Getting your Trinity Audio player ready...
|
Àhesọ: Aṣàmúlò TikTok kan, nípasẹ̀ fọ́nrán kan sọ pé Donald Trump ti pàṣe ìdíwọ́ ìwé-ìrìnà fún àwọn aṣíkiri láti orílẹ̀-èdè Nàìjíríà lọ sí US.
Àbájáde Ìwádìí: Ìwádìí DUBAWA fi hàn pé wọ́n tí fí ẹ̀rọ́ ayélujára yí fọ́nrán yìí padà láti jọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ lótìítọ́. Bákannáà, ó ṣì di oṣù àkọ́kọ́, ọdún 2025 kí wọ́n tó búra fún Ọgbẹ́ni Trump. Dì’gbà náà, kò tíì lágbára láti máà pàṣẹ.
Ìròyìn Lẹ́kùńrẹ́rẹ́
Orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà (US) ṣe ìdìbò ààrẹ wọn ní ọjọ́ kẹrin, oṣù kọkànlá, ọdún 2024, nínú èyí tí Ọ̀gbẹ́ni Trump àti Kamala Harris figagbága, ṣúgbọ́n tí Ọ̀gbẹ́ni Trump pàpà borí.
Lẹ́yìn ìdìbò tí wọ́n ròyìn rẹ̀, aṣàmúlò TikTok kan, Queen of All, pín fídíò kan tí ó sọ pé Ọ̀gbẹ́ni Trump ti kéde ìdènà ìwé ìrìnnà tuntun tí ó dojú kọ àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tí wọ́n ń wá ọ̀nà láti wọ US.
Fídíò ìṣẹ́jú àáyá aádọ̀rún náà fi hàn pé Ọ̀gbẹ́ni Trump ń kéde ìfòfindè ìwé ìrìnnà lórí àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Ó rọ̀ wọ́n láti dúró sí orílẹ̀-èdè wọn kí wọ́n sì máa ṣe ìdókòwò.
“Mò ń kéde ìyípadà ìlànà fún ìgbà díẹ̀, èyí tí ó ní èrògbà láti gba àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà níyànjú, pàápàá jùlọ àwọn tí wọ́n wà nínú iṣẹ́ pàtàkì, láti dúró, ṣe ìdókòwò, kí wọ́n sì ṣiṣẹ́ ní orílẹ̀-èdè wọn. Gẹ́gẹ́ bí ara ìlànà yìí, orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà yóò dín àwọn ìfọwọ́sowọ́pọ̀ ìwé ìrìnnà kan kù fún àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, pẹ̀lú dókítà, nọ́ọ̀sì, onímọ̀-ẹ̀rọ, àti àwọn mìíràn ní àwọn àgbègbè pàtàkì.”
Ó fi kún un pé, “Èyí kì í ṣe ìgbésẹ̀ tí àwọ́n gbé pẹ̀lú ìrọ̀rùn, bẹ́ẹ̀ ni kò yẹ kí ó pinnu ìpààrọ̀ àṣà tàbí ìfọwọ́sowọ́pọ̀ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè wa. Kàkà bẹ́ẹ̀, èyí jẹ́ ìpè sí ìgbésẹ̀ fún àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà láti ya ọgbọ́n wọn sí ìlọsíwájú Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà fúnra rẹ̀.”
Ní Nov. 16, 2024, aṣàmúlò 26,000 ló ti buwolu ìkéde yìí tí 3,000 sì dá sí ọ̀rọ̀ náà. Àwọn aṣàmúlò kan gbàgbọ́ pé òtítọ́ ní àtẹ̀jíṣẹ́ náà, nígbà tí àwọn mìíràn dábàá pé Artificial Intelligence (AI) ló ṣẹ̀dá fídíò náà.
A rí irúfẹ́ fídíò kan náà lórí X (níbí, níbí, níbí, àti níbí).
DUBAWA ṣe ìwádìí fídíò TikTok yìí láti ṣàyẹ̀wò bóyá ààrẹ orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà tí wọ́n yàn sọ àwọn ọ̀rọ̀ tí wọ́n wípé ó sọ.
Ìfìdíòdodomúlẹ̀
DUBAWA ṣe àkíyèsí àìṣedéédé láàrin ìgbésẹ̀ ètè Trump àti àwọn ọ̀rọ̀, èyí tí kò ní ìṣọ̀kan. Èyí sábà máa ń jẹ́ àléébù tí ó hàn kedere tí wọ́n ṣe nígbà tí wọ́n bá ti yí àwọn ohun ìní fídíò padà. A tún fi díẹ̀ lára àwọn abala fídíò náà sí Google Reverse Image Search. Èsì náà mú wa lọ sí ọ̀rọ̀ ìṣẹ́gun Ọ̀gbẹ́ni Trump, nibi ayeye aseyori idibo re, laipe yii, yí tí ó ní ìbámu pẹ̀lú ẹ̀yà tí ẹni tí ó fi ìkéde yìí sórí afẹ́fẹ́.
Wọ́n bo apá ìsàlẹ̀ fídíò TikTok yìí pẹ̀lú àwọn àwòrán Ààrẹ Bola Tinubu àti Ààrẹ tí wọ́n sẹ̀sẹ̀ yàn, Trump láti jẹ́ kí àwọn aṣàmúlò gbàgbọ́ nínú òtítọ́ fídíò náà. Sùgbọ́n, a kò rí èyí nínú ojúlówó fọ́nrán tí wọ́n yípadà.
Nígbà tí a ṣe àkíyèsí àìṣedéédé nínú ìmúṣiṣẹ́pọ̀ ọ̀rọ̀, a ṣe àtúpalẹ̀ fídíò nípa lílo Deepwater, irinṣẹ́ ìwádìí ìjìnlẹ̀. Èsì náà kò fi ẹ̀rí kankan hàn nípa àwọn àbùdá deepfake.
Ṣíṣ’iyemeji lórí àbájáde láti Deepware, DUBAWA ló ẹ̀rọ olùwárí ohùn àfetígbọ́ “Hive Moderation,” èyí tó fihàn pé 99% fọ́nrán ọ̀hún jẹ́ ayédèrú.
Síwájú sí i, ọ̀rọ̀ ìṣẹ́gun Ọ̀gbẹ́ni Trump níbi ayẹyẹ náà kò mẹ́nuba ìdènà ìwé ìrìnnà US kankan tí wọ́n ní wọ́n gbé kalẹ̀ lórí àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.
Bákannáà, a ṣàyẹ̀wò ojú òpó X Ọ̀gbẹ́ni Trump fún àwọn àlàyé nípa ẹ̀sùn tí wọ́n sọ ṣùgbọ́n a kò rí àtẹ̀jíṣẹ́ kankan lorí ẹ̀sùn náà.
Ó yẹ kí ó ṣe àkíyèsí pé bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ti kéde ààrẹ tẹ́lẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olùborí, wọn kò tí ì búra fún un gẹ́gẹ́ bí ààrẹ orílẹ̀-èdè Àríwá Amẹ́ríkà – àṣà òṣèlú tí ó fún un lágbára láti ṣòfin gẹ́gẹ́ bí ààrẹ. Gẹ́gẹ́ bí ìròyìn ṣe sọ, wọ́n yóò ṣètò ibúra ìgbàjọba fún ùn ní Jan. 20, 2025.
Àkótán
Ìwádìí DUBAWA fi hàn pé wọ́n tí fí ẹ̀rọ́ ayélujára yí fọ́nrán yìí padà láti jọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ lótìítọ́. Bákannáà, ó ṣì di oṣù àkọ́kọ́, ọdún 2025 kí wọ́n tó búra fún Ọgbẹ́ni Trump. Dì’gbà náà, kò tíì lágbára láti máà pàṣẹ.
Miracle Akubuo ló kọ́kọ́ ṣ’àkọsílẹ ìwádìí yìí lé’dè gẹ̀ẹ́sì, tí Sunday Awóṣòro sì túmọ̀ rẹ̀ sí ède Yorùbá.