ElectionsMedia LiteracyYoruba

Àlàyé: Ẹ̀tọ́ àti idojukọ àwọn àkàndá ẹ̀dá l’ásìkò ìdìbò ní Nàìjíríà

Ẹ̀tọ́ àwọn àkàndá ẹ̀dá ṣe pàtàkì nínu ètò ìdìbò. Ni orílè-èdè Nàìjíríà, awon àkàndá ẹ̀dá maá ń saba kojú ìṣòro ailedibo torí aisedeede awọn oṣiṣẹ àjọ elétò ìdìbò tàbí ti àwọn ènìyàn míràn ni ibùdó ìdìbò.  

Òfin tí n bojuto eto awon akanda eda (Article 29 of the Convention on the Rights of Persons with Disabilities (CRPD), ṣ’agbekalẹ àwọn ẹ̀tọ́ àti ànfààní ti àkàndá ẹ̀dá gbọdọ jẹgbadun rẹ̀ lásìkò ìdìbò. Àmọ́ṣá, botilẹjẹ́pe òfin yìí wà, wọ́n ti fi ẹ̀tọ́ àwọn àkàndá ẹ̀dá dù wọn lásìkò ìdìbò.

Kí gbogbo ènìyàn lè ni ẹ̀tọ́ láti dìbò, àjọ ètò ìdìbò, INEC ti gbe ìlànà kan kalẹ lati se iranwọ fún àwọn àkàndá ẹ̀dá lásìkò ìdìbò. Eyi ni a mo sí Framework for Access for Persons with Disabilities (PWDs) ti ọdún 2018.

A ṣ’agbeyewo ẹ̀tọ́ awon àkàndá ẹ̀dá ti iwe òfin orílè-èdè Nàìjíríà ti la kalẹ, òfin ìdìbò tuntun (electoral act) àti ti ti òfin tí n bojuto ẹ́tọ́ awọn akanda eda (article 29 of CRPD) l’ojo ìdìbò.

Ẹ̀tọ́ lati dibo, ati lati dije dupò

Ìpín kinni ti àtòjọ náà sọ nípa ẹ̀tọ́ àwọn àkàndá ẹ̀dá ni ibamu pẹlu òfin; eto lati dibo ati eto lati dije du ipò ìjọba.

“Lati se àrídájú pé àwọn àkàndá ẹ̀dá kópa nínú ètò òṣèlú àti ọrọ àwùjọ ẹda l’orekoore, ni gbogbo igba, yálà ni tikarawọn tabi nipasẹ ẹlòmíràn tí yóò soju wọn, pẹlupẹlu ẹ̀tọ́ ati ànfààní fún àwọn àkàndá ẹ̀dá lati dibo ati lati gbe apoti ibo,” abala kinni òfin náà ló sọ eyi.

Ẹ̀tọ́ sí oun àmúlò ìdìbòyàn tó tọ́, tí kò sì sòro láti lò

Abala akọkọ, ipin kinni òfin náà filelẹ pé oun èlò ìdìbò gbọ́dọ̀ rọrùn fún àwọn àkàndá eda ni ibùdó ìdìbò, “ni sise àrídájú pe ilana ìdìbò, ati àwọn oun elo miran yẹ, wọn sì rọrùn fún akanda eda láti lò.”

Ipin kerin, abala kerinlelaadota, apa keji ti òfin ìdìbò tuntun so pe, “Àjo idibo gbọdọ gbé ìgbésẹ tó yẹ lati ṣ’aridaju pe iranwọ ń bẹ fún àwọn àkàndá ẹ̀dá ni ibùdó ìdìbò, nipasẹ ṣíṣe ètò ohùn èlò ibaraẹnisọrọ tí ó bá aleebu wọn mú, eyi le jẹ ni ti ìpèsè oun elo fún àwọn tí kò riran, èdè adití ati awọn oun míràn. 

Ẹtọ láti dìbò ni ìkọkọ

A gbọdọ ṣe ààbò ẹtọ awọn àkàndá ẹ̀dá láti dibo yan oludije yòówù ni ìkọkọ láìsí ihale tabi idunkokomọni. 

Abala kinni, ipin keji ti Article 29 filelẹ pé, “sise ìdáàbòbò ẹtọ àwọn àkàndá ẹ̀dá nipasẹ ìdìbò ikọkọ ni àsìkò ìdìbò láìsí ihale tabi idunkokomoni.”

Ẹ̀tọ́ sí iranwọ lásìkò ìdìbò

Awọn àkàndá eda ni ẹtọ lati diboyan oludije yòówù tí wọn bá fẹ dibo fún, bẹẹ sì ni wọn ni ẹtọ lati gba iranwọ lọwọ ẹnikẹni tó wun wọn lásìkò ìdìbò.

Ọgbọn orí kọ́ wa pé, tí àkàndá ẹ̀dá ba nilo iranlọwọ lati gbe igbe aye àlàáfíà, bẹẹ ni wọn yóò nilo iranlọwọ ni ibùdó ìdìbò. 

Apa kerin, abala kerinlelaadota, ipin kinni ti òfin ìdìbò tuntun salaye pé, “Oludibo ti ko riran tabi ti o ni aleebu kankan ti ko sí lè ṣe idayatọ ààmì tabi eni ti o fọ́jú, ni anfààní lati wọ àgọ́ ìdìbò pẹlu ẹnikẹni tó bá yan láàyò, o sì se dandan fún oṣiṣẹ àjọ ètò ìdìbò láti fún onítọ̀ún ni anfaani lati wọ agọ ìdìbò pẹlu àkàndá ẹda yìí, kí o le ranlọwọ lati teka botitọ ni ìbámu pẹlu òfin àjọ ìdìbò yii.”

Ààbò fún àwọn àkàndá ẹ̀dá ti wahala tabi idamu bá ṣẹlẹ lásìkò ìdìbò  

Ijoba gbọ́dọ̀ gbé ìgbésẹ̀ to yẹ, lati ríi wípé ààbò tó péye wà fún àwọn àkàndá ẹ̀dá ti wahala tabi ikọlu bá bẹ́ sílẹ̀ lásìkò ìdìbò. Abala keedogbon ti òfin tí n bojuto eto awon akanda eda ṣàlàyé pé, “Ninu gbogbo ewu tàbí ijamba, ikọlu ati àjálù, ijoba gbodo pèsè ààbò tó péye fún àwon akanda eda pàápàá pẹlu bi wọn ṣe jẹ aláìlágbára.”

Idojukọ

Botilejepe ofin ṣe ìpèsè wọnyi fún àwọn àkàndá eda, awọn idojukọ kan ṣi n ṣe idiwọ fún ìkópa wọn ni àsìkò ìdìbò.

Chris Agbo, ẹni tí o je alagbawi awọn àkàndá ẹ̀dá sọ laipe yii ninu ìfòròwánilénuwò kan pẹlu DUBAWA, pé botilejepe àjọ ètò ìdìbò INEC ti ni yóò ran àwọn àkàndá eda lọwọ láti kópa nínú ìdìbòyàn, ọpọlọpọ nkan lo n dojukọ awọn àkàndá ẹ̀dá. 

Agbo so wipe ikan ninu awọn idojukọ yìí ni ìṣòro ati gbera lati ibìkan lọ sí ibùdó ìdìbò nítorí pé ni ọjọ́ ìbò, o feèrè dàbí pé ọkọ̀ ayọkẹlẹ ò kii sábà rìn. 

O f’ikun wípé ìṣòro ètò ààbò tun jẹ oun kan tó n dojukọ ìkópa àwọn àkàndá ẹ̀dá nínú ìdìbòyàn. Ti ikọlu bá ṣẹlẹ ní ibùdó ìdìbò, “a ko le sáré, a sì lè kọ sí inú ewu tori ti ikọlu bá ṣẹlẹ, awon ènìyàn máa sa asala fún èmí won. Ko si ẹnikẹni ti o máa ran akanda eda lọwọ.”

O ni àwọn ẹṣọ aláàbò o tíì ní òye pé l’asiko ikọlu tabi wàhálà, àwọn àkàndá ẹ̀dá ni won gbọ́dọ̀ kọkọ pèsè ààbò fún gege bi ipin keedogbon ti òfin tí n dabobo eto awon akanda eda ti ọdún 2018 (Discrimination against Persons with Disabilities (Prohibition) Act 2018).

Ogbeni Agbo fikun pe ni ọpọlọpọ ìgbà, o ṣòro fún àwọn akanda eda láti ráyè sí ibùdó ìdìbò ati pé ni ìgbà míràn, ipò tí wọn gbé ohùn elo ìdìbò sí máa n ṣe inira fún àwọn àkàndá ẹ̀dá. Àjọ INEC ò tíì pèsè alaye bi awọn afọ́jú/awọn ti kò riran daada ṣe lè lo iwe pelebe ìdìbò  (braille ballot guide), ko sì akọle kankan lori ìwé alẹmọde fún àwọn ènìyàn tí ko gboran dáadáa, ikunna INEC láti pèsè àwọn nkan wonyi je idojukọ fún àwọn akanda ẹda.  

O ṣàlàyé pé awọn iṣọrọ wọnyi ò yọ awọn àfín silẹ. O f’ikun pe ni ọpọlọpọ ìgbà, àwọn eniyan tó je àfín ò ní anfààní lati diboyan olùdíje ni ìkọkọ bi àwọn ènìyàn tó kù, nítorípé ko sí digi (magnifying glass) ti o yẹ ki wọn lọ, tabi ki àwọn oṣiṣẹ INEC ma mọ digi ọ̀ún lò.

Botilẹjẹpe awọn isoro yii wọpọ, ogbeni naa ni àjọ INEC ń ṣe ọpọlọpọ nkan lati ṣe ìrànwọ́ fún àwọn àkàndá ẹ̀dá kí wọ́n lè kópa nínú ìdìbò, lara re ni lilo akanda eda gẹgẹbi oṣiṣẹ ati pé àwọn àjọ tó n soju akanda eda láwùjọ n se aṣamojuto ìbò.

Ọgbẹni Agbo ní o hàn gbangba pé àjọ INEC ń gbiyanju ṣugbọn èyí kò rí béè fun àwọn ẹgbẹ òṣèlú. O fi ehọnu rẹ hàn pé kò sí ìwúrí kankan fún ìkópa àwọn àkàndá ẹda nínú ètò awoṣe àwọn ẹgbẹ òṣèlú. O ni, “akanda eda méjìlá pere lo máa dije dupò ní ìdìbò odun tó n bo.”

Àmọ́ṣá, o ni òun ìwúrí kan fún òun ní pé àwọn àkàndá ẹda ń kópa dáradára ninu ẹgbẹ òṣèlú ti wọ́n darapọ mọ. Atejade Inclusive Friends Association (IFA) kan fihàn pé àwọn àkàndá ẹ̀dá náà wà ní ipò agbára lorile-ede Naijiria.

O f’ikun pe awọn ohun ìwúrí miran ni pé àwọn àkàndá ẹda ti darapọ mọ ètò ìpolongo ìbò awọn ẹgbẹ òṣèlú kọọkan.

Show More

Related Articles

Leave a Reply

Back to top button