Getting your Trinity Audio player ready...
|
Aheso: Oju opo kan lori ikanni Ibaraenisore, Ramadan Gift, sọ wipe ìjọba ń fún awon ọdọ Yoruba ni ẹ̀bùn egberun lona ọgọta naira fun ayeye Ramadan.

Abajade iwadii: Iro ni! Linki ti won fi si oju opo naa gbe wa lọ akosile miran ti o ni oun kan se pelu Ramadan tabi Ijoba ipinle Ekiti.
Ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé
Láìpẹ́ ọjọ́, àwẹ̀ Ramadan a bẹ̀rẹ̀ ni orilede Naijiria ati lagbaye. Ramadan je àsìkọ ti àwọn ẹlẹ́sìn Islam maa n tọrọ iforiji lọwọ Ọlọrun, ó si je oṣù àánú.
Ojú òpó, Ramadan Gift, fi àwòrán kan s’órí ikanni ibaraenisọrẹ (Facebook). Wọn gbe fọ́tò gomina ipinle Ekiti, Biodun Oyebanji, pelu akosile pe ijoba n fun awon ọ̀dọ́ Yoruba ni ẹ̀bùn ẹgbẹrun l’ọna ọgọ́ta náírà.
Linki kan wa ninu aworan naa ti awon olumulo ikanni naa ma te ti yoo gbe won lo ibi ti won ma ti forukosile fun ebun naa.
A rii wipe idahun awon olumulo fihan pe wọ́n kò fura si akosile naa. Niseni won bere sii gba adura fun gomina naa.
Sugbon, àkíyèsi wa ni wipe, àwòrán ààrẹ̀ Bola Tinubu ni won gbe si oju opo naa, ki o le dabi pe ijoba Naijiria fowosi.
Ìṣamudaju
A tele linki iforukosile ti won fi si oju opo naa, sugbon ibomiran lo gbe wa lọ. Aaye ayelujara ti kiise ti ijoba lo gbe wa lo, “job.xinancaida”. Aaye ayelujara ijoba Naijiria maa n saba ni ‘.ng’ leyin sugbon ko si oun to jo bee lara linki yii.
Ni àkọ́kọ́, aaye ayelujara naa p’alaṣe pé ki a fi orukọ sílẹ̀, o bere bi eniyan ba ti forukosile tẹ́lẹ̀ rii, o si ni ki a tesiwaju.
A tesiwaju sii, a lérò boya yoo bere alaye miran bii nomba telefoonu, sugbon oun miran la fojuri.
Linki naa gbe wa lọ akosile kan nipa bi eeyan ṣelè tètè rin ìrìn àjò lọ si orileede Amerika ti o si jepe agbanisise naa ni yoo se olugbọwọ.
O da wa loju pe kii se akọsile naa ni awon olumulo to ba tele linki naa fe fojuri sugbon oju opo naa fi oro nipa owo iranwo Ramadan se ìdọdẹ lasan ni.
Bakan naa, ko si iru oro bee lori ojulowo iwe iroyin kankan. Ti o ba je ododo ni oro naa, yoo ti wa ninu ojulowo ile-ise iroyin. Awon iranwo Ramadan ti ijoba ati awon ile-ise miran n se fun awon eniyan la le ri ka ninu awon linki wonyi.
Koda, ni osu keji odun 2025 ni won sese ṣẹda oju opo naa si ori ikanni naa.
Akotan
Ṣọ́ra ṣe o! Ìtànjẹ lasan ni ọrọ naa, ko si oun to jọ bee. Koda, linki iforukosile gbe wa lo si akosile miran. Idọde ni won fi aworan gomina naa se.