Ni ọjọ ẹtì, ogunjọ́ oṣù kini, ọdún 2023, àjọ tí ó n gbogun ti àjàkálẹ̀ aàrùn ni Naijiria, NCDC kéde pé ìpínlè Èkó àti Kano ti ní àkọsílẹ ààrùn Diphtheria. Àjọ náà ti bẹrẹ síi ṣe itọju àwọn ti àìsàn náà mú, o sì n ṣ’abojuto ìtànkálẹ̀ ààrùn náà ni ìpínlè Ọ̀ṣun àti ìpínlè Yobe.
Ti àjàkálẹ̀ aàrùn bá bé sílè, ọrisisiri ìròyìn ni o máa n sábà tẹle, pàápàá ìròyìn èké, nítorínà, ó ṣe pàtàkì fún wa láti mọ̀ nípa ààrùn Diphtheria.
Kini ààrùn Diphtheria àti pe kini o n ṣokunfa?
Ààrùn Diphtheria jẹ ọkan lara àwọn ààrùn akalekako to máa n gbogun ti ètò eya mimi tabi ìpòyìdà ara. Oun tí ó n ṣokunfa ààrùn yi ni kòkòrò aifojuri Corynebacterium diphtheriae, ti o máa n ṣe àkóbá fun ìlera ọkan, ẹyà ẹṣọ ara, ati àwọn eya ara miran.
Àìsàn yìí lè fa ìnira fún ènìyàn, o sì lè la emi lo ti kò bá sí itọju tó dájú. Ni orílè-èdè Nàìjíríà, egbò adaajina le so si ara awọn eniyan to ba ti ko ààrùn yíì.
Oríṣi melo ààrùn Diphtheria ló wà?
Oríṣi méjì ni àìsán yìí: eyi ti o dojú ìjà kọ eya ìpòyìdà ara (classical diphtheria) ati eyi ti o niiṣe pẹlu àwọ̀ ará (cutaneous diphtheria).
Ààrùn diphtheria tí máa ń kọlu eya ìpòyìdà ara: Eyi ni o wọpọ julọ laarin oríṣi méjì ààrùn yìí. Eya àìsàn yìí máa n dojú ìjà kọ imu, ọna ofun ati ɡòɡòńɡò. Àpẹẹrẹ àìsàn niiṣe, lọpọlọpọ igba, pẹlu eya ara ti àìsàn yìí bá dojuko ninu ara èèyàn. Ni ìgbà míràn, a máa n pèé ni ààrùn diphtheria ti ọnà ọfun, pharyngeal diphtheria.
Ààrùn Diphtheria ti máa n kolu àwọ̀ ara, cutaneous diphtheria: èyí ò wọ́pọ̀, eniyan tó ba ni àisàn yìí lè ní kuruna, egbò tabi ileroro ní èyíkéyìí eya ara rẹ. Eyi wọpọ julọ ni ibi ti àwọn ènìyàn pọ̀ sí àti ibi ìdọ̀tí.
Kini àpẹẹrẹ àìsàn Diphtheria?
Àpẹẹrẹ àìsàn diphtheria pe orisirisi, o sì máa n farahàn laarin ojo meji sí márùún lẹ́yìn ti ènìyàn bá ti ko kòkòrò aifojuri ti máa n fa. Àpẹẹrẹ àìsàn je: bèlúbèlú, ibà, tabi ki orun eniyan wú. Àpẹẹrẹ tó lamilaka jùlọ ni egbò ni ọna ọfun tàbí orí imu. Egbò yìí tí a mò sí pseudomembrane, le fa idiwọ sí èémí tabi ki iru ènìyàn bẹẹ má lè gbé oúnje mi.
Ààrùn Diphtheria le mu àpẹẹrẹ miran dani: bíi ki ènìyàn máa mí lákọlákọ, aárẹ̀, àti kí ohùn ènìyàn há. Àìsàn náà lè mú kí ọkàn ènìyàn má ṣiṣe, ijamba bá ẹyà ẹṣọ ara tàbí kí ènìyàn ni ààrùn rọpárọsẹ̀.
Bawo ni ènìyàn ṣe lè kó ààrùn yi?
Ààrùn Diphtheria máa n tanka ti ẹnikẹni to ni aarun náà bá sín tàbí hú ìkọ sínú afẹ́fẹ́, ẹni to ba sunmọ le fa C. diphtheria si imú. O ṣeeṣe ki ènìyàn ko ààrùn diphtheria ti o ba fi ọwọ kan oun tí kòkòrò aifojuri yìí bá kàn. Ènìyàn le ko Diphtheria to ba fi ọwọ kan egbò ara ènìyàn to ni àisàn yìí tàbí fi ara kan asọ ti iru eniyan bẹẹ bá wọ. Eniyan lè ko Diphtheria ni ọpọlọpọ ìgbà.
Awon eniyan ti kò tii gba abere àjẹsára ti n dekun ààrùn Diphtheria le tete ko ààrùn yii; ààrùn ti máa n tete tanka ni, o sì ṣeéṣe kí ó la ẹ̀mí lọ ti alaisan ò bá rí ìtọ́jú tó dájú.
Èèyàn tún lè kó ààrùn yii, to ba fi ọwọ kan àwọn ohun èlò ẹni tó ní ààrùn diphtheria bíi tiṣu pẹpa tabi aṣọ inuwọ, nítorí pé ó ṣéeṣe kí ààrùn náà ti wà nínú awọn ohun èlò wọnyi.
O lè ṣ’àgbákò ààrùn Diphtheria ti oò bá tíì gba abẹrẹ ajẹsara ti n Dẹkun Diphtheria, ti o bà wá ní àárín èrò tàbí ti agbegbe rẹ ba dótì. Àìsàn yìí wọpọ ni awọn orilẹ-ede ti kò tíì laju dáadáa torí ọpọlọpọ ènìyàn ní koiti gba abẹrẹ àjẹsára.
Bawo ni mo se le dáàbòbo ara mi ati ìdílé mi kuro lọwọ ààrùn Diphtheria?
Onisegun oyinbo, Dr Adeolu Olusodo tí ó jẹ ọ̀gá àgbà Ileeṣẹ Atayeshe Health Network ṣalaye pé abẹrẹ àjẹsára ní a lè fi dẹkùn àjàkálẹ̀ àrùn yii.
“Nitori eyi, ẹẹ ríi wípé a máa n fún àwọn ọmọ kékeré jòjòló ní abẹrẹ yii ki won ma se ṣ’àgbákò àìsàn alunipa yìí,” Olusodo lo sọ bẹẹ.
Ti a ba fe dekun bi aarun yìí se n tanka, “a ni lati wọ ibomu-benu”.
Fún àwọn ènìyàn tí ọrẹ tàbí ẹbí wọn ti kó ààrùn Diphtheria yìí, “won ni lati lo ògùn antibiotics ki won ma le ko ààrùn yi,” onisegun naa lo sọ bẹ́ẹ̀.
Ọnímọ̀ nípa ipoogun, Pharmacist Omale Ogbe ti o je oṣiṣẹ Evans Therapeutics ṣalaye pe oun tó n ṣokunfa Diphtheria ni kòkòrò àìlèfojúrí tí o n ṣe ijamba fún ona ọfun, o fikun wipe abẹrẹ àjẹsára ni ọna ti a le gbà dẹkun àìsàn yìí.
O salaye pe, “ago ara eniyan lè tikalararẹ já àìsàn yìí.”
Èyí le ṣẹlẹ tí ọpọlọpọ ènìyàn ní agbègbè kan ba ti gba abere àjẹsára tàbí ti ènìyàn ba ti ní àisàn yìí tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀.
Fun ààrùn COVID-19, ọpọlọpọ ènìyàn tó ni ààrùn yíì lo ṣẹgun rẹ̀, láìpẹ́ àgọ̀ ara wọn bẹrẹ síi ba ààrùn náà jà. Ni ìgbà tí wọn kò COVID-19 lẹẹkan sí, wọn kò nílò abẹrẹ àjẹsára mọ, nise ni ara wọn já lòdì sí àìsàn yìí láì gba abẹrẹ àjẹsára tàbí itọju kankan
“Eyi lè dẹkùn bi ààrùn diphtheria ṣe lè tànká láti ọdọ ẹnikan sí òmíràn,” Ogbe ló sọ bayii.
Amosa, abẹrẹ ajẹsara Diphtheria yìí ní àbuku tirẹ. Àwọn ọmọdé to ba je àjẹsára yíi lè ní iba, aárẹ̀, egbò ni ibi ti o ti gba abẹrẹ. E bèrè lọwọ dókítà yín, oun ti e le ṣe lati dawọ ìrora duro.
Botilejepe abuku àjẹsára yíi o wọpọ, àjẹsára lè mú aami to buru dani pàápàá ninu ọmọde, bíi ki ọmọ náà ní kuruna lẹyìn iṣẹju díẹ tó bá gba àjẹsára yíi.
Awon ọmọde kookan bi awọn ti o ni wárápá tabi àìsàn míràn to niiṣe pẹlu eya ẹṣọ ara le ma nii ànfààní láti gba abẹrẹ ajẹsara yii.
Akotan
A gbọ́dọ̀ fi ọwọ líle mu ajakalẹ aàrùn diphtheria nitori ọ le mu ikú dání ti itoju o ba daju.
Biotilẹjẹpe diphtheria ko wọpọ ni awọn orilẹ-ede nlánlá, o sì lè bẹ sílẹ ní àwọn ibi tí ọpọlọpọ ènìyàn ò tíì gba abẹrẹ àjẹsára. Nítorí èyí, o ṣe pàtàkì ki a gba abẹrẹ àjẹsára yíi ki a sì mọ nipa oun tó n sele nipasẹ bi a selè dẹkùn ààrùn Diphtheria tàbí àwọn ààrùn míràn.




