|
Getting your Trinity Audio player ready...
|
Aheso: Olùmúlò Instagram kan, @Drbelswelness, sọ pé ìwádìí tuntun fihàn pé àbùkù kìí débá ẹyin obìnrin pẹ̀lú ọjọ́-orí, àti pé bi okunrin ṣe n dagba sii, bee ni aleebu àtọ̀ rẹ̀ n pọ si.

Àbajade iwadii: Aṣinílọ́nà. Ẹ̀rí tí ìmọ̀-jìnlẹ̀ fihàn pé ati àtọ̀ ọkùnrin àti eyin obìnrin ni abuku maa n deba bi won see n dagba sii, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ní ọ̀nà ọtọọtọ ni. Àwọn obìnrin pàdánù iye eyin ati didára àwọn eyin, nigba tí àwọn ọkùnrin a ni idínkù didára àtọ̀ àti àwọn ìyípadà miran.
Alaye l’ekunrere
Ìmọ̀ iṣegun igbalode n kọ wa ni oun titun nipa ara ènìyàn. Ní aye ode oni, àwọn ìlọsíwájú nínú imọ jiini àti ìmọ̀-jìnlẹ̀ molékúlà, ní ìdàpọ̀ pẹ̀lú àwòrán ìṣògùn tuntun àti àwọn irinṣẹ́ ìtúpalẹ̀ data, ti yípadà òye ti ìlera àti àrùn. Àwọn ìtẹ̀síwájú wọ̀nyí ti yọrí sí ìwòsàn àti àwọn ìwádìí tí ó dà bí ẹni pé kò ṣeé ṣe nígbà kan rí, tí ó fihàn pé púpọ̀ nípa ara ènìyàn ṣì wà tí a kò tii ṣàwárí.
Láìpẹ́ yìí, olùmúlò Instagram kan @Drbelswelness sọ pé iwadii tuntun ti fihàn pé ẹyin obìnrin kò ni abuku pẹ̀lú ọjọ́-orí, ṣugbọn atọ ọkùnrin ni ó ní maa n ni aleebu bi okunrin ṣe n dagba si.
Olùmúlò náà kọwe pe, “Wa ti ma gbọ pé ilẹ obírín kii pẹ ṣu. Iwadii sayẹnsi fidi rẹ̀ mú’lẹ̀ bayii pé àwọn ọkùnrin pẹ̀lú ní aago ibi. Awon oniwadii ṣ’ayẹwo ohun t’o wa ninu atọ okunrin ati ẹyin obinrin, oun ti wọn ri si je kayefi. Abuku kii saba deba eyin obinrin bi obinrin ṣe n dagba sii, ṣugbọn ti okunrin maa bere sii ni aleebu.”
@Drbelswelness tún ṣàlàyé pé nítorí pé ìyípadà a maa ṣẹlẹ̀ ninu atọ pẹ̀lú ọjọ́ orí okunrin, àwọn ọmọ bàbá àgbàlagbà lè kojú àwọn ewu tí ó ga jùlọ bíi ji ọpọlọ ma pe, Down syndrome, ìpèníjà autism, àti ọdẹ ori, schizophrenia.
Olùmúlò náà jẹ́wọ́ pé ọjọ́-orí le dínkù iye àwọn ẹ̀yin obìnrin, èyítí ó lè jẹ́ kí oyún le àti mú eewu iṣẹ́yún pọ̀ síi, ṣùgbọ́n o jiyàn pé DNA ẹ̀yin ṣi dara sibe sugbon atọ okunrin kò ri bee.
Ni ojo kerinlelogun, oṣù kẹwaa odun 2025, ọpọlọpọ eeyan lo ti bu owo ife luu atejade naa.
A rii pe awon olumulo bere sii se ariyanjiyan lori ọ̀rọ̀ naa.
Pelu ìdùnnú nípa ìfihàn yìí, olumulo @Nanaya102 kọ̀wé, “Mo rii pe sáyẹ́nsì ní lati ra’wọ ẹbẹ sí awa obinrin nítorí pé a ti ní ìpalára fún ìgbà pípẹ́ nípa eya ara ibimọ. Ògo ni fún Ọlọ́run, sayensi ti se idálare ile omo wa. Jẹ́ kí n sùn ní àlàáfíà”. Olumulo miran, @Deborah kọ̀wé, “Ẹ̀yin àgbàlagbà obìnrin, e bere sii fẹ àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin. Iwo agbalagba okunrin, tí ó bá wun ọ́, má ṣe lọ gbéyàwó, àkókò rẹ ń lọ.”
@Official Dralex béèrè orísun ìwádìí náà. Ó kọ̀wé, “Ìlú wo ni a ti ṣe nkan ìwádìí náà, àti orílẹ̀-èdè wo ni ó ṣe? Kí ni àwọn oníyẹ̀mẹ̀yà, àwọn àyẹ̀wò tí a lò láti inú àpẹrẹ wo, àgbègbè, àti ẹ̀dá ènìyàn?”
@Dr Amandajordan, ko faramo oun ti dokita naa sọ, o kowe, “Iro gbaa ni ọ̀rọ̀ yii. Ẹyin obinrin maa n dagba sii gegebi gbogbo eya ara eniyan ṣe n dagba sii. Otito ni oro to sọ pe atọ okunrin maa n gbo. Ko daa ki o mu iro ati otito papo.”
@Davev ṣ’afikun pe, “Irọ ni ọrọ naa. Imo sayensi o sọ oun to jọ bẹẹ.”
Ariyanjiyan wa lori oro naa. Awon olumulo kookan faramo, koda inu won dun sii, nigba ti awon kan lero pe iro tabi asinilona ni oro naa. DUBAWA se iwadii lati fi idi ododo mule.
Ifidiododomule
A kan si eni ti o soro ki o le tokasi orisun iwadii naa sugbon ko fesi. DUBAWA se itopinpin koko oro lori eyin obinrin ati ato okunrin ati pe bawo gaan ni ojo ori se le ṣ’akoba fun awon nkan wonyi.
Itopinpin naa je ki a sawari orisiriri iwadii lori oro naa to fihan pe looto ojo ori le sakoba fun ato okunrin ati eyin obinrin ṣugbọn akoba naa ni odiwon fun okunrin ati obinrin.
Iwadii odun 2025 ni inu iwe iwadii awon onimo, Journal of Ovarian Research fihan pe bi obinrin ṣe n dagba sii, bee ni iyipada n de ba ago ara re ti o si maa sakoba fun eyin leyin o reyin. Iwadii na fikun pe awon iyipada wonyi le faa ki obinrin ti o dagba díẹ̀ bi ọmọ to ni ipenija Down Syndrome.
Iwadii miran lori PubMed fihan pe ti omobinrin ba pe odun marunlelogbon, o le ni aneuploidy ti o maa n mu ki kromosomu po si lara obinrin. Awon iwadii wonyi fidire mule pe ojo ori le se akoba fun eyin obinrin, eyi tumo si pe oun ti Dokita Bels so lori oju opo re je oro asinilona.
Ni ida keji, iwadii fihan pe awon okunrin a maa se ato titi ti won a fi ku ni sugbon o seese ki okunrin maa dagba sii, ki ato re si di alailokun. Iwadii kan lori Nature Reviews Genetics ṣ’agbekale rẹ pe awon omo baba agbalagba wa ninu ewu ipenija bii autism ati aarun ọpọlọ. Iwadii miran lori Nature ṣ’atileyin oro naa.
Awon iwadii yii je ki a mo pe t’akọ t’abo ni ojo ori maa n se akoba fun sugbon ona otooto ni. Iye eyin ti o maa wa ninu ile eyin obinrin a maa dinku bi o ṣee n dagba sii, okunrin a bere sii ni ipenija ato ti ko lokun.
Gbogbo awon iwadii wonyi ko fi idi re mule pe eyin obinrin dara si pelu ojo ori tabi okunrin ko ni le bimo bi o se n dagba sii. Iwadii fihan pe ati okunrin ati obinrin lo wa ninu ewu ti o niise pelu eya ara bibi omo ti won se n dagba sii.
Akotan
Iwadii ṣi tẹsiwaju lori eya ara ti a fi n bimo, sugbon ko si iwadii kankan to fidiremule pe eyin obinrin dara sii bi o se n dagba sii. Ati akọ ati abo lo ni idojuko pelu omo bibi bi ojo ori won ṣe n pọ sii. Nitori eyi, asinilona ni ọrọ ti @Drbelswelness sọ.




