Getting your Trinity Audio player ready...
|
Aheso: Olumulo ikanni ibaraenisore sọ wípé ènìyàn lè fi ìtọ àárọ̀ kùtùkùtù ṣe ìtọ́jú aarun conjunctivitis.

Abajade iwadii: Irọ nla! Àkọsílẹ̀ àti ifọrọwanilẹnuwo pelu àwọn onímọ̀ fihan pé itọ ò le ṣe nkankan nínu itọju ojú pipọn.
Ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé
Ni ọjọ abameta, ọjọ kejidinlọgbọn oṣù kejila ọdún tó kọjá, olumulo ìkànnì Facebook Millicent Xandercs, pin fọ́nrán kan tó ṣ’afihan bi o ti n nu ojú ọmọ re ti o ni Apollo. Olumulo náà ṣàlàyé pé ọmọbìnrin òun ji laarọ kùtùkùtù, ko si le làjú nít’orí ipin ti lé si ojú ọmọbìnrin naa.
Awon olumulo miran lori ìkànnì naa báa dásí ọ̀rọ̀ naa, àwọn kan bẹ̀rẹ̀ sii daruko oun to le sokunfa aisan naa, bee lawon kan ba n wa ojútùú si ìṣòro naa.
Àwọn kan ni ki arábìnrin naa yára gbe ọmọ rẹ̀ lọ ilé ìwòsàn, awon ẹlomiran sọ pe ki o fi omi to lọ woro fọ ojú ọmọ náà.
Olumulo kan, Abigail Chollom so wipe, “Aarun oju pipon re o. E jọ̀wọ́, ẹ lo oogun chloramphenicol ti wọn ma n kan si oju fun omo náà. Ṣé ọmọbìnrin náà n wu ikó, ṣé o gbé ikun le’mu, se o ni eela tàbí ìgbónára? Tí ọmọ náà bá ní àwọn nkan wọ̀nyí, jọ̀wọ́ je kín mọ.”
Arábìnrin Naomi Le Bourne bù ẹnu ate lu ọna ti obìnrin inú fọ́nrán náà lo láti nù ipin ojú ọmọ náà, o gba níyànjú pe ki o sa tọ àwọn oníṣègùn oyinbo lọ.
“Bí wọn ṣe ń ṣe itoju oju kọ lèyí. Lílọ aṣọ kanna fún ojú méjèèjì lè mú kí àkóràn bo si oju kejì. Gbe lọ sí ilé ìwòsàn ni kíákíá,” arábìnrin Naomi lo sọ eyi.
Òun ti o pe àkíyèsí wá ní ọ̀rọ̀ tí Veralove Onoja sọ pe ki arábìnrin naa fi ito àárọ̀ kùtùkùtù fọ ojú ọmọ náà.
O ni, “Aarun oju pipon rèé. O maa pajude ni. Fi ito àárọ̀ kùtùkùtù fọ ojú ọmọ rẹ̀. Kìí ṣe gbogbo ìgbà là má lọ sí ilé ìwòsàn. Lo ito àárọ̀ kùtùkùtù kí ọmọ rẹ̀ gba ìmúláradá.”
Ni igba ti a ṣàgbéyẹ̀wò irú àbá arábìnrin Onoja ati awọn ọ̀rọ̀ asinilona miran ti awon eniyan sọ, niṣeni DUBAWA ṣe ìwádìí oro naa.
Ifidiododomule
Kini o sokunfa kí ojú èèyàn pọn lójijì?
A satunpin fonran arábìnrin Xandercs pelu awọn oníṣègùn òyìnbó láti wádìí òdodo, àwọn méjèèjì sọ pe looto, Apollo lọ ń dá ọmọ náà láàmú.
Kiri aarun Conjunctivitis (Ojú pipon)?
Aarun conjunctivitis tí a tún mo sì apollo tàbí oju pipon máa ń sábà ń wáyé nígbà ti conjunctiva àsopọ tinrin ti o bo apa funfun ti oju, bá wú. Apa funfun oju a bere sii pọn.
Àkóràn oju yìí lè ṣẹlẹ̀ sí ẹnikẹ́ni, yálà ọmọdé tabi àgbàlagbà sugbon kiise àìsàn tó burú. Ilé ìwòsàn Cleveland ṣàlàyé pé ìdá meedogun sì ogójì ènìyàn ni ó lè ní àkóràn conjunctivitis nítorí bí oju ọjọ ṣe rí nj awon igba kookan lodun. Ẹya conjunctivitis miran le sele ni àwọn àkókò miran.
Àkóràn conjunctivitis le sele fún ìgbà ranpe (laarin ose merin) tàbí kó pẹ díè (èyí máa kọjá ose merin). Àkóràn náà lè mú oju kán tàbí oju méjèèjì leekàn naa.
Kini àwọn aami àpẹẹrẹ conjunctivitis?
Àwọn aami àpẹẹrẹ conjunctivitis ni:
Kí ojú èèyàn pọn
Oju yíyún
Kí ojú máa wò bàìbàì
Ipin ti o ni je kí onitohun le laju laaro
Kí omi máa jabo lójú lai sukún
Kí ojú wù.
Kí ojú má ro ènìyàn.
Kini o maa n sokunfa conjunctivitis?
Àwọn ọlọjẹ tabi kòkòrò aarun àìlèfojúrí miran le sokunfa conjunctivitis, tí èèyàn bá jẹ eewọ, kẹ́míkà tàbí tí òun kan ba bo sínú ojú.
Ni igba miran, ó lè je àkóràn láti ọ̀dọ̀ èèyàn tó ní aarun conjunctivitis.
Oríṣi aarun conjunctivitis melo lo wa?
Òun to ṣokùnfà aarun conjunctivitis laa fi mọ nkan ti a má fi wòsàn. Fún àpẹẹrẹ, aarun conjunctivitis tí kòkòrò afaisan àìlèfojúrí dasile wa, tí oloje náà sì wà.
Oríṣi aarun conjunctivitis mẹta lo wá, gẹ́gẹ́bí àjò DeanMcGee Eye. Àwọn wọ̀nyí ni aarun conjunctivitis tí kòkòrò afaisan àìlèfojúrí dasile wa, aarun conjunctivitis ti oloje àti èyí tí jíjẹ eewọ fà.
Bawo ni a ṣẹlẹ̀ ṣe itoju conjunctivitis?
Ni ọpọlọpọ igba, aarun conjunctivitis ò nílò itoju nítorí ó máa ń lọ fúnra rẹ̀, àkóràn to burú ò sábà wọ́pọ̀. Ti ètò òkí-ara ènìyàn bá kún ojú òṣùwọ̀n, kò s’ewu. Alaisan má gba ìmúláradá laarin ose kan si méjì.
Àkóràn conjunctivitis tí ọlọjẹ máa ń sáábà lọ fúnra rẹ̀ laarin ojo méjì sí marun. Ṣùgbọ́n, fún àkóràn tí ó fà ìnira tàbí tí èèyàn ò lè laju bí ọmọbìnrin inú fonran yìí, ènìyàn tí kò lè wo iná, ìgbónára tàbí kí ara máa ro ni, ó ṣe pàtàkì kí a gbé aláìsàn lọ òdo dókítà ojú fún ìtọ́jú.
Ní ọ̀pọ̀ ìgbà, dókítà náà má fún aláìsàn ni egbògi apakokoro aarun fún ìgbà tí àkóràn náà ń bá fira kí àkóràn má bàa mú àwọn ẹlòmíràn.
Ile ise DeanMcGee Eye sọ awon igbese kookan ti èèyàn lè gbé láti dẹ́kun àkóràn conjunctivitis. Àwọn igbese náà ni kí èèyàn ló omi tí wọn kan soju kí ìrora àti yiyun ojú lè dinku.
Eniyan si le gbe aṣọ tútù lè ojú kì ipin lè dinku sugbon aṣọ náà gbodo wa ni imọ tótó. A tún lè lo egbògi ibuprofen àti àwọn oogun miran ti wọn fí ń díwọ̀n ìrora.
O ṣé pàtàkì kí a yàgò fún eewọ, aláìsàn sì lè lo àwọn ogún mìíràn. Lákòótán, ó ṣé pàtàkì kí aláìsàn bá dókítà rẹ soro, kí ó to bere sii lo oogun.
Iforowanulenuwo pelu onimo
Arákùnrin Okpanachi Achile eni ti o jẹ oníṣègùn oyinbo nù ilé ìwòsàn tí ipinle Kogi ṣàlàyé pé aarun conjunctivitis kòkòrò ailefojuri ni ó ṣé ọmọ inú fonran tí wọn satunpin sì orí ayelujara.
Dókítà náà sọ wípé àwọn èèyàn gbagbọ pé ito aaro kùtùkùtù ṣíṣe fún àkóràn conjunctivitis sugbon aheso lásán nii. Kódà, onimo náà tí gbó nípa àwọn tí wọn lọ àlubosa àti adùn.
Sugbon, ó gba ni nímọ̀ràn pé àwọn egbògi kookan wa ti wọn fín ṣé itoju àìsàn náà.
“Àwọn ipara kan wà tí wọn lo fún ìtọ́jú àkóràn conjunctivitis. Omi tí wọn kan soju wá sugbon, ipara ni kò ní je kí ojú lẹpọ.”
Sunday Idoko, dókítà miran ni ile iwosan Garki ni Ilu Abuja náà sọ pé aarun conjunctivitis lo ń dá omo inú fonran náà láàmú.
“Conjunctivitis nìyí. Apollo ni won pe. O le je tí oloje tabi ti kòkòrò afaisan àìlèfojúrí. Nko mo bí ito aaro kùtùkùtù lè sì ojú náà, sugbon omi lásán gan ń ṣíṣe. “
Nígbà tí a bere pé ìtọ́jú tí awọn dókítà máa ń lo fún aisan ọun, dókítà náà ṣàlàyé pé àwọn egbògi kan wà tí wọn máà ń lo fi se ìtọ́jú.”
Akotan
Ìwádìí wà fihan gedegbe pé àìsàn to dojú kọ arábìnrin inú fonran náà ni conjunctivitis, kii sì ṣe ito aaro kùtùkùtù ni ó má ṣe itoju aarun náà.