan míràn fún itọju.

Adi àgbon: Wọn máa n gba àdí agbon silẹ lataara agbọn. Ọpọlọpọ anfaani ni o wa lara àdí agbọn. Ìwádìí fihàn pé àdí agbọn síse lodi sì kòkòrò Candida Albicans. Ti o ba fe ṣe itoju àìsàn ojú ara pelu àdí agbọn rà ojúlówó àdí agbọn. O le fi adi àgbọn yìí sí ojú egbo náà. Àwọn oun míràn ni Boric acid, apple cider vinegar ati hydrogen peroxide.

Lilo òògùn 

Òògùn ti o n gbógun ti elu: Àwọn òògùn yìí máa n gbógun ti aisan ojú ara obìnrin. Ṣugbọn, òògùn kan ni pato ni ìṣe ti o n ṣe. 

Àwọn òógún wọnyi a máa gbógun ti elu ni àgọ ara ènìyàn. Aláìsàn lè gbe òògùn yìí mi, wọn sì lè fi pa ara fún bíi ọjọ méje.. 

Won le fi òògùn náà sí sàkání ojú ará tabi ki wọn fi oun èlò fi sí inú ojú ara gangan (suppository). 

Òògùn ti o gbogun ti elu ti o wọpọ julọ ni a mọ sí miconazole tabi terconazole. Dokita tabi oniyọnu ni yóó ṣàlàyé bi wọn a ṣe lo òògùn naa. O se pàtàkì kí aláìsàn tẹle ilana ti dókítà filelẹ, fún itọju to péye. 

Ti eniyan ba n gba ìtọjú fún aisan ojú ara, o se pàtàkì kí wọn yàgò fun Ibalopọ fun asiko naa. Ibalopọ lè mu inira dání, kódà, àwọn òógún ti o.gbigun ti elu yìí lè mu ki roba idaabobo má sise daadaa.

Aporó (Antibiotics): Wọn máa n fi òògùn yìí se itoju àìsàn ojú ara obìnrin. Metronidazole bíi Flagyl, Metrogel-Vaginal ati bẹẹbẹẹlọ). Òògùn náà lè wà gẹgẹbi koro ogún tabi bíi ipara. Alaisan máa gbe koro ogun mi sugbon wọn a fi ipara tabi jeeli náà sí inú ojú ara gangan. Yàgò fún mímú ọtí líle tí o ba n lo òògùn yìí nítorí akanpọ náà lè fa inú rirun. Ki o sì ṣe ayẹwo ikilọ to wa lára òògùn náà.   Clindamycin (Cleocin, Clindesse, ati bẹẹbẹẹlọ). Ipara ni èyí, óò sí fi sí inú ojú ara rẹ, o sì lè lo koro oogun. 

Òògùn yìí lè ṣe ikọlu fún roba idaabobo lásìkò Ibalopọ. Yẹra fún Ibalopọ tí o bá n lo òògùn yìí, kò sí fi ọjọ meta kun leyin Ibalopọ.

O sì lè lo ìlànà ifetosọmọbibi míràn bíi ipara estrogen tabi kóró òògùn estrogen, èyí lè ṣe iranlọwọ fún itọju ojú ara to gbẹ, ti o máa n fa àìsàn ojú ara ti a mọ sí atrophic vaginitis.

Kini onimọ sọ?

Dókítà Hussayan Hussaini ti o jẹ oṣiṣẹ Maitama District Hospital, ṣàlàyé pé àwọn oun tó lè fa àìsàn ojú ara obìnrin ni aiṣedede omi ara (PH) ati ààrùn ibalopọ. Botilẹjẹpe èyí sọwọn, àtọgbẹ, ààrùn HIV àti kí eniyan máa lo òògùn aporo (antibiotics) fun ìgbà pípẹ́, lè fa àìsàn ojú ara. O fikun pé o ṣeéṣe kí oúnjẹ ti a n jẹ ni ipá lórí àìsàn ojú ara obìnrin. 

“Awon aporó míràn (antibiotics) lè má ṣiṣe botiyẹ, nítorí èyí, o se pàtàkì kí a mọ itan ìlera ènìyàn. O ṣeéṣe kí lilọ òògùn lọnà àìtọ́ fa ìjàmbá fún aisan yìí,” dókítà náà ló sọ bẹẹ. 

Àkótán

Botilẹjẹpe idọti ati ìwà ọbun lè ṣokunfa àìsàn ojú ara obìnrin, kìí se oun nikan lo le fàá. Ìwádìí ati ọ̀rọ̀ àwọn onimọ fihàn pé ìwà ọbun kii ṣe papanbari oun tó n ṣokunfa àìsàn náà.

Show More

Related Articles

Leave a Reply

Back to top button