YorubaExplainersHealth

Ìdáhùn sí ìbéèrè mẹ́rin lórí ooru àmúlàágùn t’ó gbòde kan

Getting your Trinity Audio player ready...

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ló ń kérora ooru àmújù tí ó gbòde kan, tí oníkálukú sì ń fi àìdunú wọn hàn ní oríṣiríṣi ọ̀nà. Bí àwọn àgbàlagbà ṣe ń k’áyàsókè lórí ọ̀rọ̀ ooru àmúlàágùn amúnim’ẹ́dọ̀ yìí, ni àwọn ọ̀dọ̀ pàápàá ń ṣe àfihàn oríṣiríṣi ọ̀nà tí ó gbà kan àwọn náà. Èyí kò yọ àwọn ọmọdé sílẹ̀ rárá. 

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ fọ́nrán ni púpọ̀ àwọn ènìyàn lórí ayélujára ti ṣe láti sọ̀rọ̀ lórí ooru tí ó ń mú tayọ bótiyẹ. Gẹ́gẹ́ bí àwọn ènìyàn kan ṣe ń sọ’pé ẹ̀ṣẹ̀ àpọ̀jù ni ó ṣokùnfà ooru mímú, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ẹlòmíràn tilè ń wípé ìjọba tí ó ń bẹ lóde ni ó ṣokùnfà ooru àmújù. Àwọn kan tilẹ̀ gbàgbó wípé, iná mànàmáná tí ó ń kúwárápá ni ó ṣe kókó jù lọ nínú àwọn ohun tí ó ṣokùnfà ooru.

Kíni a ní láti mò nípa ooru àbadì?

Ooru àbadì jẹ́ gbígbóná afẹ́fẹ́ ní ọ̀nà tí ó kọjáa bí o ti yẹ ní agbègbè kan, pàápàá nígbà tí ìwọ̀n gbígbóná afẹ́fẹ́ yìí bá ti ju ìdiwọ̀n tí àkọsílẹ̀ ìrírí agbègbè náà lọ. Ooru àbadì jẹ́ afẹ́fẹ́ gbígbóná tí ó s’àjèjì sí àyíká, agbègbè tàbí ibì kan. Èyí túmọ̀ sí pé, bí ooru mímú bá ti rékọjáa bótiyẹ tàbí tí ó tayọ àkọsílẹ̀ àtẹ̀yìnwá ní agbègbè kan nígbà tí a bá fi ohun èlò tí a fi ń yẹ ìgbóná àbí ìtutù afẹ́fẹ́ wò, a leè sọ wípé ó ti di ooru àbadì.

Gẹ́gẹ́ bí àjọ ìjọba ilẹ̀ Ọsitéríà (Australia) tó ń ṣe àbójútó ìwádìí lórí ọ̀rọ̀ gbogbo tó jẹ́ mọ́ afẹ́fẹ́, omi, àti ojú ọjọ́ – Bureau of Meteorology, ooru àbadì jẹ́ àkókò ìgbà tí ìdiwọ̀n afẹ́fẹ́ tí ó tútù jù tàbí tí ó gbóná jù, bá gbóná hanhan ju ọjọ́ mẹ́ta ní èékánná láì sí ìdádúró. 

Eléyìí ni a máa ń fi ṣe àfiwé pẹ̀lú bí afẹ́fẹ́ agbègbè náà ti ṣe ń gbóná sí látẹ̀yín wà. Ooru àbadì máa ń ju bí afẹ́fẹ́ bá ti ṣe gbóná sí lójúmọ́. O tún máa ń ní ṣe pẹ̀lú bí afẹ́fẹ́ tí ó tí ń gbóná tẹ́lẹ̀ ní ọ̀sán ti ṣe tútù sí ní òru mójú. 

Ǹjẹ́ orílè-èdè Nàìjíríà nìkan ni ooru àbadì yìí pọ́ń mọ́?

Ó ṣe pàtàkì láti kọ́kọ́ mọ̀ wípé ooru àmújù dàbí àrùn tí ń ṣe abọ́yadé ni. Kìí ṣe ọ̀rọ̀ orílè-èdè Nàìjíríà nìkan. Gẹ́gẹ́ bí àjọ kan tí ó ń fi ìmọ̀ ìgbàlódé àti ẹ̀rọ kọ̀mpútà ṣe ìwádìí lórí àwọn ọ̀rọ̀ tí ó jé mọ́ afẹ́fẹ́, àyípadà ojú ọjọ́ àti bí wọ́n ṣe leè ṣokùnfà àwọn ìjàmbá tó rọ̀ mọ́ àyípadà ojú ọjọ́ – World Weather Attribution (WWA), ooru àbadì ń bá àwọn orílè-èdè míràn fínra pẹ̀lú. Fún àpẹẹrẹ, àkọsílẹ̀ ń bẹ wípé, nínú àwọn orílè-èdè tí ó ní ìrírí ooru àbadì ní oṣù keje ọdún 2023 ni àwọn orílè-èdè tí ó wà ní kọ́ńtínẹ́ńti Éṣíà (Àsìá), Yúróòpù (Europe) àti Àríwá Amẹ́rík (North America).

Àjọ Earth Observatory fi ìdí ọ̀rọ̀ yìí múlẹ̀ bákan náà wípé, ooru àbadì ń sọṣẹ́ káàkiri agbègbè Áfíríkà pẹ̀lú ìwọ̀n afẹ́fẹ́ gbígbóná tí ó ju ìdiwọ̀n ti àtẹ̀yìnwá lọ. Fún àpẹẹrẹ, orílè-èdè South Sudan pa àṣẹ láti ti àwọn ilé ẹ̀kọ́ ní oṣù kẹta ọdún 2024 látàrí ìwòye àti àpèsílẹ̀ ooru gbígbóná tí wọ́n lérò pé yíò mú ní orílè-èdè náà, tí yíò sì dúró bẹ́ẹ̀ fún ọ̀sẹ̀ méjì gbáko.

Látàrí àwọn ẹ̀rí wọ̀nyí, a ní àníkún òye wípé, ooru àbadì, pàápàá ní àsìkò yìí, kìí ṣe ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó pọ́ń mọ́ orílè-èdè Nàìjíríà nìkan. Bó ti ṣe rí níhìn-ín náà ló rí l’ọ̀pọ̀ ibi.

Kíni àwọn ohun tí ó ń ṣokùnfà ooru àbadì?

Bí kò bá ní’dìí, ẹ̀sẹ́ kìí dédé ṣẹ́. Ìkan nínú àwọn ohun tí ó ń ṣokùnfà ooru àbadì ni àyípadà ojú ọjọ́ tí ó ń sábà máa ń wáyé nígbà tí àwọn afẹ́fẹ́ burúkú bíi Carbon Dioxide, Chlorofluorocarbon, Methane, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ, bá pò jù ní ojú òfurufú.

Bákan náà, ooru àbadì a máa mú nígbà tí afẹ́fẹ́ títẹ̀ bá regún sí ojú òfurufú ní agbègbè kan. Èyí yíò dí afẹ́fẹ́ gbígbóná lọ́wọ́ láti fẹ́ jáde lọ sí òkè. Dípò bẹ́ẹ̀, afẹ́fẹ́ gbígbónáa nì yíò máa bì wá sí ìsàlẹ̀ tí yíò sì fa ooru àbadì.

Ooru àbadì a tún máa wáyé nípa àfọwọ́fà ènìyàn nígbà tí a bá ń dáná sun igbó fún ìdí kan tàbí òmíràn, tí a bá ń dáná sun ilẹ̀ àbí igi gígé, láì gbin òmíràn rọ́pò. 

Ǹjẹ́ ooru àbadì ní ewu tàbí àkóbá tí ó leè ṣé fún àgọ́ara wa bí?

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìjàmbá ni ooru àbadì leè ṣé fún ènìyàn bí a bá kùnà láti ṣé ìtọ́jú ara wa. Ooru mímú tayọ bótiyẹ leè se àkóbá fún ọmọdé, àgbàlagbà, ọkùnrin, obìnrin àti awon aláboyún nípa díndín ìwọ̀n ọmọ inú aláboyún náà kù, rírọbí àìtọ́jọ́, àbí bíbí àbíkú àbí kí ó já sí ẹ̀jẹ̀ ríru fún àláboyún náà. Ooru àmújù leè ṣokùnfà àìtó omi nínú ara, ẹyin tó sì lewu púpọ̀ fún ẹ̀mí ènìyàn. 

Àwọn ọ̀nà wo la leè fi dènà àkóbá ooru àbadì? 

Bí a bá fẹ́ dènà àwọn àkóbá tí ooru àbadì ń ṣe fún àgọ́ara wa, a ní láti ríi dájú wípé a ní òye nípa ìròyìn tó jẹ mọ́ ooru àbadì àti àsìkò tí ó seése kí irú ooru báyìí mú. Eléyìí yíò ràn wá lọ́wọ́ láti lè ṣe ìpinnu àti ìmúra sílè tí ó péyẹ nípa àsìkò tí a fẹ́ jáde. 

A gbọ́dọ̀ ríi dájú wípé a ká àwọn aṣọ ojú fèrèsé wá sílẹ̀ nígbà tí ọ̀sán bá pọ́n kí a lè dènà ooru fífẹ́ wọlé. Bákan náà, a leè lo àwọn ẹ̀rọ amúlétutù láti dín ọwọ́jà ooru àbadì kù. 

A ní láti wọ irú aṣọ tí yíò jẹ́ kí àtẹ̀gùn kí ó fẹ́ sí wa dáadáa. Pàtàkì jù lọ ni wípé, a gbọ́dọ̀ gbìyànjú láti máa mú omi lóòrèkóòrè kí ó lè bá rọ́pò omi tí a bá pàdánù nípa òógùn lílà. 

The researcher produced this fact-check per the DUBAWA 2024 Kwame KariKari Fellowship, in partnership with Diamond 88.5 FM Nigeria, to enrich the ethos of “truth” in journalism and enhance media literacy in the country.

Show More

Related Articles

Leave a Reply

Back to top button
Translate »