Getting your Trinity Audio player ready...
|
Aheso: Ààrẹ Tinubu bu ẹnu àtẹ́ lu ìwádìí ti BBC gbé jáde l’órí olóògbé oníwàásù T.B. Jóṣúà.
Àbájáde ìwádìí: Irọ́ ni. Àyẹ̀wò fínífíní ti DUBAWA ṣe lori fónrán ọ̀ún fihàn pé kò nííṣe pẹlu ìwádìí BBC ati wípé wọ́n ti fi àwọn oun èlò ìgbàlódé ṣ’àfọwọ́yí fọ́nrán náà.
Iroyin lẹkunrẹrẹ
Ilé-isé ìròyìn BBC ṣ’agbejade ìwádìí kan l’órí oníwàásù ti o di olóògbé, TB Jóṣúà, oludasile ilè ìjósìn Synagogue Church of All Nations (SCOAN). Olumulo kan l’órí ìkànnì Instagram sọ wípé ààrẹ orílè-èdè Nàìjíríà, Bọla Tinubu bu ẹnu àtẹ́ lu ìwádìí náà.
Nínú fónrán ti olumulo náà (Sylvester Lumenchristi_eboh) fí síta, a gbọ́ tí ààrẹ Tinubu ń bu ẹnu àtẹ́ lu fọ́nrán náà, pé ibanilorukojẹ ni àwọn ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn olóògbé TB Jóṣúà.
“Gegebi ààrẹ orile-ede Nàìjíríà, nkò faramọ́ àwọn ẹ̀rí àti ẹ̀sùn tí ilé-isé ìròyìn BBC fi kàn wòlíì náà. Ọlọ́kàn rere ni woli TB Jóṣúà, kódà ó fi ipò rẹ̀ ko òpòlopò ọmọ ilẹ gẹẹsi wọlé sí ìlú Èkó ní ìgbà tí mo jẹ́ Gómìnà. Ó dámilójú pé àwón ènìyàn kan kò feran àlùfáà náà nítorí ó jẹ́ èèyàn dúdú,” ààrẹ Tinubu sọ bẹ́ẹ̀ nínú fónrán naa.
Àwọn olumulo ẹ̀rọ alatagba wo fídíò náà ni ọpọlọpọ ìgbà, ṣùgbọ́n a sẹ àkíyèsí pé èrò wọn s’ọtọọtọ l’órí bóyá fídíò náà je afọwọyi tabi ojúlówó.
“Eyi dara, ààrẹ.” Sanusirufus ló sọ bẹ́ẹ̀.
“Èyí kìíṣe ohùn ààrẹ Tinubu. Ẹ jáwọ́ nínú ìròyìn ofege tẹ n gbé kiri,” Ismailyusuf913 sọ bayii.
Nítorí àríyànjiyàn to tẹ̀lẹ́ fọ́nrán náà àti wípé ọ̀rọ̀ to wúwo ni, DUBAWA ṣe ìwádìí fínífíní l’órí fónrán ọ̀ún.
Ifidiododomule
DUBAWA ṣe àyẹwò fónrán náà, ìwádìí wa filelẹ pé wọn ti ṣ’àfọwọ́yí fídíò náà. Àwòrán ààrẹ to wa nínú fónrán náà ko dan mọran dáadáa, èyí ti ó jẹ́ àpẹẹrẹ fọ́nrán ti wọn ṣẹda l’ọna aito tàbí ti wọn ti fọwọyi.
DUBAWA ṣe itọpinpin ojúlówó fọ́nrán ọ̀ún, a ríi wípé o jẹ́ èyí ti ààrẹ ti ki gbogbo ọmọ orile-èdè Nàìjíríà ku ọdún tuntun. Ààrẹ ò mẹnuba àlùfáà náà kódà ko s’ọrọ nipa ìwádìí BBC. Ati wípé, wọn ti satunpin ojúlówó fónrán ti ààrẹ ti s’ọ̀rọ̀ láti ọjọ́ kini ọdún yìi, ìwádìí BBC jáde ní ọ̀sẹ̀ kẹta oṣù kini.
Àwọn àpẹẹrẹ miran nínú fọ́nrán ayédèrú náà ni pé kò sí ìṣọ̀kan nínú òhun tí ó ń jáde nínú fónrán ati bí ààrẹ ṣe n sọrọ. Kódà, ojúlówó fọ́nrán náà hàn kedere, nígbàtí ayédèrú ò hàn daada.
DUBAWA ṣakiyesi pé kò sí ojúlówó ìwé ìròyìn kankan tó gbé ìròyìn pé Tinubu sọ̀rọ̀ l’órí ìwádìí BBC to nííṣe pẹlu oníwàásù TB Jóṣúà.
Akotan
Irọ́ ni ọ̀rọ̀ náà. Ayewo fínífíní ti a ṣe l’órí fónrán náà fihàn pé ayédèrú ni, kódà wọ́n ṣ’afowoyi fónrán kan ti ààrẹ ti sọ̀rọ̀.