African LanguagesFact CheckHealthYoruba

Bẹẹni! Eniyan lè máa jẹun dáadáa kí ó sì ní ọgbẹ́-inú 

Àhesọ: Ènìyàn tó bá jẹun dáadáa, kò lè ní ọgbẹ́-inú. 

Bẹẹni! Eniyan lè máa jẹun dáadáa kí ó sì ní ọgbẹ́-inú 

Aṣinilọ́nà ní àhesọ yìí: Botilẹjẹpe bí ènìyàn bá kọ̀ látì jẹun lásìkò, èyí lè mú kí inilara ọgbẹ́-inú pọ̀ si, ṣùgbọ́n kìíse òkùnfà rẹ̀. Ènìyàn lè máa jẹun dáadáa, kí ó sì ní ọgbẹ́-inú.

Ìròyìn L’ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ 

Ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà, àwọn ènìyàn ní ìgbàgbọ́ wípé wọn kò le ní ọgbẹ́-inú tí wọ́n bá ń jeun dáadáa, àmọ́ ṣé àwọn tí kìí jẹun lásìkò nìkan ló ń ní ogbẹ́-inú?

Láìpẹ́ yìí, akẹgbẹ onkowe yìí fi tóo leti pe ìwádìí àìsàn kan tó ṣe fihan pé ó ní ogbẹ́-inú, ṣùgbọ́n kò gba èsì ìwádìí yìí gbọ nítorí ó máa ń jẹun dáadáa, ó sì ní ìgbàgbọ pé ènìyàn tí máa ń f’ọwọ́ gún oúnjẹ nìkan ni ó lè ní ọgbẹ́-inú. 

Ọgbẹ́-inú jẹ egbò tí kìí tètè jiná. Ó sì lè farahàn ní inú ara tàbí lórí àwọ̀ ènìyàn.

Oríṣiríṣi ọgbẹ́ ló wà: arterial ulcers ni èyí tí ó farahàn ní ẹsẹ̀ ènìyàn, ọgbẹ́ míràn lè  farahàn nínú iṣan (venous ulcers), ọgbẹ́ inú ẹnu (mouth ulcers), ọgbẹ́ inú ikùn (peptic ulcers) àti ọgbẹ́ oju-ara tàbí tí ǹkán ọmọkùnrin (genital ulcers). Nínú àkọsílẹ yìí, à ń sọrọ nípa ọgbẹ́-inú àti àwọn ohun tó ń ṣokunfa rẹ̀.

Ọgbẹ́-inú

Ọgbẹ́-inú jẹ egbò tó wà ní inú tí a kò lè fi ojú rí, ó lè wà ní ibi tí a ń gbà jẹun, tàbí ibití oúnjẹ ń gbà kọjá, o sì lè wà ní ibi apakan ọ̀fun, òun ní wọ́n ṣe ń pèé ní ọgbẹ́-inú. 

Ọgbẹ́-inú jẹ́ àìlera tó wọ́pọ̀, ó sì jẹ́ ìkan lára àwọn ọgbẹ́ tí a kò lè fi ojú rí. Fún ọ̀pọ̀lopọ̀ ènìyàn, àmì àkọ́kọ́ ní inú rirun tabi ki inu máa ta èèyàn.

Oríṣi mẹta ọgbẹ́-inú ló wà: àkọ́kọ́ ni gastric ulcers, èyí tó wà ní ibi tí à ń gbàá jẹun (stomach), esophageal ulcers, ọgbẹ́-inú ọ̀fun ati duodenal ulcers, ọgbẹ́ tó wà ní ibi tí oúnjẹ ń gbàá kọjá, duodenum je eya ara to wa lapakan ifun.

Ènìyàn kan le ni ọgbẹ́ inú ikùn ati ibi tí oúnjẹ n gbàá kọjá ni ìgbà kan-náà, eyi ni awọn onimọ sáyẹnsì ń pè ní gastroduodenal.

Bẹẹni! Eniyan lè máa jẹun dáadáa kí ó sì ní ọgbẹ́-inú 
Orísun àwòrán; Mayo Clinic

Okùnfà ọgbẹ́-inú 

Kòkòrò-àrùn Helicobacter pylori (H. pylori) le ṣ’okunfa ọgbẹ́-inú, tàbí kí ènìyàn lo àwọn òògùn kan. Àwọn oun míràn le ṣ’okunfa ọgbẹ́-inú.

Kòkòrò afàìsàn àìlèfojúrí H. Pylori

Kòkòrò afàìsàn àìlèfojúrí H. pylori ni o máán sábà fa ọgbẹ́-inú ikùn àti ọgbẹ́ ibi tí oúnjẹ n gbàá kọjá (gastric and duodenal ulcers) nítorí kòkòrò afàìsàn yìí maá ń ni ipa lórí ikun to dabobo awọ inú àti apa-kinni ìfun, eyi le fún acid inú ikùn lati fa wàhálà sí inú.

Botilẹjẹ wípé kò sí àlàyé lórí bí kòkòrò afàìsàn àìlèfojúrí yìí ṣe n tànká l’agọ ara, àwọn oluwadi sọ pé inú omi ati oúnjẹ ìdọ̀tí ni kòkòrò-àrùn yìí maán wà. Ènìyàn lè kọ kòkòrò H. pylori yìí láti inú itọ́.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ní o maán ko kòkòrò afàìsàn àìlèfojúrí yìí ni ìgbà tí wọn jẹ ọmọdé ṣugbọn kìí sábà di ọgbẹ́-inú lásìkò náà, ọ̀pọ̀lopọ̀ ninu won ni ko ni ri awọn àpẹẹrẹ yìí titi wọn yóò fi dàgbà.

Òògùn 

Ilokulo òògùn aporó bíi aspirin, ibuprofen, naproxen ati àwọn egbògi kan kan ti a mọ̀ sì anti-inflammatory drugs le ṣe alekun inilara ọgbẹ́-inú.

Awọn oun míràn to lè ṣ’alekun inilara ọgbẹ́-inú pàápàá ninu eniyan tó ní kòkòrò afàìsàn àìlèfojúrí H. pylori ni tí onítọ̀ún bá ń mu ọtí amupara, wàhálà ati iporuru ọkàn, ki ènìyàn máa fà siga, ati oúnjẹ tó ní ata púpọ̀.

IFILỌ PATAKI

Àwọn oun ti a ka silẹ wọnyi kọ́ ni ó n ṣ’okunfa ogbẹ́-inú ṣugbọn wọn lè mú kí ewu pọ sí, wọ́n a sì tún jẹ kí ó ṣoro láti wòsàn.

Ìwádìí àìsàn yìí 

Ọ̀nà meji ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni a lè gbà ṣ’ayẹwo ọgbẹ́-inú. Àkọ́kọ́ ní a mọ̀ sí upper endoscopy, yiya àwòrán inu lati mo ipò tí ọgbẹ́ náà wà, ìkejì sì jẹ́ upper gastrointestinal (GI) series, àlàyé nípa rẹ̀ wà nínú linki yìí. 

Ààmì àpẹẹrẹ ọgbẹ́-inú

Kò sí àmì àpẹẹrẹ lara ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn tí o ni ọgbẹ́-inú, sùgbón awọn àpẹẹrẹ kankan máan famihan lara ẹlòmíràn. Awọn àpẹẹrẹ wọnyi ni inú rirun, ki ènìyàn má gufe, aileje oúnjẹ ọlọra, ki ènìyàn máa bì ati inilara ni àyà.

Ọgbẹ́-inú lè jẹ́ kí ènìyàn máa bi ẹ̀jẹ̀, enu onítọ̀ún ò ní ṣí sí oúnjẹ, ogbẹ́-inú yóò ní ipa lori bi ènìyàn ṣe máa mí, ó lè fa irẹwẹsi, ó lè jẹ́ ki ènìyàn máa rù ati ìyípadà nínú bí ènìyàn ṣe n jẹun.

Ó se pàtàkì kí ènìyàn tó bá ri awọn aami àpẹẹrẹ wọ̀nyí kí ó lọ rí dọ́kítà rẹ̀ tàbí ti àwọn oògùn atunilara ti a mo sì antacids àti acid blockers ba ṣiṣẹ fún ìgbà díẹ̀.

Bẹẹni! Eniyan lè máa jẹun dáadáa kí ó sì ní ọgbẹ́-inú 
Orísun àwòrán: Verywell Health

Ìtọ́jú ogbẹ́-inú 

Ni ìgbà míràn, ogbẹ́-inú a pora fúnra rẹ. Ni àwọn ìgbà míràn, ènìyàn tó ni ogbẹ́-inú ní láti lo àwọn oògùn atunilara kan kí ó má baà yíwọ́.

Tí a kò bá ṣe itọju ogbẹ́-inú fún ìgbà pípẹ́, ó lè jalu ọ̀pá tí ó ń gbé oúnje nínú ikùn (perforation), o le jékí inu máa ṣẹ̀jẹ̀, o le di ounjẹ lọwọ, o sì lè fa ààrùn jẹjẹrẹ inú ikùn.

Àkótán 

Botilẹjẹ pé àìjẹun k’ánu ati ki ènìyàn má jẹun lasiko lè ṣe àlékún ìnilára ọgbẹ́-inú, kìíse òkùnfà rẹ̀. Ènìyàn lè máa jẹun dáadáa, ko sì tún ni ogbẹ́-inú. 

Show More

Related Articles

Leave a Reply

Back to top button
Translate »