ExplainersHealthYoruba

Ààrùn yinrunyinrun: Gbogbo oun tí o ní láti mọ̀ nípa àpẹẹrẹ àìsàn, okùnfà, ìdènà àìsàn àti ìtọ́jú

Ìròyìn lẹkunrẹrẹ 

Lọdọọdun ni àjàkálẹ̀ ààrùn yinrunyinrun máa n bé sílẹ̀ ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, pàápàá jùlọ ní àsìkò ẹ̀ẹ̀rùn. Ààrùn yi le ṣ’eku pani láàrin ìṣẹ́jú mẹ́rìnlélógún. Ní oṣù kinní ọdún 2023, ìjọba àpapọ̀ kéde ìtànkálẹ̀ ẹyà ààrùn yinrunyinrun kan ni ìpínlẹ̀ Jigawa eyi ti àwọn oloyinbo ń pè ní cerebrospinal meningitis, wọn sì fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ènìyàn méjìlá ló ti fi orí lugbadi àìsàn yìí, àmọ́ṣá ènìyàn ẹ̀ta dín ní ọgọ́fà lo wà lábé àkíyèsí àwọn onisegun.

Nítorí èyí, àjọ tó ń mójútó ìtànkálẹ̀ àwọn àrùn lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà NCDC rán àwọn òṣìṣẹ́ ìlera ló sì ìpínlẹ̀ Jigawa, Yobe àti Katsina, kí wọn lọ dojukọ ìtànkálẹ̀ ààrùn náà. Ṣùgbọ́n, ní ọjọ́ ketadinlogun oṣù kejì ọdún yii, ènìyàn méjì dín logoji ló jẹ Ọlọrun n’ipe latari ààrùn yinrunyinrun ni ilu Jigawa. Ìtànkálẹ̀ àrùn yìí ni ilu Jigawa jẹ ipenija pàtàkì fún gbogbo ènìyàn pe ààrùn burúkú ti bẹ silẹ ni ìha àríwá orile-ede Nàìjíríà tí o si nílò ètò ìlera tó péye àti amojuto àìsàn.  

Ààrùn yinrunyinrun àti okùnfà rẹ̀ 

Ààrùn yinrunyinrun jẹ igbínikùn àwọn iwọ ti o bo ọpọlọ ati ẹsọ ọpa-ẹhin, eleyi ti a npe ni iwọ-ọpọlọ. Keneth Ayange, oṣiṣẹ ìṣẹgun òyìnbó ní ile-iwosan Anglican Hospital Kafanchan, sàlàyé pe ikọlu ẹyà èṣó ara lè ṣ’okunfa igbínikùn iwọ ọpọlọ.

Ààrùn yinrunyinrun: Gbogbo oun tí o ní láti mọ̀ nípa àpẹẹrẹ àìsàn, okùnfà, ìdènà àìsàn àti ìtọ́jú
Àwòrán tí o ṣàpèjúwe ààrùn yinrunyinrun. Orísun àwòrán: Healthline

Okùnfà ààrùn yíì ti ó wọpọ jùlọ ni àkóràn ti alamọ (bacteria) ati ti ọlọjẹ (virus). Tí o bá jẹ àkóràn alamọ (bacteria), ajenirun (parasite) tabi elu/osun ara (fungi) lo maa n ṣokunfa igbínikùn. 

Àmọ ni igba miran, egbò ati àwọn òògùn ti a nlo le fa igbínikùn. Dókítà Ayange, ṣàlàyé pé àìsàn yìí máa n tànká ni àsìko èèrùn. 

“Igba èèrùn maa n fi àye silẹ fún ààrùn yinrunyinrun lati tànká, ni asiko naa, imu eniyan a gbẹ, eyi ma je ki ènìyàn mi alamọ (bacteria) to wa ninu ategun sinu ara. Ati wípé, eya mimi ati ipoyida ara ni asiko náà máa di aláìlágbára, eyi sì máa jẹ kí ènìyàn kò orisirisi àìsàn to ma tàn káàkiri agọ ara.”

Oun míràn to le ṣokunfa ààrùn yinrunyinrun ni ikunna lati gba abẹ́rẹ́ àjẹsára lati gbógun ti alamọ to n fa àisàn yìí. Ìtànkálẹ̀ yinrunyinrun wọpọ ni àwọn ìletò kọọkan lágbayé pàápàá ni ilẹ̀ adúláwọ̀, bíi orile-ede Nàìjíríà. Dókítà Ayange ṣàlàyé pé àwọn ipinlẹ mokandinlogun ti iha Àríwá ni àìsàn yìí tí wọpọ julọ ni orilẹ-ède Nàìjíríà.

“Aarun yinrunyinrun máa n saba bẹ silẹ ni ìletò yìí. Ẹ̀yà àìsàn náà ti a n pe ni (Neisseria meningitides type C strain) ló wọ́pọ̀ julọ ní àgbègbè naa, ọ sí ti ṣọṣẹ ni bẹ.”

Ààrùn yinrunyinrun: Gbogbo oun tí o ní láti mọ̀ nípa àpẹẹrẹ àìsàn, okùnfà, ìdènà àìsàn àti ìtọ́jú
Máàpù awọn ilu ti ààrùn yinrunyinrun ti máa n sọsẹ́. Orísun: Travel Vaccines

Àpẹẹrẹ ààrùn yinrunyinrun 

Àpẹẹrẹ ààrùn yinrunyinrun tó wọpọ julọ ni ọrùn gígan, ìgbóná, aileduro ni ibi to mọlẹ, orí fífọ́, èébì, ara aiṣegiri (ki enia ma tilẹ naani nkan). Ninu awon omo ọwọ, àpẹẹrẹ àìsàn lè jẹ igbe púpọ̀, ìgbóná tabi ki ara tutù ju bó ti yẹ lo, ara aisegiri, ailejeun tabi mu ọmú. Àmì àpẹẹrẹ aàrùn yinrunyinrun to tipase alamọ tàbí elu máa lọ láàrin ọjọ díẹ̀ sí ọsẹ kan lẹ́yìn ìtọ́jú. Àmọ́ aláìsàn le ma ri ìwòsàn titi ẹyin ọsẹ tabi oṣù melo kan. Ẹlòmíràn le ma bọ ninu àìsàn yìí. 

Oríṣi ààrùn yinrunyinrun

Ààrùn yinrunyinrun ti alamọ 

Ààrùn yíì je àrànmọ́, alamọ sí ni ọ máa n fa.

Eyi je oun kan to lè fa ewu fún ìlera ọpọ eniyan láwùjọ nitori ọ le la emi lọ ti a ko ba se ìtọ́jú re daada. Ọ le bẹ silẹ lagbegbe kan, èyí dá lé orí irú alamọ to fàá, sùgbón ìtọjú wà fúun, a sì lè yago fún àìsàn yìí. 

Aarun yinrunyinrun ti ọlọjẹ 

Aarun yinrunyinrun ti awọn ọlọjẹ (viruses) ńfà ló wọpọ, wọn ko si ni inira pupọ. Ẹ̀yà ààrùn yíì máa n lọ fúnra rẹ. Sugbon ni igba miran, a ni lati se itoju àìsàn yìí. 

Ààrùn yinrunyinrun ti osun ara/elu

Eyi o wọpọ rara. Elu ló máa n saba ṣokunfa àìsàn yìí. Ni igba ti elu yìí ba wọ inú àgọ́ ara, a gba awọn inu iṣan ẹjẹ lati lọ si iwọ-ọpọlọ. Awọn eniyan ti ètò òkí ara wọn ò dápé daada máa tètè kó àìsàn yìí. 

Ààrùn yinrunyinrun latari kòkòrò ajẹnirun

Oríṣiríṣi kòkòrò ajẹnirun lo n ṣokunfa ààrùn yinrunyinrun. Ajẹnirun yìí le wa nínú idọti, ìgbẹ́, lára ẹranko tàbí oúnjẹ bíi ìgbín, eja tútù, adìẹ.  A ò lè ṣ’agbako ààrùn yinrunyinrun ti kòkòrò ajenirun ṣokunfa, latara aláìsàn. Awọn kòkòrò yii máa n sapamọ s’ára ẹranko tàbí oúnjẹ tí ènìyàn máa jẹ.

Ààrùn yinrunyinrun ti kìí ṣe àkóràn 

Èyí kii se àrànmọ́ tabi àkóràn. Dipo àkóràn, oògùn tàbí àìsàn míràn lo máa n fàá, bíi ààrùn jẹjẹrẹ, iṣẹ abẹ inu ọpọlọ, ìpalára orí tàbí àwọn egbòogi míràn.

Ààrùn yinrunyinrun tó mu ewu dání 

Elu, làkúrègbé ati ààrùn jẹjẹrẹ le ṣokunfa irufẹ ààrùn yíì. Itọju okùnfà yii se pàtàkì.

Ìtànkálẹ̀ ààrùn yinrunyinrun

Àjọ eleto ilera lagbaye, WHO, salaye pe alamọ to n fa ààrùn yinrunyinrun máa ntan kaakiri lati awọn omi-ara ẹni to ba ni aisan yi, yala lati ọfun rẹ tabi lati imu rẹ̀. Atẹgun le gbe omi-ara yi nigbati alaisan yi ba fẹnuko ẹlòmíràn, koda ti alaisan ba wukọ, sọrọ tabi ti o ba sín, eyi le fa àkóbá fun ẹni to ba wa ni tòsí alaisan. 

Àkókò ìṣàba fún àìsàn yinrunyinrun le jẹ ọjọ́ mẹrin, ṣùgbọ́n ni ìgbà míràn, o le jẹ ọjọ́ méjì sí méwàá. Alamọ to n fa àisàn yìí le wà nínú ọ̀fun, yóò sì mú kí èyà òkí ara ma ṣiṣe déédé, èyí a je ki àìsàn náà wọ inú iṣan ẹjẹ sí inú iwọ ọpọlọ. 

Muhammad Adamu, onisegun oyinbo ni eka ijoba to n risi ọrọ ìlera ipinle Jigawa (Ministry of Health) mẹnuba orisirisi okunfa ààrùn yinrunyinrun ni agbegbe naa. “Apọju alabagbe, òṣì, ẹkun omi ni ipinle Jigawa.  Ekùn omi ni ipinle Jigawa ti le awọn eniyan kuro ni ibugbe wọn lo ibomiran, eyi sì máa n fa apọju eniyan láwùjọ miran.” 

Iyagofun ààrùn yinrunyinrun

O dara ki awon eniyan láwùjọ mọ nípa àìsàn yinrunyinrun àti bí o ṣe lè tànká, nítorí inú atẹgun lo máa n wà. Dókítà Ayange ṣàlàyé pé idanileko àwọn ènìyàn láwùjọ nipa ààrùn náà se pataki, gẹgẹbi a ṣe dẹkun ààrùn COVID-19. Onisegun oyinbo naa fi kun wípé agbọdọ ṣe idanilẹkọ ọpọlọpọ onisegun òyìnbó lati le ṣawari àìsàn náà nínú agọ ara. O sọ wípé dókítà to n ṣe ìtọ́jú àìsàn náà ni agbegbe yii ò tó.

Lati dẹkùn àìsàn náà, dokita naa menuba gbigbe igbe ayé tó dára, oorun sísun lasiko, ìyàgò fún aláìsàn, ìmọ́tótó (fọ ọwọ déédé), gbogbo èyí ṣe pàtàkì. Kódà, abéré àjẹsára máa dènà ẹ̀yà ààrùn yinrunyinrun. 

Dókítà Muhammad Adamu salaye pé ijoba ipinle Jigawa ti n gbaradi fun idena ààrùn yinrunyinrun. Ẹka ìjọba to n risi ìlera àwujọ ni ipinle Jigawa ti bèrè síí se ìwárí àwọn ènìyàn tó ní àìsàn naa, bẹẹ itọju ti bẹrẹ, lati dènà itankalẹ ààrùn náà. Ìjọba sí n pèsè itọju ọfẹ fun àwọn to f’orí lugbadi àìsàn yìí. 

Itọju ààrùn yinrunyinrun

Ìtọjú àìsàn náà dálé ori irufe ẹ̀yà yinrunyinrun tó jẹ́. Wọn máa n fi egboogi apalamọ (antibiotics) ṣe itọju ààrùn yinrunyinrun ti alamọ. Ààrùn yinrunyinrun ti ọlọjẹ le lọ fúnra rẹ láàrin ọsẹ kan láìsí ìtọjú. Dókítà máa fi oogun se itoju ààrùn yinrunyinrun ti osun ara. 

Àkótan

Botilejepe ìpolongo abẹrẹ àjẹsára ń ṣiṣe lati gbogun ti ìtànkálẹ̀ àìsàn yinrunyinrun, o se pàtàkì fún ìjọba orile-ede Nàìjíríà láti ṣe ìpèsè oun ti ara-ilu ma lo lati dènà ààrùn yíì. Àkójọpọ̀ oríṣiríṣi igbese ni a le fi gbógun ti okùnfà ati ipa ààrùn yinrunyinrun, bíi igbese lati ọdọ ìjọba, ọpọ eniyan l’awujọ, ati àwọn ẹlòmíràn tí ọrọ kan. 

Show More

Related Articles

Leave a Reply

Back to top button