YorubaFact CheckMainstream

Aṣinilọna ni àwòrán to ṣ’afihan ibi ti àwọn ọmọ Yoruba ti péjọ fun ounje ajeku

Getting your Trinity Audio player ready...

Ahesọ: Olumulo ikanni abẹyẹfo, Marquis Of Infamy (@Unabombaar), fi àwòrán kan ti o ṣ’afihan àwọn eniyan ti wọ́n tò sórí ìlà l’ẹgbẹ títì, olumulo naa si ṣ’alaye pe àwọn eniyan nínú àwòràn naa péjọ fun oúnjẹ́ ti won jẹkù ni òde àwọn ọmọ Ígbò ti wọn ṣe ni ipinle Eko ni ọjọ keedogun oṣù kẹfa ọdún yii.

Aṣinilọna ni àwòrán to ṣ’afihan ibi ti àwọn ọmọ Yoruba ti péjọ fun ounje ajeku

Abajade iwadii: Irọ́ ni. Àwòran na ò ni oun kan ṣe pẹ̀lú òde àwọn ọmọ Ígbò ni ipinle Eko. Àworan yii ti wa lori ayelujara lati oṣù kejila odun 2024, o si ṣ’afihan awon olugbe ipinle Eko (laisi alaye nipa ẹ̀yà) ti wọn pejọ fun iranwọ ni iwaju ile ààrẹ Tinubu l’àsìkò ọdún kérésìmesì. 

Ekunrere alaye

Ni ọjọ kẹẹdogun oṣù kẹfa odun 2025, awujọ awon omo Ígbò ni ipinle Eko pejọ fun ayẹyẹ kan ti wọn maa fi n ṣe igbelaruge iṣẹṣẹ àṣà ati ìṣe Ígbò, ati fun iṣọkan orileede Naijiria. Wọn ṣe ayẹyẹ naa ni ìlú FESTAC ni ipinle Eko.

Olumulo kan, Marquis Of Infamy (@Unabombaar), fi aworan kan si ojú òpó rẹ̀ ti o ṣ’afihan awon eniyan ti wọn pejọ si ẹ̀gbẹ́ títì, o ni, “awon omo Yoruba tò si enu ona abawọle ojude awon omo Igbo, won duro fun ounje ajeku awon omo Igbo.”

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ eniyan lo ri fonran ọ̀ún, wọn bu ọwọ ifẹ lùú, wọn si ṣ’atunpin rẹ̀, àwọn olumulo kan ṣ’alaigbagbọ ahesọ naa, àwọn kan bu ẹnu atẹ lu, awon olumulo gba aheso naa gbọ, won si bere sii pẹgan awon omo Yoruba.

Olumulo kan, President Eniola Daniel (@UnlimitedEniola) kọ wipe, “Èmi ọmọ Yoruba, mo san owó fun apejọ ọmọ Igbo yii, mo mura bii omo Ígbò, mo si ba won d’ọ̀rẹ́. Opolopo omo Yoruba lo wa nibi apejo naa. Njẹ́ o mọ oun ti atẹjade re le dasile.”

Olumulo miran, Aji Sebi OYO (@OLUWALONIII) sọ wipe, “Aworan ti o satunpin yii, ibi apejo miran ni won ti ya.”

Somtobechukwu (sire) (@sire_sommy) sọ wipe: “Ọmọ Igbo ni mo jẹ́, atejade yii ò si safihan ibasepo wa pelu awon ore wa ti won je Yoruba.”

Power Ranger (@Felicia091148) sọ wipe, “Àwọn ọmọ Yoruba n binu si atejade yii nitori  won mọ pe ododo ọrọ ni.”

Nitori pataki ọ̀rọ̀ naa, ati wipe o la fa rudurudu ni àwùjọ eniyan, DUBAWA se iwadii lori oro naa ki a le fi idi ododo mule. 

Ifidiododomule

Itopinpin aworan ateyinwa fihan pe awon iwe iroyin gbe aworan naa laarin ojo keedogbon si ojo ketadinlogbon oṣù kejila ọdún 2024. Iroyin salaye pe awon eniyan inu aworan naa pejo niwaju ile aare Bola Tinubu ki won le gba ebun/owo iranwo odun keresimesi.

Itopinpin koko oro tunbo fi idi re mule pe awon eniyan inu aworan naa to lati gba owo odun lati odo aare ni, koda awon fonran kookan wa lori ayelujara to jerisi oro naa.  

Awon atejade kan gbe ọrọ sẹnatọ Ali Ndume ni ibi ti o ti bu enu ate lu ijoba Tinubu. O sọ wipe, “awon eeyan tò jọ si iwaju ile aare Tinubu, eyi safihan iru ìṣẹ́ ati iya ti opolopo omo orileede Naijiria ba n fira. Iṣe ko mo eya tabi ẹ̀sìn. Ìṣẹ́ n ba onile ati alejo ja, o si se pataki ki gbogbo wa fi owo so wopo ki a wa ojutuu si oro yii.”

Bakan naa, iwe iroyin The PUNCH gbe iroyin pe awon egbe alatako satunpin aworan awon eeyan to pejo si iwaju ile aare Tinubu lati fi kan ijoba re labuku lori osi ati ise to n ja lorileede yii.

Akotan

Iro ni aheso pe awon omo Yoruba n duro fun ounje ajeku awon omo igbo nibi apejo kan ti won se ni ipinle Eko. Olumulo ikanni X satunpin aworan kan ti o ti wa lori ayelujara lati osu mefa seyin. Ko ni oun kan se pelu apejopo awon omo igbo bee si ni ko si alaye lori eya awon eniyan to tojo ninu aworan oun.

Show More

Related Articles

Leave a Reply

Check Also
Close
Back to top button
Translate »