Fact CheckYoruba

Ǹjẹ́ àjọ NDLEA yan Naira Marley sípò aṣojú?

Getting your Trinity Audio player ready...

Aheso: Orísirísi aheso àti ìròyìn ni ó tanka orí ẹrọ alatagba pé gbajugbaja olorin takasufe, Azeez Fasola, ti awọn eniyan mọ sí Naira Marley, ni wọ́n fí ṣe aṣojú àjọ tó ń gbógunti lílo egbògi olóró ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, NDLEA.

Ǹjẹ́ àjọ NDLEA yan Naira Marley sípò aṣojú?

Àbájáde iwadii: Irọ́ ni ọ̀rọ̀ náà. Nínú atẹjade kan tí agbẹnusọ àjọ náà fi síta l’ọ́jọ́ kọkandinlogun oṣù kẹjọ ọdún yìí, àjọ NDLEA ṣàlàyé pé àwọn kò yan Naira Marley sípò aṣojú. 

Ìròyìn lẹkunrẹrẹ 

Lẹyìn ikú gbajúmọ̀ olórin Promise Aloba ti àwon ènìyàn mọ sí Mohbad ni ọjọ kejìlá oṣù kẹsán ọdún 2023, oríṣiríṣi ìròyìn lo tanka orí ayélujára pe oga rẹ teleri, Azeez Fasola (Naira Marley) fi ìyà jẹẹ́. Fónrán akalekako kàn, ṣafihan ibi ti olóògbé ti ṣàlàyé pe àjọ NDLEA fún òun ní májèlé mu, awon eniyan sì n soro nipa fónrán oun àti oun tó fa ikú oloogbe. 

Awọn olumulo ẹ̀rọ alatagba ń fi abuku kan Náírà Marley àti ile-ise orin, Marlian Music, lórí ikú Mohbad. Bí awọn ọmọ orilẹ-ede Nàìjíríà ti n rọ awọn ẹṣọ aláàbò pé kí wọ́n ṣe ìwádìí to péye lórí ọrọ naa, àwọn ẹlòmíràn bu enu àtẹ́ lu NDLEA fún ibaṣepọ won pelu ọgbẹni Fasola (Naira Marley).

Àjọ ti o n gbogun ti lilo oògùn olóró ni ile Afirika (African Council on Narcotics), ta àjọ NDLEA lolobo pe kí wọn fi opin sí iyansipo Naira Marley gegebi aṣojú, pàápàá lasiko ìwádìí oun to ṣe ikú pa Mohbad. 

Nínú awọn orin wọn, ogbeni Fasola àti ilé iṣẹ Marlian Music máa ń sábà ṣẹ atilẹyin fún lílo oògùn olóró, èyí lo fàá ti àjọ NDLEA fi kọlu ilé Naira Marley ti wọn si ri oògùn olóró níbẹ̀, ní oṣù kejì ọdún tó kọjá. 

Ni ọjọ ketadinlogun oṣù kẹjọ ọdún 2023, ọgbẹni Fasola, ti a mọ̀ ṣì Naira Marley ṣ’abẹwo sí olú Ileeṣẹ àjọ NDLEA ni ibi ti o ti polongo pẹ kí awọn eniyan yago fún lílo oògùn olóró. 

Nítorí fónrán ọ̀ún, àwọn eniyan bèrè síí gbé ahesọ pé aṣojú àjọ NDLEA ni Náírà Marley jẹ́, pàápàá leyin iku olorin takasufe Mohbad. Lórí ikanni abeyefo, ọpọlọpọ eniyan ló gbé ahesọ wọnyi, lára wọn ni @DrOlufunmillayo, @FS_Yusuf_, @instablog9ja, àti beebeelo.

Ifidiododomule

Leyin ti fónrán Naira Marley gbilẹ ni ọjọ ketadinlogun oṣù kejo odun yii, awọn eniyan bù enu atelu àjọ NDLEA. Sugbon ni ọjọ kokandinlogun oṣù kẹjọ kanna, agbẹnusọ àjọ NDLEA, Femi Babafemi fi atẹjade kan sita, ni ibi ti o ti ṣàlàyé pe kó si ibaṣepọ kankan laarin àjọ NDLEA àti Naira Marley. 

“O ṣe pàtàkì ki a fi ìdí òdodo múlẹ nitori ọpọlọpọ ènìyàn ló túmọ abewo Naira Marley ṣi ileese wa l’ọna odi, koda àwọn ẹlòmíràn rò wipe a fi olorin naa jẹ aṣojú àjọ wa”, díẹ lára atejade NDLEA lo sọ èyí.

O tunbọ ṣàlàyé pé, “Asinilona àti irọ to jina sí ooto ni ọ̀rọ̀ náà, nítorí a ṣ’àlàyé lẹkunrẹrẹ oun ti Náírà Marley ba wa sí ilẹ iṣẹ wà ninu aworan àti fónrán ti a gba silẹ. Kó si ibi ti a ti mẹnuba iyansipo olorin naa gegebi aṣojú àjọ wa. 

Àkótan

Irọ àti asinilona ni ahesọ pe Naira Marley jẹ aṣojú àjọ NDLEA. Ninu atejade kan ti àjọ NDLEA gbejade ni ọjọ ketadinlogun oṣù kẹjọ ọdún yii, àjọ náà ṣàlàyé bi ọrọ naa ti rí, pe Naira Marley kìí ṣe aṣojú wọn. 

Show More

Related Articles

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Back to top button
Translate »